ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • fy orí 1 ojú ìwé 4-12
  • Àṣírí Kan Ha Wà fún Ayọ̀ Ìdílé Bí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àṣírí Kan Ha Wà fún Ayọ̀ Ìdílé Bí?
  • Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • KÍ NI ÌDÍLÉ?
  • ÌDÍLÉ LÁBẸ́ MÁSÙNMÁWO
  • ÀṢÍRÍ AYỌ̀ ÌDÍLÉ
  • Máa Lépa Àlàáfíà Ọlọ́run Nínú Ìgbésí Ayé Ìdílé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Gbádùn Ìgbésí Ayé Ìdílé
    Gbádùn Ìgbésí Ayé Ìdílé
  • Ìdílé—Ohun Kòṣeémánìí fún Ẹ̀dá Ènìyàn!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Ṣíṣàjọpín Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé Pẹ̀lú Àwọn Ẹlòmíràn
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1997
Àwọn Míì
Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé
fy orí 1 ojú ìwé 4-12

ORÍ KÌÍNÍ

Àṣírí Kan Ha Wà fún Ayọ̀ Ìdílé Bí?

1. Èé ṣe tí àwọn ìdílé tí ó fìdí múlẹ̀ ṣinṣin fi ṣe pàtàkì nínú àwùjọ ẹ̀dá ènìyàn?

ÌDÍLÉ ni ìgbékalẹ̀ tí ó lọ́jọ́ lórí jù lọ lórí ilẹ̀ ayé, ó sì ń kó ipa pàtàkì nínú àwùjọ ẹ̀dá ènìyàn. Jálẹ̀ ìtàn, àwọn ìdílé tí ó fìdí múlẹ̀ ṣinṣin ti mú àwùjọ tí ó fìdí múlẹ̀ ṣinṣin jáde. Ìdílé ni ètò tí ó dára jù lọ fún títọ́ àwọn ọmọdé di àgbàlagbà tí ó dàgbà dénú.

2-5. (a) Ṣàpèjúwe ìfọkànbalẹ̀ tí ọmọ máa ń nímọ̀lára rẹ̀ nínú ìdílé aláyọ̀. (b) Àwọn ìṣòro wo ni a ròyìn rẹ̀ nínú àwọn ìdílé kan?

2 Ìdílé aláyọ̀ jẹ́ ibi ààbò àti ìfọkànbalẹ̀. Fi ọkàn yàwòrán ìdílé rere kan, fún ìṣẹ́jú díẹ̀. Lákòókò oúnjẹ alẹ́ wọn, àwọn òbí tí ó bìkítà jókòó ti àwọn ọmọ wọn, wọ́n sì jíròrò àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ọjọ́ náà. Inú àwọn ọmọ ń dùn ṣìnkìn bí wọ́n ti ń sọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ ní ilé ẹ̀kọ́ fún bàbá àti ìyá wọn. Àkókò ìdẹ̀ra, tí wọ́n jọ lò pa pọ̀, tu gbogbo wọn lára láti lè kojú ọjọ́ mìíràn lẹ́yìn òde ìdílé.

3 Nínú ìdílé aláyọ̀, ọmọ́ mọ̀ pé bàbá àti ìyá òun yóò tọ́jú òun nígbà tí òún bá ń ṣàìsàn, bóyá kí wọ́n tilẹ̀ pín dídúró ti òun láàárín ara wọn, títí tí ilẹ̀ yóò fi mọ́. Ó mọ̀ pé òún lè mú àwọn ìṣòro ìgbà èwe òun tọ ìyá tàbí bàbá òun lọ, kí wọ́n sì fún òun ní ìmọ̀ràn àti ìṣírí. Bẹ́ẹ̀ ni, ọkàn ọmọ náà balẹ̀, láìka bí ipò ayé lẹ́yìn òde ìdílé ti lè kún fún rúkèrúdò tó sí.

