Àwọn Olùpòkìkí Ìjọba Ròyìn
Awọn Ẹlẹ́rìí Tú Yááyáá Sígboro Ilẹ̀ Faransé
LÁTI kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ Friday, January 29, 1999, títí dòpin ọ̀sẹ̀ náà ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nílẹ̀ Faransé fi tú sójú pópó, tí wọ́n ń lọ láti ilé dé ilé láti fìtara pín mílíọ̀nù méjìlá ìwé àṣàrò kúkúrú tí àkọlé rẹ̀ sọ pé, Ẹ̀yin Ará Ilẹ̀ Faransé, Irọ́ Ni Wọ́n Ń Pa Fún Yín! Kí ló fa irú ìpolongo bẹ́ẹ̀?
A ṣàlàyé ìdí tí ìpolongo náà fi wáyé níbi ìpàdé táa ṣe pẹ̀lú àwọn akọ̀ròyìn ní Paris lówùúrọ̀ ọjọ́ Friday yẹn. Ẹnì kan tó ṣe agbẹnusọ fún àwọn Ẹlẹ́rìí ṣàlàyé pé: “Ohun táa fẹ́ ṣe lónìí ni láti jẹ́ káwọn èèyàn lè mọ báa ṣe jẹ́, ká sì pa àwọn tó ń bà wá lórúkọ jẹ́ lẹ́nu mọ́. A ò sọ pé kí wọ́n má ṣe lámèyítọ́ wa o, àmọ́, a ò fẹ́ gbọ́ gbogbo irọ́ àti ọ̀rọ̀ tí wọ́n fi ń bà wá lórúkọ jẹ́ mọ́.”
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló ṣe ìkẹta nínú àwọn ẹ̀sìn Kristẹni tó pọ̀ jù nílẹ̀ Faransé, ọ̀pọ̀ ọmọ àwọn Ẹlẹ́rìí ni wọ́n ti fàbùkù kàn, tí wọ́n sì ti fòòró nílé ìwé. Wọ́n ti lé àwọn àgbà kúrò lẹ́nu iṣẹ́, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń kó ìpayà bá wọn nítorí ẹ̀sìn wọn. Èyí tó ṣeni ní kàyéfì jù ni pé, wọ́n tún ní kí wọ́n máa san ìpín ọgọ́ta nínú ọgọ́rùn-ún lára owó ọrẹ tí wọ́n ń rí nínú ẹ̀sìn wọn gẹ́gẹ́ bí owó orí. Ipa wo ni ìpolongo náà wá ní lórí ẹ̀tanú yìí?
Ìwé àṣàrò kúkúrú náà sọ pé: “Gbogbo ọ̀kẹ́ méjìlá ààbọ̀ [250,000] àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà àti àwọn alábàákẹ́gbẹ́ wọn tó ń gbé nílẹ̀ Faransé fi Ẹ̀HÓNÚ wọn hàn sí ọ̀nà àbòsí tí wọ́n fi ń ka ẹ̀sìn Kristẹni wọn tó ti wà nílẹ̀ Faransé láti ọdún 1900 mọ́ àwọn ẹ̀ya ẹ̀sìn eléwu láti ọdún 1995. . . . Wọ́n fi Ẹ̀HÓNÚ wọn hàn sí bí wọ́n ṣe ń fòòró wọn ní gbogbo ìgbà.” Bí àṣírí ọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ tí wọ́n ti sọ sí àwọn Ẹlẹ́rìí nílẹ̀ Faransé àti ọ̀nà àrékérekè tí àwọn abani-lórúkọ-jẹ́ ń gbà láti fèrò òdì sáwọn aráàlú lọ́kàn se tú nìyẹn. Àṣàrò kúkúrú náà wá parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ ní sísọ pé: “Lóde òní, ó lé ní ọgọ́rùn-ún ọ̀kẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà àti àwọn alábàákẹ́gbẹ́ wọn tó ń gbé ní Yúróòpù. Wọ́n bọ̀wọ̀ fún òfin Orílẹ̀-Èdè tí wọ́n ń gbé nípa híhùwà lọ́nà tó bá ohun tí Ìhìn Rere wí mu. Ẹ̀yin ara Faransé, ohun tó ń ṣẹlẹ̀ gan-an nìyí o. Ojúṣe wa ni láti sọ bọ́ràn ṣe rí gan-an!”
Kíá Mọ́sá Làwọn Èèyàn Fọhùn Ìdùnnú
Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ìwe àṣàrò kúkúrú ni wọ́n pín ní ọjọ́ kìíní. Ní Paris nìkan ṣoṣo, nígbà tó fi máa di ọ̀sán, àwọn ẹgbẹ̀rún méje Ẹlẹ́rìí ti pín ìwé àṣàrò kúkúrú mílíọ̀nù kan àti ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọ̀ọ́dúnrún fún àwọn ènìyàn. Àwọn èèyàn kò tí ì rí ibi táwọn Ẹlẹ́rìí ti pọ̀ tó báyìí tí wọ́n ń pin ìwé àṣàrò kúkúrú lójú pópó rí. Gbogbo ilé iṣẹ́ ìbánisọ̀rọ̀, títí kan ìwé ìròyìn àdúgbò àti ti orílẹ̀-èdè, àti tẹlifíṣọ̀n, ló fọhùn ìdùnnú nípa ìpolongo yìí. Ìwé ìròyìn Le Progrès de Lyon sọ pé: “Àtinúdá tí wọ́n lò yìí . . . gbé ọ̀rọ̀ kan tí wọ́n ń ṣì lóye sójútáyé. Láti ọdún mẹ́wàá síbí, ọ̀rọ̀ náà ‘ẹ̀ya ẹ̀sìn’ . . . ti ní ìtumọ̀ ẹ̀sìn tó kún fún àyídáyidà, tó léwu, tó sì lè pani lára. . . . Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í ṣe eléwu ẹ̀dá tó lè da àwùjọ rú.”
Àwọn tó mọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọyì bí wọ́n ṣe jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà, tí wọ́n sì ní ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ fún ètò táwùjọ gbé kalẹ̀. Nípa bẹ́ẹ̀, ọ̀pọ̀ èèyàn tó wà lójú pópó ló sọ ìmọrírì wọn jáde fún àwọn ẹgbẹẹgbàárùn-ún Ẹlẹ́rìí tó kópa nínú ìpolongo náà, wọ́n sì fi hàn pé àwọn tì wọ́n lẹ́yìn. Kíá làwọn èèyàn ń tẹ̀ wọ́n láago lórí tẹlifóònù, tí wọ́n ń lo ẹ̀rọ aṣàdàkọ ìsọfúnni, tí wọ́n sì ń kọ lẹ́tà láti dúpẹ́ ìwé àṣàrò kúkúrú náà. Lékè gbogbo rẹ̀, ó fún àwọn olóòótọ́ ọkàn láyè láti gbọ́ òtítọ́ nípa àwọn Ẹlẹ́rìí ní ìyàtọ̀ sí ọ̀rọ̀ tí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ àti ti òpònú tí àwọn kan ń sọ nípa wọn, ó sì tún mú káwọn táa ti sọ̀rọ̀ búburú nípa ìgbàgbọ́ wọn lè fìmọ̀lára wọn hàn fún ohun tó jẹ́ ọ̀wọ́n sí wọn.