Bibeli—Ìwé Kan Tí Ó Yẹ Kí A Lóye Rẹ̀
AWỌN ènìyàn kan gbàgbọ́ pé Bibeli jẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọrun tí ó ṣe kedere tí ó yẹ kí a tẹ̀lé ní ṣangiliti. Lójú awọn mìíràn, “ìhìn-iṣẹ́ Bibeli jẹ́ onítumọ̀ méjì.” Ìyẹn ni ohun tí ìgbìmọ̀ onímẹ́ḿbà 12 lórí ìgbàgbọ́ ati ẹ̀kọ́ ìsìn fún ẹ̀ka-ìsìn Protẹstanti tí ó tóbi jùlọ ní Canada sọ. Àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì naa Clifford Elliott, ti United Church, nímọ̀lára pé lójú awọn kan “Bibeli ṣòroólóye, kò gbatẹnirò, kò sì ṣeé fisílò.”
Irú awọn ojú-ìwòye bẹ́ẹ̀ gbé awọn ìbéèrè tí ó báamu wẹ́kú tí ó nílò awọn ìdáhùn dìde. Awọn tí ó ṣe pàtàkì lára ìwọ̀nyí jẹ́, Kí ni ìdí tí a fi kọ Bibeli? Ó ha jẹ́ àdììtú tí ó sì díjú jù lati lóye bí? Awọn ènìyàn gbáàtúù ha lè lóye rẹ̀ bí? Ìrànlọ́wọ́ wo ni ẹnìkan nílò lati lóye ìtumọ̀ Ìwé Mímọ́? Èésìtiṣe tí ìmọ̀ pípéye nipa Bibeli fi ṣekókó ní awọn àkókò làásìgbò wọnyi?
Kí Ni Ìdí tí A Fi Kọ Bibeli?
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọrun ti fìgbàgbogbo jẹ́ ohun àkọ́kọ́ tí a ń béèrè fún lọ́wọ́ awọn wọnnì tí wọn yoo jèrè ojúrere ati ìtẹ́wọ́gbà Ọlọrun Gíga Jùlọ, Jehofa. Awọn ọba, àlùfáà, òbí, ọkùnrin, obìnrin, ati awọn ọmọdé—ọlọ́rọ̀ ati tálákà bákan náà—ni a fún ní ìtọ́ni lati wá àkókò lati inú àlámọ̀rí ojoojúmọ́ ninu ìgbésí-ayé lati gbé àkọsílẹ̀ Ọ̀rọ̀ Ọlọrun wo tìṣọ́ratìṣọ́ra ati tàdúràtàdúrà.—Deuteronomi 6:6, 7; 17:18-20; 31:9-12; Nehemiah 8:8; Orin Dafidi 1:1, 2; 119:7-11, 72, 98-100, 104, 142; Owe 3:13-18.
Fún àpẹẹrẹ, a darí Joṣua pé: “Rí i dájú pé ìwé Òfin ni a ń ka nígbà gbogbo ninu ìjọsìn rẹ. Kẹ́kọ̀ọ́ lati inú rẹ̀ lọ́sàn-án ati lóru, kí o sì rí i dájú pé o ṣègbọràn sí gbogbo ohun tí a kọ sínú rẹ̀. Nígbà naa iwọ yoo láásìkí iwọ yoo sì ṣàṣeyọrísírere.” (Joṣua 1:8, Today’s English Version) Irúfẹ́ ìfarabalẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ bẹ́ẹ̀ ati ìfisílò Òfin Ọlọrun yoo yọrísí àṣeyọrísírere ati ayọ̀. Ète Jehofa kìí ṣe kìkì pé kí “gbogbo onírúurú ènìyàn” lóye Bibeli, Ọ̀rọ̀ rẹ̀, ṣugbọn kí wọ́n ṣègbọràn sí i, pẹlu ìfojúsọ́nà fún gbígba ẹ̀bùn ìyè.—1 Timoteu 2:3, 4, NW; Johannu 17:3.
