Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí
March 15, 2013
© 2013 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania.
Ẹ̀DÀ TÓ WÀ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́
APRIL 29, 2013–MAY 5, 2013
‘Kò Sí Ohun Ìkọ̀sẹ̀’ fún Àwọn Tó Nífẹ̀ẹ́ Jèhófà
MAY 6-12, 2013
MAY 13-19, 2013
Ní Báyìí Tá A Ti “Wá Mọ Ọlọ́run”—Kí Ló Kàn?
MAY 20-26, 2013
MAY 27, 2013–JUNE 2, 2013
ÀWỌN ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́
▪ ‘Kò Sí Ohun Ìkọ̀sẹ̀’ fún Àwọn Tó Nífẹ̀ẹ́ Jèhófà
Gbogbo àwa Kristẹni là ń sá eré ìje ìyè àìnípẹ̀kun. Àmọ́, torí pé a jẹ́ aláìpé, gbogbo wa la máa ń kọsẹ̀. Àpilẹ̀kọ yìí ṣàlàyé àwọn ohun márùn-ún tó lè mú ká kọsẹ̀. Ó tún ṣàlàyé bá a ṣe lè sá fún wọn ká lè sá eré ìje náà dé ìparí.
▪ Ǹjẹ́ Ó Wù Ẹ́ Láti Mọ Jèhófà?
Ọ̀pọ̀ nǹkan ni ìwé Jeremáyà sọ fún wa nípa ọkàn ìṣàpẹẹrẹ. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa mọ ohun tí ‘àìdádọ̀dọ́ ọkàn-àyà’ túmọ̀ sí àti ewu tó wà níbẹ̀ táwa Kristẹni bá ní irú ọkàn bẹ́ẹ̀. Bákan náà, a tún máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa bá a ṣe lè mọ Jèhófà.—Jer. 9:26; 24:7.
▪ Ní Báyìí Tá A Ti “Wá Mọ Ọlọ́run”—Kí Ló Kàn?
Àwọn ìgbésẹ̀ wo la gbé ká lè mọ Ọlọ́run, kí Ọlọ́run sì lè mọ̀ wá? Bó bá tiẹ̀ ti pẹ́ tá a ti ṣèrìbọmi, báwo la ṣe lè máa tẹ̀ síwájú? Kí sì nìdí tó fi yẹ ká máa tẹ̀ síwájú? A máa rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè yìí nínú àpilẹ̀kọ yìí.
▪ Jèhófà Ni Ibùgbé Wa
Inú ayé táwọn èèyàn ti kórìíra wa là ń gbé, àmọ́ kò yẹ ká máa bẹ̀rù. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa rí i pé gbogbo ìgbà ni Jèhófà ń dáàbò bo àwọn èèyàn rẹ̀.
▪ Máa Gbé Orúkọ Ńlá Jèhófà Ga
Kí ló túmọ̀ sí láti mọ orúkọ Ọlọ́run? Kí ló túmọ̀ sí láti máa rìn ní orúkọ Jèhófà? Ojú wo sì ni Ọlọ́run fi ń wo àwọn tí kò bá bọ̀wọ̀ fún orúkọ rẹ̀? A máa rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè yìí nínú àpilẹ̀kọ yìí.
ÀWỌN ÀPILẸ̀KỌ MÍÌ NÍNÚ ÌTẸ̀JÁDE YÌÍ
18 Gba Ìtùnú, Kó O sì Tu Àwọn Míì Nínú
29 Ṣé Josephus Ló Kọ Ọ́ Lóòótọ́?
ÀWÒRÁN Ẹ̀YÌN ÌWÉ: Etíkun tó gùn gan-an wà ní orílẹ̀-èdè Finland. Àwọn erékùṣù sì wà káàkiri etíkun náà. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún adágún tún wà níbẹ̀, pàápàá jù lọ ní àárín gbùngbùn Finland àti ní apá ìlà oòrùn orílẹ̀-èdè náà. Àwọn akéde kan lọ lo àkókò díẹ̀ níbẹ̀ kí wọ́n lè wàásù níbi tí wọ́n ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i. Wọ́n máa ń lo ọkọ̀ ojú omi nígbà míì tí wọ́n bá wà lóde ẹ̀rí
FINLAND
IYE ÈÈYÀN:
5,375,276
ÌPÍNDỌ́GBA:
Akéde 1 máa wàásù fún 283 èèyàn
AṢÁÁJÚ-Ọ̀NÀ DÉÉDÉÉ:
1,824