Àwọn Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Fún February
Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní February 1
Orin 154
10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Àwọn Ìfilọ̀ tí a yàn láti inú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa. Rán gbogbo akéde létí pé kí wọ́n fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti oṣù January sílẹ̀.
17 min: “Fi Ìwé Ayọ̀ Ìdílé Lọ Tàgbàtèwe.” Alàgbà bá akéde dídángájíá méjì tàbí mẹ́ta jíròrò àpilẹ̀kọ yìí. Pọkàn pọ̀ sórí góńgó ríran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti mọ̀ pé títẹ̀lé ìmọ̀ràn Bíbélì ni àṣírí ayọ̀ ìdílé. (Wo ìwé Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé, ojú ìwé 10 sí 12.) Ṣàṣefihàn ọ̀kan nínú àwọn ìgbékalẹ̀ tí a dábàá. Fi bí a ṣe lè ṣètò fún ìpadàbẹ̀wò hàn.
18 min: “Ẹ Gbé Àkópọ̀ Ìwà Tuntun Wọ̀.” Àsọyé, tí ń ṣàlàyé Éfésù 4:20-24. (Wo Ilé-Ìṣọ́nà, March 1, 1993, ojú ìwé 14 sí 18, ìpínrọ̀ 4 sí 17.) Ṣàlàyé bí a ṣe ń bọ́ ògbólógbòó àkópọ̀ ìwà sílẹ̀ tí a sì ń gbé tuntun wọ̀. Jíròrò díẹ̀ lára ànímọ́ tí àwọn tí wọ́n ti ṣe bẹ́ẹ̀ máa ń fi hàn.
Orin 4 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní February 8
Orin 12
10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò.
15 min: Àìní àdúgbò.
20 min: “A Jàǹfààní Láti Inú Àwọn Àpéjọpọ̀ ‘Ọ̀nà Ìgbésí Ayé Tí Ọlọ́run Fẹ́.’ ” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Fi ìwé tuntun náà àti ìwé pẹlẹbẹ tuntun náà hàn, kí o sì sọ àwọn ọ̀nà tí a lè gbà lò wọ́n dáadáa.
Orin 42 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní February 15
Orin 40
10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Ìròyìn ìnáwó. Ìròyìn Ìṣàkóso Ọlọ́run.
18 min: Báwo Ni A Ṣe Ń Jàǹfààní Nípa Fíforúkọ Sílẹ̀ Ní Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run? Kí alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ jíròrò pẹ̀lú àwùjọ. Ète ilé ẹ̀kọ́ yìí kì í ṣe láti kọ́ni bí a ṣe ń bá gbogbo ènìyàn sọ̀rọ̀ nìkan. Àwọn ọ̀nà mìíràn wà tí a fi ń jàǹfààní ní tààràtà. (Wo Iwe-Amọna Ile Ẹkọ, ojú ìwé 12 àti 13.) A ń kọ́ nípa bí a ṣe lè bá àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀ lọ́nà tí ó dára sí i. A ń kọ́ wa nípa bí a ṣe lè sọ̀rọ̀ lọ́nà tí ó ṣe kedere, tí ó já gaara, tí ó sì fi ìgboyà hàn. A túbọ̀ ń di ọ̀jáfáfá nínú dídáhùn àwọn ìbéèrè nípa ohun tí a gbà gbọ́ àti nínú ṣíṣàlàyé àwọn ìpinnu wa tí a gbé karí Bíbélì. Ìmọ̀ wa nípa Bíbélì ń pọ̀ sí i, èyí sì ń ràn wá lọ́wọ́ láti túbọ̀ gbéṣẹ́ sí i nínú jíjẹ́rìí fún àwọn ẹlòmíràn. A ń kẹ́kọ̀ọ́ láti tẹ́wọ́ gba ìkù-díẹ̀-káàtó wa, àti láti tẹ́wọ́ gba ìmọ̀ràn, èyí sì ń mú kí a túbọ̀ máa fi pẹ̀lẹ́tù bá àwọn ẹlòmíràn lò. Ìdálẹ́kọ̀ọ́ tí ilé ẹ̀kọ́ yìí ń pèsè lápapọ̀ ń ràn wá lọ́wọ́ láti máa “tóótun tẹ́rùntẹ́rùn” gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ Ọlọ́run.—2 Kọ́r. 3:5, 6.