Ó Ha Díjú Jù Lati Lóye Bí?
Ṣáájú ìgòkè re ọrun Jesu, ó mú un ṣe kedere pé oun fẹ́ kí ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìmọ̀-ẹ̀kọ́ gbígbòòrò nípa Bibeli máa báa nìṣó kárí ayé. (Iṣe 1:8) Ó mọ̀ pé ó yẹ kí a lóye Bibeli. Lẹ́yìn ṣíṣàlàyé pé Jehofa ti fún oun ní gbogbo ọlá-àṣẹ ní ọ̀run ati lórí ilẹ̀-ayé, ó pa àṣẹ tààràtà naa pé: “Nitori naa ẹ lọ kí ẹ sì máa sọ awọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ-ẹ̀yìn [tabi, akẹ́kọ̀ọ́], ẹ máa batisí wọn ní orúkọ Baba ati ti Ọmọkùnrin ati ti ẹ̀mí mímọ́, ẹ máa kọ́ wọn lati máa pa gbogbo ohun tí mo ti paláṣẹ fún yín mọ́.”—Matteu 28:19, 20, NW.
Ṣáájú ìrìbọmi, awọn ọmọ-ẹ̀yìn titun ni a nilati kọ́lẹ́kọ̀ọ́ nipa Jehofa, Ọmọkùnrin rẹ̀, ati ìṣiṣẹ́ ẹ̀mí mímọ́. Ní àfikún síi, a nilati fún wọn ní ìtọ́ni ninu òfin ètò ìgbékalẹ̀ awọn nǹkan ti Kristian. (1 Korinti 9:21; Galatia 6:2) Lati ṣàṣeyọrí èyí, awọn ẹni tí ó yẹ nilati kọ́kọ́ gbàgbọ́ pé Bibeli wá lati ọ̀dọ̀ Jehofa ati lọ́nà kejì pé ó yẹ kí a lóye rẹ̀.—Matteu 10:11-13.
Kí ni ohun tí ó béèrè níhà ọ̀dọ̀ tìrẹ lati lóye Bibeli? Ọmọkùnrin Ọlọrun ṣe àkànṣe ìsapá lati ṣàlàyé Ìwé Mímọ́. Ó mọ̀ pé awọn Ìkọ̀wé Mímọ́ jẹ́ òtítọ́ ati pé ohun tí ń bẹ ninu wọn jẹ́ àsọjáde ìfẹ́-inú Jehofa. (Johannu 17:17) Nipa iṣẹ́ tí a yàn fún un lati ṣe, Jesu Kristi wí pé: “A bí mi mo sì wá sí ayé fún ète kanṣoṣo yii, lati sọ̀rọ̀ nipa òtítọ́. Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́ ti òtítọ́ ń fetísílẹ̀ sí mi.” (Johannu 18:37, TEV; Luku 4:43) Jesu kò fàsẹ́yìn ní kíkọ́ awọn wọnnì tí wọ́n ní etígbọ̀ọ́ ati àyà ìgbàṣe. Ní Luku 24:45 (NW), a sọ fún wa pé: “Nígbà naa ó [Kristi Jesu] ṣí èrò-inú wọn payá lẹ́kùn-ún-rẹ́rẹ́ lati mòye ìtúmọ̀ Ìwé Mímọ́.”
Nígbà iṣẹ́-òjíṣẹ́ Jesu ó fa ọ̀rọ̀ yọ fàlàlà lati inú Ọ̀rọ̀ tí a kọsílẹ̀ naa, ní ṣíṣàlàyé ati títọ́ka sí ìwé mímọ́ ninu “òfin Mose ati ninu awọn Wòlíì ati awọn Psalmu.” (Luku 24:27, 44, NW) Awọn wọnnì tí wọ́n gbọ́ awọn àlàyé rẹ̀ lórí Ìwé Mímọ́ ni ìṣekedere òye rẹ̀, ati agbára ìṣe rẹ̀ lati kọ́ni rusókè gidigidi. (Matteu 7:28, 29; Marku 1:22; Luku 4:32; 24:32) Sí i, Ìwé Mímọ́ jẹ́ ìwé kan tí ó rọrùn lati lóye.