4 Nígbà tí àwọn ọmọdé bá dàgbà, lọ́pọ̀ ìgbà, wọ́n máa ń ṣègbéyàwó, wọ́n sì máa ń ní ìdílé tiwọn. Òwe Ìlà Oòrùn ayé kan sọ pé: “Ẹnì kan ń mọ bí òún ti jẹ àwọn òbí òun ní gbèsè tó, nígbà tí ó bá bí ọmọ tirẹ̀.” Pẹ̀lú ẹ̀mí ìmoore àti ìfẹ́ jíjinlẹ̀, àwọn ọmọ tí ó ti dàgbà ń gbìyànjú láti mú kí ìdílé tiwọn náà láyọ̀, wọ́n sì tún ń bójú tó àwọn òbí wọn tí ń darúgbó, tí ń láyọ̀ láti wà pẹ̀lú àwọn ọmọ-ọmọ wọn.

5 Bóyá o ń ronú níbi tí a dé yìí pé: ‘Họ́wù, mo nífẹ̀ẹ́ ìdílé mi, ṣùgbọ́n kò rí bí irú èyí tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ júwe tán yìí. Àkókò iṣẹ́ mi yàtọ̀ sí ti alábàáṣègbéyàwó mi pátápátá, a kì í sì í fi bẹ́ẹ̀ ríra. Ìṣòro owó ni àwọn ọ̀rọ̀ wa sábà máa ń dá lé lórí.’ Tàbí o ha sọ pé, ‘Ìlú mìíràn ni àwọn ọmọ àti àwọn ọmọ-ọmọ mi ń gbé, ó sì ti pẹ́ tí mo ti rí wọn kẹ́yìn’? Bẹ́ẹ̀ ni, lọ́pọ̀ ìgbà, fún àwọn ìdí tí ó ré kọjá agbára àwọn tí ọ̀rán kàn, ìgbésí ayé ọ̀pọ̀ ìdílé kò dára tó. Síbẹ̀, àwọn kan ń gbé ìgbésí ayé ìdílé aláyọ̀. Báwo? Àṣírí kan ha wà fún ayọ̀ ìdílé bí? Bẹ́ẹ̀ ni, ni ìdáhùn náà. Ṣùgbọ́n, ṣáájú jíjíròrò ohun tí ó jẹ́, ó yẹ kí a dáhùn ìbéèrè pàtàkì kan.

KÍ NI ÌDÍLÉ?

6. Irú ìdílé wo ni a óò jíròrò nínú ìwé yìí?

6 Ní àwọn ilẹ̀ Ìwọ̀ Oòrùn, lọ́pọ̀ ìgbà, bàbá, ìyá, àti àwọn ọmọ ní ń para pọ̀ jẹ́ ìdílé. Àwọn òbí àgbà lè gbé ní ilé tiwọn fúnra wọn, títí dìgbà tí kò bá ṣeé ṣe fún wọn mọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀. Bí wọ́n tilẹ̀ ń ní ìbáṣe pẹ̀lú àwọn ìbátan jíjìnnà réré, ìwọ̀nba ni ojúṣe wọn sí àwọn wọ̀nyí. Ní pàtàkì, irú ìdílé yìí ni a óò jíròrò nínú ìwé yìí. Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn ìdílé mìíràn ti ń wọ́pọ̀ gan-an ní àwọn ọdún àìpẹ́ yìí​—ìdílé olóbìí kan, ìdílé onígbeyàwó àtúnṣe, àti ìdílé tí àwọn òbí kì í ti í gbé pa pọ̀, fún ìdí kan tàbí òmíràn.

