Bá a Ṣe Lè Wádìí “Àwọn Ohun Ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run”
“Ẹ̀mí ń wá inú ohun gbogbo, àní àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run.” —1 KỌ́RÍŃTÌ 2:10.
1. Kí ni díẹ̀ lára àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì tó ń múnú àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì dùn gan-an?
Ọ̀PỌ̀ jù lọ àwa tó wà nínú ìjọ Kristẹni la lè rántí bínú wa ṣe dùn tó nígbà tá a kọ́kọ́ kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Ìgbà yẹn la mọ ìdí tí orúkọ Jèhófà fi ṣe pàtàkì, ìdí tó fi fàyè gba ìyà tó ń jẹ àwa èèyàn, ìdí táwọn kan fi ń lọ sọ́run, àti bọ́jọ́ ọ̀la ṣe máa rí fáwọn yòókù tó jẹ́ olóòótọ́. A lè ti ṣàyẹ̀wò Bíbélì ṣáájú ìgbà yẹn, àmọ́ a ò rí gbogbo nǹkan wọ̀nyí, bí ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn ò ṣe rí wọn. Ńṣe la dà bí ọkùnrin kan tó fẹ́ mọ àwọn nǹkan ẹlẹ́wà tó wà nísàlẹ̀ omi. Tí kò bá gbé awò sójú láti fi wò ó, ìwọ̀nba díẹ̀ ló máa rí lára àwọn nǹkan tó lẹ́wà tó wà nísàlẹ̀ odò náà. Àmọ́ nígbà tó bá gbé awò tó ń jẹ́ kéèyàn rí nǹkan tó wà nísàlẹ̀ omi kedere sójú tàbí tó bá wọnú ọkọ̀ ojú omi tí wọ́n fi gíláàsì ṣe ìsàlẹ̀ rẹ̀, inú rẹ̀ á dùn gan-an nígbà tó bá rí àwọn ẹ̀dá omi abìlẹ̀kẹ̀ aláwọ̀ mèremère, àwọn ẹja, àwọn ẹ̀dá omi tí wọ́n dà bí òdòdó, àtàwọn nǹkan mìíràn tó fani mọ́ra gan-an. Lọ́nà kan náà, ìgbà tẹ́nì kan bẹ̀rẹ̀ sí í ràn wá lọ́wọ́ láti lóye Ìwé Mímọ́ ni ìgbà àkọ́kọ́ tá a rí “àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run.”—1 Kọ́ríńtì 2:8-10.
2. Kí nìdí tí ayọ̀ téèyàn máa ń ní nígbà tó bá kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fi lè jẹ́ èyí tí kò ní dópin?
2 Ǹjẹ́ ó yẹ ká jẹ́ kí ìwọ̀nba ìmọ̀ díẹ̀ tá a ní nínú Bíbélì tó wa? Gbólóhùn náà, “àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run” ní í ṣe pẹ̀lú kéèyàn lóye ọgbọ́n Ọlọ́run tí ẹ̀mí mímọ́ ṣí payá fún àwọn Kristẹni àmọ́ táwọn èèyàn yòókù ò mọ̀. (1 Kọ́ríńtì 2:7) Ẹ ò rí i pé ọgbọ́n Jèhófà ò láàlà, a óò sì láyọ̀ gan-an tá a bá ń wádìí àwọn ọ̀nà rẹ̀! Kò sí bá a ṣe lè mọ gbogbo ohun tó jẹ mọ́ ọgbọ́n tí Ọlọ́run fi ń ṣe àwọn nǹkan rẹ̀. Tá ò bá jẹ́ kó sú wa láti máa wádìí “àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run, ìgbà gbogbo la ó máa ní irú ayọ̀ tá a ní nígbà tá a lóye àwọn ohun téèyàn kọ́kọ́ ń mọ̀ nínú Bíbélì.”
