ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w93 2/15 ojú ìwé 17-22
  • Mímú Animọ-iwa Titun Dagba Ninu Igbeyawo

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Mímú Animọ-iwa Titun Dagba Ninu Igbeyawo
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Didojukọ Awọn Masunmawo Igbeyawo
  • Sọ Ipá naa Di Alagbara
  • Awọn Apẹẹrẹ Iwa Yiyatọsira Gédégédé
  • Sọ Ìdè Igbeyawo naa Di Alagbara
  • Bí Tọkọtaya Ṣe Lè Láyọ̀ Lóde Òní
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
  • Máa Jẹ́ Kí Ìgbéyàwó Rẹ Jẹ́ “Okùn Onífọ́nrán Mẹ́ta”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Mú Kí Ìgbéyàwó Rẹ Jẹ́ Ìsopọ̀ Wíwàpẹ́títí
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Ìgbéyàwó Jẹ́ Ẹ̀bùn Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run Tó Nífẹ̀ẹ́ Wa
    ‘Ẹ Dúró Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run’
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
w93 2/15 ojú ìwé 17-22

Mímú Animọ-iwa Titun Dagba Ninu Igbeyawo

“Ki ẹ sì di titun ni ẹmi inu yin; ki ẹ sì gbé ọkunrin titun nì wọ̀.”—EFESU 4:23, 24.

1. Eeṣe ti a kò fi nilati fọwọ dẹngbẹrẹ mu igbeyawo?

IGBEYAWO jẹ́ ọ̀kan lara awọn igbesẹ ti ó gba ironujinlẹ julọ ti ẹnikan lè gbé ninu igbesi-aye, nitori naa a kò nilati fọwọ dẹngbẹrẹ mú un. Eeṣe ti iyẹn fi rí bẹẹ? Idi ni pe ó beere fun ẹ̀jẹ́-àdéhùn titi ayé fun ẹlomiran. Ó tumọsi ṣiṣajọpin gbogbo igbesi-aye ẹni pẹlu ẹni yẹn. Iṣediyele ti a fi idagbadenu ṣe jẹ́ àìní-ọ̀rayàn bi ẹ̀jẹ́-àdéhùn yẹn yoo bá yekooro. Ó tun beere fun agbara-idari agbeniro ‘ti ń sún ero-inu ṣiṣẹ ti ó sì ń tipa bẹẹ pinnu ohun ti animọ-iwa titun naa yoo jẹ́.’—Efesu 4:23, 24; fiwe Genesisi 24:10-58; Matteu 19:5, 6.

2, 3. (a) Ki ni a nilo lati yan ẹnikeji ninu igbeyawo lọna ti ó bọgbọn mu? (b) Ki ni ó wémọ́ igbeyawo?

2 Idi rere wà lati maṣe sáré kówọnú igbeyawo, lati maṣe di ẹni ti ifẹkufẹẹ ti ara ń yára lo agbara-idari lé lori ti ó sì ṣẹ́pá rẹ̀. Akoko ni a nilo fun animọ-iwa ati iṣe agbalagba lati gbèrú. Iriri ati ìmọ̀ ti o lè ṣiṣẹ gẹgẹ bi ipilẹ fun ipinnu yiyekooro ti a farabalẹ ṣe tun ń bá akoko rìn pẹlu. Lẹhin naa, yíyan ẹnikeji-ẹni ti ó banidọgba ninu igbesi-aye lè ní ìwọ̀n ikẹsẹjari ti o gadabú. Owe awọn ará Spain kan sọ ọ́ ni kedere pe: “Ó sàn lati rìn ni àpọ́n ju lati ṣi igbeyawo ṣe lọ.”—Owe 21:9 Oniwasu 5:2.

