Ẹ Gbé Àkópọ̀ Ìwà Tuntun Wọ̀
1 Àwọn Kristẹni mà mọyì mímọ òtítọ́ o! A ti kọ́ bí a ṣe lè gbé ìgbé ayé wa láti yẹra fún ọ̀nà tí àwọn tí ó wà nínú ayé ń tọ̀. Níwọ̀n bí wọ́n ti “di àjèjì sí ìyè tí ó jẹ́ ti Ọlọ́run,” wọ́n “wà nínú òkùnkùn ní ti èrò orí.” (Éfé. 4:18) A ti kọ́ wa láti gbọ́kàn wa kúrò nínú ìrònú ayé nípa bíbọ́ ògbólógbòó àkópọ̀ ìwà sílẹ̀ kí a sì gbé tuntun wọ̀.—Éfé. 4:22-24.
2 Ògbólógbòó àkópọ̀ ìwà a máa ṣamọ̀nà sí bíba ìwà rere jẹ́ láìdáwọ́dúró, tí yóò sì wá yọrí sí ìsọdẹ̀gbin àti ikú. Nítorí náà, a ń ké sí àwọn tí yóò bá fetí sílẹ̀ sí ìhìn iṣẹ́ Ìjọba náà pé kí wọ́n kọ gbogbo ìrunú, ìbínú, ìwà búburú, ọ̀rọ̀ èébú, àti ọ̀rọ̀ rírùn sílẹ̀. Gbogbo àwọn tí ó bá ń fẹ́ ojú rere Ọlọ́run gbọ́dọ̀ bọ́ ògbólógbòó àkópọ̀ ìwà sílẹ̀ pátápátá poo—lọ́nà tí wọn yóò gbà bọ́ aṣọ tí ó ti dọ̀tí sílẹ̀.—Kól. 3:8, 9.
3 Ipá Tuntun Tí Ń Mú Èrò Inú Ṣiṣẹ́: Gbígbé àkópọ̀ ìwà tuntun wọ̀ jẹ́ dídi tuntun nínú ipá tí ń mú èrò inú wa ṣiṣẹ́. (Éfé. 4:23) Báwo lá ṣe ń sọ ipá, tàbí ìtẹ̀sí èrò orí yẹn di tuntun kí a lè tẹ̀ sí ọ̀nà títọ́? A lè ṣe èyí nípa fífi aápọn kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé kí a sì ṣàṣàrò nípa ohun tí ó túmọ̀ sí. Lẹ́yìn èyí, ọ̀nà ìrònú tuntun yóò bẹ̀rẹ̀, ẹni náà yóò wá máa wo àwọn nǹkan bí Ọlọ́run àti Kristi ṣe ń wò ó. Ìgbésí ayé ẹni náà yóò wá yí padà bí ó ṣe ń fi àwọn ànímọ́ bí ti Kristi wọ ara rẹ̀ láṣọ, irú bí ìyọ́nú, inú rere, ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú, ìwà tútù, ìpamọ́ra, àti ìfẹ́.—Kól. 3:10, 12-14.
4 Nípa gbígbé àkópọ̀ ìwà tuntun wọ̀, a ń ya ara wa sọ́tọ̀ kúrò nínú ayé. Ọ̀nà ìgbésí ayé wa mú kí a yàtọ̀. A ń sọ òtítọ́, a sì ń fi ọ̀rọ̀ gbígbámúṣé gbé àwọn ẹlòmíràn ró. A máa ń ṣàkóso ìbínú wa, ìwà kíkorò, ìlọgun, ọ̀rọ̀ èébú, àti gbogbo ìwà búburú, a sì ń fi àwọn ànímọ́ òdodo ti Ọlọ́run dípò ìwọ̀nyí. A máa ń dárí jini ju bí a ṣe sábà máa ń fojú sọ́nà fún lọ. A ń ṣe gbogbo èyí látọkànwá.—Éfé. 4:25-32.
5 Má ṣe bọ́ àkópọ̀ ìwà tuntun kúrò láé. Láìsí i, a kò lè sin Jèhófà lọ́nà tí ó tẹ́wọ́ gbà. Jẹ́ kí ó ṣèrànwọ́ láti fa àwọn ènìyàn sún mọ́ òtítọ́, sì jẹ́ kí ó fògo fún Jèhófà, Ẹlẹ́dàá àgbàyanu àkópọ̀ ìwà wa tuntun.—Éfé. 4:24.