Awọn Ibukun Jìngbìnnì ni Apejọpọ Agbegbe “Awọn Olùtan Ìmọ́lẹ̀”
NI NǸKAN bi 2,700 ọdun sẹhin, wolii Isaiah kọwe pe: “Nitori kiyesi i, okunkun bo ayé mọlẹ, ati okunkun biribiri bo awọn eniyan.” (Isaiah 60:2) Ẹ wo bi awọn ọ̀rọ̀ wọnni ti jásí otitọ tó! Bi o ti wu ki o ri, ireti wà, nitori Jehofa ti mú ki ìmọ́lẹ̀ tàn jade. Ni ọdun ti o kọja, awọn ti wọn fẹran ìmọ́lẹ̀ Ọlọrun ni a fi tọyayatọyaya késí lati wá si Apejọpọ Agbegbe “Awọn Olùtan Ìmọ́lẹ̀.”
Itolẹsẹẹsẹ apejọpọ naa ni a kọkọ gbejade ni June ni ìhà Ariwa America. Ni awọn oṣu ti o tẹle, a ti gbe e jade pẹlu ni ìhà Ila-oorun ati ìhà Iwọ-oorun Europe, Aarin Gbungbun ati Guusu America, Africa, Asia, ati ni awọn erekuṣu òkun pẹlu. Awọn ti wọn ti wá ti wọ araadọta-ọkẹ ni iye. Ẹ si wo iru apejẹ tẹmi ọlọ́ràá ti wọn ti gbadun!
“Ẹ Kaabọ, Gbogbo Ẹyin Olùtan Ìmọ́lẹ̀!”
Ni ibi pupọ julọ apejọpọ naa bẹrẹ ni ọjọ Friday ó sì pari ni ọsan ọjọ Sunday. Bi awọn olupejọpọ naa ṣe jokoo si ori ijokoo wọn ni owurọ ọjọ Friday, a mú wọn gbadun akojọpọ ni ṣoki nipa ọ̀nà ti ìmọ́lẹ̀ Jehofa ti gbà tàn yòò ju ti ìgbàkígbà rí lọ ni awọn ọjọ ikẹhin wọnyi. Lẹhin naa ni alaga apejọpọ naa gun ori pepele. O tẹnumọ ọn pe awọn Kristian tootọ gbọdọ jẹ́ olùtan ìmọ́lẹ̀ ó sì fi tọyayatọyaya wi pe: “Ẹ kaabọ, gbogbo ẹyin olùtan ìmọ́lẹ̀!” Itolẹsẹẹsẹ apejọpọ naa yoo ran awọn àyànṣaṣojú lọwọ lati maa baa lọ lati ṣagbeyọ ìmọ́lẹ̀ Jehofa.
Lajori ọrọ-asọye naa fidii bi gbogbo apejọpọ naa yoo ṣe ri ni gbogbogboo mulẹ. Olubanisọrọ yii rán awọn olupejọpọ leti pe ìmọ́lẹ̀ naa kú fun iran-eniyan tipẹtipẹ sẹhin ni ọgba Edeni. Lati ìgbà naa wa, Satani ti fọ́ awọn eniyan loju si ìmọ́lẹ̀ otitọ. (2 Korinti 4:4) Bi o tilẹ ri bẹẹ, Jesu wá gẹgẹ bi “ìmọ́lẹ̀ awọn [awọn orilẹ-ede, NW].” (Isaiah 42:1-6) O tudii aṣiiri èké ti ń bẹ ninu isin, ó fi awọn iṣẹ́ aitọ ti o jẹ́ ti okunkun hàn, o gbe ipo ọba-alaṣẹ Jehofa larugẹ, ó sì waasu ihinrere Ijọba naa. Awọn ọmọlẹhin Jesu ṣe bakan naa—wọn sì ń baa lọ ni ṣiṣe bẹẹ! (Matteu 28:19, 20) Olubanisọrọ naa lọna ti ń taniji sọ pe: ‘Awa, gẹgẹ bii Jesu, lè jẹ́ olùtan ìmọ́lẹ̀. Kò sí iṣẹ́ ti o ṣe pataki jù ú ni ọjọ wa. Kò sì sí anfaani kan ti o tobi jù lọ.’