3 Yíyan ẹnikeji ti ó tọ́ ṣe pataki lọna ti ó hàn gbangba fun igbeyawo ti ó kẹsẹjari. Fun iyẹn Kristian naa nilati tẹle awọn ilana-itọsọna ti o bá Bibeli mu, lai di ẹni ti òòfà ti ara lasan ati awọn ikimọlẹ ti ero-imọlara ati ti ifẹ eléré-ìfẹ́ ń dari. Igbeyawo fi pupọpupọ ju siso ara meji papọ lọ. Ó jẹ́ siso awọn animọ-iwa meji, idile ati ipilẹ ẹkọ-iwe meji, boya iṣẹdalẹ ati èdè meji paapaa papọ. Siso awọn meji pọ ṣọkan ninu igbeyawo dajudaju ń beere fun lílo ahọ́n lọna títọ́; pẹlu agbara ọrọ-sisọ, a lè banijẹ tabi gbeniro. Lati inu gbogbo eyi, a tun ri ọgbọn imọran Paulu lati ‘gbeyawo kìkì ninu Oluwa,’ iyẹn ni pe, onigbagbọ ẹlẹgbẹ-ẹni.—1 Korinti 7:39; Genesisi 24:1-4; Owe 12:18; 16:24.

Didojukọ Awọn Masunmawo Igbeyawo

4. Eeṣe ti aáwọ̀ ati aifararọ fi maa ń dide nigba miiran ninu igbeyawo?

4 Àní pẹlu ipilẹ rere paapaa, awọn akoko aáwọ̀, ikimọlẹ, ati aìfararọ yoo wà. Iwọnyi wà deedee fun ẹnikẹni, yala a ti gbeyawo tabi bẹẹkọ. Awọn iṣoro iṣunna-owo ati ti ilera lè ṣokunfa masunmawo ninu ipo-ibatan eyikeyii. Awọn iyipada ninu iwa lè ṣamọna si ìkọlura ti animọ-iwa ninu awọn igbeyawo ti o dara julọ. Kókó abajọ miiran ni pe kò sí ẹni ti ó ni akoso pipe lori ahọ́n rẹ̀, gẹgẹ bi Jakọbu ti sọ: “Ninu ohun pipọ ni gbogbo wa ń ṣì í ṣe. Bi ẹnikan kò bá ṣì í ṣe ninu ọ̀rọ̀, oun naa ni ẹni pipe, oun ni ó sì lè kó gbogbo ara ni ijanu. . . . Ahọ́n jẹ́ ẹ̀yà kekere, ó sì ń fọ́nnu ohun ńlá. Wo igi ńlá ti ina kekere ń sun jona!”—Jakọbu 3:2, 5.

5, 6. (a) Ki ni a nilo nigba ti edekoyede bá dide? (b) Igbesẹ wo ni a lè nilati gbé lati wo iyapa inu ajọṣepọ kan sàn?

5 Nigba ti awọn ikimọlẹ bá dide ninu igbeyawo, bawo ni a ṣe lè ṣakoso ipo naa? Bawo ni a ṣe lè dá edekoyede duro lati maṣe gbèrú di ìjà ki ìjà sì wa jalẹ si ipoibatan ti a ba alaafia rẹ̀ jẹ́? Nihin-in ni ipá ti ń sún ero-inu ṣiṣẹ ti wọnu ọ̀ràn naa. Ẹmi ti ń sunniṣiṣẹ yii lè jẹ́ yala onifojusọna fun rere tabi òdì, agbeniro ati eyi ti o tẹ̀ siha tẹmi tabi arẹninípòwálẹ̀, tí awọn itẹsi-ọkan ti ẹran-ara ń ṣakoso. Bi ó bá ń gbeniro, ẹnikọọkan yoo gbegbeesẹ lati wo iyapa inu ajọṣepọ naa sàn, lati pa igbeyawo rẹ̀ lọkunrin tabi lobinrin mọ́ soju-ọna títọ́. Iyàn ati edekoyede kò nilati fopin si igbeyawo kan. A lè mú ohun ti ó fa edekoyede kuro ki a sì mú ọ̀wọ̀ tọtuntosi ati àgbọ́yé padabọsipo nipa fifi imọran Bibeli silo.—Romu 14:19; Efesu 4:23, 26, 27.

