ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w13 4/1 ojú ìwé 16
  • Ohun Tí Bíbélì Sọ

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2013
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bibeli—Ìwé Kan Tí Ó Yẹ Kí A Lóye Rẹ̀
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Báwo La Ṣe Lè Tẹ́tí sí Ọlọ́run?
    Tẹ́tí sí Ọlọ́run Kó O Lè Wà Láàyè Títí Láé
  • Ewu Tó Wà Nínú Kéèyàn Ṣi Bíbélì Lóye
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2017
  • Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó O Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Ọlọ́run?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2013
w13 4/1 ojú ìwé 16

Ohun Tí Bíbélì Sọ

Ǹjẹ́ èèyàn lè lóye Bíbélì?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ló wà nínú Bíbélì. Ńṣe ló dà bíi lẹ́tà tí bàbá onífẹ̀ẹ́ kan kọ sí àwọn ọmọ rẹ̀. (2 Tímótì 3:16) Nínú Bíbélì, Ọlọ́run ṣàlàyé bí a ṣe lè ṣe ìfẹ́ rẹ̀ àti ìdí tó fi fàyè gba ìwà ibi àti ohun tó máa ṣe fún aráyé lọ́jọ́ iwájú. Ṣùgbọ́n, àwọn tó ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ ìsìn ti lọ́ àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì lọ́rùn, èyí sì ti mú kí ọ̀pọ̀ rò pé àwọn kò lè lóye àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì láéláé.—Ìṣe 20:29, 30.

Jèhófà Ọlọ́run fẹ́ ká mọ ẹni tí òun jẹ́ gan-an. Ìdí nìyẹn tó fi fún wa ní ìwé kan tó rọrùn láti lóye.—Ka 1 Tímótì 2:3, 4.

Báwo ni o ṣe lè lóyè Bíbélì?

Yàtọ̀ sí pé Jèhófà fún wa ní Bíbélì, ó tún ṣe ọ̀nà bí a ṣe máa lóye rẹ̀. Ó rán Jésù pé kó wá kọ́ wa. (Lúùkù 4:16-21) Bí Jésù ṣe máa ń ṣàlàyé Bíbélì lẹ́sẹẹsẹ mú kí àwọn tó n gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ lóye Bíbélì dáadáa.—Ka Lúùkù 24:27, 32, 45.

Jésù dá ìjọ Kristẹni sílẹ̀, kí wọ́n lè máa bá iṣẹ́ tó bẹ̀rẹ̀ nìṣó. (Mátíù 28:19, 20) Lónìí, àwọn ojúlówó ọmọlẹ́yìn Jésù ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè lóye ohun tí Bíbélì fi kọ́ni nípa Ọlọ́run. Tí o bá fẹ́ lóye ohun tí Bíbélì sọ, inú àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa dùn láti ràn ẹ́ lọ́wọ́.—Ka Ìṣe 8:30, 31.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́