Bibeli ati Awọn Ọmọlẹ́yìn Jesu
Aposteli Paulu, ẹni tí ń ṣàfarawé Jesu Kristi, rí àìní naa lati kọ́ awọn ẹlòmíràn ní ohun tí ó wà ninu Ìwé Mímọ́. Oun pẹlu mọ̀ pé ó yẹ kí a lóye wọn. Ìdí nìyẹn tí ó fi kọ́ni ní gbangba tí ó sì ṣàlàyé Ìwé Mímọ́ láìsí iyèméjì ninu ilé awọn wọnnì tí wọn fẹ́ lati lóye rẹ̀. Paulu fí ibi tí ó dúró sì hàn nígbà tí ó wí pé: “Ẹ mọ̀ pé emi kò fawọ́ ohunkohun tí ó lè ṣèrànlọ́wọ́ fún yin sẹ́yìn bí mo ti ń wàásù tí mo sì ń kọ́ni ní gbangba ati ninu awọn ilé yin.” (Iṣe 20:20, TEV) Nígbà tí ó bá ń bá awọn ènìyàn jíròrò ó ń bá wọn fọ̀rọ̀wérọ̀ lati inú Ìwé Mímọ́, ní ṣíṣàlàyé ati jíjẹ́rìí sí awọn kókó rẹ̀ nípasẹ̀ awọn ìtọ́ka. (Iṣe 17:2, 3) Ó lọ́kàn-ìfẹ́ ninu ríran awọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ lati lóye ìtumọ̀ Ìwé Mímọ́.
Iwọ ha ní ìyánhànhàn fún lílóye awọn nǹkan tí Jesu ati awọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ fi kọ́ni bí? (1 Peteru 2:2) Awọn olùgbé Berea ìgbàanì ní irú ìfẹ́-ọkàn bẹ́ẹ̀, wọn sì ń háragàgà lati gba ohun tí aposteli Paulu ń kọ́ wọn nipa Kristi gbọ́. Nitori naa a fún wọn ní ìṣírí lati kẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́ lójoojúmọ́ kí wọn sì tipa bẹ́ẹ̀ ní ìdánilójú pé ìhìnrere tí wọn gbọ́ jẹ́ òtítọ́ níti gidi. Nitori pé wọn ní àyà ìgbàṣe, “púpọ̀ ninu wọ́n di onígbàgbọ́.”—Iṣe 17:11, 12, NW.
Lati lóye Bibeli, ó béèrè pé kí ẹnìkan ní ipò ọkàn-àyà tí ó tọ́, ìfẹ́-ọkàn olótìítọ́-inú lati kẹ́kọ̀ọ́, kí ‘àìní nipa tẹ̀mí sì jẹ ẹ́ lọ́kàn.’ (Matteu 5:3) Nígbà tí a bi Jesu pé: “Èéṣe tí o fi ń bá wọn sọ̀rọ̀ nipa lílo awọn àpèjúwe?” ó fèsìpadà pé: “Ẹ̀yin ni a yọ̀ǹda fún lati lóye awọn àṣírí mímọ́-ọlọ́wọ̀ ti ìjọba awọn ọ̀run, ṣugbọn awọn ènìyàn wọnnì ni a kò yọ̀ǹda fún.” A ti sọtẹ́lẹ̀ pé oun ‘yoo la ẹnu pẹlu àpèjúwe yoo sì kéde awọn ohun tí a fi pamọ́.’ (Matteu 13:10, 11, 35, NW) Èyí fihàn pé Jesu fi àpèjúwe sọ̀rọ̀ lati fìyàtọ̀ sáàárín awọn olùfetísílẹ̀ lásán tí wọ́n wá lati ṣojúmìító ati awọn tí wọn ń fi òtítọ́-inú ṣèwádìí. Awọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu fi òtítọ́-inú wọn hàn ní àkókò kan nígbà tí wọ́n bá a lọ sínú ilé kan tí wọ́n sì wí pé: “Ṣàlàyé àpèjúwe awọn èpò inú pápá fún wa.”—Matteu 13:36, NW.