6 Labẹ awọn ipo ayika wọnyi awọn ọ̀rọ̀ Paulu baamu wẹku pe: “Nitori naa, bi ayanfẹ Ọlọrun, ẹni mimọ ati olufẹ, ẹ gbé ọkàn ìyọ́nú wọ̀, iṣeun, irẹlẹ, inu tutu, ipamọra; ẹ maa farada a fun ara yin, ẹ sì maa dariji ara yin bi ẹnikẹni bá ni ẹ̀sùn si ẹnikan: bi [Jehofa, NW] ti dariji yin, gẹgẹ bẹẹ ni ki ẹyin ki o maa ṣe pẹlu. Ati bori gbogbo nǹkan wọnyi, ẹ gbé ifẹ wọ̀, tii ṣe amure iwa pipe.”—Kolosse 3:12-14.

7. Iṣoro wo ni awọn kan lè ni ninu igbeyawo wọn?

7 Ọrọ-ẹsẹ iwe mimọ yẹn rọrun lati kà, ṣugbọn labẹ ikimọlẹ igbesi-aye ode-oni, kò maa ń fi ìgbà gbogbo rọrun lati fisilo. Ki ni o lè jẹ́ iṣoro pataki kan? Nigba miiran, laimọ ọn, Kristian kan lè maa gbé pẹlu ọpa-idiwọn meji. Ni Gbọngan Ijọba, ó wà laaarin awọn ara, ó sì ń fi inurere ati igbatẹniro huwa. Lẹhin naa, lọhun-un ni ile, ninu igbokegbodo inu ile, ó lè ni itẹsi lati gbagbe ipo-ibatan tẹmi rẹ̀. Nibẹ ọkunrin ati iyawo rẹ̀ lasan ni, “tòun” “tìrẹ.” Ati labẹ ikimọlẹ oun lọkunrin (tabi lobinrin) lè pari rẹ̀ si sisọ awọn ohun alaininuure ti oun kò nii sọ lae ni Gbọngan Ijọba. Ki ni ó ti ṣẹlẹ? Fun sáà kukuru kan, animọ-iwa Kristian rẹ̀ ti pòórá. Iranṣẹ Ọlọrun ti gbagbe pe oun lọkunrin (tabi lobinrin) ṣì jẹ́ Kristian arakunrin (tabi arabinrin) kan ni ile. Ipá ti ń sún ero-inu ṣiṣẹ ti di alaigbeniro dipo ki ó jẹ́ ti agbeniro.—Jakọbu 1:22-25.

8. Ki ni ó lè yọrisi nigba ti ipá tí ń sún ero-inu ṣiṣẹ bá jẹ́ ti òdì?

8 Ki ni iyọrisi rẹ̀? Ọkọ naa lè dawọ duro lati ‘gbé pẹlu aya rẹ̀ ni ibamu pẹlu ìmọ̀, ni fifi ọlá fun un gẹgẹ bi oun eelo ti kò ni agbara, eyi ti i ṣe obinrin.’ Aya lè má bọ̀wọ̀ fun ọkọ rẹ̀ mọ́; “ẹmi irẹlẹ ati ẹmi tutu” rẹ̀ ni o ti sọnu. Ipá ti ń sún ero-inu ṣiṣẹ ti di ti ara dipo tẹmi. “Ọna-igbekalẹ ero-inu ti ẹran-ara” kan ti gbapò. Nitori naa, ki ni a lè ṣe lati pa ipá ti ń sunniṣiṣẹ yẹn mọ́ ní tẹmi ati agbeniro? A gbọdọ fun ipo tẹmi wa lokun.—1 Peteru 3:1-4, 7; Kolosse 2:18.

