“Ẹ Maa Baa Lọ Ní Rírìn Gẹgẹ Bi Awọn Ọmọ Ìmọ́lẹ̀”
“Gbé akopọ-animọ-iwa titun wọ̀ eyi ti a dá gẹgẹ bi ifẹ-inu Ọlọrun ninu ododo tootọ ati iduroṣinṣin.”—EFESU 4:24, NW.
1. Ki ni awọn ohun ti a fi bukun awọn olujọsin Jehofa? Eeṣe?
JEHOFA ỌLỌRUN ni “Baba ìmọ́lẹ̀,” “òkùnkùn kò sì sí lọdọ rẹ̀ rara.” (Jakọbu 1:17; 1 Johannu 1:5) Ọmọkunrin rẹ̀, Jesu Kristi, sọ nipa araarẹ̀ pe: “Emi ni ìmọ́lẹ̀ ayé; ẹni ti o bá tọ̀ mi lẹhin kì yoo rìn ninu òkùnkùn, ṣugbọn yoo ni ìmọ́lẹ̀ ìyè.” (Johannu 8:12) Nitori naa, awọn olujọsin tootọ ti Jehofa, awọn ọmọlẹhin Ọmọkunrin rẹ̀, ni a fi ìlàlóye bukun—niti ero-ori, iwarere, ati tẹmi—wọn sì “ń tàn gẹgẹ bi awọn olufunni ni ìmọ́lẹ̀ ninu ayé.”—Filippi 2:15, NW.
2. Iyatọ gédégédé wo laaarin awọn eniyan Ọlọrun ati ayé ni a sọtẹlẹ?
2 Tipẹ sẹhin, wolii Isaiah ni a mísí lati sọ asọtẹlẹ iyatọ gédégédé yii pe: “Nitori kiyesi i, òkùnkùn bo ayé mọ́lẹ̀, ati òkùnkùn biribiri bo awọn eniyan: ṣugbọn Oluwa yoo yọ lara rẹ, a o sì rí ògo rẹ̀ lara rẹ.” Niti tootọ, gbogbo iran eniyan ti a ti sọ dajeji si Ọlọrun ni a sọrọ nipa wọn pe wọn wà labẹ agbara idari awọn “alaṣẹ ibi òkùnkùn ayé yii.”—Isaiah 60:2; Efesu 6:12.
3. Fun awọn idi wo ni a fi ni ọkàn-ìfẹ́ gidigidi ninu imọran Paulu ti ó bá ìgbà mu?
3 Aposteli Paulu daniyan-ọkan gidigidi pe ki awọn Kristian ẹlẹgbẹ oun wà lominira kuro ninu iru òkùnkùn bẹẹ. Ó rọ̀ wọn pe ki wọn “maṣe rìn mọ́, àní gẹgẹ bi awọn Keferi ti ń rìn” ṣugbọn pe ki ‘wọn maa baa lọ ní rírìn gẹgẹ bi awọn ọmọ ìmọ́lẹ̀.’ (Efesu 4:17, NW; 5:8) Ó tun ṣalaye bi wọn ṣe lè kẹsẹjari ninu ṣiṣe eyi. Lonii, òkùnkùn ati ipokudu ti o bo awọn orilẹ-ede ti tubọ ṣúdudu sii. Ayé ti rì wọlẹ̀ sii sinu àfọ̀ ibajẹ iwarere ati tẹmi. Awọn olujọsin Jehofa ní ìjà-ogun ti ó ṣoro lati ṣẹgun ti ń ga sii lati jà. Nitori naa, a ni ọkàn-ìfẹ́ mimuna ninu ohun ti Paulu ni lati sọ.