Ó ṣe kedere pé a nílò ìrànlọ́wọ́ bí a óò bá lóye Bibeli. Àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì Hal Llewellyn, akọ̀wé ẹ̀kọ́-ìsìn, ìgbàgbọ́ ati àwùjọ olùwá ìṣọ̀kan awọn ṣọ́ọ̀ṣì àgbáyé ti United Church, wí pé: “Ó ṣe pàtàkì lati mú ohun tí Bibeli túmọ̀sí fún wa ati bí a ṣe ń kà á tí a sì ń túmọ̀ rẹ̀ ṣe kedere.” Ṣugbọn bí gbogbo ènìyàn kò tilẹ̀ mọ̀ ọ́n, òtítọ́ naa ni pé a kò lè dá lóye Bibeli. A nílò ìrànlọ́wọ́.
Ìrànlọ́wọ́ Wo Ni Ó Wà Lárọ̀ọ́wọ́tó?
Awọn ọ̀rọ̀ àdìtú, awọn ìbéèrè rírúnilójú, ati awọn gbólóhùn tí ó jinlẹ̀ kan wà ninu Bibeli tí ó béèrè pé kí a mú wọn ṣe kedere. Wọn lè má rọrùn lati lóye, bí a bá lo awọn àfiwé tí ó ní ìtumọ̀ tí a kò pète pé kí a lóye rẹ̀ ní àkókò tí a kọ wọ́n. Ṣugbọn wọn ní awọn ète Jehofa ninu. Fún àpẹẹrẹ, Ìfihàn 13:18 sọ pé “iye tí ń bẹ lára ẹranko naa” jẹ́ “ọ̀tàlélẹ́gbẹ̀ta ó lé mẹ́fà.” Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹsẹ naa sọ pé “níhìn-ín ni ọgbọ́n gbé wà,” kò ṣàlàyé ìjẹ́pàtàkì iye yẹn. Bí ó ti wù kí ó rí, nípasẹ̀ ètò-àjọ rẹ̀, Jehofa ti yọ̀ǹda fún awọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olùṣòtítọ́ lati lóye ìtumọ̀ rẹ̀ lónìí. (Wo àpótí, “Ipa-Ọ̀nà sí Lílóye Bibeli.”) Iwọ pẹlu lè jèrè òye yii pẹlu ìrànwọ́ awọn wọnnì tí wọn ní ìrírí ninu ‘fífi ọwọ́ títọ̀nà mú ọ̀rọ̀ òtítọ́.’—2 Timoteu 2:2, 15, 23-25; 4:2-5, NW; Owe 2:1-5.