7. Kí ni ìdílé amẹ́bí-múbàátan?

7 Ìdílé amẹ́bí-múbàátan wọ́pọ̀ nínú àwọn ẹgbẹ́ àwùjọ kan. Nínú ìṣètò yìí, níbi tí ó bá ti ṣeé ṣe, àwọn ọmọ ń pín títọ́jú àwọn òbí àgbà láàárín ara wọn, a sì ń nawọ́ ìbáṣe tímọ́tímọ́ àti ojúṣe sí àwọn ìbátan jíjìnnà réré. Fún àpẹẹrẹ, àwọn mẹ́ḿbà ìdílé lè ṣèrànwọ́ nínú ṣíṣètìlẹ́yìn fún àwọn ọmọ àbúrò, ọmọ ẹ̀gbọ́n, tàbí àwọn ìbátan jíjìnnà réré, nípa títọ́ wọn dàgbà, tàbí rírán wọn lọ sí ilé ẹ̀kọ́ pàápàá. Àwọn ìlànà tí a óò jíròrò nínú ìtẹ̀jáde yìí kan àwọn ìdílé amẹ́bí-múbàátan pẹ̀lú.

ÌDÍLÉ LÁBẸ́ MÁSÙNMÁWO

8, 9. Àwọn ìṣòro wo ní àwọn ilẹ̀ kan ni ó fi hàn pé ìdílé ń yí padà?

8 Lónìí, ìdílé ń yí padà​—ó bani nínú jẹ́ pé kì í ṣe sí rere. Àpẹẹrẹ kan ni ti India, níbi tí aya ti lè máà gbé pẹ̀lú ìdílé ọkọ rẹ̀, kí ó sì máa ṣiṣẹ́ nínú ilé lábẹ́ ìdarí àwọn àna rẹ̀. Bí ó ti wù kí ó rí, lóde òní, ó wọ́pọ̀ fún àwọn aya ní India láti wáṣẹ́ síta. Síbẹ̀, ó ṣe kedere pé, a ṣì retí pé kí wọ́n ṣe ojúṣe wọn nínú ilé, ní ìbámu pẹ̀lú àṣà ìbílẹ̀. Ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀, a gbé ìbéèrè dìde pé, Ní ìfiwéra pẹ̀lú àwọn mẹ́ḿbà ìdílé yòókù, báwo ni ó ṣe yẹ kí iṣẹ́ tí a retí pé kí obìnrin kan tí ń ṣiṣẹ́ lóde ṣe nínú ilé ti pọ̀ tó?

9 Nínú àwọn àwùjọ Ìlà Oòrùn ayé, ìbáṣepọ̀ tí ó fìdí múlẹ̀ ṣinṣin láàárín ìdílé amẹ́bí-múbàátan jẹ́ àṣà ìbílẹ̀. Bí ó ti wù kí ó rí, lábẹ́ agbára ìdarí àṣà Ìwọ̀ Oòrùn ayé ti oníkóńkó-jabele àti másùnmáwo ìṣòro ìṣúnná owó, àṣà ìbílẹ̀ ìdílé amẹ́bí-múbàátan ti ń di ahẹrẹpẹ. Nítorí èyí, ọ̀pọ̀ ka títọ́jú àwọn mẹ́ḿbà ìdílé tí ó ti darúgbó sí ẹrù ìnira, dípò wíwò ó gẹ́gẹ́ bí ojúṣe tàbí àǹfààní kan. A ń ṣìkà sí àwọn òbí àgbàlagbà kan. Ní ti gidi, ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè lónìí ni a ti ń hùwà ìkà sí àwọn arúgbó, tí a sì ń pa wọ́n tì.

10, 11. Àwọn òtítọ́ wo ni ó fi hàn pé ìdílé ń yí padà ní àwọn ilẹ̀ Europe?

