ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w13 9/15 ojú ìwé 3-6
  • Àfiwé Máa Ń Mú Kí Ọ̀rọ̀ Túbọ̀ Yéni

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àfiwé Máa Ń Mú Kí Ọ̀rọ̀ Túbọ̀ Yéni
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2013
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • ÀǸFÀÀNÍ TÓ WÀ NÍNÚ LÍLO ÀFIWÉ
  • Kọ́ Bí A Ṣe Ń Jẹ́ Olùkọ́ Tó Múná Dóko
    Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
  • “Ẹ Maa Baa Lọ Ní Rírìn Gẹgẹ Bi Awọn Ọmọ Ìmọ́lẹ̀”
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • “Jèhófà Kan Ṣoṣo” Ń kó Ìdílé Rẹ̀ Jọ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
  • “Ṣàṣeparí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Ní Kíkún”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2013
w13 9/15 ojú ìwé 3-6
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 3]

Àfiwé Máa Ń Mú Kí Ọ̀rọ̀ Yéni

Kò sí àní-àní pé Jésù ni Olùkọ́ tó mọ̀ọ̀yàn kọ́ jù lọ nínú gbogbo àwọn olùkọ́ tó tíì gbé láyé yìí! Ó tiẹ̀ ṣeé ṣe kí ìwọ náà ti lo díẹ̀ lára àwọn ọ̀nà tó ń gbà kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́, irú bó ṣe máa ń lo ìbéèrè àti àpèjúwe. Ṣùgbọ́n, ǹjẹ́ o tún kíyè sí i pé nígbà tí Jésù bá ń kọ́ àwọn èèyàn, ó máa ń lo àfiwé tó ń mú kí ìyàtọ̀ tó wà láàárín ohun méjì ṣe kedere?

Ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa ń lo irú àfiwé yìí nígbà tí wọ́n bá ń sọ̀rọ̀. Ìwọ pẹ̀lú lè lò ó lọ́pọ̀ ìgbà láìmọ̀ rárá. Nígbà míì, èèyàn lè sọ pé, “Wọ́n sọ pé gbogbo èso yìí ti pọ́n; àmọ́, àwọn eléyìí ṣì le gan-an.” Tàbí kéèyàn sọ pé, “Ọmọbìnrin yìí máa ń tijú gan-an nígbà tó ṣì kéré, àmọ́ ní báyìí ara rẹ̀ ti ń yá mọ́ọ̀yàn dáadáa.”

Nígbà tá a bá fẹ́ lo irú àwọn àfiwé yìí, a máa ń kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ nípa ohun kan; lẹ́yìn náà a máa wá sọ̀rọ̀ nípa ohun míì tó yàtọ̀ sí i nípa lílo àwọn ọ̀rọ̀ bíi ṣùgbọ́n, bí ó ti wù kí ó rí, kàkà bẹ́ẹ̀, bí kò ṣe tàbí lọ́wọ́ kejì ẹ̀wẹ̀. Ọ̀nà míì tá a tún lè gbà lo àfiwé ni pé ká sọ̀rọ̀ nípa ohun kan, lẹ́yìn náà ká wá fi ọ̀rọ̀ míì kún un tó máa mú kí èyí tá a kọ́kọ́ sọ túbọ̀ lágbára. Nígbà tá a bá lo irú àwọn ọ̀rọ̀ yìí, ó máa ń mú kí ọ̀rọ̀ wa dùn-ún gbọ́, ó sì máa ń mú kí ọ̀rọ̀ wá yé àwọn èèyàn dáadáa.

Bó bá tiẹ̀ jẹ́ pé wọn kì í sábà lo àfiwé nínú àwọn èdè tàbí àṣà ìbílẹ̀ kan, ó ṣì yẹ ká mọyì irú àwọn ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀. Kí nìdí? Ìdí ni pé irú àwọn ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ pọ̀ nínú Bíbélì. Yàtọ̀ síyẹn, ọ̀pọ̀ ìgbà ni Jésù lo àfiwé. Díẹ̀ lára wọn rèé: “Àwọn ènìyàn a tan fìtílà, wọn a sì gbé e kalẹ̀, kì í ṣe sábẹ́ apẹ̀rẹ̀ ìdíwọ̀n, bí kò ṣe sórí ọ̀pá fìtílà.” “Èmi kò wá láti pa [Òfin] run, bí kò ṣe láti mú ṣẹ.” “Ẹ gbọ́ pé a sọ ọ́ pé, ‘Ìwọ kò gbọ́dọ̀ ṣe panṣágà.’ Ṣùgbọ́n mo wí fún yín pé olúkúlùkù ẹni tí ń bá a nìṣó ní wíwo obìnrin kan . . . ” “A sọ ọ́ pé, ‘Ojú fún ojú àti eyín fún eyín.’ Bí ó ti wù kí ó rí, mo wí fún yín pé: Má ṣe dúró tiiri lòdì sí ẹni burúkú; ṣùgbọ́n ẹnì yòówù tí ó bá gbá ọ ní ẹ̀rẹ̀kẹ́ ọ̀tún, yí èkejì sí i pẹ̀lú.”—Mát. 5:15, 17, 27, 28, 38, 39.