3. Kí nìdí tó fi yẹ ká ni òye tó jinlẹ̀ nípa ìdí tá a fi gba àwọn nǹkan kan gbọ́?
3 Kí nìdí tó fi yẹ ká lóye àwọn “ohun ìjìnlẹ̀” wọ̀nyẹn? Tá a bá lóye àwọn ohun tá a gbà gbọ́, tá a tún lóye ìdí tá a fi gbà wọ́n gbọ́, ìyẹn ni pé ká mọ àwọn ohun tó mú ká gba irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ gbọ́, èyí á gbé ìgbàgbọ́ wa ró, ohun tá a gbà gbọ́ náà á sì dá wa lójú. Ìwé Mímọ́ sọ fún wa pé ká lo “agbára ìmọnúúrò” wa láti ‘fúnra wa ṣàwárí ìfẹ́ Ọlọ́run tí ó dára, tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà, tí ó sì pé.’ (Róòmù 12:1, 2) Lílóye ìdí tí Jèhófà fi ní ká máa gbé ìgbésí ayé wa lọ́nà kan pàtó yóò jẹ́ ká túbọ̀ múra tán láti ṣègbọràn. Nítorí náà, níní ìmọ̀ àwọn “ohun ìjìnlẹ̀” wọ̀nyẹn lè fún wa lókun láti dènà ìdẹwò tó lè mú ká lọ́wọ́ nínú àwọn ohun tí kò bófin mu, ó sì lè mú ká jẹ́ “onítara fún iṣẹ́ àtàtà.”—Títù 2:14.
4. Kí làwọn ohun téèyàn gbọ́dọ̀ ṣe tó bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?
4 A gbọ́dọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ ká tó lè lóye àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run. Àmọ́ o, kéèyàn kẹ́kọ̀ọ́ yàtọ̀ sí kéèyàn kàn ka ohun kan lóréfèé. Ó gba pé ká fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò àwọn ẹ̀kọ́ tá à ń kọ́ láti rí i bó ṣe tan mọ́ ohun tá a ti mọ̀ tẹ́lẹ̀. (2 Tímótì 1:13) Ó tún ní í ṣe pẹ̀lú kéèyàn mọ ìdí tí wọ́n fi sọ ohun kan. A tún gbọ́dọ̀ ṣàṣàrò nígbà tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ká lè mọ ọ̀nà tá a lè gbà lo ohun tá a ń kọ́ láti ṣèpinnu tó mọ́gbọ́n dání àti láti ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́. Àti pé, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé “gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí, [tó] sì ṣàǹfààní,” “gbogbo àsọjáde tí ń jáde wá láti ẹnu Jèhófà” ló gbọ́dọ̀ wà lára ìkẹ́kọ̀ọ́ wa. (2 Tímótì 3:16, 17; Mátíù 4:4) Iṣẹ́ ni ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì o! Àmọ́ ó tún lè fúnni láyọ̀, “àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run” kò sì le púpọ̀ jù láti lóye.
Jèhófà Ń Ran Àwọn Ọlọ́kàn Tútù Lọ́wọ́ Láti Lóye
5. Àwọn wo ló lè lóye “àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run?”
5 Bó ò tiẹ̀ fi bẹ́ẹ̀ mọ̀wé nígbà tó o wà nílé ìwé, tí ẹ̀kọ́ kíkọ́ ò sì mọ́ ọ lára, má ṣe ronú pé “àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run” kọjá ohun tó o lè lóye. Kì í ṣe àwọn ọlọgbọ́n àtàwọn amòye ni Ọlọ́run ṣí ohun tó ní lọ́kàn payá fún lákòókò tí Jésù wà lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé, bí kò ṣe àwọn tí kò mọ̀wé àtàwọn gbáàtúù èèyàn tí wọ́n ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ láti jẹ́ kí ìránṣẹ́ Ọlọ́run kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́. Ńṣe ni wọ́n dà bí ọmọ ọwọ́ tá a bá fi wọ́n wé àwọn tó kàwé. (Mátíù 11:25; Ìṣe 4:13) Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa “àwọn ohun tí Ọlọ́run ti pèsè sílẹ̀ fún àwọn tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ rẹ̀,” ohun tó kọ sáwọn tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́ ni pé: “Àwa ni Ọlọ́run ti ṣí wọn payá fún nípasẹ̀ ẹ̀mí rẹ̀, nítorí ẹ̀mí ń wá inú ohun gbogbo, àní àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run.”—1 Kọ́ríńtì 2:9, 10.