10 Ìkọ̀sílẹ̀ ti ń wọ́pọ̀ gan-an. Ní Spain, iye ìkọ̀sílẹ̀ ti ròkè dé ìgbéyàwó 1 nínú 8, ní ìbẹ̀rẹ̀ ẹ̀wádún tí ó kẹ́yìn ọ̀rúndún ogún yìí​—ìlọsókè pípabambarì láti orí ìgbéyàwó 1 nínú 100 ní kìkì ọdún 25 ṣáájú. Britain, tí a ròyìn pé ó ní àròpọ̀ iye ìkọ̀sílẹ̀ tí ó ga jù lọ ní Europe (a retí pé kí ìgbéyàwó 4 nínú 10 forí ṣánpọ́n), ti rí ìbísí ńlá nínú iye ìdílé olóbìí kan.

11 Ó jọ pé ọ̀pọ̀ ní Germany ń kọ ìdílé àṣà ìbílẹ̀ sílẹ̀ pátápátá. Àwọn ọdún 1990 ti rí ìpín 35 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn agbo ilé Germany tí ó jẹ́ kìkì ẹnì kan ṣoṣo, tí ìpín 31 nínú ọgọ́rùn-ún sì jẹ́ kìkì ènìyàn méjì. Àwọn ará Faransé pẹ̀lú kì í fi bẹ́ẹ̀ ṣègbéyàwó mọ́, àwọn tí ó sì ń ṣègbéyàwó tètè máa ń kọ ara wọn sílẹ̀, wọ́n sì ń ṣe bẹ́ẹ̀ lemọ́lemọ́ ju bí ó ti máa ń rí tẹ́lẹ̀ lọ. Àwọn ènìyàn púpọ̀ sí i yàn láti máa gbé pọ̀ láìsí àwọn ojúṣe ìgbéyàwó. A ń rí àwọn ìtẹ̀sí tí ó jọ èyí kárí ayé.

12. Báwo ni àwọn ọmọ ṣe ń jìyà nítorí àwọn ìyípadà nínú ìdílé òde òní?

12 Àwọn ọmọ ńkọ́? Ní United States àti ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀ míràn, a ń bí àwọn ọmọ púpọ̀ sí i lẹ́yìn òde ìgbéyàwó, àwọn ọ̀dọ́langba sì ni òbí àwọn kan. Ọ̀pọ̀ ọmọdébìnrin ọ̀dọ́langba ń bí àwọn ọmọ fún àwọn bàbá ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Ìròyìn kárí ayé ń sọ nípa àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn ọmọ kékeré, tí kò nílé, tí ń ráre ká ìgboro; ọ̀pọ̀ ń sá lọ kúrò nílé tí a ti ń hùwà ìkà sí wọn, tàbí àwọn ìdílé tí kò lè gbọ́ bùkátà lórí wọn mọ́ ń tì wọ́n síta.

13. Àwọn ìṣòro títàn kálẹ̀ wo ní ń du ìdílé láyọ̀?

13 Bẹ́ẹ̀ ni, ìdílé wà nínú yánpọnyánrin. Ní àfikún sí àwọn ohun tí a ti mẹ́nu kàn ṣáájú, ìṣọ̀tẹ̀ àwọn ọ̀dọ́langba, ìhùwà ìkà sí ọmọdé, ìwà ipá alábàáṣègbéyàwó, ìmukúmu, àti àwọn ìṣòro abaninínújẹ́ mìíràn, ń du ọ̀pọ̀ ìdílé láyọ̀. Fún ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ọmọdé àti àgbà, ìdílé kì í ṣe ibi tí ń fi ọkàn ènìyàn balẹ̀ rárá.

14. (a) Gẹ́gẹ́ bí àwọn kan ti sọ, kí ni okùnfà yánpọnyánrin ìdílé? (b) Báwo ni amòfin kan ní ọ̀rúndún kìíní ṣe ṣàpèjúwe ayé òde òní, ipa wo sì ni ìmúṣẹ ọ̀rọ̀ rẹ̀ ní lórí ìgbésí ayé ìdílé?