Sọ Ipá naa Di Alagbara

9. Awọn yíyàn wo ni a nilati ṣe ninu igbesi-aye ojoojumọ?

9 Ipá ti ń sunniṣiṣẹ naa ni itẹsi ero-ori ti ń ṣiṣẹ nigba ti a bá nilati ṣe awọn ipinnu ati yíyàn. Igbesi-aye ń nawọ́ oniruuru yíyàn síni lemọlemọ—rere tabi buburu, onimọtara-ẹni-nikan ati alaimọtara-ẹni-nikan, oniwarere ati oniwapalapala. Ki ni yoo ràn wá lọwọ lati ṣe awọn ipinnu ti o tọ́? Bi ipá ti ń sún ero-inu ṣiṣẹ bá kori afiyesi jọ si ṣiṣe ifẹ-inu Jehofa. Olorin naa gbadura pe: “Oluwa, kọ́ mi ni ọ̀nà rẹ; emi ó sì maa pa á mọ́ de opin.”—Orin Dafidi 119:33; Esekieli 18:31; Romu 12:2.

10. Bawo ni a ṣe lè sọ ipá tí ń sún ero-inu ṣiṣẹ di alagbara lọna kan ti ń gbeniro?

10 Ipo-ibatan lilagbara pẹlu Jehofa yoo ràn wá lọwọ lati wù ú ki a sì yipada kuro ninu ibi, titikan aiṣotitọ ninu igbeyawo. Israeli ni a fun ni iṣiri lati “ṣe eyi ti ó dara ti ó sì tọ́ ni oju OLUWA Ọlọrun [wọn].” Ṣugbọn Ọlọrun tun gbaninimọran pe: “Ẹyin ti ó fẹ́ Oluwa, ẹ koriira ibi.” Ni oju-iwoye ikeje ninu awọn Ofin Mẹwaa: “Iwọ kò gbọdọ ṣe panṣaga,” awọn ọmọ Israeli nilati koriira panṣaga. Ofin yẹn fi oju-iwoye aláìgbagbẹ̀rẹ́ ti Ọlọrun ninu igbeyawo hàn.—Deuteronomi 12:28; Orin Dafidi 97:10; Eksodu 20:14; Lefitiku 20:10.

11. Bawo ni a ṣe lè fokunfun ipá tí ń sún ero-inu ṣiṣẹ siwaju sii?

11 Bawo ni a ṣe lè fun ipá ti ń sún ero-inu ṣiṣẹ lókun siwaju sii? Nipa mimọriri awọn igbokegbodo ati awọn iniyelori tẹmi. Iyẹn tumọsi pe a gbọdọ tẹ́ aini lati kẹkọọ Ọ̀rọ̀ Ọlọrun deedee lọ́rùn a sì gbọdọ kọ́ lati ní idunnu ninu jijiroro awọn èrò ati imọran Jehofa papọ. Awọn ironu-imọlara atọkanwa wa nilati dabi ti olorin wọnni: “Tinu-tinu mi gbogbo ni emi fi ṣe àfẹ́rí rẹ: maṣe jẹ ki emi ṣina kuro ninu àṣẹ rẹ. Ọ̀rọ̀ rẹ ni mo pamọ ni àyà mi, ki emi ki ó má baa ṣẹ̀ sí ọ. Oluwa, kọ́ mi ni ọ̀nà rẹ; emi ó sì maa pa á mọ́ de opin. Fun mi ni òye, emi ó sì pa ofin rẹ mọ́; nitootọ, emi ó maa kiyesi i tinu-tinu mi gbogbo.”—Orin Dafidi 119:10, 11, 33, 34.