6. Kí ni ohun tó wà nínú 1 Kọ́ríńtì 2:10 túmọ̀ sí?
6 Báwo ni ẹ̀mí Ọlọ́run ṣe ń wá “inú ohun gbogbo, àní àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run?” Dípò kí Jèhófà máa ṣí òtítọ́ rẹ̀ payá fún Kristẹni kọ̀ọ̀kan, ètò rẹ̀ tó ń fi ẹ̀mí rẹ̀ darí, èyí tó ń jẹ́ káwọn èèyàn Ọlọ́run tó wà níṣọ̀kan lóye Bíbélì ló ń lò. (Ìṣe 20:28; Éfésù 4:3-6) Ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan náà ni gbogbo ìjọ ń gbádùn jákèjádò ayé. Láàárín ọdún bíi mélòó kan, wọ́n á kẹ́kọ̀ọ́ gbogbo ohun tó jẹ́ kókó ẹ̀kọ́ inú Bíbélì. Ẹ̀mí mímọ́ sì ń tipasẹ̀ ìjọ ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti ní ọkàn tó dára tó máa jẹ́ kí wọ́n lè lóye “àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run.”—Ìṣe 5:32.
Kí Ni “Àwọn Ohun Ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run”?
7. Kí nìdí tí ọ̀pọ̀ èèyàn ò fi lóye “àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run”?
7 Kò yẹ ká ronú pé “àwọn ohun ìjìnlẹ̀” ní láti jẹ́ àwọn nǹkan tó ṣòro lóye. Kì í ṣe nítorí pé ó ṣòro láti ní ọgbọ́n Ọlọ́run ni ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn ò ṣe lóye “àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run,” bí kò ṣe torí pé Sátánì ń tan àwọn èèyàn jẹ, kò jẹ́ kí wọ́n tẹ́wọ́ gba ìrànlọ́wọ́ tí Jèhófà ń pèsè nípasẹ̀ ètò rẹ̀.—2 Kọ́ríńtì 4:3, 4.
8. Àwọn ohun ìjìnlẹ̀ wo ni Pọ́ọ̀lù tọ́ka sí nínú orí kẹta ìwé tó kọ sáwọn ará Éfésù?
8 Orí kẹta ìwé tí Pọ́ọ̀lù kọ sáwọn ará Éfésù jẹ́ ká rí i pé ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ òtítọ́ tí ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn èèyàn Jèhófà lóye dáadáa wà lára “àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run.” Àwọn nǹkan bí ẹni tí Irú-Ọmọ tá a ṣèlérí náà jẹ́, bí Ọlọ́run ṣe yan àwọn kan lára àwọn èèyàn láti lọ sí ọ̀run, àti Ìjọba Mèsáyà. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ní àwọn ìran mìíràn, àṣírí yìí ni a kò sọ di mímọ̀ fún àwọn ọmọ ènìyàn gẹ́gẹ́ bí a ti ṣí i payá nísinsìnyí fún àwọn wòlíì àti àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ mímọ́ nípasẹ̀ ẹ̀mí, èyíinì ni, kí àwọn ènìyàn àwọn orílẹ̀-èdè jẹ́ àwọn ajùmọ̀jogún àti ajùmọ̀ jẹ́ ẹ̀yà ara àti alábàápín pẹ̀lú wa nínú ìlérí náà ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Kristi Jésù.” Pọ́ọ̀lù sọ pé a ti yan òun láti “mú kí àwọn ènìyàn rí bí a ṣe ń bójú tó àṣírí ọlọ́wọ̀ tí a ti fi pa mọ́ tipẹ́tipẹ́ sínú Ọlọ́run.”—Éfésù 3:5-9.