Nígbà mìíràn Jesu máa ń lo awọn àkàwé lati fi ìdáhùnpadà tabi àìdáhùnpadà sí ìhìn-iṣẹ́ Ìjọba naa hàn. Ó fihàn pé awọn kan kò ní tẹ̀síwájú nitori ìrẹ̀wẹ̀sì tí àtakò lati ọ̀dọ̀ awọn ọ̀rẹ́ ati mọ̀lẹ́bí yoo mú wá. Awọn mìíràn yoo yọ̀ǹda fún “ìpọ́njú tabi inúnibíni” lati pa ìmọrírì wọn fún ìhìn-iṣẹ́ Ìjọba naa run. Síbẹ̀ awọn mìíràn yoo fàyègba awọn àlámọ̀rí ojoojúmọ́ ninu ìgbésí ayé, “àníyàn ètò-ìgbékalẹ̀ awọn nǹkan yii ati agbára ìtannijẹ ọrọ̀,” lati dínà ìfẹ́ yòówù tí wọn lè ní fún ìhìnrere. Ní ìdà kejì, awọn kan wà tí wọn ń fayọ̀ dáhùnpadà tí wọn sì múratán lati gbọ́ ọ̀rọ̀ ṣíṣeyebíye naa kí wọn sì lóye rẹ̀. Wọn ‘ń kẹ́dùn wọn sì ń kígbe nitori ohun ìríra tí wọn ń ṣe’ ninu Kristẹndọm, tí wọn rò pé ó jẹ́ ní orúkọ Jesu Kristi. Irú awọn ẹni bẹ́ẹ̀ ń ṣàníyàn lati gba ìtọ́ni ní ọ̀nà Jehofa kí wọn sì tipa bẹ́ẹ̀ lóye ohun tí wọn ń kà ninu Bibeli.—Matteu 13:3-9, 18-23, NW; Esekieli 9:4; Isaiah 2:2-4.
Fún awọn wọnnì tí wọn fẹ́ lati jèrè òye tí ó jinlẹ̀ nipa awọn ète Jehofa fúnraawọn, Jehofa lè rí sí i pé ìrànwọ́ tí wọ́n nílò ni a pèsè. Lati ṣàkàwé èyí, Bibeli ròyìn pé ẹ̀mí Jehofa darí ajíhìnrere naa Filippi lati ṣèrànwọ́ fún ọkùnrin ará Etiopia kan tí ń ṣàgbéyẹ̀wò ìwé Bibeli naa Isaiah bí ó ti ń rìnrìn-àjò bọ̀ lati Jerusalemu. Lójú ọ̀nà rẹ̀ padà sí ilé, ó ń kà á ninu kẹ̀kẹ́-ẹṣin rẹ̀. Ní ìgbọràn sí ìdarí ẹ̀mí mímọ́ Jehofa, Filippi sáré lẹ́gbẹ̀ẹ́ kẹ̀kẹ́-ẹṣin naa ó sì béèrè pé: ‘O ha lóye ohun tí o ń kà bí?’ Ọkùnrin naa ní ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn ó sì jẹ́ aláìlábòsí tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi gbà pé oun nílò ìrànlọ́wọ́. Filippi fi tayọ̀tayọ̀ kọ́ ẹni tí ebi tẹ̀mí ń pa tí ó sì ṣeé kọ́lẹ́kọ̀ọ́ yii. Ìtọ́ni naa ràn án lọ́wọ́ lati lóye Ìwé Mímọ́. Ó kẹ́kọ̀ọ́ ohun tí ó yẹ kí ó ṣe nísinsìnyí lati gbádùn ipò-ìbátan olójúrere pẹlu Jehofa kí ó baà lè jèrè ìyè àìnípẹ̀kun. Ó di ìránṣẹ́ Jehofa tí ó láyọ̀, tí a sì batisí, ẹni tí ó lépa ìgbésí-ayé tí ó mú inú Ọlọrun dùn.—Iṣe 8:26-39.
O lè ní Bibeli ninu ilé rẹ, o sì ti lè kà á lọ́pọ̀ ìgbà. Ó sì ṣeéṣe kí o ti nírìírí ìṣòro kan naa irú èyí tí ará Etiopia olótìítọ́-inú, onírẹ̀lẹ̀ ọkàn yii ní ìrírí rẹ̀. Kò lè lóye ohun tí ó kà. Ó nílò ìrànlọ́wọ́ kò sì ṣetìkọ̀ lati gba ìrànlọ́wọ́ tí ó dùn mọ́ Jehofa Ọlọrun ninu lati pèsè. Bíi ti Filippi, awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa láyọ̀ lati ràn ọ́ lọ́wọ́ lati lóye awọn nǹkan nipa Ọlọrun tí a kọ sínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀, Bibeli. Wọn mọ̀ pé Jehofa pèsè Bibeli ó sì fẹ́ kí a lóye rẹ̀.—1 Korinti 2:10; Efesu 3:18; 2 Peteru 3:16.