Bi akoko ijokoo fun apejọpọ akọkọ ti ń sunmọ ipari rẹ̀, iyanu kan ṣẹlẹ. Alaga apejọpọ naa pada si ori pepele ó sì ṣefilọ imujade akọkọ ninu awọn ọ̀wọ́ iwe-aṣaro-kukuru mẹrin. Atẹwọ onitara pade ifilọ yii, a sì jẹ ki ẹ̀dà kọọkan iwe-aṣaro-kukuru yii wà larọọwọto fun àyànṣaṣojú kọọkan ti o wá sibẹ.
Ni ọsan ọjọ Friday, itolẹsẹẹsẹ apejọpọ naa dori imọran ti o ṣekoko kan fun awọn Kristian olùtànmọ́lẹ̀. Awọn ọrọ-asọye meji akọkọ pese imọran daradara lori bi a ṣe lè yẹra fun jijẹ ẹni ti a sọ di ẹlẹgbin nipasẹ òkùnkùn ayé. Niwọn bi Satani ti lè farahan bi angẹli ìmọ́lẹ̀, o ṣekoko lati mú oju-iwoye tẹmi dagba ki awọn nǹkan aláìmọ́ ti ayé má baà ré wa lọ. (2 Korinti 11:14) Paulu gbaninimọran pe: “Ki ẹ ma sì da ara yin pọ mọ ayé yii: ṣugbọn ki ẹ parada lati di titun ni iro-inu yin, ki ẹyin ki o lè rí idi ifẹ Ọlọrun, ti o dara, ti o sì ṣe itẹwọgba, ti o si pe.” (Romu 12:2) Awọn àyànṣaṣojú sibi apejọpọ naa gbọ pe iyipada Kristian kan jẹ ohun kan ti ń baa lọ laidawọduro. Ọkàn wa ni a ń sọ di mímọ́ ti a si ń mọ lemọlemọ bi a ti ń kẹkọọ Ọ̀rọ̀ Ọlọrun ti a sì ń fi ohun ti a ń kọ́ silo. Nipa bayii, a ń dabii Jesu siwaju ati siwaju sii, ẹni ti “o kun fun oore-ọfẹ ati otitọ.”—Johannu 1:14.
Awọn Ọ̀dọ́ Olùtan Ìmọ́lẹ̀
Apa ilaji ti o gbẹhin ni ọ̀sán ọjọ Friday ni a dari si awọn èwe. Ọrọ-asọye akọkọ naa (“Ẹyin Èwe—Kí Ni Ẹyin Ń Lépa?”) gboriyin fun awọn ọ̀dọ́ Kristian ti wọn jẹ iru apẹẹrẹ iduroṣinṣin rere bẹẹ. Ṣugbọn ó rán wọn létí pe wọn jẹ́ àdásọjú fun Satani ni pato. Àní oludije ti a ti kọ́ daradara kan paapaa nilo olukọ kan. Ni ọ̀nà kan-naa, awọn ọ̀dọ́ nilo iranlọwọ awọn òbí wọn ati ti ijọ kí wọn baà lè maa baa lọ ninu ririn ninu ìmọ́lẹ̀.