9. Kí nìdí tó fi jẹ́ àǹfààní ńlá fún wa láti lòye “àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run”?
9 Pọ́ọ̀lù tún ṣàlàyé ìfẹ́ Ọlọ́run pé “nípasẹ̀ ìjọ, a sọ ọ̀pọ̀ oríṣiríṣi ọgbọ́n Ọlọ́run di mímọ̀ . . . ní àwọn ibi ọ̀run.” (Éfésù 3:10) Àwọn áńgẹ́lì rí ẹ̀kọ́ kọ́ bí wọ́n ti ń wo ọgbọ́n tí Jèhófà fi ń bá ìjọ Kristẹni lò, tí wọ́n sì ń lóye rẹ̀. Ẹ ò rí i pé àǹfààní ńlá ló jẹ́ fún wa láti lóye àwọn nǹkan táwọn áńgẹ́lì pàápàá fẹ́ mọ̀! (1 Pétérù 1:10-12) Ẹ̀yìn ìyẹn ni Pọ́ọ̀lù wá sọ pé a gbọ́dọ̀ sapá kí àwa “pẹ̀lú gbogbo ẹni mímọ́ bàa lè fi èrò orí mòye ní kíkún ohun tí ìbú àti gígùn àti gíga àti jíjìn [ìgbàgbọ́ àwa Kristẹni] jẹ́.” (Éfésù 3:11, 18) Ẹ jẹ́ ká wá ṣàyẹ̀wò díẹ̀ lára àwọn ohun ìjìnlẹ̀ tó lè mú kí òye wa túbọ̀ pọ̀ sí i.
Díẹ̀ Lára Àwọn Ohun Ìjìnlẹ̀
10, 11. Gẹ́gẹ́ bí ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ, ìgbà wo ni Jésù di ẹni àkọ́kọ́ lára “irú-ọmọ” “obìnrin” Ọlọ́run ti ọ̀run?
10 A mọ̀ pé Jésù ni ẹni àkọ́kọ́ lára “irú-ọmọ” “obìnrin” Ọlọ́run ti ọ̀run, èyí tí Jẹ́nẹ́sísì 3:15 sọ̀rọ̀ rẹ̀. Kí òye wa bàa lè gbòòrò sí i, a lè béèrè pé: ‘Ìgbà wo ni Jésù di Irú-Ọmọ tá a ṣèlérí náà? Ṣé nígbà tó ṣì wà lókè ọ̀run tí kò tíì di èèyàn ni àbí nígbà tí wọ́n bí i sáyé gẹ́gẹ́ bí èèyàn? Ṣé nígbà tó ṣèrìbọmi ni àbí lẹ́yìn tó jíǹde?’
11 Ọlọ́run ti ṣèlérí pé apá tó jẹ́ ti ọ̀run lára ètò rẹ̀, tí àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì pè ní “obìnrin” rẹ̀ yóò mú irú-ọmọ kan jáde tí yóò fọ́ ejò náà ní orí. Àmọ́ ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún kọjá, síbẹ̀ obìnrin Ọlọ́run yìí kò mú irú-ọmọ kankan jáde tó lágbára láti pa Sátánì àti iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ run. Ìdí nìyẹn tí àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà fi pè é ní “àgàn” tí a “pa ẹ̀mí rẹ̀ lára.” (Aísáyà 54:1, 5, 6) Ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, wọ́n wá bí Jésù ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù. Àmọ́ ìgbà tó ṣèrìbọmi tán, tí Ọlọ́run fi ẹ̀mí mímọ́ yàn án, tó sì tipa bẹ́ẹ̀ di ọmọ tó ní àjọṣe àrà ọ̀tọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run ni Jèhófà ṣẹ̀ṣẹ̀ kéde pé: “Èyí ni Ọmọ mi.” (Mátíù 3:17; Jòhánù 3:3) Bí ẹni tó jẹ́ ẹni àkọ́kọ́ lára “irú-ọmọ” obìnrin náà ṣe fara hàn níkẹyìn nìyẹn. Ẹ̀yìn ìyẹn làwọn ọmọlẹ́yìn Jésù tún di ẹni àmì òróró tí Ọlọ́run fẹ̀mí mímọ́ yàn. “Obìnrin” Jèhófà tó ti dà bí “àgàn tí kò bímọ” fún ìgbà pípẹ́ lè wá “fi ìdùnnú ké jáde” nígbẹ̀yìngbẹ́yín.—Aísáyà 54:1; Gálátíà 3:29.
12, 13. Àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wo ló fi hàn pé gbogbo Kristẹni ẹni àmì òróró tó wà láyé ló para pọ̀ jẹ́ “ẹrú olóòótọ́ àti olóye”?