Àwọn àfiwé míì tó jọ èyí tún wà níbòmíì nínú Bíbélì. Wọ́n lè jẹ́ kí kókó ọ̀rọ̀ kan tètè yẹ́ ẹ tàbí kí wọ́n jẹ́ kó o mọ ọ̀nà tó dára jù láti gbà ṣe nǹkan. Tó bá jẹ́ pé òbí ni ẹ́, ronú lórí àfiwé yìí: “Ẹ̀yin baba, ẹ má ṣe máa sún àwọn ọmọ yín bínú, ṣùgbọ́n ẹ máa bá a lọ ní títọ́ wọn dàgbà nínú ìbáwí àti ìlànà èrò orí Jèhófà.” (Éfé. 6:4) Ká sọ pé ńṣe ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù wulẹ̀ sọ pé kí àwọn baba (tàbí ìyá) máa tọ́ àwọn ọmọ wọn dàgbà ní ọ̀nà Ọlọrun, ọ̀rọ̀ tó mọ́gbọ́n dání nìyẹn á jẹ́, òótọ́ ọ̀rọ̀ sì ni. Síbẹ̀, àfiwé tó ṣe nígbà tó sọ pé kí àwọn òbí ‘má ṣe mú wọn bínú ṣùgbọ́n kí wọ́n tọ́ wọn dàgbà nínú ìlànà èrò orí Jèhófà,’ mú kí ọ̀rọ̀ rẹ̀ túbọ̀ ṣe kedere.

Nígbà tí Pọ́ọ̀lù tún ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ ní orí kan náà, ó sọ pé: “Àwa ní gídígbò kan, kì í ṣe lòdì sí ẹ̀jẹ̀ àti ẹran ara, bí kò ṣe lòdì sí . . . àwọn agbo ọmọ ogun ẹ̀mí burúkú ní àwọn ibi ọ̀run.” (Éfé. 6:12) Àfiwé yẹn jẹ́ kó o mọ bí ìjà tó o máa jà ṣe le tó. Kì í ṣe àwọn èèyàn ẹlẹ́ran ara lo fẹ́ bá jà, bí kò ṣe agbo ọmọ ogun ẹ̀mí burúkú.

ÀǸFÀÀNÍ TÓ WÀ NÍNÚ LÍLO ÀFIWÉ

Ọ̀pọ̀ ibòmíì tún wà nínú ìwé Éfésù tí Pọ́ọ̀lù ti lo àfiwé. Tá a bá ń ronú lórí àwọn ọ̀rọ̀ yìí, ó lè jẹ́ kí ohun tí Pọ́ọ̀lù ń sọ yé wa dáadáa, ó sì lè jẹ́ ká túbọ̀ mọ ohun tá a gbọ́dọ̀ ṣe.

Tó o bá wo àtẹ ìsọfúnni tó wà nínú àpilẹ̀kọ yìí, o máa gbádùn rẹ̀ gan-an ni, o sì máa rí ẹ̀kọ́ kọ́ níbẹ̀. Àtẹ ìsọfúnni náà dá lórí àwọn ọ̀nà tí Pọ́ọ̀lù gbà lo àfiwé nínú Éfésù orí 4 àti 5. Bó o ṣe ń ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ náà, máa ronú nípa ìgbésí ayé rẹ. Kó o sì máa bi ara rẹ pé: ‘Irú ìwà wo gan-an ni mò ń hù? Bí irú nǹkan yìí tàbí ohun tó jọ ọ́ bá ṣẹlẹ̀ sí mi, kí ni mo máa ń ṣe? Èwo nínú apá méjèèjì tí àfiwé náà pín sí ni àwọn tó mọ̀ mí máa gbà pé ó bá mi mu?’ Tó o bá rí i pé apá kan nínú àwọn àfiwé náà bá ẹ wí, ńṣe ni kó o gbìyànjú láti ṣàtúnṣe. Rí i dájú pé o jàǹfààní látinú àfiwé náà.