14 Kí ni ó fa yánpọnyánrin ìdílé? Àwọn kan di ẹ̀bi yánpọnyánrin ìdílé, tí a ń rí lónìí, ru wíwọ̀ tí àwọn obìnrin ń wọṣẹ́. Àwọn mìíràn tọ́ka sí ìwólulẹ̀ ìwà rere. A tún mẹ́nu kan àwọn ìdí mìíràn. Ní nǹkan bí ẹgbàá ọdún sẹ́yìn, amòfin kan tí a mọ̀ bí ẹní mowó sọ tẹ́lẹ̀ pé ìkìmọ́lẹ̀ púpọ̀ yóò yọ ìdílé lẹ́nu, nígbà tí ó kọ̀wé pé: “Ní awọn ọjọ́ ìkẹyìn awọn àkókò lílekoko tí ó nira lati bálò yoo wà níhìn-ín. Nitori awọn ènìyàn yoo jẹ́ olùfẹ́ ara wọn, olùfẹ́ owó, ajọra-ẹni-lójú, onírera, asọ̀rọ̀-òdì, aṣàìgbọràn sí òbí, aláìlọ́pẹ́, aláìdúróṣinṣin, aláìní ìfẹ́ni àdánidá, aláìṣeé bá ṣe àdéhùn kankan, afọ̀rọ̀-èké-banijẹ́, aláìní ìkóra-ẹni-níjàánu, òǹrorò, aláìní ìfẹ́ ohun rere, afinihàn, olùwarùnkì, awúfùkẹ̀ pẹlu ìgbéraga, olùfẹ́ adùn dípò olùfẹ́ Ọlọrun.” (2 Timoteu 3:​1-4) Ta ni yóò ṣiyè méjì pé àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ti ń ní ìmúṣẹ lónìí? Nínú ayé tí ó kún fún irú àwọn ipò bí ìwọ̀nyí, ó ha yani lẹ́nu pé ọ̀pọ̀ ìdílé wà nínú yánpọnyánrin bí?

ÀṢÍRÍ AYỌ̀ ÌDÍLÉ

15-17. Nínú ìwé yìí, ọlá àṣẹ wo ni a óò tọ́ka sí gẹ́gẹ́ bí èyí tí ó ní àṣírí sí ayọ̀ ìdílé nínú?

15 Ibi gbogbo ni a ti ń fúnni ní ìmọ̀ràn lórí bí ọwọ́ ṣe lè tẹ ayọ̀ ìdílé. Ní Ìwọ̀ Oòrùn ayé, a ń tẹ àìlóǹkà ìwé àti ìwé ìròyìn, tí ń pèsè ìtọ́ni àti ìmọ̀ràn bí-a-tií-ṣe-é, jáde. Ìṣòro náà ni pé, àwọn ènìyàn tí ń gbani nímọ̀ràn máa ń ta ko ara wọn, àwọn ìmọ̀ràn tí ó bóde mu lónìí ni a lè wò gẹ́gẹ́ bí èyí tí kò gbéṣẹ́ lọ́la.

16 Nígbà náà, ibo ni a lè yíjú sí fún ìdarí tí ó ṣeé fọkàn tẹ̀ fún ìdílé? Ó dára, ìwọ yóò ha yíjú sí ìwé tí a parí kíkọ rẹ̀ ní nǹkan bí 1,900 ọdún sẹ́yìn bí? Tàbí ìwọ yóò ha ronú pé irú ìwé bẹ́ẹ̀ kì yóò bágbà mu páàpáà? Òtítọ́ náà ni pé, orísun yẹn gan-an ni a ti ń rí àṣírí tòótọ́ fún ayọ̀ ìdílé.

17 Bibeli ni orísun náà. Ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo ẹ̀rí, Ọlọrun fúnra rẹ̀ ni ó mí sí i. A rí gbólóhùn yìí nínú Bibeli pé: “Gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọrun mí sí ó sì ṣàǹfààní fún kíkọ́ni, fún fífi ìbáwí tọ́nisọ́nà, fún mímú awọn nǹkan tọ́, fún ìbániwí ninu òdodo.” (2 Timoteu 3:16) Nínú ìtẹ̀jáde yìí, a óò rọ̀ ọ́ láti gbé bí Bibeli ṣe lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti “mú awọn nǹkan tọ́” nígbà tí o bá ń bójú tó àwọn másùnmáwo àti ìṣòro tí ń dojú kọ àwọn ìdílé lónìí yẹ̀ wò.

