Ìròyìn Ìṣàkóso Ọlọ́run
◼ A forúkọ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sílẹ̀ lábẹ́ òfin ní Bulgaria ní October 7, 1998. A dara pọ̀ mọ́ àwọn akéde òjìlélẹ́ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún ó lé mẹ́fà [946] tí ó wà níbẹ̀ láti fi ọpẹ́ fún Jèhófà nítorí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí.
◼ Ní October 12, 1998, ìjọba orílẹ̀-èdè Latvia fọwọ́ sí ìforúkọsílẹ̀ ìjọ méjì àkọ́kọ́ nínú mọ́kànlélógún tí ó wà ní orílẹ̀-èdè yẹn.
◼ Láìka àtakò sí, àwọn ará tí ó wà ní ilẹ̀ Faransé ń bá iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba náà nìṣó. Ní oṣù November àti December, a pín ìwé pẹlẹbẹ náà, Ìwé Kan Tí Ó Wà fún Gbogbo Ènìyàn, káàkiri lákànṣe fún ìgbétáásì kan láti pe àfiyèsí orílẹ̀-èdè náà sí Bíbélì. Nǹkan bí àádọ́ta òṣìṣẹ́ ní Bẹ́tẹ́lì ti ṣí láti ilẹ̀ Faransé lọ sí ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì láti ṣèrànwọ́ nínú títẹ̀wé àti pípín wọn kiri ní ẹ̀ka náà, nígbà tí àwọn àádọ́talérúgbà [250] mẹ́ńbà tó ṣẹ́ kù ní ìdílé Bẹ́tẹ́lì ní ilẹ̀ Faransé àti àwọn ará tí ń bẹ ní pápá ń bá a nìṣó láti máa fi ìdùnnú sìn lábẹ́ ipò tí ó fara rọ.