Èéṣe tí Bibeli fi Ṣekókó?
A ń gbé ní àkókò tí ó jẹ́ kánjúkánjú jùlọ ninu ìtàn ènìyàn. Bibeli pè é ní “ìparí ètò-ìgbékalẹ̀ awọn nǹkan.” (Matteu 24:3, NW) Ọ̀pọ̀ awọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ń wáyé ní ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ Bibeli lati ọdún 1914 wá fihàn pé láìpẹ́ púpọ̀ sí ìgbà tí a wà yii Ìjọba ọ̀run ti Ọlọrun yoo “fọ́ túútúú, yoo sì pa gbogbo ìjọba wọnyi run.”—Danieli 2:44.
Ka ohun tí a sọtẹ́lẹ̀ ninu Bibeli ní Matteu orí 24, Marku orí 13, ati Luku orí 21 fúnraàrẹ. Iwọ yoo kíyèsi pé awọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí a ṣàpèjúwe jẹ́ èyí tí ó kan gbogbo ayé. Wọn ní awọn ogun àgbáyé ninu—tí wọn yàtọ̀ sí gbogbo awọn ogun yòókù. Lati ìgbà Ogun Àgbáyé I, a ti ṣẹlẹ́rìí àìtó oúnjẹ, ìsẹ̀lẹ̀, ati àkókò ìwà-àìlófin lọ́nà yíyọyẹ́ tí a ti sọtẹ́lẹ̀. Nísinsìnyí ó dàbí ẹni pé awọn orílẹ̀-èdè wà ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ ṣíṣe ìkéde kan tí yoo pèsè àmì tí kò ní àṣìmú pé ìparun ayé kù sí dẹ̀dẹ̀. Nipa èyí aposteli Paulu kọ̀wé pé: “Ọjọ́ Jehofa ń bọ̀ gan-an gẹ́gẹ́ bí olè ní òru. Ìgbà yòówù tí ó jẹ́ tí wọ́n bá ń wí pé: ‘Àlàáfíà ati ààbò!’ nígbà naa ni ìparun òjijì yoo dé lọ́gán sórí wọn gan-an . . . wọn kì yoo sì yèbọ́ lọ́nàkọnà.” (1 Tessalonika 5:2, 3, NW) Awọn wo ni kò ní yèbọ́? Paulu ṣàlàyé pé: “Awọn wọnnì tí kò mọ Ọlọrun ati awọn wọnnì tí kò ṣègbọràn sí ìhìnrere nipa Jesu Oluwa wa.” (2 Tessalonika 1:7-9, NW) Ìmúṣẹ apákan àmì alápá pupọ naa yoo jẹ́ lati ọwọ́ awọn wọnnì tí wọn ṣègbọràn sí àṣẹ tí a fifúnni ní Matteu 24:14 lati wàásù ‘ìhìnrere ìjọba naa ní gbogbo ayé.’
Àràádọ́ta-ọ̀kẹ́ awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ń mú àṣẹ yii ṣẹ ní 231 ilẹ̀ ati erékùṣù òkun. Wọ́n ń ṣe ìkésíni sí ilé awọn ènìyàn tí wọn sì ń ké sí wọn lẹ́nìkọ̀ọ̀kan lati kọ́ nipa àkóso Ìjọba Jehofa. Wọn ń fi pẹlu inúrere tọ́ka sí ipa ọ̀nà tí ó yẹ kí ẹnìkọ̀ọ̀kan tọ̀ lati wà lára awọn olùla ètò-ìgbékalẹ̀ awọn nǹkan ìsinsìnyí já kí wọn sì gbé lórí paradise ilẹ̀-ayé kan níbi tí kì yoo ti sí ọ̀fọ̀, mímí ìmí-ẹ̀dùn, ìrora, tabi ikú.—Ìfihàn 21:3, 4.