12 Àpẹẹrẹ ohun kejì tó jẹ́ ohun ìjìnlẹ̀ tá a ti ṣí payá fún wa ni ohun tó mú kí Ọlọ́run yan ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì lára ọmọ aráyé. (Ìṣípayá 14:1, 4) A gbà pé gbogbo àwọn ẹni àmì òróró tó bá wà lórí ilẹ̀ ayé ní àkókò èyíkéyìí ló para pọ̀ jẹ́ “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” tí Jésù sọ pé yóò máa pèsè “oúnjẹ” tó bọ́ sásìkò fún àwọn ará ilé òun. (Mátíù 24:45) Àwọn ẹsẹ Bíbélì wo ló fi hàn pé òye tá a ní yìí tọ̀nà? Ǹjẹ́ ó lè jẹ́ pé Kristẹni èyíkéyìí tó bá ṣáà ti ń fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run bọ́ àwọn ará ni Jésù ń tọ́ka sí?
13 Ọlọ́run sọ fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì pé: “Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí mi . . . àní ìránṣẹ́ mi tí mo ti yàn.” (Aísáyà 43:10) Àmọ́ ní ọjọ́ kọkànlá oṣù Nísàn, ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, Jésù sọ fún àwọn aṣáájú Ísírẹ́lì pé Ọlọ́run ti kọ orílẹ̀-èdè wọn sílẹ̀, pé wọ́n kì í ṣe ìránṣẹ́ rẹ̀ mọ́. Ó ní “A ó gba ìjọba Ọlọ́run kúrò lọ́wọ́ yín, a ó sì fi fún orílẹ̀-èdè tí yóò máa mú èso rẹ̀ jáde.” Jésù wá sọ fáwọn èrò tó wà níbẹ̀ pé: “Wò ó! A pa ilé yín tì fún yín.” (Mátíù 21:43; 23:38) Ilé Ísírẹ́lì tó jẹ́ ẹrú Jèhófà kò jẹ́ olóòótọ́ bẹ́ẹ̀ ni kò jẹ́ olóye. (Aísáyà 29:13, 14) Nígbà tó yá, ní ọjọ́ yẹn kan náà, tí Jésù tún béèrè pé: “Ní ti tòótọ́, ta ni ẹrú olóòótọ́ àti olóye?” Ohun tó ń béèrè ní ṣókí ni pé, ‘Orílẹ̀-èdè wo ló jẹ́ ọlọgbọ́n tó máa rọ́pò Ísírẹ́lì láti jẹ́ ẹrú olóòótọ́ fún Ọlọ́run?’ Àpọ́sítélì Pétérù dáhùn ìbéèrè yìí nígbà tó sọ fún ìjọ àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró pé: “Ẹ̀yin jẹ́ . . . ‘orílẹ̀-èdè mímọ́, àwọn ènìyàn fún àkànṣe ìní.’” (1 Pétérù 1:4; 2:9) Orílẹ̀-èdè tẹ̀mí yẹn, “Ísírẹ́lì Ọlọ́run,” di ẹrú tí Jèhófà ṣẹ̀ṣẹ̀ yàn. (Gálátíà 6:16) Bí gbogbo àwọn tó wà ní Ísírẹ́lì ìgbàanì ṣe para pọ̀ jẹ́ “ìránṣẹ́” kan, bẹ́ẹ̀ náà ni gbogbo àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tó bá wà lórí ilẹ̀ ayé ní àkókò èyíkéyìí ṣe para pọ̀ jẹ́ “ẹrú olóòótọ́ àti olóye.” Ẹ ò rí i pé àǹfààní ńlá ló jẹ́ fún wa láti máa gba “oúnjẹ” látọ̀dọ̀ ẹrú Ọlọ́run!