Kẹkọọ Nipa Kristi
4. Ki ni Paulu ní lọkan nigba ti ó wi pe: “Ẹyin kò kẹkọọ pe Kristi rí bẹẹ”?
4 Lẹhin ṣiṣapejuwe awọn ilepa aláìlérè ati iwa-aimọ ti ayé, aposteli Paulu yí afiyesi rẹ̀ pada si awọn Kristian ẹlẹgbẹ rẹ̀ ni Efesu. (Jọwọ ka Efesu 4:20, 21, NW.) Paulu ti lo nǹkan bi ọdun mẹta ni wiwaasu ati kikọni ninu ilu-nla yẹn, oun sì ti gbọdọ mọ ọpọlọpọ ninu ijọ naa dunju funraarẹ. (Iṣe 20:31-35) Nipa bayii, nigba ti o sọ pe, “Ẹyin kò kẹkọọ pe Kristi ri bẹẹ,” oun ń sọ ohun ti oun funraarẹ mọ̀, pe awọn Kristian ará Efesu ni a kò kọ́ ni awọn ẹ̀dà otitọ onígbọ̀jẹ̀gẹ́, omilàró ti o fààyè gba iru iwa-aitọ wiwuwo ti oun ti ṣapejuwe ni ẹsẹ 17 si 19. Ó mọ pe a ti kọ́ wọn ni ọ̀nà igbesi-aye Kristian tootọ lọna ti ó bojumu ti ó sì péye gẹgẹ bi Jesu Kristi ti ṣapẹẹrẹ rẹ̀. Fun idi yẹn, wọn kò tún rìn ninu òkùnkùn mọ́ gẹgẹ bi awọn orilẹ-ede ti ṣe, ṣugbọn wọn jẹ́ ọmọ ìmọ́lẹ̀.
5. Iyatọ wo ni ó wà laaarin wíwà ninu otitọ ati níní otitọ ninu wa?
5 Ó ti ṣe pataki tó, nigba naa, lati ‘kẹkọọ Kristi’ ni ọ̀nà ti ó bojumu! Awọn ọ̀nà òdì lati kẹkọọ Kristi ha wà bi? Bẹẹni, nitootọ. Ni iṣaaju, ni Efesu 4:14, Paulu ti kilọ fun awọn ará pe: “Ki awa má baa jẹ́ ọmọ-ọwọ́ mọ́, ti a ń fi sọ̀kò kiri gẹgẹ bii lati ọwọ́ awọn ìgbì ti a sì ń gbé lọ sihin-in ati sọhun-un lati ọwọ́ olukuluku ẹfuufu ẹkọ nipasẹ iwa-agalamaṣa awọn eniyan, nipasẹ alumọkọrọyi ninu fifi ọgbọ́n-àyínìke humọ.” Ni kedere awọn kan wà ti wọn ti kẹkọọ nipa Kristi ṣugbọn ti wọn ṣì ń rìn ni awọn ọ̀nà ti ayé ti wọn tilẹ ń gbiyanju lati sun awọn miiran lati ṣe bẹẹ. Eyi ha fi ewu wiwulẹ wà ninu otitọ hàn wá bi, gẹgẹ bi awọn kan ti ń lo gbolohun-ọrọ naa, ni iyatọ gédégédé si jijẹ ki otitọ wà ninu wa? Ni ọjọ Paulu awọn wọnni ti wọn ní kìkì òye oréfèé ni awọn miiran ń fi tirọruntirọrun ati ni kiakia yí ni ironu pada, ohun kan-naa ni ó sì jẹ́ otitọ. Lati dena eyi, Paulu ń baa lọ lati sọ pe awọn ará Efesu ti nilati ‘gbọ́ Kristi ati pe a sì ti nilati kọ́ wọn nipasẹ Jesu.’—Efesu 4:21.