Eyi ni a tẹnumọ nipa awokẹkọọ ti o pegede naa Ṣiṣe Ohun Ti O Tọ́ Ni Oju Jehofa, eyi ti o pari itolẹsẹẹsẹ ọjọ Friday. A tẹnumọ apẹẹrẹ Ọba Josiah. Àní gẹgẹ bi ọdọmọdekunrin paapaa, o pinnu lati ṣiṣẹsin Jehofa. Awọn agbara-idari buburu wà yí i ká, ṣugbọn pẹlu itọsọna alufaa agba Hilkiah ati nitori ifẹ oun funraarẹ fun Ofin Ọlọrun, Josiah ṣe ohun ti o tọ́ ni oju Jehofa. Ǹjẹ́ ki awọn ọdọ Kristian lonii gbe igbesẹ ni ọ̀nà kan-naa.
Jẹ́ Ki Ìmọ́lẹ̀ Tàn
Lẹhin isinmi alẹ, awọn àyànṣaṣojú wá si apejọpọ ni owurọ Saturday ni mimuratan fun imọran agbeniro ti o bá Iwe Mimọ mu siwaju sii. A kò já wọn kulẹ. Lẹhin ijiroro ẹsẹ iwe mimọ ọjọ naa, itolẹsẹẹsẹ naa ń baa lọ pẹlu apinsọ ọrọ-asọye kan ti o lapa oriṣiriṣi ọ̀nà ti Kristian kan lè gba jẹ ki ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ tan. (Matteu 5:14-16) Wiwaasu jẹ́ ọ̀nà ṣiṣekoko kan, iwa ti o dara sì tun kó ipa ti o ṣe pataki. Gẹgẹ bi olubanisọrọ naa ṣe sọ, “wiwaasu ń sọ ohun ti a gbagbọ fun awọn ẹlomiran, ṣugbọn lilo ifẹ ni ń fi i hàn.”
Aranṣe iwaasu kan ti o ṣekoko ni a mú wa si afiyesi awọn olupejọpọ lẹhin naa—awọn ìwé-àṣàrò-kúkúrú. Pẹlu ifilọ ọjọ akọkọ ti o ṣi ṣe kedere ninu ọkàn wọn, awọn àyànṣaṣojú gbọ iriri ti o fihàn bi awọn irin-iṣẹ keekeeke yii ṣe lagbara tó. Awọn àyànṣaṣojú ni a fun ni iṣiri lati ni ipese awọn ìwé-àṣàrò-kúkúrú pẹlu wọn nigba gbogbo, ni imuratan fun gbogbo akoko.
Tẹle e ni a yiju afiyesi si awọn aṣaaju-ọna, awọn olupokiki Ijọba alakooko kikun wọnni ti wọn ń ṣiṣẹ kára ni mimu ki ìmọ́lẹ̀ tàn. Ẹ wo bi a ṣe mọriri awọn aṣaaju-ọna wa ti wọn jẹ́ oṣiṣẹ kára tó! Iye wọn si ń ga sii. Àní ni awọn ilẹ ti a ti ṣẹṣẹ yọọda fun ominira ijọsin paapaa, òtú awọn aṣaaju-ọna ń roke sii. Awọn aṣaaju-ọna ni a fun ni iṣiri lati ka anfaani wọn si iṣura iyebiye. Awọn ti kò tii maa ṣe aṣaaju-ọna ni a rọ̀ lati gbe ipo wọn yẹwo. Boya awọn naa lè ṣeto alamọri wọn lati jẹ ki ìmọ́lẹ̀ wọn tàn siwaju sii ninu iṣẹ-isin alakooko kikun.
Jijẹ olùtan ìmọ́lẹ̀ sábà maa ń ni awọn irubọ ninu, eyi ni a sì tẹnumọ ninu ọrọ-asọye ti o tẹle e, “Ṣiṣiṣẹsin Jehofa Pẹlu Ẹ̀mí Ifara-ẹni-rubọ.” Paulu rọ̀ wa pe: “Ki ẹyin ki o fi ara yin fun Ọlọrun ni ẹbọ ààyè, mímọ́, itẹwọgba.” (Romu 12:1) Ẹmi ifara-ẹni-rubọ ni a fihàn niha ọ̀dọ̀ awọn ti wọn bá farada inunibini. Awọn aṣaaju-ọna ń ṣe irubọ lojoojumọ ki wọn baà lè duro ninu iṣẹ-isin alakooko kikun. Nitootọ, gbogbo awọn Kristian tootọ ń ṣe irubọ, ni mimu ọwọ́ wọn dí ninu iṣẹ-isin Jehofa dipo ki o jẹ́ ninu ilepa onimọ-tara-ẹni-nikan, onifẹẹ ọrọ̀-àlùmọ́nì ti ayé yii. Ipa-ọna kan bẹẹ ń yọrisi ibukun jìngbìnnì lati ọ̀dọ̀ Jehofa.