12. Awọn nǹkan wo ni wọn lè so wá pọ̀ ninu fifi ero-inu Kristi hàn?

12 Iru imọriri yii fun awọn ilana ododo ti Jehofa ni a ń pamọ kìí ṣe kìkì nipa kikẹkọọ Bibeli nikan ni bikoṣe nipa ṣiṣajọpin deedee ninu awọn ipade Kristian ati nipa lilọwọ ninu iṣẹ-ojiṣẹ Kristian papọ pẹlu. Awọn agbara-idari lilagbara meji wọnyi lè fun ipá tí ń sún ero-inu wa ṣiṣẹ lókun lemọlemọ debi pe ọ̀nà igbesi-aye alainimọtara-ẹni-nikan wa yoo maa fi ero-inu Kristi hàn nigba gbogbo.—Romu 15:5; 1 Korinti 2:16.

13. (a) Eeṣe ti adura fi jẹ́ kókó abajọ ṣiṣeyebiye ninu sisọ ipá tí ń sún ero-inu ṣiṣẹ di alagbara? (b) Apẹẹrẹ wo ni Jesu fi lélẹ̀ ni ọ̀nà yii?

13 Kókó abajọ miiran ni ohun ti Paulu tẹnumọ ninu lẹta rẹ̀ si awọn ará Efesu: “Pẹlu gbogbo adura ati ẹ̀bẹ̀, . . . ẹ maa gbadura nigba gbogbo ninu ẹmi.” (Efesu 6:18) Awọn ọkọ ati aya nilati gbadura papọ. Niye ìgbà awọn adura wọnni ń ṣí ọkan-aya ó sì maa ń ṣamọna si awọn ijumọsọrọpọ alaifọrọ sabẹ ahọ́n ti ń wo iyapa eyikeyii sàn. Ni awọn akoko idanwo ati idẹwo, a nilati yiju si Ọlọrun ninu adura, ni bibeere fun iranlọwọ, fun okun tẹmi lati ṣe ohun ti ó wà ni ibamu pẹlu ero-inu Kristi. Àní Jesu ti ó jẹ́ ẹni pipe paapaa yiju si Baba rẹ̀ ninu adura ni ọpọlọpọ ìgbà, ni bibeere fun okun. Awọn adura rẹ̀ jẹ́ tọkantọkan ó sì gbona janjan. Bakan naa lonii, ni awọn akoko idẹwo, a lè rí okun lati ṣe ipinnu títọ́ nipa kikepe Jehofa lati ràn wá lọwọ lati dena ìfẹ́-ọkàn lati juwọsilẹ fun ẹran-ara ki a sì da ẹ̀jẹ́ igbeyawo.—Orin Dafidi 119:101, 102.

Awọn Apẹẹrẹ Iwa Yiyatọsira Gédégédé

14, 15. (a) Bawo ni Josefu ṣe huwapada si idẹwo? (b) Ki ni ó ran Josefu lọwọ lati dena idẹwo kan?

14 Bawo ni a ṣe lè dojukọ idẹwo? Ni ọ̀nà yii a ní iyatọ kedere laaarin awọn ipaọna tí Josefu ati Dafidi tọ̀. Nigba ti aya Potifari fi itẹpẹlẹ gbiyanju lati yí Josefu arẹwà, ẹni ti ó ṣe kedere pe ó jẹ́ àpọ́n ni akoko naa leropada ṣagbere, oun dá a lohun nikẹhin nipa sisọ pe: “Kò si ẹni ti ó pọ̀ ju mi lọ ninu ile yii; bẹẹ ni [ọkọ rẹ] kò sì pa ohun kan mọ́ kuro lọwọ mi bikoṣe iwọ, nitori pe aya rẹ̀ ni iwọ íṣe: ǹjẹ́ emi ó ha ti ṣe hu iwa-buburu ńlá yii, ki emi sì dẹṣẹ si Ọlọrun?”—Genesisi 39:6-9.