6. Bawo ni a ṣe lè kẹkọọ, gbọ́, ki a sì di ẹni ti a kọ́ nipasẹ Kristi lonii?
6 Awọn gbolohun-ọrọ naa “lati kẹkọọ,” “lati gbọ́,” ati “lati di ẹni ti a kọ́” ti Paulu lò ni gbogbo wọn dọgbọn tumọsi ọ̀nà igbakẹkọọ ati itọni, bi o ti maa ń rí ni ile-ẹkọ. Dajudaju, awa kò lè gbọ́, kẹkọọ lati ọ̀dọ̀, tabi di ẹni ti a kọ́ ni taarata nipasẹ Jesu funraarẹ lonii. Ṣugbọn oun ń dari igbetaasi imọ-ẹkọ Bibeli kari-aye kan nipasẹ “ẹrú oluṣotitọ ati ọlọgbọn-inu” rẹ̀. (Matteu 24:45-47; 28:19, 20) Awa lè ‘kẹkọọ Kristi’ lọna ti o bojumu ati lọna pipeye bi a bá ń jẹ ounjẹ tẹmi ti ẹgbẹ́ ẹrú naa pese lakooko, ti a ń kẹkọọ rẹ̀ taapọntaapọn yala gẹgẹ bi ẹnikan tabi ninu ijọ, ti a ń ronu jinlẹ lé e lori, ti a sì ń fi ohun ti a kọ́ silo. Ẹ jẹ ki a rí i daju pe a lo gbogbo awọn ipese naa ni kikun ki a baa lè sọ tootọtootọ pe a “gbọ́ ọ a sì ti tipasẹ rẹ̀ kọ́ wa.”
7. Ijẹpataki wo ni a lè rí ninu awọn ọ̀rọ̀ Paulu naa pe, “otitọ wà ninu Jesu”?
7 Ó fanilọkanmọra pe ni Efesu 4:21, lẹhin titẹnumọ ọ̀nà-ìgbàṣe ikọnilẹkọọ naa, Paulu fikun un pe: “Gan-an gẹgẹ bi otitọ ti wà ninu Jesu.” Awọn alálàyé Bibeli kan pe afiyesi si otitọ naa pe Paulu kò lo orukọ ara-ẹni Jesu funraarẹ deedee ninu awọn iwe rẹ̀. Nitootọ, eyi ni kìkì apẹẹrẹ iru ilo bẹẹ ninu lẹta ti ó kọ si awọn ará Efesu. Ijẹpataki akanṣe kan ha wà fun eyi bi? Boya Paulu ń pe afiyesi si apẹẹrẹ tí Jesu gẹgẹ bi ọkunrin kan fi lélẹ̀ ni. Ranti pe Jesu sọ nigbakan ri nipa araarẹ pe: “Emi ni ọ̀nà, ati otitọ, ati ìyè.” (Johannu 14:6; Kolosse 2:3) Jesu sọ pe: “Emi ni . . . otitọ” nitori pe oun kò wulẹ sọ ọ́ tabi fi í kọni nikan ni ṣugbọn ó gbé ni ibamu pẹlu otitọ ó sì fi ṣèwàhù. Bẹẹni, isin Kristian tootọ kìí wulẹ ṣe èrò kan lasan ṣugbọn ọ̀nà igbesi-aye. Lati ‘kẹkọọ Kristi’ wemọ kikẹkọọ lati ṣafarawe rẹ̀ ninu gbigbe ni ibamu pẹlu otitọ. Iwọ ha ń mú ki ọ̀nà ìgbàgbé igbesi-aye tìrẹ dabii ti Jesu bi? Iwọ ha ń tẹle awọn iṣisẹ rẹ̀ timọtimọ lojoojumọ bi? Kìkì nipa ṣiṣe bẹẹ ni a fi lè maa baa lọ ni rírìn gẹgẹ bi awọn ọmọ ìmọ́lẹ̀.
“Ẹ Bọ́ Akopọ-animọ-iwa Ogbologboo naa Silẹ”
8. Àkàwé wo ni Paulu lò ni Efesu 4:22, 24, eesitiṣe ti o fi bamu?
