ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w92 10/1 ojú ìwé 30-31
  • Wá sí Apejọpọ Agbegbe “Awọn Olùtan Ìmọ́lẹ̀”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Wá sí Apejọpọ Agbegbe “Awọn Olùtan Ìmọ́lẹ̀”
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Awọn Ibukun Jìngbìnnì ni Apejọpọ Agbegbe “Awọn Olùtan Ìmọ́lẹ̀”
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Awọn Wo ni Wọn Ń Tẹle Ìmọ́lẹ̀ Ayé?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Awọn Olùtan Ìmọ́lẹ̀—Fun Ète Wo?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • “Kí Ìmọ́lẹ̀ Yín Máa Tàn”
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2001
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
w92 10/1 ojú ìwé 30-31

Wá sí Apejọpọ Agbegbe “Awọn Olùtan Ìmọ́lẹ̀”

“NITORI kiyesi i, okunkun bo ayé mọlẹ, ati okunkun biribiri bo awọn eniyan.” (Isaiah 60:2) Ẹ wo bi awọn ọ̀rọ̀ wọnni ti jẹ́ otitọ tó lonii! Laisi iyemeji, ijọsin èké ń pa awọn eniyan mọ sinu okunkun niti iru ijọsin ti ó wu Ọlọrun. Eeṣe? Nitori pe Satani, ọlọrun eto igbekalẹ awọn nǹkan yii, “ti sọ ọkàn awọn ti kò gbagbọ di afọ́jú.”—2 Korinti 4:4.

Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa yatọ gédégédé ni ifiwera si awọn wọnni ti Satani fọ́ lójú. Awọn ni a lè lo awọn ọ̀rọ̀ wolii Isaiah naa fun pe: “Oluwa yoo yọ lara rẹ, a o sì rí ògo rẹ̀ lara rẹ.” (Isaiah 60:2) Ẹ wo bi wọn ti kún fun ọpẹ́ tó lati jade kuro ninu okunkun sinu ìmọ́lẹ̀ agbayanu Ọlọrun! Ó jẹ́ ìmọ́lẹ̀ tẹmi, otitọ Ọ̀rọ̀ Ọlọrun ti ń la ọkàn loye, debi pe awọn wọnni ti oju wọn fọ́ niti gidi lè rí otitọ.

Dajudaju, iranlọwọ ni a nilo. Kò jọ bi ohun ti o ṣeeṣe ki ẹnikan ti ó wulẹ ka Bibeli lailo anfaani awọn aranṣe ipese atọrunwa loye ìmọ́lẹ̀ naa. Idi niyẹn ti Jehofa Ọlọrun fi pese “ẹrú oluṣotitọ ati ọlọgbọn-inu,” ti a sọtẹlẹ ni Matteu 24:45-47 (NW). Lonii “ẹrú” naa ni Ẹgbẹ́ Oluṣakoso ti Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ń ṣoju fun. Labẹ idari ẹgbẹ́ yii ni a ti ṣeto fun Apejọpọ Agbegbe “Awọn Olùtan Ìmọ́lẹ̀.”

Ète apejọpọ yii ni lati ran gbogbo awọn eniyan Jehofa lọwọ lati jẹ́ olùtan ìmọ́lẹ̀ daradara sii, ni ibamu pẹlu awọn ọ̀rọ̀ Paulu ni Filippi 2:15. Nibẹ, awọn Kristian ni a ṣileti lati tàn yòò gẹgẹ bii “awọn afúnni ní ìmọ́lẹ̀ ninu ayé.”—Matteu 5:14, 16, NW.

Ni Nigeria, ọ̀wọ́ Apejọpọ Agbegbe “Awọn Olùtan Ìmọ́lẹ̀” ni a ṣetolẹsẹẹsẹ rẹ̀ lati bẹrẹ ni ọjọ Friday, November 6. Ni 9:20 òwúrọ̀, itolẹsẹẹsẹ ohùn-orin yoo ran gbogbo eniyan lọwọ lati wà ni ipo ọkan-aya ati ero-inu titọna, ní imuratan fun itolẹsẹẹsẹ tẹmi ti o wà niwaju. Ọjọ kọọkan ní ẹṣin-ọ̀rọ̀ tirẹ̀, ẹṣin-ọ̀rọ̀ ọjọ Friday sì ni “Rán Ìmọ́lẹ̀ Rẹ ati Otitọ Rẹ Jade.”—Orin Dafidi 43:3, NW.

