Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí
September 15, 2013
© 2013 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania.
Ẹ̀DÀ TÓ WÀ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́
OCTOBER 28, 2013–NOVEMBER 3, 2013
Àwọn Ìránnilétí Jèhófà Ṣeé Gbẹ́kẹ̀ Lé
NOVEMBER 4-10, 2013
Jẹ́ Kí Àwọn Ìránnilétí Jèhófà Máa Múnú Rẹ Dùn
NOVEMBER 11-17, 2013
NOVEMBER 18-24, 2013
NOVEMBER 25, 2013–DECEMBER 1, 2013
ÀWỌN ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́
▪ Àwọn Ìránnilétí Jèhófà Ṣeé Gbẹ́kẹ̀ Lé
▪ Jẹ́ Kí Àwọn Ìránnilétí Jèhófà Máa Múnú Rẹ Dùn
Ìgbà gbogbo ni Jèhófà máa ń lo àwọn ìránnilétí láti tọ́ àwọn èèyàn rẹ̀ sọ́nà. Àwọn nǹkan wo ló máa ń wà lára àwọn ìránnilétí Jèhófà? Àpilẹ̀kọ àkọ́kọ́ ṣàlàyé ìdí tá a fi lè gbẹ́kẹ̀ lé àwọn ìránnilétí Ọlọ́run. Àpilẹ̀kọ kejì jíròrò ohun mẹ́ta tó lè mú ká túbọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé àwọn ìránnilétí Jèhófà.
▪ Ǹjẹ́ Ẹ Ti Para Dà?
▪ Máa Fi Ọgbọ́n Ṣe Ìpinnu
Bí wọ́n ṣe tọ́ wa dàgbà àti ibi tá a gbé dàgbà máa ń nípa púpọ̀ lórí ojú tá a fi ń wo nǹkan àtohun tá a yàn láàyò. Báwo la ṣe lè rí i dájú pé àwọn ìpinnu wa bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu? Kí ló sì lè ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe ohun tá a pinnu? Àpilẹ̀kọ méjèèjì yìí máa jẹ́ ká fi àwọn ìbéèrè yìí yẹ ara wa wò dáadáa.
▪ Iṣẹ́ Aṣáájú-Ọ̀nà Máa Jẹ́ Kó OTúbọ̀ Sún Mọ́ Ọlọ́run
A máa jíròrò ọ̀nà mẹ́jọ tí iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà fi lè mú kí Kristẹni kan túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. Tó o bá jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà, kí ló lè mú kó o máa ṣe é nìṣó, láìka ìṣòro sí? Tó bá sì jẹ́ pé ó wù ẹ́ láti ṣe aṣáájú-ọ̀nà kó o sì máa rí ìbùkún tó wà nínú iṣẹ́ náà, kí lo lè ṣe?
ÀWÒRÁN Ẹ̀YÌN ÌWÉ: Ní àgbègbè Amazonas, ní apá àríwá orílẹ̀-èdè Peru, àǹfààní púpọ̀ ló wà fáwọn ará wa láti wàásù láìjẹ́ bí àṣà
PERU
IYE ÈÈYÀN
29,734,000
IYE AKÉDE
117,245
ÀWỌN TÓ ṢÈRÌBỌMI LỌ́DÚN MÁRÙN-ÚN SẸ́YÌN
28,824
Ní orílẹ̀-èdè Peru, oríṣi èdè mẹ́fà là ń tú àwọn ìtẹ̀jáde wa sí. Àwọn aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe àtàwọn míṣọ́nnárì tó lé ní ọgọ́fà [120] ló ń fi àwọn èdè tó yàtọ̀ sí Sípáníìṣì wàásù