8 Lati fihàn bi a ṣe lè fi ikẹsẹjari ‘kẹkọọ Kristi’ ki a sì rìn gẹgẹ bi awọn ọmọ ìmọ́lẹ̀, Paulu ń baa lọ lati sọ, ni Efesu 4:22-24, pe awọn igbesẹ mẹta ọtọọtọ ti a gbọdọ tẹle wà. Akọkọ ninu iwọnyi ni pe: “Ẹ nilati bọ́ akopọ-animọ-iwa ogbologboo naa silẹ, eyi ti o bá ipa-ọna iwa yin ti iṣaaju ṣedeedee ati eyi ti a ń sọ dibajẹ gẹgẹ bi awọn ìfẹ́-ọkàn itannijẹ rẹ̀.” (Efesu 4:22, NW) Awọn gbolohun-ọrọ naa “bọ́ silẹ” (“bọ́ kuro,” Kingdom Interlinear) ati “gbé wọ̀” (ẹsẹ 24) pe aworan afinuro ti bíbọ́ ẹ̀wù kan kuro ati gbígbé e wọ̀ wá sọkan. Eyi jẹ́ àfiwé-ẹlẹ́lọ̀ọ́ ti Paulu sábà maa ń lò, ó sì jẹ́ ọ̀kan ti ó gbéṣẹ́. (Romu 13:12, 14; Efesu 6:11-17; Kolosse 3:8-12; 1 Tessalonika 5:8) Nigba ti ẹ̀wù wa bá dọ̀tí tabi lábàwọ́n, iru bii ni akoko ounjẹ, lọgan ni a ó pa á dà bi ààyè bá ti ṣí silẹ. Kò ha yẹ ki a daniyan-ọkan nipa idọti eyikeyii nipa ipo tẹmi wa bi?
9. Ni ọ̀nà wo ni ẹnikan ń gbà bọ́ akopọ-animọ-iwa ogbologboo silẹ?
9 Bawo, nigba naa, ni ẹnikan ṣe ń bọ́ akopọ-animọ-iwa ogbologboo silẹ? Ọ̀rọ̀-ìṣe naa “bọ́ silẹ” ni èdè ipilẹṣẹ wà ni ohun ti a ń pe ni ọ̀rọ̀-ìṣe atọka iṣẹlẹ laitọka akoko. Ó tọka si igbesẹ kan ti a gbé lẹẹkanṣoṣo gíro tabi lẹẹkan fun gbogbo ìgbà. Eyi sọ fun wa pe “akopọ-animọ-iwa ogbologboo” (“ogbologboo ọkunrin,” Kingdom Interlinear), papọ pẹlu ‘ipa-ọna iwa wa atijọ,’ ni a gbọdọ bọ́ silẹ pẹlu igbesẹ pato ati onipinnu, jalẹjalẹ ati patapata. Kìí ṣe ohun kan ti a lè kẹ́sẹjárí nipa rẹ̀ bi a bá ṣẹṣẹ ń pèrò sii tabi tilẹ lọ́ra. Eeṣe ti kò fi rí bẹẹ?
10. Eeṣe ti ẹnikan fi nilati jẹ́ aduro gbọnyingbọnyin ati onipinnu ninu bíbọ́ akopọ-animọ-iwa ogbologboo danu?
10 Gbolohun-ọrọ naa, “ti a ń sọ dibajẹ” fihàn pe “ogbologboo ọkunrin naa” wà ni ipa-ọna ilọsilẹ iwarere ti ń baa lọ ati ni ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé, tí ń lọ lati ori buburu si buburu jù. Niti tootọ, nitori kíkọ ìlàlóye tẹmi silẹ, gbogbo araye ń ṣubúlébú. Eyi jẹ́ abajade “awọn ìfẹ́-ọkàn ìtannijẹ,” ni Paulu sọ. Awọn ìfẹ́-ọkàn jẹ́ atannijẹ nitori pe wọn lè farahan bi alailepanilara, ṣugbọn wọn jẹ́ aṣeparun nigbẹhin-gbẹhin. (Heberu 3:13) Bi a kò bá dá a duro, opin naa yoo jẹ́ isọdẹgbin ati ikú. (Romu 6:21; 8:13) Idi niyẹn ti a fi gbọdọ bọ́ akopọ-animọ-iwa ogbologboo silẹ, ki a bọ́ ọ kuro tipinnu-tipinnu ati patapata, ni ọ̀nà ti a gbà ń bọ́ ẹ̀wù didọti kan, ti ó ti gbó, kuro.
