Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Yóò Ṣe Àpéjọpọ̀ Àgbáyé
Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń wéwèé láti ṣe àpéjọpọ̀ àgbáyé ní 1998. Ayọ̀ ńláǹlà ni a fi tẹ́wọ́ gba ìkéde yìí níbi ìpàdé ọdọọdún ti Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania, tí ó wáyé ní Gbọ̀ngàn Àpéjọ Ìlú Jersey, ní Saturday, October 5, 1996.
A óò ṣe ọ̀pọ̀ àpéjọpọ̀ àgbáyé ní Àríwá America ní àárín 1998, pẹ̀lú àwọn àpéjọpọ̀ àgbègbè tí a sábà máa ń ṣe. A retí pé àwọn àpéjọpọ̀ wọ̀nyí yóò mú ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rọ̀ọ̀rún Ẹlẹ́rìí wà papọ̀ láti apá ibi púpọ̀ lórí ilẹ̀ ayé. Kí ó baà lè ṣeé ṣe láti ṣojú fún ọ̀pọ̀ ilẹ̀ bí ó bá ti lè ṣeé ṣe tó, ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì Watch Tower Society tí ó lé ní 100 yóò ní iye àyànṣaṣojú kan pàtó fún ìlú àpéjọpọ̀ àgbáyé tí a bá yàn wọ́n sí ní Àríwá America.
Ó ṣe kedere pé, kì í ṣe gbogbo ẹni tí yóò fẹ́ láti rin ìrìn àjò lọ sí Àríwá America ni yóò lè ṣe bẹ́ẹ̀. Ṣùgbọ́n, ó lè ṣeé ṣe fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún láti lọ sí àpéjọpọ̀ àgbáyé tí ó sún mọ́ wọn. Ètò ti ń lọ lọ́wọ́ láti ṣe àwọn àpéjọpọ̀ àgbáyé ní àwọn orílẹ̀-èdè méjì tàbí mẹ́ta ní Europe, àti àwọn mìíràn ní Áfíríkà, Éṣíà, Latin America, Gúúsù Pacific, àti ní Caribbean.
Nígbà tí àkókò bá tó, àwọn ọ́fíìsì ẹ̀ka Society yóò fi tó àwọn ìjọ tí ó wà ní àgbègbè ìpínlẹ̀ wọn létí nípa ìlú tàbí àwọn ìlú àpéjọpọ̀ tí a óò ké sí wọn sí. A óò fúnni ní ìsọfúnni nípa ọjọ́ àpéjọpọ̀ àti ètò yíyan àwọn àyànṣaṣojú. Àwọn tí wọ́n bá ní in lọ́kàn láti kọ̀wé béèrè fún jíjẹ́ àyànṣaṣojú lè tètè bẹ̀rẹ̀ sí í fi owó pamọ́ díẹ̀díẹ̀ ní ìfojúsọ́nà fún àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ àkànṣe wọ̀nyí.
Gbogbo Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé lè fojú sọ́nà fún ohun tí ó wà ní ìpamọ́ ní àwọn àpéjọpọ̀ àgbáyé fún 1998. Àwọn àpéjọpọ̀ àgbègbè ní gbogbo orílẹ̀-èdè yóò ní ìtòlẹ́sẹẹsẹ kan náà.