Itolẹsẹẹsẹ òwúrọ̀ ọjọ Friday yoo ṣe ìgbéjáde kókó ọ̀rọ̀-àsọyé naa, “Awọn Olùtan Ìmọ́lẹ̀—Fun Ète Wo?” Dajudaju, awọn Kristian kìí ṣe olùtan ìmọ́lẹ̀ pẹlu ète isunniṣe ara-ẹni, ti onimọtara-ẹni-nikan eyikeyii. Kaka bẹẹ, wọn ń ṣiṣẹsin fun awọn idi kan-naa ti Jesu Kristi, Olori Olùtan Ìmọ́lẹ̀, fi wá si ilẹ̀-ayé, iyẹn ni, lati jẹrii si otitọ ati lati fogo fun orukọ Ẹlẹdaa. Lọna yíyẹwẹ́kú, Jesu sọ nipa araarẹ̀ pe: “Niwọn ìgbà ti mo wà ni ayé, emi ni ìmọ́lẹ̀ ayé.” (Johannu 9:5) Nipa bayii, ó fi apẹẹrẹ awokọṣe kan silẹ fun wa lati tẹle awọn ipasẹ rẹ̀ timọtimọ. (1 Peteru 2:21) Ọ̀sán ọjọ akọkọ yẹn yoo tẹnumọ ọ̀rọ̀-àsọyé kan ati awokẹkọọ Bibeli kan ti o dá lori Ọba Josiah, eyi ti awọn ọ̀dọ́ yoo ní akanṣe ọkàn-ìfẹ́ si.

Ẹṣin-ọ̀rọ̀ ọjọ Saturday ni “Ẹyin Ni Ìmọ́lẹ̀ Ayé . . . Ẹ Jẹ Kí Ìmọ́lẹ̀ Yin Ki O Mọ́lẹ̀.” (Matteu 5:14, 16) Itolẹsẹẹsẹ òwúrọ̀ yoo gbé ọ̀rọ̀-àpínsọ kan ti o ni àkọlé naa “Jijẹ Ki Ìmọ́lẹ̀ Yin Tàn” jade. A o pese anfaani fun awọn wọnni ti wọn ti ṣe iyasimimọ si Jehofa lati ṣe iribọmi. Itolẹsẹẹsẹ ọ̀sán yoo gbé ọ̀rọ̀-àpínsọ kan ti ń lani lóye kalẹ ti o ni àkọlé naa “Titan Ìmọ́lẹ̀ Sori Wíwàníhìn-ín ati Iṣipaya Kristi.”

Ẹṣin-ọ̀rọ̀ ti a yàn fun Sunday, tii ṣe ọjọ kẹta ati ọjọ ti o kẹhin apejọpọ naa, ni “Ẹ Maa Rìn Gẹgẹ Bi Awọn Ọmọ Ìmọ́lẹ̀.” (Efesu 5:8) Itolẹsẹẹsẹ òwúrọ̀ yoo ni ninu ọ̀rọ̀-àpínsọ ti o ni àkọlé naa “Bibojuto Ẹnikinni Keji Ninu Agbo-ile Kristian” eyi ti yoo bojuto awọn iṣẹ aigbọdọmaṣe idile. Ọ̀rọ̀-àsọyé kan ti ń ṣalaye ohun ti o tumọsi lati wà ni itẹriba si Ọlọrun ati Kristi yoo wà pẹlu.

Apejọpọ naa yoo dé òtéńté rẹ̀ ni ọ̀sán ọjọ Sunday pẹlu ọ̀rọ̀-àsọyé fun gbogbo eniyan ti o ni àkọlé naa “Ẹ Tẹle Ìmọ́lẹ̀ Ayé Naa.” Àsọyé yii yoo ni ijiroro Johannu 1:1-16 ninu yoo sì fi aini naa fun ìmọ̀ Bibeli hàn, ni titẹnumọ ọn pe Jesu Kristi ni imọlẹ ayé naa. Apejọpọ naa yoo pari pẹlu igbaniniyanju onitara-ọkan lati “Maa Ba a Lọ Ni Rínrìn Ninu Ìmọ́lẹ̀.”

Fi imọriri rẹ hàn fun àsè tẹmi ti Jehofa ń pese nipasẹ eto-ajọ rẹ̀ ti a lè fojuri. Wà nibẹ lati orin ibẹrẹ ni òwúrọ̀ ọjọ Friday titi di adura ipari ni ọ̀sán ọjọ Sunday. Fi iyè gidigidi si gbogbo ohun ti a sọ lati ori pepele. Ṣe akọsilẹ lati ràn ọ́ lọwọ lati pa ọkàn pọ̀ ati fun ìtọ́ka ọjọ iwaju. Nikẹhin, wéwèé lati nipin-in ninu iru iṣẹ-isin iyọnda ara-ẹni kan. Nipa bayii, iwọ yoo gbadun kìí ṣe kiki ibukun ti rírígbà nikan ṣugbọn ibukun titobi ju ti fifunni paapaa.—Iṣe 20:35.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́