“Ẹmi Ero-inu” Titun Kan
11. Nibo ni isọdọtun tẹmi ti nilati bẹrẹ?
11 Ẹnikan ti o ti inu ẹrẹ̀ jade kì yoo nilati bọ́ awọn aṣọ rẹ̀ ti ó ti dọ̀tí kuro nikan ni ṣugbọn ó tun nilati wẹ araarẹ mọ tonitoni ṣaaju ki ó tó wọ ohun kan ti ó rí nigín-nigín ti ó sì mọ́ tonitoni. Ohun ti Paulu kọ silẹ gẹgẹ bi igbesẹ keji si ìlàlóye tẹmi gan-an niyẹn: “A nilati sọ yin di titun ninu ipá ti ń sún ero-inu yin ṣiṣẹ.” (Efesu 4:23) Gẹgẹ bi o ti ṣalaye ni iṣaaju, ni ẹsẹ 17 ati 18, awọn orilẹ-ede ń rìn “ninu àìlérè ero-inu wọn” ‘ero-ori wọn sì wà ninu òkùnkùn.’ Lọna ti ó bá ọgbọn mu, ero-inu, ibùdó ìfòyemọ̀ ati ìlóye, ni ibi ti isọdọtun naa ti gbọdọ bẹrẹ. Bawo ni a ṣe lè ṣe eyi? Paulu ṣalaye pe ó jẹ́ nipa sisọ ipá tí ń sún ero-inu wa ṣiṣẹ dọtun. Ki ni ipá yẹn?
12. Ki ni ipá tí ń sún ero-inu ṣiṣẹ?
12 Ẹmi mímọ́ ha ni ipá tí ń sún ero-inu wa ṣiṣẹ, ti Paulu tọka si bi? Bẹẹkọ. Àpólà-ọ̀rọ̀ naa “ipá tí ń sún ero-inu yin ṣiṣẹ” ni olówuuru kà pe “ẹmi ero-inu tiyin.” Kò sí ibikankan ninu Bibeli ti a ti sọrọ nipa ẹmi mimọ Ọlọrun gẹgẹ bi eyi ti ó jẹ́ ti eniyan tabi jẹ apakan eniyan kan. Ọ̀rọ̀ naa “ẹmi” ni ipilẹ tumọsi “èémí,” ṣugbọn a tun lò ó ninu Bibeli “lati duro fun ipá ti ń sún ẹnikan lati fi iru iṣarasihuwa, ìtẹ̀sí èrò-inú, tabi ero-imọlara kan hàn tabi gbé iru igbesẹ tabi gba ipa-ọna kan.” (Insight on the Scriptures, Idipọ 2, oju-iwe 1026) Nitori naa “ẹmi ero-inu” ni ipá tí ń mú tabi sún ero-inu wa ṣiṣẹ, ìtẹ̀sí ero-ori tabi ìtẹ̀sí-ọkàn tiwa funraawa.