Ọ̀rọ̀ awiye yẹn ṣiṣẹ gẹgẹ bi inasẹ-ọrọ yiyẹ fun ohun ti o tẹle e—ọ̀rọ̀ iribọmi. Awọn ti a ṣe iribọmi fun ni Apejọpọ Agbegbe “Awọn Olùtan Ìmọ́lẹ̀” dajudaju kì yoo gbagbe ọrọ-asọye yii. Iribọmi wọn yoo maa baa lọ lati gbé itẹnumọ pataki rù ninu igbesi-aye wọn. Awọn ni a rán létí pe wọn ń tẹle apẹẹrẹ Jesu Kristi, ẹni ti a baptisi ni ẹni 30 ọdun. Siwaju sii, awọn olunaga fun anfaani iribọmi naa ni inu wọn dùn lati ranti pe awọn ti “bọ́ ara iṣẹ́ òkùnkùn silẹ,” ti wọn sì ti ṣe ipinnu lati “maa sin Oluwa.” (Romu 12:11; 13:12) Wọn fi tayọtayọ duro niwaju awọn awujọ apejọpọ wọn sì ṣe ikede itagbangba ti a lè gbọ́ ketekete ṣaaju ki wọn tó jade lọ fun iribọmi. (Romu 10:10) A gbadura fun ibukun Jehofa lori gbogbo awọn wọnni ti wọn fami ṣapẹẹrẹ iyasimimọ wọn fun un nipa ṣiṣe iribọmi ninu omi nigba awọn Apejọpọ Agbegbe “Awọn Olùtan Ìmọ́lẹ̀.”
Ọ̀sán Saturday jẹ́ akoko fun awọn ikilọ ti o sọ oju abẹ nikoo. Iwọnyi ni a sọ gẹgẹ bi ọrọ-asọye ti a fun ni akori naa “Yẹra fun Awọn Ìdẹkùn Ìwọra.” “Ẹnikan Ha Ń Ba Awọn Ìwà Wíwúlò Rẹ Jẹ́ Bi?” ati ‘Ẹ Sọra fun Gbogbo Oniruuru Ìbọ̀rìṣà.’ Awọn ọrọ-asọye mẹta wọnyi fi diẹ ninu awọn ọgbọn-ẹwẹ tí Satani ń lò lati mú ki Kristian kan di alailera hàn. Aposteli kan ni Judasi Iskariotu jẹ́, ṣugbọn o da Jesu nitori owó. Samueli ọ̀dọ́ dagbasoke ni aarin gbungbun ijọsin Jehofa ti orilẹ-ede kan, ṣugbọn oun laisi ọ̀nà ajabọ ni a ṣipaya si ibakẹgbẹpọ buburu jai meloo kan. (1 Samueli 2:12, 18-20) Ibọriṣa lè ni awọn nǹkan bi iwa-palapala takọtabo ati ojukokoro ninu. (Efesu 5:5; Kolosse 3:5) Bẹẹni, ìwọra, awọn ẹgbẹ́ buburu, ati ibọriṣa léwu a sì gbọdọ yẹra fun wọn.