17 min: “Bí Àwọn Mẹ́ńbà Ìdílé Ṣe Máa Ń Fọwọ́ Sowọ́ Pọ̀ Láti Nípìn-ín Kíkún—Nínú Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.” Ìjíròrò láàárín ìdílé kan. Wọ́n ṣàlàyé bí àwọn ṣe ń fi àwọn àbá tí a fúnni nípa Bíbélì kíkà àti ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé sílò, èyí tí ó wà nínú Ilé-Ìṣọ́nà, May 15, 1996, ojú ìwé 14 àti 15, àti Ilé-Ìṣọ́nà, October 15, 1992, ojú ìwé 16 àti 17.
Orin 57 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní February 22
Orin 170
10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò.
15 min: Jíjẹ́rìí ní Àwọn Ilé Ńláńlá Alákọ̀ọ́pọ̀ àti ní Àwọn Ilé Tí Ọdẹ Ń Ṣọ́. (Bí ilé ńláńlá alákọ̀ọ́pọ̀ tàbí ilé tí ọdẹ ń ṣọ́ kò bá pọ̀ ní ìpínlẹ̀ rẹ, ṣàgbéyẹ̀wò àpilẹ̀kọ náà “Èéṣe Tí A Fi Níláti Ní Àkọsílẹ̀ Àwọn Kò-sí-nílé?” nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti May 1995.) Kí a jíròrò rẹ̀ pẹ̀lú akéde méjì tàbí mẹ́ta. Ó ṣòro láti jẹ́rìí fún àwọn ènìyàn tí ń gbé ní àwọn ilé ńláńlá alákọ̀ọ́pọ̀ níbi tó jẹ́ pé nípasẹ̀ ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ tí a ń lò láàárín ilé nìkan ni a fi lè báni sọ̀rọ̀. Ó tún máa ń ṣòro níbi tó bá jẹ́ pé ọdẹ nìkan lo rí tí kò sì jẹ́ kí o rí àwọn tí ó ń gbé ilé náà. Ṣàgbéyẹ̀wò àwọn ọ̀nà tí a fi lè fani lọ́kàn mọ́ra. Fi ìwà ọ̀rẹ́ hàn, fi ara rẹ hàn pé aládùúgbò ni ọ́; dárúkọ onílé náà bí ó bá wà nínú ìwé nọ́ńbà tẹlifóònù; mẹ́nu kan kókó ẹ̀kọ́ kan tí ó bágbà mu tí o fẹ́ jíròrò, tàbí kí o ka ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ kan ní tààràtà láti inú ìwé Reasoning, ojú ìwé 9 sí 15; kí o sì ṣàlàyé pé o fẹ́ láti fún un ní ìwé àṣàrò kúkúrú kan, ìwé ìròyìn kan, tàbí ìwé pẹlẹbẹ kan tí ó dáhùn ìbéèrè pàtàkì kan, kí o sì sọ ìbéèrè náà. Níbi tí kò bá ti ṣeé ṣe láti rí ẹni náà lójúkojú, kọ lẹ́tà sí àwọn ayálégbé náà tàbí kí o jẹ́rìí fún wọn ní òpópónà bí wọ́n ṣe ń lọ tí wọ́n ń bọ̀. Ní ti àwọn ọlọ́dẹ, fún wọn ní ìtẹ̀jáde náà kí o sì sọ pé kí wọ́n fi han onílé náà tàbí àwọn mẹ́ńbà ìdílé rẹ̀ kí o sì sọ iye ọrẹ rẹ̀ fún un. Ṣàṣefihàn ọ̀nà kan tí a ti lò ládùúgbò tí ó ti mú àbájáde rere wá lọ́dọ̀ àwọn tí ń gbé ní ilé ńláńlá alákọ̀ọ́pọ̀.
20 min: Bí A Ṣe Lè Rí Ayọ̀ Nínú Sísọni Di Ọmọ Ẹ̀yìn. Àsọyé tí a gbé karí Ilé-Ìṣọ́nà, February 15, 1996, ojú ìwé 19 sí 22.
Orin 91 àti àdúrà ìparí.