13. Eeṣe ti a fi gbọdọ sọ ìtẹ̀sí ero-ori wa di titun?
13 Ìtẹ̀sí tí ó bá iwa ẹ̀dá mu naa ati ìtẹ̀sí-ọkàn tí ero-inu alaipe jẹ́ siha awọn ohun ti ara, ẹran-ara, ati ti ọrọ̀-àlùmọ́nì. (Oniwasu 7:20; 1 Korinti 2:14; Kolosse 1:21; 2:18) Àní bi ẹnikan bá tilẹ bọ́ akopọ-animọ-iwa ogbologboo naa silẹ pẹlu awọn iṣe-aṣa buburu rẹ̀, ìtẹ̀sí ero-ori rẹ̀ ti ó kun fun ẹṣẹ bi kò bá yipada laipẹ tabi laijinna yoo mú un lápàpàǹdodo lati pada si ohun ti o ti patì. Eyi kìí ha ṣe iriri ọpọlọpọ ti wọn ti gbiyanju, fun apẹẹrẹ, lati pa siga mímu, ọtí-àmujù, tabi awọn iṣe-aṣa buburu miiran tì bi? Bi wọn kò bá ṣe isapa lati di titun ninu ipá ti ń sún ero-inu wọn ṣiṣẹ, àtúnpadà ni ó fẹrẹẹ maṣe yẹra fun. Iyipada gidi eyikeyii gbọdọ wemọ yíyí ero-inu pada jalẹjalẹ.—Romu 12:2.
14. Bawo ni ipá ti ń sún ero-inu ṣiṣẹ ṣe lè di eyi ti a sọ di titun?
14 Bawo, nigba naa, ni ẹnikan ṣe lè sọ ipá yẹn di titun ki o baa lè jẹ pe yoo tẹ ero-inu ẹni si ìhà títọ́? Ọ̀rọ̀-ìṣe naa “di titun” ninu ọrọ-ẹsẹ-iwe Griki ń tọ́ka lọwọlọwọ, ni ṣiṣalaye igbesẹ tí ń baa lọ. Nitori naa ó jẹ́ nipa bibaa lọ lati kẹkọọ Ọ̀rọ̀ otitọ ti Ọlọrun ati rironu jinlẹ lori ohun ti ó tumọsi ni ipá tí ń súnni ṣiṣẹ naa tó lè di eyi ti a sọ di titun. Awọn onimọ ijinlẹ sọ fun wa pe ninu ọpọlọ wa, isọfunni ti a fi awọn àmì bii ti iná manamana tabi kẹ́míkà kójọ ń lọ lati ara lajori sẹẹli ọpọlọ kan si omiran, ti ó sì ń sọda awọn ìsokọ́ra ti ó wà gẹgẹ bi alafo ààyè tóóró laaarin awọn ṣẹẹli ọpọlọ. “Iru irannileti kan ni a ń dá silẹ laaarin alafo tóóró ti ń bẹ ninu iṣan nigba ti ikojọpọ àmì naa bá gba inú rẹ̀ kọja, ti yoo sì fi ojú ipasẹ kọọkan silẹ sẹhin,” ni iwe naa The Brain sọ. Nigba ti àmì kan-naa bá kọja ni ìgbà miiran, awọn sẹẹli iṣan naa yoo dá a mọ̀ wọn yoo sì tubọ yara dahunpada. Bi akoko ti ń lọ, eyi yoo ṣẹ̀dá ọ̀nà igbaronu titun kan ninu ẹni naa. Bi a ti ń tẹpẹlẹmọ ọn lati maa gba isọfunni tẹmi ti o peye sinu, ọ̀nà ironu titun kan ni a ń gbéró, ipá tí ń sún ero-inu wa ṣiṣẹ ni a sì ń sọ di titun.—Filippi 4:8.
‘Ẹ Gbé Akopọ-animọ-iwa Titun Wọ̀’
15. Ni èrò itumọ wo ni akopọ-animọ-iwa titun fi jẹ́ titun?
15 Lakootan, Paulu sọ pe: “Ẹ sì nilati gbé akopọ-aimọ-iwa titun wọ̀ eyi ti a dá gẹgẹ bi ìfẹ́-inú Ọlọrun ninu òdodo tootọ ati iduroṣinṣin.” (Efesu 4:24, NW) Bẹẹni, Kristian kan gbé akopọ-animọ-iwa titun kan wọ̀. “Titun” nihin-in tọka si, kìí ṣe akoko, bikoṣe ijojulowo. Iyẹn ni pe, kìí ṣe titun ni ero itumọ ti jijẹ ẹ̀dà ti o dé kẹhin. Ó jẹ́ akopọ-animọ-iwa titun patapata, ti o tutùyọ̀yọ̀, “ti a dá gẹgẹ bi ìfẹ́-inú Ọlọrun.” Ni Kolosse 3:10, Paulu lo èdè kan-naa ó sì sọ pe oun ni a ń “sọ di titun . . . gẹgẹ bi aworan ẹni ti ó dá a.” Bawo ni akopọ-animọ-iwa titun yii ṣe wá?