15 Ki ni ó ran Josefu lọwọ lati tọ ipa-ọna títọ́ nigba ti kì bá ti rọrun lati juwọsilẹ? Oun ní ipá alagbara kan ti ń sún ero-inu rẹ̀ ṣiṣẹ. Oun jẹ́ kí ipo-ibatan rẹ̀ pẹlu Jehofa jẹ ẹ́ lọkan. O mọ̀ pe ṣiṣe agbere pẹlu obinrin onifẹẹ ainijaanu yii yoo jẹ́ ẹṣẹ nitootọ kìí ṣe kìkì si ọkọ rẹ̀ nikan, ṣugbọn ni pataki ju si Ọlọrun.—Genesisi 39:12.

16. Bawo ni Dafidi ṣe huwapada si idẹwo?

16 Ni iyatọ gédégédé, ki ni ó ṣẹlẹ si Dafidi? Oun jẹ́ ọkunrin kan ti ó ti gbeyawo, ti o sì ni ọpọlọpọ aya gẹgẹ bi Ofin ti yọnda. Ni irọlẹ ọjọ kan ó ṣakiyesi obinrin kan ti ń wẹ̀ lati inu ààfin rẹ̀. Batṣeba arẹwa, aya Uriah ni. Ni kedere Dafidi ní yíyàn niti igbesẹ ti o yẹ ki o gbé—lati maa baa lọ ni wiworan nigba ti ifẹkufẹẹ ń ru soke ninu ọkan-aya rẹ̀ tabi lati yiju kuro ki ó sì kọ idẹwo naa silẹ. Ki ni oun yàn lati ṣe? Ó jẹ ki a mú un wa sinu ààfin rẹ̀, ó sì huwa panṣaga pẹlu rẹ̀. Àní eyi ti o buru ju, ó tẹsiwaju lati ṣokunfa iku ọkọ rẹ̀.—2 Samueli 11:2-4, 12-27.

17. Ki ni a lè rí fàyọ nipa ipo tẹmi Dafidi?

17 Ki ni iṣoro Dafidi? Lati inu ijẹwọ onirobinujẹ rẹ̀ lẹhin naa ni Orin Dafidi 51, a lè rí awọn otitọ diẹ fàyọ. Ó sọ pe: “Dá ọkan-aya mimọgaara si inu mi, Óò Ọlọrun, ki o sì fi ẹmi titun si inu mi, ọ̀kan ti o duroṣanṣan.” Ó ṣe kedere pe ni akoko idẹwo rẹ̀, oun kò ni ẹmi ti o mọ́ gaara ti ó sì duroṣanṣan. Boya oun ti ṣainaani kika Ofin Jehofa, ati gẹgẹ bi iyọrisi, ipo tẹmi rẹ̀ di alailera. Tabi oun ti lè jẹ́ ki ipo ati agbara rẹ̀ gẹgẹ bi ọba ba ironu rẹ̀ jẹ́ debi pe ó ṣubu sọwọ ìfẹ́-ọkàn iwapalapala takọtabo. Dajudaju, ipá tí ń sún ero-inu rẹ̀ ṣiṣẹ ni akoko yẹn jẹ́ onimọtara-ẹni-nikan ati eyi ti o kun fun ẹṣẹ. Nipa bayii, ó wá mọ aini rẹ̀ fun “ẹmi titun kan, ọ̀kan ti o duroṣanṣan.”—Orin Dafidi 51:10, NW; Deuteronomi 17:18-20.

