Wíwá Àyè Láti Fara Mọ́ Ìdílé
“Wò ó! Ó mà dára o, ó mà dùn o, pé kí àwọn ará máa gbé pa pọ̀ ní ìṣọ̀kan!”—SÁÀMÙ 133:1.
Ìdí tí àwọn kan fi ń ṣe ọdún Kérésìmesì.
Níwọ̀n bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti jẹ́ àtọmọdọ́mọ Jákọ́bù tàbí Ísírẹ́lì, gbogbo wọn jẹ́ “ará,” ìyẹn ni pé wọ́n wá látinú ìdílé kan náà. Tí wọ́n bá pé jọ sí Jerúsálẹ́mù fún àjọyọ̀, ó máa ń “dára” ó sì máa ń “dùn.” Bákan náà, ọ̀pọ̀ ìdílé lónìí máa ń fi ojú sọ́nà fún bí wọ́n ṣe máa wà pa pọ̀ kí wọ́n lè gbádùn àkókò tó “dára” tó sì “dùn” lásìkò ọdún Kérésì.
Kí nìdí tí kì í fi í rọrùn?
Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ kan tó sọ̀rọ̀ nípa àsìkò ọdún sọ pé: “Àwọn ìkùnsínú pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ tó ti wà láàárín àwọn mọ̀lẹ́bí sábà máa ń di rannto nígbà tí gbogbo ilé bá pé jọ lásìkò ọdún.”—Encyclopedia of Christmas and New Year’s Celebrations.
Àwọn ìlànà Bíbélì wo ló lè tọ́ni sọ́nà?
“Kí wọn kí ó sì san oore àwọn òbí wọn padà nípa ṣíṣe ìtọ́jú wọn.” (1 Tímótì 5:4, Bíbélì Mímọ́) Rí i pé o máa ń lọ kí àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ déédéé. Kódà tí àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ kò bá tiẹ̀ sí nítòsí, ẹ ṣì lè máa kàn sí ara yín déédéé. O lè máa kọ lẹ́tà sí wọn, o lè pè wọ́n lórí fóònù, o lè fi lẹ́tà orí kọ̀ǹpútà ránṣẹ́ tàbí kí o máa bá wọn jíròrò lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Tí ẹ bá ń gbúròó ara yín déédéé, ìyẹn máa jẹ́ kí ìkùnsínú dín kù.
“Àyè há fún yín ní inú ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ ti ẹ̀yin fúnra yín. . . . Ẹ gbòòrò síwájú.” (2 Kọ́ríńtì 6:12, 13) Àjọṣe àwọn mọ̀lẹ́bí tí wọ́n máa ń ríra lẹ́ẹ̀kan lọ́dún kì í fi bẹ́ẹ̀ ṣe tímọ́tímọ́, àwọn míì tiẹ̀ lè dà bí àjèjì lójú àwọn ọmọdé. Àwọn ọmọdé míì lè máa wò ó pé àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ ọmọ bàbá àti ìyá kan náà nìkan ló jà jù, pé kò sí ohun tó kan àwọn pẹ̀lú àwọn òbí wọn àgbà tàbí àwọn mọ̀lẹ́bí yòókù. Torí náà, ẹ gba àwọn ọmọ yín níyànjú pé kí wọ́n máa lọ kí àwọn ìbátan wọn tó ti dàgbà, kí wọ́n lè mú kí ìfẹ́ni wọn “gbòòrò síwájú.”a Àwọn ọmọdé tó bá ń rìn sún mọ́ àwọn àgbà máa ń lójú àánú, wọ́n sì máa ń mọyì àwọn tó bá dàgbà jù wọ́n lọ.
“Ọ̀rọ̀ tí ó sì bọ́ sí àkókò mà dára o!” (Òwe 15:23) Kí ni ẹ lè ṣe tí èdèkòyédè kò fi ní dá wàhálà sílẹ̀ láàárín ìdílé? Ọ̀kan lára ohun tí ẹ lè ṣe ni pé kí ẹ wá àkókò tí ó wọ̀ láti fi sọ̀rọ̀ nípa ohun tó bá ń bí yín nínú. Tí àwọn mọ̀lẹ́bí bá ń kàn sí ara wọn déédéé, ó máa rọrùn fún ẹnì kìíní láti lọ bá ẹnì kejì rẹ̀ kí wọ́n sì yanjú ìṣòro èyíkéyìí tó bá wà láàárín wọn. Nígbà tí gbogbo mọ̀lẹ́bí bá sì wà pa pọ̀ wọ́n á gbádùn ara wọn, àárín wọn á “dára” á sì “dùn” bí oyin.
a Wo àpilẹ̀kọ náà “Èé Ṣe Tó Fi Yẹ Kí N Sún Mọ́ Àwọn Òbí Mi Àgbà?” àti “Báwo Ni Mo Ṣe Lè Lájọṣe Tímọ́tímọ́ Pẹ̀lú Àwọn Òbí Mi Àgbà?” nínú ìwé ìròyìn Jí! May 8 àti June 8, 2001. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.