Itolẹsẹẹsẹ apejọpọ naa yà bàrá, gẹgẹ bi a ṣe lè sọ pe o jẹ́. Ọrọ-asọye ti o tẹle e gbé awọn ibeere Bibeli ti o fanilọkanmọra pupọ dide o sì dahun wọn. Fun apẹẹrẹ, iwọ ha lè ṣalaye boya awọn eniyan ti wọn kò tẹwọgba otitọ ti wọn sì kú ṣaaju ipọnju nla ni a o ji dide bi? Ki ni Kristian kan lè ṣe nigba ti oun lọkunrin tabi lobinrin kò ba ri olubaṣegbeyawo ti o yẹ wẹku? Lati mú ki ìmọ̀ Bibeli wọn jinlẹ sii, awọn àyànṣaṣojú ni a rọ̀ lati lo Watch Tower Publications Index, ni pataki julọ labẹ akori naa “Ibeere Lati Ọwọ́ Awọn Òǹkàwé.”
Wíwàníhìn-ín Kristi ati Iṣipaya
Apa ti o kẹhin itolẹsẹẹsẹ Saturday dálé asọtẹlẹ pẹlu apinsọ ọrọ-asọye ti a fun ni akọle naa “Titan Ìmọ́lẹ̀ Sori Wíwàníhìn-ín ati Iṣipaya Kristi.” Apa-iha “ami naa” ti o jẹrii si wíwàníhìn-ín Jesu Kristi ni a tun gbeyẹwo. (Matteu 24:3) Ninu apa keji, awọn igbokegbodo “ẹrú oluṣotitọ ati ọlọgbọn-inu naa” ni a jiroro. (Matteu 24:45-47, NW) A ṣalaye pe lati 1919 ẹgbẹ́ ẹrú naa ti fi iṣotitọ ṣagbatẹru iṣẹ́ wiwaasu ihinrere Ijọba naa. Lẹhin naa ni a kó awọn ogunlọgọ nla jọ lati inu gbogbo orilẹ-ede lati ṣajọpin pẹlu awọn Kristian ẹni-ami-ororo ninu gbigbe ìmọ́lẹ̀ Jehofa yọ. Olubanisọrọ naa pari rẹ̀ pe: “Ẹ jẹ ki gbogbo wa maa baa lọ pẹlu itara lati ti ẹrú oluṣotitọ ati ọlọgbọn-inu naa lẹhin. Kìkì nipa ṣiṣe eyi ni yoo fi jẹ pe lọjọ kan laipẹ gbogbo awọn ẹni-bi-agutan yoo lè gbọ́ ọ̀rọ̀ onidunnu naa pe: “Ẹ wa, ẹyin alabukun fun Baba mi, ẹ jogun ijọba, ti a ti pese silẹ fun yin lati ọjọ ìwà.”—Matteu 25:34.
Olubanisọrọ ti o kẹhin jiroro itumọ ati ohun ti awọn iṣipaya Jesu Kristi dọgbọn tumọsi. (1 Korinti 1:7) Ẹ wo iru iriri ti iṣipaya yẹn yoo jẹ́! Babiloni Nla ni a o parun. Ogun nla ti o wà laaarin ayé Satani ati Jesu ati awọn angẹli rẹ̀ ni yoo dopin nigba iparun eto-igbekalẹ yii. Lakootan, Satani funraarẹ ni a o jù sinu ọgbun ti a o si sọ di alaiṣiṣẹ mọ. Ṣugbọn itura yoo wà fun awọn eniyan Ọlọrun, pẹlu iyawo Ọdọ-agutan ni ọrun ati imujade ori ilẹ̀-ayé titun kan. Olubanisọrọ naa dun awọn awujọ olugbọ rẹ̀ ninu nipa mimu iwe-pẹlẹbẹ titun naa Ọlọrun Ha Bikita Nipa Wa Niti Gidi Bi? jade. Ẹ wo iru iranlọwọ didara ti iyẹn yoo jẹ fun gbogbo eniyan onirẹlẹ ti wọn nilati mọ̀ nipa Ẹlẹdaa wa ti o bikita ati awọn ète rẹ̀ fun wa!