Ẹ sì lè lo àtẹ ìsọfúnni yìí nígbà Ìjọsìn Ìdílé yín. Ó máa dárá kí gbogbo yín kọ́kọ́ ka àwọn àfiwé náà dáadáa. Lẹ́yìn náà, kí ẹnì kan wá sọ apá àkọ́kọ́ nínú àfiwé náà, kí àwọn tó kù sì gbìyànjú láti rántí apá kejì. Ẹ wá lè fi àkókò yẹn sọ̀rọ̀ nípa bẹ́ ẹ ṣe lè fi kókó tó wà ní apá kejì àfiwé náà sílò nínú ìgbésí ayé yín, ìjíròrò yẹn sì máa lárinrin gan-an ni. Kò sí àní-àní pé tá a bá ń fara balẹ̀ wo àwọn ọ̀nà tá a gbà lo àfiwé bí irú èyí, ó máa ran tọmọdé tàgbà wa lọ́wọ́ ká lè máa gbé ìgbé ayé tó yẹ Kristẹni nínú ìdílé wa àti láwọn ibòmíì.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]

Ṣó o lè rántí apá kejì àfiwé náà?

Bó o bá ṣe túbọ̀ ń mọyì àwọn àfiwé, kíákíá ni wàá máa dá irú àwọn ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ mọ̀ nígbà tó o bá ń ka Bíbélì, wàá sì rí i pé ó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ gan-an lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Bí àpẹẹrẹ, tó o bá fẹ́ wàásù fún ẹnì kan, o lè sọ pé: “Ọ̀pọ̀ èèyàn ló gbà gbọ́ pé tí àwa èèyàn bá kú, ńṣe ni ẹ̀mí wa máa ń rìn káàkiri tàbí kó lọ máa gbé ibòmíì. Ṣùgbọ́n kíyè sí ohun tí Bíbélì sọ níbí.” Tó bá sì jẹ́ pé ńṣe lò ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, o lè sọ pé: “Àwọn tó pọ̀ jù ládùúgbò yìí ló gbà gbọ́ pé ẹnì kan náà ni Ọlọ́run àti Jésù; àmọ́, kí la rí kọ́ nípa èyí nínú Bíbélì? Kí ni ìwọ fúnra rẹ gbà gbọ́ nípa èyí?”

Ó ṣe kedere pé àwọn àfiwé pọ̀ dáadáa nínú Bíbélì. Wọ́n ń mú kí ọ̀rọ̀ yéni, wọ́n sì máa ń ràn wá lọ́wọ́ ká lè máa rìn ní ọ̀nà Ọlọ́run. A sì tún lè lo àfiwé láti ran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́ kí wọ́n lè lóye ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì.

Díẹ̀ Rèé Lára Àwọn Àfiwé Tó Wà Nínú Éfésù Orí 4 àti 5

Ẹ Gbìyànjú Kẹ́ ẹ Lo Àtẹ Ìsọfúnni Yìí Nínú Ìjọsìn Ìdílé Yín

[Àwòrán]

“Kí a má ṣe jẹ́ ẹni tí a . . . ń gbé síhìn-ín sọ́hùn-ún . . . nípasẹ̀ ìwà àgálámàṣà àwọn ènìyàn, nípasẹ̀ àlùmọ̀kọ́rọ́yí nínú dídọ́gbọ́n hùmọ̀ ìṣìnà.”​—4:14.

“Ṣùgbọ́n ní sísọ òtítọ́, ẹ jẹ́ kí a fi ìfẹ́ dàgbà sókè nínú ohun gbogbo sínú ẹni tí í ṣe orí, Kristi.”​—4:15.

[Àwòrán]

“[Àwọn orílẹ̀-èdè] wà nínú òkùnkùn ní ti èrò orí, . . . nítorí yíyigbì ọkàn-àyà wọn.”​—4:18, 19.

“Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò kẹ́kọ̀ọ́ Kristi bẹ́ẹ̀, bí ó bá jẹ́ pé, ní tòótọ́ ni ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, tí a sì tipasẹ̀ rẹ̀ kọ́ yín.”​—4:20, 21.