Ìdákẹ́kọ̀ọ́ Máa Ń Gbádùn Mọ́ni
14. Kí nìdí tí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì fi ń fúnni láyọ̀ ju kéèyàn kàn ka Bíbélì lásán?
14 Nígbà tá a bá ṣẹ̀ṣẹ̀ lóye ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan lákọ̀tun, ǹjẹ́ inú wa kì í dùn nítorí pé ó mú kí ìgbàgbọ́ wa lágbára sí i? Ìdí nìyẹn tí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì fi máa ń fúnni láyọ̀ tó pọ̀ gan-an ju kéèyàn kàn ka Bíbélì lásán. Nítorí náà, bó o bá ń ka àwọn ìwé wa, máa bi ara rẹ léèrè pé: ‘Báwo ni àlàyé tuntun yìí ṣe bá òye tí mo ní tẹ́lẹ̀ lórí kókó yìí mu? Àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tàbí àwọn àlàyé mìíràn wo ni mo lè ronú kàn tó máa túbọ̀ fi hàn pé àlàyé tí wọ́n ṣe nínú àpilẹ̀kọ tí mò ń kà yìí tọ̀nà?’ Bó o bá rí i pé o ní láti ṣèwádìí síwájú sí i, kọ ìbéèrè tó o fẹ́ láti rí ìdáhùn sí sílẹ̀, kó o sì fi ṣe ohun tó o máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa rẹ̀ nígbà mìíràn.
15. Àwọn nǹkan wo lo lè kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ tó máa múnú rẹ dùn, báwo sì ni wọ́n ṣe lè ṣe ọ́ láǹfààní títí lọ?
15 Àwọn nǹkan wo lo lè kẹ́kọ̀ọ́ nípa rẹ̀ tó máa fún ọ ní òye tuntun tó ń múnú ẹni dùn? Òye rẹ á túbọ̀ pọ̀ sí i tó o bá ṣàyẹ̀wò tó kún rẹ́rẹ́ nípa onírúurú májẹ̀mú tí Ọlọ́run ti bá àwọn èèyàn dá, èyí tó máa ṣe ọmọ aráyé láǹfààní. O tún lè jẹ́ kí ìgbàgbọ́ rẹ lágbára sí i nípa kíkẹ́kọ̀ọ́ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ nípa Jésù Kristi tàbí kó o mú ọ̀kan lára àwọn ìwé àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Bíbélì kó o sì ṣàyẹ̀wò gbogbo ẹsẹ tó wà níbẹ̀ lọ́kọ̀ọ̀kan. Ohun mìíràn tó tún lè fún ìgbàgbọ́ rẹ lágbára ni pé kó o ṣàyẹ̀wò ìtàn àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà òde òní, kó o lo ìwé Jehovah’s Witnesses—Proclaimers of Gods Kingdom, tó bá wà ní èdè rẹ.a Ó dájú pé ṣíṣe àtúnyẹ̀wò àwọn “Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé” nínú àwọn Ilé Ìṣọ́ tó ti jáde sẹ́yìn yóò mú kí òye tó o ní lórí àwọn kókó kan túbọ̀ pọ̀ sí i. Rí i pé o kíyè sí àlàyé Ìwé Mímọ́ tí wọ́n ṣe lórí ìbéèrè náà. Èyí á ràn ọ́ lọ́wọ́ láti kọ́ “agbára ìwòye” rẹ, á sì jẹ́ kó o túbọ̀ máa fòye mọ àwọn nǹkan. (Hébérù 5:14) Bó o bá ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́, máa kọ àwọn kókó pàtàkì sílẹ̀, o lè kọ wọ́n sínú Bíbélì rẹ tàbí sínú ìwé kékeré kan kí ẹ̀kọ́ tó ò ń kọ́ lè ṣe ìwọ àtàwọn tó o bá lè ràn lọ́wọ́ láǹfààní.
Ran Àwọn Ọmọdé Lọ́wọ́ Láti Gbádùn Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì
16. Báwo lo ṣe lè ran àwọn ọmọdé lọ́wọ́ láti gbádùn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?
16 Ọ̀pọ̀ nǹkan làwọn òbí lè ṣe láti ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ kí wọ́n lè fẹ́ láti ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú Ọlọ́run. Má ṣe rò pé àwọn ọmọdé ò lè lóye àwọn ohun ìjìnlẹ̀. Tó o bá yan kókó táwọn ọmọ rẹ á ṣèwádìí lé lórí fún wọn nígbà tí wọ́n bá ń múra ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ìdílé sílẹ̀, o lè bí wọ́n ní ìbéèrè tó dá lórí ohun tí wọ́n ṣèwádìí rẹ̀. Ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé tún lè kan ṣíṣe àwọn ìfidánrawò láti ran àwọn ọmọdé lọ́wọ́ kí wọ́n lè mọ báwọn á ṣe máa ṣàlàyé ohun tí wọ́n gbà gbọ́ àti bí wọ́n á ṣe máa fi hàn pé òótọ́ ni ohun tí wọ́n fi ń kọ́ àwọn. Láfikún sí i, o lè lo ìwé pẹlẹbẹ Wo “Ilẹ̀ Dáradára” Náàb láti kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn ilẹ̀ tí Bíbélì sọ̀rọ̀ rẹ̀ kó o sì fi ṣàlàyé tó ṣe kedere lórí ibi tẹ́ ẹ̀ ń kà nínú Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀.
17. Kí nìdí tí kò fi yẹ ká jẹ́ kí ìdákẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì dí wa lọ́wọ́ mímúra àwọn ìpàdé ìjọ sílẹ̀?
17 Ìdákẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lè gbádùn mọ́ni kó sì mú kí ìgbàgbọ́ ẹni lágbára, àmọ́ ṣọ́ra kó o má jẹ́ kó gba àkókò tó yẹ kó o fi múra ìpàdé ìjọ sílẹ̀. Àwọn ìpàdé wọ̀nyẹn jẹ́ ọ̀nà mìíràn tí Jèhófà gbà ń fún wa nítọ̀ọ́ni nípasẹ̀ “ẹrú olóòótọ́ àti olóye.” Àmọ́ ṣá o, ṣíṣe ìwádìí síwájú sí i lè jẹ́ káwọn àlàyé tó ò ń ṣe láwọn ìpàdé túbọ̀ nítumọ̀, irú bí ìgbà tó o bá ń dáhùn ní Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ tàbí tó o bá ń sọ̀rọ̀ nílé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run lórí àwọn kókó pàtàkì tó wà nínú Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀.
18. Kí nìdí tí ipa tó yẹ kéèyàn sà láti kẹ́kọ̀ọ́ “àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run” fi ṣe pàtàkì púpọ̀?
18 Dídákẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jinlẹ̀ lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti sún mọ́ Jèhófà. Ká lè mọ bí irú ìkẹ́kọ̀ọ́ bẹ́ẹ̀ ti ṣe pàtàkì tó ni Bíbélì ṣe sọ pé: “Ọgbọ́n jẹ́ fún ìdáàbòbò, gẹ́gẹ́ bí owó ti jẹ́ fún ìdáàbòbò; ṣùgbọ́n àǹfààní ìmọ̀ ni pé ọgbọ́n máa ń pa àwọn tí ó ni ín mọ́ láàyè.” (Oníwàásù 7:12) Nítorí náà, ipa tó yẹ kó o sà kí òye rẹ nípa àwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́ lè túbọ̀ jinlẹ̀ sí i ṣe pàtàkì púpọ̀. Ìlérí tí Bíbélì ṣe fáwọn tí kò jẹ́ kó sú wọn láti máa ṣèwádìí ni pé: “Ìwọ yóò sì rí ìmọ̀ Ọlọ́run gan-an.”—Òwe 2:4, 5.
[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ̀ ẹ́ jáde.
b Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ̀ ẹ́ jáde.
Ǹjẹ́ O Lè Ṣàlàyé?
• Kí ni “àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run”?
• Kí nìdí tá a fi gbọ́dọ̀ máa kẹ́kọ̀ọ́ àwọn ohun ìjìnlẹ̀ nìṣó?
• Kí nìdí tó fi jẹ́ pé gbogbo Kristẹni ló lè ní ayọ̀ téèyàn máa ń ní nígbà tó bá lóye “àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run”?
• Báwo lo ṣe lè túbọ̀ jàǹfààní nínú “àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run”?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]
Ìgbà wo ni Jésù di Irú-Ọmọ tá a ṣèlérí?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]
Àwọn òbí lè yan kókó táwọn ọmọ wọn á ṣèwádìí lé lórí fún wọn nígbà tí wọ́n bá ń múra sílẹ̀ fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ìdílé