Awọn Agbo-ile Kristian
Sunday, ọjọ ti o kẹhin apejọpọ naa, ti de nisinsinyi. Bi o ti wu ki o ri, pupọ sii ni o ṣì wà lati gbejade. Lẹhin ijiroro ẹsẹ iwe mimọ ojoojumọ ti ọjọ naa, afiyesi ni a fifun idile Kristian pẹlu apinsọ ọrọ-asọye naa “Bibojuto Ẹnikinni Keji Ninu Agbo-ile Kristian.” Apa akọkọ ran awọn olupejọpọ lọwọ lati mọ aṣiri nini idile Kristian alaṣeyọrisirere: fifi awọn ohun ti ẹmi sipo akọkọ. Apa keji fun awọn idile niṣiiri lati ṣe awọn nǹkan papọ, boya iyẹn wemọ lilọ si ipade, iṣẹ-isin papa, ikẹkọọ idile, tabi eré-ìtura. Apa kẹta apinsọ ọrọ-asọye naa si rán awọn àyànṣaṣojú létí anfaani ati ẹrù-iṣẹ́ wọn lati bojuto awọn agbalagba. “Awọn arakunrin ati arabinrin wa jẹ ohun eelo kan fun ijọ,” ni olubanisọrọ naa wi. Ẹ jẹ ki a ka iriri wọn si iṣura iyebiye ki a si ṣafarawe ipawatitọmọ wọn.
Itumọ ọ̀rọ̀ naa “wà ni airekọja” ni a gbeyẹwo tẹle e. (1 Peteru 4:7) Ẹnikan ti o wa ni airekọja wà deedee, ó loye, ó lọgbọn ninu, ó jẹ́ onirẹlẹ, ó sì níyè-nínú. O le fi iyatọ saaarin rere ati buburu, otitọ ati èké. Siwaju sii, o ń lakaka lati di ilera daradara nipa tẹmi mu.
Ọ̀rọ̀ ti o kẹhin lori itolẹsẹẹsẹ òwúrọ̀ Sunday jiroro itẹriba wa si Ọlọrun ati Kristi. “Ijẹpataki wíwà ni ijuwọsilẹ oniduuroṣinṣin si Jehofa Ọlọrun ati si Ọmọkunrin rẹ̀, Jesu Kristi, ni a kò lè gbojufoda,” ni olubanisọrọ naa sọ. O ń baa lọ lati fihàn bi eyi ṣe nipa lori gbogbo apa ìhà igbesi-aye wa. Ki ni yoo ràn wá lọwọ lati maa baa lọ ni jijuwọsilẹ? Animọ mẹrin ni: ifẹ, ibẹru oniwa-bi-Ọlọrun, igbagbọ, ati irẹlẹ.
Ọ̀sán Sunday
Kátówí-kátófọ̀, o di ọ̀sán Sunday ati akoko ijokoo fun apa ti o kẹhin apejọpọ naa. Fun ọpọlọpọ, ó dabi ẹni pe apejọpọ naa ṣẹṣẹ bẹrẹ ni, ó sì ti ń sunmọ ipari rẹ̀ ni akoko yii.
Asọye fun gbogbo eniyan ni a fun ní akọle naa “Ẹ Tẹle Ìmọ́lẹ̀ Ayé Naa.” Gbogbo awọn ti o wà nibẹ ni a tẹlọrun pẹlu àlàyé ti ń fanimọra nipa ipa ti ìmọ́lẹ̀ gidi ń kó lati gbé iwalaaye ró. Lẹhin naa ni olubanisọrọ fi ijẹpataki giga ju ti ìmọ́lẹ̀ tẹmi hàn. Ìmọ́lẹ̀ gidi ń mu wa walaaye fun awọn ẹwadun diẹ, ṣugbọn ìmọ́lẹ̀ tẹmi lè mu ki a maa walaaye titi ayeraye. Akopọ ọrọ-asọye naa jẹ ijiroro Johannu 1:1-16 lẹsẹẹsẹ, nibi ti a ti fi Jesu hàn gẹgẹ bi ìmọ́lẹ̀ ayé. Lonii, ni awọn ọdun ikẹhin ti eto-igbekalẹ buburu yii, o jẹ kanjukanju ju ti igbakigba ri lọ lati tẹle Jesu ninu ila-iṣẹ yii.