16. Eeṣe ti a fi lè sọ pe akopọ-animọ-iwa titun ni “a dá ni ibamu pẹlu ifẹ-inu Ọlọrun”?
16 Jehofa Ọlọrun dá ẹ̀dá eniyan meji akọkọ, Adamu ati Efa, ni aworan ati jíjọ Rẹ̀. A fi awọn animọ iwarere ati tẹmi jíǹkí wọn eyi ti o yà wọn sọtọ kuro ti o sì mú ki wọn ju awọn ẹda ẹranko lọ fíìfíì. (Genesisi 1:26, 27) Àní bi o tilẹ jẹ pe iṣọtẹ wọn ri gbogbo araye sinu ẹṣẹ ati aipe, awa, gẹgẹ bi iran-atẹle Adamu, ṣì ní agbara lati fi awọn animọ iwarere ati tẹmi hàn. Ifẹ-inu Ọlọrun ni pe awọn wọnni ti wọn ń lo igbagbọ ninu ẹbọ irapada kò nilati ni ohunkohun ṣe pẹlu akopọ-animọ-iwa ogbologboo ki wọn baa lè gbadun “ominira ògo awọn ọmọ Ọlọrun.”—Romu 6:6; 8:19-21; Galatia 5:1, 24.
17. Eeṣe ti òdodo ati iduroṣinṣin fi jẹ́ animọ titayọ ti akopọ-animọ-iwa titun naa?
17 Òdodo ati iduroṣinṣin tootọ ni awọn animọ meji ti Paulu dá fihàn gedegbe gẹgẹ bi eyi ti ń gbé akopọ-animọ-iwa titun naa yọ. Eyi tẹnumọ ọn siwaju sii pe akopọ-animọ-iwa titun naa ni a ń sọ di titun ni ibamu pẹlu aworan Ẹni ti ó dá a. Orin Dafidi 145:17 (NW) sọ fun wa pe: “Jehofa jẹ́ olódodo ni gbogbo awọn ọ̀nà rẹ̀ ati aduroṣinṣin ninu gbogbo iṣẹ rẹ̀.” Ìfihàn 16:5 (NW) sì sọ nipa Jehofa pe: “Iwọ, Ẹni ti ń bẹ ti o sì ti wà, Aduroṣinṣin, jẹ́ olódodo.” Loootọ, òdodo ati iduroṣinṣin jẹ́ animọ ti o pọndandan bi awa yoo bá huwa gẹgẹ bi ẹni ti a dá ni aworan Ọlọrun, ni gbigbe ògo rẹ̀ yọ. Ǹjẹ́ ki a dabi Sekariah, baba Johannu Arinibọmi, ẹni ti ẹmi mimọ sún lati yin Ọlọrun fun yiyọnda ti o yọnda fun awọn eniyan Rẹ̀ lati “lè maa sìn ín laifoya, ni mímọ́ iwa ati ni òdodo.”—Luku 1:74, 75.