18. Èé ṣe tí ó fi bọ́gbọ́n mu láti gba Bibeli gẹ́gẹ́ bí ọlá àṣẹ nínú fífúnni nímọ̀ràn nípa ìgbéyàwó?

18 Bí o bá nítẹ̀sí láti rọ́ ṣíṣeé ṣe náà pé Bibeli lè ṣèrànwọ́ láti mú kí ìdílé láyọ̀ tì sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan, ronú nípa èyí: Ẹni náà tí ó mí sí Bibeli ni Olùdásílẹ̀ ètò ìgbéyàwó. (Genesisi 2:​18-25) Bibeli sọ pé Jehofa ni orúkọ rẹ̀. (Orin Dafidi 83:18) Òun ni Ẹlẹ́dàá àti ‘Baba, ẹni tí olúkúlùkù ìdílé jẹ ní gbèsè fún orúkọ rẹ̀.’ (Efesu 3:​14, 15) Jehofa ti kíyè sí ìgbésí ayé ìdílé láti ìgbà ìbẹ̀rẹ̀ aráyé. Ó mọ àwọn ìṣòro tí ó lè dìde, ó sì ti pèsè ìmọ̀ràn fún yíyanjú wọn. Jálẹ̀ ìtàn, àwọn tí ó fi tinútinú fi àwọn ìlànà Bibeli sílò nínú ìgbésí ayé ìdílé wọn rí ayọ̀ púpọ̀.

19-21. Àwọn ìrírí òde òní wo ni ó fi agbára tí Bibeli ní láti yanjú àwọn ìṣòro ìgbéyàwó hàn?

19 Fún àpẹẹrẹ, ìyàwó ilé kan ní Indonesia jẹ́ atatẹ́tẹ́ láìníjàánu. Fún ọ̀pọ̀ ọdún, kò bójú tó àwọn ọmọ rẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta, ó sì máa ń bá ọkọ rẹ̀ jà nígbà gbogbo. Nígbà tí ó yá, ó bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli. Kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, obìnrin náà bẹ̀rẹ̀ sí í gba ohun tí Bibeli sọ gbọ́. Nígbà tí ó lo àwọn ìmọ̀ràn rẹ̀, ó di aya rere. Ìsapá rẹ̀, tí a gbé karí àwọn ìlànà Bibeli, mú ayọ̀ wá fún ìdílé rẹ̀ lódindi.

20 Ìyàwó ilé kan ní Spain sọ pé: “Kò tí ì ju ọdún kan tí a ṣègbéyàwó tí a ti bẹ̀rẹ̀ sí í ní àwọn ìṣòro líle koko.” Ìwà òun àti ọkọ rẹ̀ kò fi bẹ́ẹ̀ bára mu, wọn kò sì ń fi bẹ́ẹ̀ bára wọn sọ̀rọ̀, àyàfi nígbà tí wọ́n bá ń jiyàn. Láìka pé wọ́n ní ọmọbìnrin kékeré kan sí, wọ́n pinnu láti pínyà lábẹ́ òfin. Ṣùgbọ́n, ṣáájú èyí, a rọ̀ wọ́n láti yẹ Bibeli wò. Wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìmọ̀ràn rẹ̀ fún àwọn tọkọtaya, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í fi í sílò. Kò pẹ́ kò jìnnà, wọ́n lè bára wọn sọ̀rọ̀ ní pẹ̀lẹ́tù, a sì so ìdílé wọn kékeré pọ̀ ṣọ̀kan.