[Àwòrán]

“Kí ẹ bọ́ ògbólógbòó àkópọ̀ ìwà sílẹ̀, èyí tí ó bá ipa ọ̀nà ìwà yín àtijọ́ ṣe déédéé.”​—4:22.

“Ṣùgbọ́n kí ẹ di tuntun nínú ipá tí ń mú èrò inú yín ṣiṣẹ́, kí ẹ sì gbé àkópọ̀ ìwà tuntun wọ̀.”​—4:23, 24.

[Àwòrán]

“Kí ẹni tí ń jalè má jalè mọ́.”​—4:28.

“Ṣùgbọ́n kàkà bẹ́ẹ̀, kí ó máa ṣe iṣẹ́ àṣekára, kí ó máa fi ọwọ́ rẹ̀ ṣe ohun tí ó jẹ́ iṣẹ́ rere.”​—4:28.

[Àwòrán]

“Kí àsọjáde jíjẹrà má ti ẹnu yín jáde.”​—4:29.

“Bí kò ṣe àsọjáde yòówù tí ó dára fún gbígbéniró.”4:29.

[Àwòrán]

“Kí ẹ mú gbogbo ìwà kíkorò onínú burúkú àti ìbínú àti ìrunú àti ìlọgun àti ọ̀rọ̀ èébú kúrò lọ́dọ̀ yín pa pọ̀ pẹ̀lú gbogbo ìwà búburú.”​—4:31.

“Ṣùgbọ́n kí ẹ di onínúrere sí ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, ní fífi ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ hàn, kí ẹ máa dárí ji ara yín fàlàlà.”​—4:32.

[Àwòrán]

“Kí a má tilẹ̀ mẹ́nu kan àgbèrè àti ìwà àìmọ́ onírúurú gbogbo tàbí ìwà ìwọra láàárín yín.”​—5:3.

“Ṣùgbọ́n kàkà bẹ́ẹ̀ ìdúpẹ́.”​—5:4.

[Àwòrán]

“Ẹ jẹ́ òkùnkùn nígbà kan rí.”​—5:8.

“Ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ ìmọ́lẹ̀ nísinsìnyí ní ìsopọ̀ pẹ̀lú Olúwa.”​—5:8.

[Àwòrán]

‘Ẹ jáwọ́ nínú ṣíṣàjọpín pẹ̀lú wọn nínú àwọn iṣẹ́ aláìléso tí ó jẹ́ ti òkùnkùn.’​—5:11.

“Ṣùgbọ́n, kàkà bẹ́ẹ̀, àní kí ẹ máa fi ìbáwí tọ́ wọn sọ́nà.”​—5:11.

[Àwòrán]

“Nítorí náà, ẹ máa ṣọ́ra lójú méjèèjì pé bí ẹ ṣe ń rìn kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí aláìlọ́gbọ́n.”​—5:15.

“Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí ọlọ́gbọ́n, ní ríra àkókò tí ó rọgbọ padà fún ara yín.”​—5:15, 16.

[Àwòrán]

“Ní tìtorí èyí, ẹ ṣíwọ́ dídi aláìlọ́gbọ́n-nínú.”​—5:17.

“Ṣùgbọ́n ẹ máa bá a lọ ní ríróye ohun tí ìfẹ́ Jèhófà jẹ́.”​—5:17.

[Àwòrán]

“Ẹ má ṣe máa mu wáìnì ní àmupara, nínú èyí tí ìwà wọ̀bìà wà.”​—5:18.

“Ṣùgbọ́n ẹ máa kún fún ẹ̀mí.”​—5:18.

[Àwòrán]

“Kí [Kristi] lè mú ìjọ wá síwájú ara rẹ̀ nínú ìdángbinrin rẹ̀, láìní èérí kan tàbí ìhunjọ kan tàbí èyíkéyìí nínú irúfẹ́ nǹkan bẹ́ẹ̀.”​—5:27.

“Ṣùgbọ́n pé kí ó lè jẹ́ mímọ́ àti láìsí àbààwọ́n.”​—5:27.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]

“Kò sí ènìyàn kankan tí ó jẹ́ kórìíra ara òun fúnra rẹ̀.”​—5:29.

“Ṣùgbọ́n a máa bọ́ ọ, a sì máa ṣìkẹ́ rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Kristi pẹ̀lú ti ń ṣe sí ìjọ.”—5:29.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́