ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w13 7/1 ojú ìwé 7
  • Ǹjẹ́ Ẹ̀sìn Kankan Tiẹ̀ Wà Téèyàn Lè Gbára Lé?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ǹjẹ́ Ẹ̀sìn Kankan Tiẹ̀ Wà Téèyàn Lè Gbára Lé?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2013
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Mọ Ìsìn Tòótọ́?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Fífọkàntánni Ló Ń Mú Kí Ìgbésí Ayé Èèyàn Láyọ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
  • Ohun Tí Bíbélì Sọ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2016
  • Ṣíṣe Isin Mimọgaara fun Lilaaja
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2013
w13 7/1 ojú ìwé 7

Ǹjẹ́ Ẹ̀sìn Kankan Tiẹ̀ Wà Téèyàn Lè Gbára Lé?

Tí ẹ̀sìn kan bá ti já ẹ kulẹ̀ rí, ó lè má rọrùn fún ẹ láti gbára lé ẹ̀sìn kankan. Àmọ́, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé ẹ̀sìn kan tí o lè gbára lé ṣì wà. Nígbà tí Jésù wà láyé, ó kó àwọn ọmọ ẹ̀yìn olóòótọ́ kan jọ, ó sì kọ́ wọn pé kí wọ́n máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà Ọlọ́run. Àwọn ojúlówó ọmọ ẹ̀yìn Jésù, ìyẹn àwọn tí wọ́n ń rí i dájú pé àwọn ń tẹ̀ lé ìlànà Kristẹni ṣì wà. Báwo ni wàá ṣe dá wọn mọ̀?

Estelle tí a sọ̀rọ̀ rẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ kejì, sọ pé: “Ìgbà tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ ni mo tó bẹ̀rẹ̀ sí í mọ̀ nípa Bíbélì. Kò pẹ́ rárá tí mo fi lóye ohun tó wà nínú Jòhánù 8:32, ó ní: ‘Ẹ ó sì mọ òtítọ́, òtítọ́ yóò sì dá yín sílẹ̀ lómìnira.’”

Ray, tí a sọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ pé: “Nígbà tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ni mo tó mọ̀ pé Ọlọ́run kọ́ ló ń fa àwọn ìṣòro aráyé. Inú mi dùn nígbà tí mo mọ̀ pé ó ní ìdí tí Ọlọ́run ṣì fi fàyè gba ìwà ibi àti pé ó ti ṣèlérí pé òun máa mú gbogbo ìwà ibi kúrò láìpẹ́.”

Òótọ́ ni pé kò rọrùn láti máa ṣe ohun tí ó tọ́ láàárín àwọn èèyàn tí ìwà rere ò jámọ́ nǹkan kan lójú wọn. Àmọ́, ó ṣeé ṣe. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń wá ẹni tó máa ran àwọn lọ́wọ́ kí wọ́n lè lóye ẹ̀kọ́ Bíbélì, kí wọ́n sì lè máa fi í sílò. Ìdí nìyẹn tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi ń kọ́ àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́fẹ̀ẹ́ kárí ayé. Lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn ló ń mọ ohun tí Bíbélì fi kọ́ni gan-an, èyí sì ń mú kí wọ́n túbọ̀ sún mọ́ Ẹlẹ́dàá wọn, wọ́n sì ń láyọ̀ nígbèésí ayé wọn.a

Bi àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà léèrè ìdí tí wọ́n fi gbára lé ẹ̀sìn wọn

Nígbà míì tó o bá tún rí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, bi wọ́n léèrè ìdí tí wọ́n fi gbára lé ẹ̀sìn wọn. Wádìí nípa wọn, kí o sì ṣàyẹ̀wò ẹ̀kọ́ tí wọ́n fi ń kọ́ àwọn èèyàn. Kó o wá pinnu fúnra rẹ bóyá ẹ̀sìn tó o lè gbára lé ṣì wà.

a Tó o bá fẹ́ ìsọfúnni síwájú sí i, ka ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́