A Jàǹfààní Láti Inú Àwọn Àpéjọpọ̀ “Ọ̀nà Ìgbésí Ayé Tí Ọlọ́run Fẹ́”
1 Níwọ̀n oṣù díẹ̀ sẹ́yìn, a ń wéwèé láti lọ sí àwọn Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Ọ̀nà Ìgbésí Ayé Tí Ọlọ́run Fẹ́.” Nísinsìnyí, wọ́n ti di ohun mánigbàgbé pàtàkì nínú ìtàn ètò àjọ ìṣàkóso Ọlọ́run. A gbádùn oúnjẹ tẹ̀mí tí a rí gbà ní àwọn ìkórajọpọ̀ títayọ lọ́lá wọ̀nyẹn dáadáa.
2 Ìròyìn yíká ayé tí a rí gbọ́ ní àwọn àpéjọpọ̀ ọdún yìí múni lọ́kàn yọ̀ gidigidi. Yálà àwọn míṣọ́nnárì àti àwọn aṣojú láti àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn wà ní àpéjọpọ̀ tí a lọ tàbí wọn kò sí, gbogbo wa ló gbọ́ àwọn ìrírí àtàtà ní ọ̀sán ọjọ́ Friday nínú apá náà, “Sísìn Gẹ́gẹ́ Bí Míṣọ́nnárì.” “Ìròyìn Nípa Ìtẹ̀síwájú Iṣẹ́ Ìkórè Náà” yíká ayé tí a gbọ́ lọ́jọ́ kọ̀ọ̀kan fúnni níṣìírí gidigidi.
3 Àwọn Ìmújáde Tuntun Tí Ó Jẹ́ Àgbàyanu: Àsọyé tí ó kẹ́yìn ní ọjọ́ Friday dáhùn ìbéèrè kan tí ọ̀pọ̀ ènìyàn tí kò mọ òtítọ́ ti béèrè pé: “Ìwàláàyè Ha Wà Lẹ́yìn Ikú Bí?” Mímú ìwé pẹlẹbẹ tuntun náà, Kí Ní Ń Ṣẹlẹ̀ sí Wa Nígbà Tí A Bá Kú? jáde ni a fi kádìí àwíyé tí ó gbádùn mọ́ni gidigidi yẹn. Ó dájú pé ní báyìí, a óò ti kà á, a óò sì ti rí bí yóò ṣe wúlò tó ní ríran àwọn ènìyàn lọ́wọ́ láti mọ ohun tí ó jẹ́ òtítọ́ nípa ipò àwọn òkú, tí yóò sì fi ìrètí àjíǹde tu àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ nínú.
4 Àsọyé náà, “Ẹlẹ́dàá—Àkópọ̀ Ìwà Rẹ̀ àti Àwọn Ọ̀nà Rẹ̀,” ni ó parí ìtòlẹ́sẹẹsẹ ọ̀sán ọjọ́ Saturday. Lọ́nà tó bọ́gbọ́n mu, ó mú wa parí èrò sí pé Ẹlẹ́dàá kan gbọ́dọ̀ wà. Láti mú kí a ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti mọ òtítọ́ yìí, a mú ìwé náà, Is There a Creator Who Cares About You? jáde. Nígbà tí ó jẹ́ pé ìwé yìí ń mú kí ìgbàgbọ́ wa nínú Jèhófà àti ìmọrírì tí a ní fún àkópọ̀ ìwà rẹ̀ àti àwọn ọ̀nà rẹ̀ pọ̀ sí i, a ṣe ìwé náà ní pàtàkì fún àwọn tí ó jẹ́ pé wọn kò gba Ọlọ́run gbọ́ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀mọ̀wé ni wọ́n nínú ayé.
5 Ìpinnu Àtọkànwá Kan: Àsọyé tí ó kẹ́yìn ní àpéjọpọ̀ náà tẹnu mọ́ bí ó ti yẹ fún gbogbo wa láti “Máa Bá A Nìṣó Ní Rírìn Ní Ọ̀nà Jèhófà.” Ẹ wo bí ó ti bá a mu tó pé a fi ìpinnu wa hàn ní gbangba pé lẹ́nì kọ̀ọ̀kan, a pinnu láti rọ̀ mọ́ ọ̀nà ìgbésí ayé tí Ọlọ́run fẹ́ pé ó dára jù lọ. A ó ṣalágbàwí rẹ̀, a ó sì máa gbé e lárugẹ nígbà gbogbo! (Aísá. 30:21) Nísinsìnyí, a gbọ́dọ̀ ṣe tán láti gbé ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ohun tí a pinnu wọ̀nyí. Ẹ wo ìmúsunwọ̀nsi nípa tẹ̀mí tí a rí gbà nípa lílọ sí Àpéjọpọ̀ “Ọ̀nà Ìgbésí Ayé” tí Ọlọ́run Fẹ́!”