ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w12 10/15 ojú ìwé 32
  • Ìṣírí “Láti Ẹnu Àwọn Ọmọdé”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìṣírí “Láti Ẹnu Àwọn Ọmọdé”
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Wọ́n Fi Wọ́n Sẹ́wọ̀n Torí Ohun Tí Wọ́n Gbà Gbọ́—Rọ́ṣíà
    Wọ́n Fi Wọ́n Sẹ́wọ̀n Torí Ohun Tí Wọ́n Gbà Gbọ́
  • Àwọn Èèyàn Àlàáfíà Gbèjà Orúkọ Rere Wọn
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • Wọ́n Yọ̀ǹda Ara Wọn Tinútinú—ní Rọ́ṣíà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
  • Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Rọ́ṣíà
    Jí!—1997
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
w12 10/15 ojú ìwé 32

Ìṣírí “Láti Ẹnu Àwọn Ọmọdé”

Ní oṣù December, ọdún 2009, Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ní Orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà fara mọ́ ìpinnu tó sọ ẹ̀sìn àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà di èyí tí kò bófin mu ní Taganrog, ní orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà, tó mú kí wọ́n gba àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba wa, kí wọ́n sì kéde pé mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n [34] lára àwọn ìwé wa jẹ́ ìwé àwọn agbawèrèmẹ́sìn. A gbé ìsọfúnni nípa ìṣẹ̀lẹ̀ yíyani lẹ́nu yìí àti àwòrán àwọn Ẹlẹ́rìí, títí kan àwọn ọmọdé, tí ìpinnu yìí kàn sórí Ìkànnì wa lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì.

Ní oṣù mélòó kan lẹ́yìn náà, Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Tó Ń Bójú Tó Iṣẹ́ Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà rí páálí àti lẹ́tà kan gbà láti ọ̀dọ̀ ìdílé Ẹlẹ́rìí kan ní ìpínlẹ̀ Queensland ní orílẹ̀-èdè Ọsirélíà. Lẹ́yìn tí wọ́n rí ìpinnu tí Ilé Ẹjọ́ náà ṣe, wọ́n kọ̀wé pé: “Ẹ̀yin Ará Ọ̀wọ́n, Ìgbàgbọ́ táwọn ọ̀rẹ́ wa ní Rọ́ṣíà ní àti bí wọ́n ṣe fara da àdánwò wú àwọn ọmọ wa Cody àti Larissa lórí gan-an ni. Àwọn ọmọ wa ṣe káàdì, wọ́n sì kọ lẹ́tà, àwa náà kó àwọn ẹ̀bùn kéékèèké sínú páálí kan ká lè fi ránṣẹ́ sí àwọn ọmọdé tó wà ní ìlú Taganrog, kí wọ́n lè mọ̀ pé àwọn ọmọdé míì bíi tiwọn wà níbi tó jìnnà gan-an sí wọn, tí wọ́n ń fi ìṣòtítọ́ sin Jèhófà, tí wọ́n sì ń ronú nípa wọn. Wọ́n fi ọ̀yàyà kí gbogbo wọn, wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ wọn gan-an.”

Nígbà tí àwọn ọmọdé tó wà ní ìlú Taganrog gba àwọn ẹ̀bùn náà, àwọn náà kọ lẹ́tà tí wọ́n yàwòrán sí láti dúpẹ́ lọ́wọ́ ìdílé tó fi lẹ́tà ránṣẹ́ sí wọn lórílẹ̀-èdè Ọsirélíà. Àwọn ọ̀rọ̀ ìṣírí “láti ẹnu àwọn ọmọdé” tó wà nínú lẹ́tà náà wú Ẹlẹ́rìí kan tó ń sìn ní ẹ̀ka iléeṣẹ́ orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà lórí débi tó fi kọ̀wé sí Cody àti Larissa. Ó sọ pé: “Ẹ wo bó ti máa ba tọmọdé tàgbà wọn nínú jẹ́ tó, nígbà tí wọ́n ń fi ìyà ohun tí wọn kò ṣe jẹ wọ́n. Àwọn ará wa ní Taganrog ò ṣẹ̀ wọ́n rárá, tí wọ́n fi gba Gbọ̀ngàn Ìjọba wọn. Èyí ti bà wọ́n nínú jẹ́ gan-an. Ìṣírí ló máa jẹ́ fún wọn láti mọ̀ pé ẹnì kan tó ń gbé níbi tó jìnnà tó bẹ́ẹ̀ ń ronú nípa wọn. Ẹ ṣeun fún ẹ̀mí ọ̀làwọ́ àti ọ̀yàyà yín!”—Sm. 8:2.

Ara ẹgbẹ́ ará kárí ayé ni wá ní tòótọ́, ìfẹ́ tá a ní síra wa ló sì ń mú kí gbogbo wa lè fara da àwọn àdánwò àti ìṣòrò ìgbésí ayé. Bí àwọn ilé ẹjọ́ ṣe ń jiyàn lórí bóyá àwọn ìtẹ̀jáde àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń gbé ẹ̀mí ìkórìíra lárugẹ tàbí kò gbé e lárugẹ, bẹ́ẹ̀ làwọn ọmọ wa ń ṣe ohun tó fi hàn pé ọ̀rọ̀ àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn láwọn orílẹ̀-èdè míì tí àṣà ìbílẹ̀ wọn yàtọ̀ sí tiwọn jẹ wọ́n lógún, èyí tó fi hàn pé òótọ́ lọ̀rọ̀ Jésù náà pé: “Nípa èyí ni gbogbo ènìyàn yóò fi mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín, bí ẹ bá ní ìfẹ́ láàárín ara yín.”—Jòh. 13:35.

[Àwọn Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 32]

Àwọn ọmọdé láti orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà (lápá òsì) tí wọ́n gba ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ àwọn ọmọdé láti orílẹ̀-èdè Ọsirélíà (lápá ọ̀tún)

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́