Àkókò ń yárakánkán tán lọ fún ayé burúkú yii, ó sì di dandan fún gbogbo awọn tí wọn fẹ́ lati la òpin ayé yii já lati kọ́ nipa ohun tí ‘ṣíṣègbọràn sí ìhìnrere’ ní ninu kí wọn sì tipa bẹ́ẹ̀ yèbọ́ lọ́wọ́ ìparun. Nígbà tí awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa bá tún ṣe ìbẹ̀wò sí ilé rẹ, èéṣe tí iwọ kò fi gba ìkésíni naa lati ní ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀? Bí bẹ́ẹ̀ sì kọ́, èéṣe tí iwọ kò fi sọ pé kí wọn kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli pẹlu rẹ nitori pé iwọ fẹ́ lati lóye rẹ?
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 8]
IPA-Ọ̀NÀ SÍ LÍLÓYE BIBELI
JESU mú un dá wa lójú pé lẹ́yìn ikú ati àjíǹde oun, oun yoo gbé “olùṣòtítọ́ ati ọlọ́gbọ́n-inú ẹrú” kan dìde tí yoo maa ṣiṣẹ́sìn gẹ́gẹ́ bí ipa-ọ̀nà ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ rẹ̀. (Matteu 24:45-47, NW) Aposteli Paulu fi ipa-ọ̀nà yii hàn fún awọn Kristian ní Efesu nígbà tí ó kọ̀wé pé “nípasẹ̀ ìjọ a sọ ọ̀pọ̀ oríṣiríṣi ọgbọ́n Ọlọrun di mímọ̀ . . . ní ìbámu pẹlu ète ayérayé tí oun gbékalẹ̀ ní ìsopọ̀ pẹlu Kristi, Jesu Oluwa wa.” (Efesu 3:10, 11, NW) Ìjọ awọn Kristian ẹni-àmì-òróró, tí a bí ní Pentekosti 33 C.E., ni a fi “ohun tí a fihàn” naa lé lọ́wọ́. (Deuteronomi 29:29) Gẹ́gẹ́ bí àwùjọ kan, awọn Kristian ẹni-àmì-òróró ń ṣiṣẹ́sìn gẹ́gẹ́ bí olùṣòtítọ́ ati ọlọ́gbọ́n-inú ẹrú. (Luku 12:42-44) Iṣẹ́ tí a yàn fún wọn lati ọ̀dọ̀ Ọlọrun ni lati pèsè òye tẹ̀mí nipa awọn “ohun tí a fihàn.”
Gan-an gẹ́gẹ́ bí àsọtẹ́lẹ̀ Bibeli ti tọ́ka síwájú sí Messia naa, ó tún darí wa sí ẹgbẹ́ ẹni-àmì-òróró ti awọn Kristian Ẹlẹ́rìí tí wọn wà ní ìṣọ̀kan tímọ́tímọ́ tí wọn ń ṣiṣẹ́sìn nísinsìnyí gẹ́gẹ́ bí olùṣòtítọ́ ati ọlọ́gbọ́n-inú ẹrú naa.* Ó ń ràn wá lọ́wọ́ lati lóye Ọ̀rọ̀ Ọlọrun. Gbogbo awọn tí wọn bá fẹ́ lati lóye Bibeli nilati mọrírì pé “ọ̀pọ̀ oríṣiríṣi ọgbọ́n Ọlọrun” lè di mímọ̀ kìkì nipasẹ olùṣòtítọ́ ati ọlọ́gbọ́n-inú ẹrú naa, ipa-ọ̀nà ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ ti Jehofa.—Johannu 6:68.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
Wo Ilé-Ìṣọ́nà, September 1, 1981, ojú-ìwé 24-30.