18. Imọran wo ni Jesu fifunni nipa panṣaga?

18 Awọn igbeyawo Kristian kan ni a ti bajẹ nitori pe ọ̀kan ninu awọn alabaakẹgbẹ naa tabi awọn mejeeji fààyè gba araawọn lati ṣubu sinu ipo ailera tẹmi ti o ri bakan naa pẹlu ti Ọba Dafidi. Apẹẹrẹ rẹ̀ nilati kilọ fun wa lodisi fifi oju ifẹ ainijaanu wo obinrin tabi ọkunrin miiran lemọlemọ, nitori pe ó lè tibẹ̀ yọrisi panṣaga. Jesu fihàn pe oun lóye awọn ero-imọlara eniyan ni ọ̀nà yii, nitori pe ó sọ pe: “Ẹyin ti gbọ bi a ti wí fun awọn ará igbaani pe, Iwọ kò gbọdọ ṣe panṣaga. Ṣugbọn emi wí fun yin, ẹnikẹni ti ó bá wo obinrin kan lati ṣe ifẹkufẹẹ si i, ó ti bá a ṣe panṣaga tán ni ọkàn rẹ̀.” Ninu iru ọ̀ràn bẹẹ, ipá tí ń sún ero-inu ṣiṣẹ jẹ́ onimọtara-ẹni-nikan ti ara sì ni, kìí ṣe tẹmi. Nigba naa, ki ni awọn Kristian lè ṣe lati yẹra fun panṣaga ki wọn sì pa igbeyawo wọn mọ ni alayọ ati eyi ti ń tẹnilọrun?—Matteu 5:27, 28.

Sọ Ìdè Igbeyawo naa Di Alagbara

19. Bawo ni a ṣe lè sọ igbeyawo kan di eyi ti o lagbara?

19 Ọba Solomoni kọwe pe: “Bi ẹnikan bá kọlu ẹnikan, ẹni meji yoo kò ó loju; ati okùn oníkọ̀ọ́ mẹta kìí yá fàjá.” Dajudaju, awọn meji ninu igbeyawo ti o wà ni iṣọkan lè duro papọ ninu ipọnju ju ẹnikan lọ. Ṣugbọn bi ìdè wọn bá dabi okùn oníkọ̀ọ́ mẹta nipa níní Ọlọrun ninu rẹ̀, igbeyawo naa yoo le koránkorán. Bawo sì ni Ọlọrun ṣe lè wà ninu igbeyawo kan? Nipa fifi ti tọkọtaya naa ń fi awọn ilana ati imọran rẹ̀ fun igbeyawo silo.—Oniwasu 4:12.

20. Imọran Bibeli wo ni ó lè ran ọkọ kan lọwọ?

20 Dajudaju, bi ọkọ kan bá fi imọran awọn ọrọ-ẹsẹ iwe mimọ ti ó tẹle e yii silo, igbeyawo rẹ̀ yoo ni ipilẹ ti ó dara ju fun ikẹsẹjari:

“Bẹẹ gẹgẹ ẹyin ọkọ, ẹ maa fi òye bá awọn aya yin gbé, ẹ maa fi ọlá fun aya, bi ohun eelo ti kò lagbara, ati pẹlu bi ajumọ-jogun oore-ọfẹ ìyè; ki adura yin ki ó má baa ni idena.”—1 Peteru 3:7.

“Ẹyin ọkọ, ẹ fẹran awọn aya yin, gẹgẹ bi Kristi sì ti fẹran ijọ, ti o sì fi ara rẹ̀ fun un. Bẹẹ ni ó tọ́ ki awọn ọkunrin ki o maa fẹran awọn aya wọn gẹgẹ bi ara awọn tikaraawọn. Ẹni ti ó bá fẹran aya rẹ̀, ó fẹran oun tikaraarẹ.”—Efesu 5:25, 28.

“[Ọkọ rẹ̀ dide], oun sì fi iyin fun un. Ọpọlọpọ awọn ọmọbinrin ni ó huwa rere, ṣugbọn iwọ ta gbogbo wọn yọ.”—Owe 31:28, 29.

“Ẹnikan ha lè gun ori ẹyin-iná gbigbona, ki ẹsẹ rẹ̀ ki o má jona? Bẹẹ ni ẹni ti ó wọle tọ obinrin ẹnikeji rẹ̀ lọ; ẹnikẹni ti o fi ọwọ́ bà á, ki yoo wà ni ailẹṣẹ. Ẹni ti ó bá bá obinrin ṣe panṣaga, . . . yoo pa ẹmi araarẹ run.”—Owe 6:28, 29, 32.