21 Bibeli ń ran àwọn àgbàlagbà pẹ̀lú lọ́wọ́. Fún àpẹẹrẹ, gbé ìrírí tọkọtaya ará Japan kan báyìí yẹ̀ wò. Ọkọ máa ń tètè bínú, ó sì máa ń fara ya lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Lákọ̀ọ́kọ́, àwọn ọmọbìnrin tọkọtaya náà bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli, láìka àtakò àwọn òbí wọn sí. Lẹ́yìn náà, ọkọ dara pọ̀ mọ́ àwọn ọmọbìnrin rẹ̀, ṣùgbọ́n aya ń bá a lọ láti ṣàtakò. Bí ó ti wù kí ó rí, bí ọdún ti ń gorí ọdún, ó kíyè sí ipa rere tí àwọn ìlànà Bibeli ń ní lórí ìdílé rẹ̀. Àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ ń tọ́jú rẹ̀, ọkọ rẹ̀ sì ti di ẹni jẹ́jẹ́. Irú àwọn ìyípadà bẹ́ẹ̀ sún obìnrin náà láti yẹ Bibeli wò fúnra rẹ̀, ó sì ní ipa rere kan náà lórí rẹ̀. Obìnrin àgbàlagbà yìí sọ léraléra pé: “A di tọkọtaya tòótọ́.”

22, 23. Báwo ni Bibeli ṣe ń ran àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè lọ́wọ́ láti rí ayọ̀ nínú ìgbésí ayé ìdílé wọn?

22 Àwọn ènìyàn wọ̀nyí wà lára ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ tí ó ti kọ́ nípa àṣírí ayọ̀ ìdílé. Wọ́n ti tẹ́wọ́ gba ìmọ̀ràn Bibeli, wọ́n sì ti fi í sílò. Òótọ́ ni pé wọ́n ń gbé nínú ayé oníwà ipá, oníwà pálapàla kan náà, tí ìṣúnná owó ti kó másùnmáwo bá, tí gbogbo ènìyàn ń gbé. Síwájú sí i, wọ́n jẹ́ aláìpé, ṣùgbọ́n wọ́n ń rí ayọ̀ nínú gbígbìyànjú láti ṣe ìfẹ́ inú Olùdásílẹ̀ ètò ìgbéyàwó. Gẹ́gẹ́ bí Bibeli ti sọ, Jehofa Ọlọrun ni ẹni ‘tí ń kọ́ ọ fún èrè, ẹni tí ń tọ́ ọ ní ọ̀nà tí ìwọ ì bá máa lọ.’​—Isaiah 48:17.

23 Bí a tilẹ̀ parí kíkọ Bibeli ní nǹkan bí ẹgbàá ọdún sẹ́yìn, ìmọ̀ràn rẹ̀ bágbà mu ní tòótọ́. Síwájú sí i, a kọ ọ́ fún gbogbo ènìyàn. Bibeli kì í ṣe ìwé àwọn ará America tàbí ti àwọn ará Ìwọ̀ Oòrùn ayé. ‘Lati ara ọkùnrin kan ni Jehofa ti ṣe gbogbo orílẹ̀-èdè awọn ènìyàn,’ Ó sì mọ ẹ̀dá àwọn ènìyàn níbi gbogbo. (Ìṣe 17:26) Àwọn ìlànà Bibeli ń ṣiṣẹ́ fún gbogbo ènìyàn. Bí o bá fi wọ́n sílò, ìwọ pẹ̀lú yóò mọ àṣírí ayọ̀ ìdílé.

O HA LÈ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ WỌ̀NYÍ BÍ?

Kí ní ń ṣẹlẹ̀ sí ìdílé lónìí?​—2 Timoteu 3:​1-4.

Ta ni ó dá ètò ìdílé sílẹ̀?​—Efesu 3:​14, 15.

Kí ni àṣírí ayọ̀ ìdílé?​—Isaiah 48:17.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́