“Ẹ Maa Baa Lọ Ní Rírìn Gẹgẹ Bi Awọn Ọmọ Ìmọ́lẹ̀”
18. Bawo ni Paulu ṣe ràn wá lọwọ lati rí awọn ọ̀nà ayé gẹgẹ bi wọn ti rí niti gidi?
18 Lẹhin ti a ti ṣe agbeyẹwo kulẹkulẹ awọn ọ̀rọ̀ Paulu ni Efesu 4:17-24, awa ni ohun pupọ lati ronu lé lori. Ni ẹsẹ 17 si 19, Paulu ràn wá lọwọ lati ri awọn ọ̀nà ayé gẹgẹ bi wọn ti rí niti gidi. Kíkọ ìmọ̀ nipa Ọlọrun silẹ ati mímú ọkan-aya wọn le gbagidi siha ọ̀dọ̀ rẹ̀, awọn wọnni ti wọn ṣì wà ninu ayé ti ké araawọn kuro lọdọ orisun ìyè tootọ naa. Nitori idi eyi, bi wọn kò ti ní ète tabi itọsọna tootọ, awọn ìsapa wọn ń pari si iwa-omugọ ati omulẹmofo. Wọn ń rì wọnu ibajẹ iwarere ati tẹmi sii ṣáá ni. Ẹ wo iru ipo aṣenilaaanu ti eyi jẹ́! Idi alagbara wo sì ni eyi jẹ́ fun wa lati pinnu lati maa baa lọ ní rírìn gẹgẹ bi awọn ọmọ ìmọ́lẹ̀!
19. Iṣiri ikẹhin wo ni a ní lati ọ̀dọ̀ Paulu lati maa baa lọ ní rírìn gẹgẹ bi awọn ọmọ ìmọ́lẹ̀?
19 Lẹhin naa, ni ẹsẹ 20 ati 21, Paulu tẹnumọ ijẹpataki kikẹkọọ otitọ ni pẹrẹwu ki o má baa jẹ́ pe a wulẹ ń darapọ mọ́ otitọ ṣugbọn ki a maa huwa ni ibamu pẹlu rẹ̀ gẹgẹ bi Jesu ti ṣe. Lakootan, ni ẹsẹ 22 si 24, ó gbà wá niyanju lati bọ́ akopọ-animọ-iwa ogbologboo danu ki a sì gbé titun wọ̀—tipinnu-tipinnu, lọna ti o ṣe gbọnyingbọnyin. Ni akoko yii ná, a gbọdọ maa baa lọ ni dídarí awọn ìtẹ̀sí ero-ori wa ni ọ̀nà pipeye, siha tẹmi. Lékè gbogbo rẹ̀, a gbọdọ maa wo Jehofa fun iranlọwọ bi a ti ń baa lọ ní rírìn gẹgẹ bi awọn ọmọ ìmọ́lẹ̀. “Nitori Ọlọrun, ẹni ti o wi pe ki ìmọ́lẹ̀ ki ó mọ́lẹ̀ lati inu òkùnkùn jade, oun ni o ti ń mọ́lẹ̀ ni ọkàn wa, lati fun wa ni ìmọ́lẹ̀ ìmọ̀ ògo Ọlọrun ni oju Jesu Kristi.”—2 Korinti 4:6.
Iwọ Ha Ranti Bi?
◻ Bawo ni a ṣe lè ‘kẹkọọ Kristi’ lonii?
◻ Eeṣe ti a fi gbọdọ bọ́ akopọ-animọ-iwa ogbologboo silẹ tipinnutipinnu?
◻ Ki ni ipá ti ń sún ero-inu ṣiṣẹ, bawo ni a sì ṣe sọ ọ́ di titun?
◻ Awọn animọ wo ni ó sami si akopọ-animọ-iwa titun naa?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Jesu sọ pe: “Emi ni ọ̀nà, ati otitọ, ati ìyè”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
“Ẹ bọ́ akopọ-animọ-iwa ogbologboo danu pẹlu awọn iṣe-aṣa rẹ̀”—ìkannú, ibinu, iwa-buburu, ọ̀rọ̀ èébú, ọ̀rọ̀ àlùfààsá, ati irọ́ pípa.—Kolosse 3:8, 9, “NW”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
“Ẹ . . . gbé akopọ-animọ-iwa titun wọ̀ . . . ti a dá gẹgẹ bi ìfẹ́-inú Ọlọrun ninu òdodo ati iduroṣinṣin.”—Efesu 4:24, “NW”