21. Imọran Bibeli wo ni ó lè ran aya kan lọwọ?

21 Bi aya kan bá fiyesi awọn ẹkọ tootọ Bibeli ti wọn tẹle e yii, yoo pakun ìwàpẹ́títí igbeyawo rẹ̀:

“Bẹẹ gẹgẹ, ẹyin aya, ẹ maa tẹriba fun awọn ọkọ yin; pe, bi ẹnikẹni bá tilẹ ń ṣe aigbọran si ọ̀rọ̀ naa, ki a lè jere wọn ni aisọrọ nipa iwa awọn aya wọn, nigba ti wọn bá ń wo iwa rere ti oun ti ẹ̀rù yin: Ọ̀ṣọ́ ẹni ti ki ó ma jẹ́ ọ̀ṣọ́ òde, ti irun dídì, ati ti wura lilo, tabi ti aṣọ wíwọ̀; ṣugbọn ki o jẹ́ ti ẹni ti o farasin ni ọkàn, ninu ọ̀ṣọ́ aidibajẹ ti ẹmi irẹlẹ ati ẹmi tutu [rẹ].”—1 Peteru 3:1-4.

“Ki ọkọ ki o maa fi ohun-ẹ̀tọ́ [ibalopọ takọtabo] aya rẹ̀ fun un, ṣugbọn jẹ ki aya pẹlu ṣe bakan naa si ọkọ rẹ̀. . . . Ẹ maṣe maa fi i du araayin, àyàfi nipa ilohunsi tọtun-tosi fun akoko kan ti a ti yànkalẹ̀.”—1 Korinti 7:3-5, NW.

22. (a) Awọn kókó abajọ miiran wo ni o lè nipa lori igbeyawo fun rere? (b) Oju wo ni Jehofa fi wo ikọsilẹ?

22 Bibeli tun fihàn pe ifẹ, inurere, ìyọ́nú, suuru, òye, iṣiri, ati iyin tun jẹ́ awọn ìhà ohun-ọṣọ ṣiṣekoko miiran nipa igbeyawo. Igbeyawo kan ti kò ní wọn dabii koriko kan ti kò ní itanṣan oorun ati omi—kìí figba gbogbo tanná. Nitori naa ẹ jẹ́ ki ipá tí ń sún awọn ero-inu wa ṣiṣẹ sọ ọ́ di dandan fun wa lati fun araawa ẹnikinni keji niṣiiri ki á sì tu ẹnikinni keji lara ninu igbeyawo wa. Ranti pe Jehofa “koriira ikọsilẹ.” Bi a bá ń fi ifẹ Kristian silo, kò nilati sí ààyè fun panṣaga ati iwolulẹ igbeyawo. Eeṣe? Nitori pe “ifẹ kìí yẹ̀ lae.”—Malaki 2:16; 1 Korinti 13:4-8; Efesu 5:3-5.

Iwọ Ha Lè Ṣalaye Bi?

◻ Ki ni ó jẹ́ ipilẹ fun igbeyawo alayọ?

◻ Bawo ni ipá tí ń sún ero-inu ṣiṣẹ ṣe le nipa lori igbeyawo kan?

◻ Ki ni a lè ṣe lati sọ ipá tí ń sún ero-inu wa ṣiṣẹ di alagbara?

◻ Bawo ni Josefu ati Dafidi ṣe yatọsira nigba ti wọn wà labẹ idẹwo?

◻ Imọran Bibeli wo ni yoo ran awọn ọkọ ati aya lọwọ lati sọ ìdè igbeyawo wọn di alagbara?

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

Awa ha ń gbé pẹlu ọpa-idiwọn meji—oninuure ninu ijọ ati onroro ni ile bi?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́