Lẹhin akopọ akojọpọ-ọrọ Ikẹkọọ Ilé-Ìṣọ́nà ti a yàn fun ọsẹ naa, akoko tó fun ọ̀rọ̀ ipari. Lọna ti o munilayọ, olubanisọrọ naa fihàn pe ọpọlọpọ nǹkan wà ti a nilati maa wọna fun lọjọ iwaju. Fun apẹẹrẹ, o ṣefilọ kasẹẹti àtẹ́tísí titun kan, awọkẹkọọ naa, Doing God’s Will With Zeal. Kò sì tán sibẹ. Ọ̀wọ́ awọn kasẹẹti fidio titun ti a fun lakọle naa The Bible—A Book of Fact and Prophecy, akọkọ ninu ọrọ-ẹkọ naa The Bible—Accurate History, Reliable Prophecy yoo wà.
Lakootan, olubanisọrọ naa ṣefilọ pe ni 1993 apejọpọ agbegbe ọlọjọ mẹrin yoo wà, eyi ti o ní awọn ikorajọpọ akanṣe jakejado awọn orilẹ-ede ni Africa, Asia, Europe, ati ìhà Guusu America ninu. Àní bi o tilẹ jẹ pe Apejọpọ Agbegbe “Awọn Olùtan Ìmọ́lẹ̀” ń pari, awọn àyànṣaṣojú lè bẹrẹ sii wewee fun ọdun ti yoo tẹle e.
Lẹhin naa ni akoko tó fun awọn àyànṣaṣojú lati lọ si ile. Dajudaju, ju ti igbakigba ri lọ wọn de ori ipinnu naa lati maa baa lọ ni fifi ìmọ́lẹ̀ hàn ninu ayé ti òkùnkùn ti bo yii. Lẹhin ọjọ mẹta ti ó kunfọfọ fun awọn ohun daradara nipa ti ẹmi, ọ̀rọ̀ iwe mimọ ti o kẹhin ti a fayọ ninu ọrọ-asọye ipari gbé ijẹpataki nla rù: “Ọlọrun ni Oluwa, ti o ti fi ìmọ́lẹ̀ hàn fun wa: . . . ẹ fi ọpẹ fun Oluwa; nitori ti o ṣeun: nitori ti aanu rẹ̀ duro laelae.”—Orin Dafidi 118:27, 29.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Itolẹsẹẹsẹ apejọpọ ni èdè Russia
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16, 17]
Awọn mẹmba Ẹgbẹ́ Oluṣakoso sọrọ ni ọpọlọpọ apejọpọ
Awọn àyànṣaṣojú ara Japan wà lara awọn wọnni ti wọn pejọ si St. Petersburg, Russia
Awokẹkọọ Bibeli ti ń taniji kan tẹnumọ aini naa lati ṣe ohun ti o tọ́ ni oju Jehofa
Awọn olùtan ìmọ́lẹ̀ titun fàmì ṣapẹẹrẹ iyasimimọ wọn si Jehofa nipa ṣiṣe iribọmi
Awọn Olupejọpọ tí itolẹsẹẹsẹ naa ni St. Petersburg wọ̀ lọ́kàn ṣinṣin
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Awọn àyànṣaṣojú ni a ru imọlara wọn soke lati gba iwe-pẹlẹbe titun naa “Ọlọrun Ha Bikita Nipa Wa Niti Gidi Bi?”