Wọ́n Pinnu Láti Tọ Ọ̀nà Ìgbésí Ayé Tí Ọlọ́run Fẹ́
Àwọn àpéjọpọ̀ “Ọ̀nà Ìgbésí Ayé Tí Ọlọ́run Fẹ́” mà kún fún ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ fún àwọn tó fẹ́ sin Ọlọ́run o! Ọ̀kan lára àwọn tó wá sí àpéjọpọ̀ náà ṣàpèjúwe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí “àkókò àgbàyanu ìtọ́ni, ìṣírí, àti ìlàlóye.”
ÒMÍRÀN lára àwọn tó wá sọ pé “ẹ̀kọ́ tí a lè kọ́, tí a lè ronú lé lórí, tí a sì lè mú lò pọ̀ lọ jàra.” Ẹ jẹ́ ká wá ṣàgbéyẹ̀wò ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà fúnra rẹ̀.
Jésù Kristi—Ọ̀nà, Òtítọ́, àti Ìyè
Ìyẹn ni ẹṣin ọ̀rọ̀ ọjọ́ àkọ́kọ́ àpéjọpọ̀ náà. (Jòhánù 14:6) Àsọyé àkọ́kọ́ ṣàlàyé pé ète tí a fi wá sí àpéjọpọ̀ náà ni: láti túbọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ nípa ọ̀nà ìgbésí ayé dídára jù lọ, ọ̀nà ìgbésí ayé tí Ọlọ́run fẹ́. Jèhófà ń kọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀ ní bí wọ́n ṣe lè máa rìn ní ọ̀nà rẹ̀. Ó ń ṣe èyí nípasẹ̀ Bíbélì, “ẹrú olóòótọ́ àti olóye,” àti ẹ̀mí mímọ́. (Mátíù 24:45-47; Lúùkù 4:1; 2 Tímótì 3:16) Ẹ wo bó ti jẹ́ àǹfààní ńláǹlà tó pé Ọba Aláṣẹ àgbáyé ń kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́!
Láti bá ẹṣin ọ̀rọ̀ ọjọ́ náà mu, “Ìràpadà Kristi—Ọ̀nà Tí Ọlọ́run Pèsè fún Ìgbàlà” ni lájorí ọ̀rọ̀ àwíyé. Láti rìn ní ọ̀nà ìgbésí ayé tí Ọlọ́run fẹ́, ó ṣe pàtàkì láti mọ ipa tí Jésù Kristi kó nínú ète Jèhófà. Olùbánisọ̀rọ̀ náà wí pé: “Láìsí ẹbọ ìràpadà Jésù Kristi, kò sí ènìyàn kankan, ohun yòówù tí ìgbàgbọ́ tàbí iṣẹ́ rẹ̀ ì báà jẹ́, tí ó lè gba ìyè ayérayé lọ́dọ̀ Ọlọ́run.” Lẹ́yìn náà ló wá fa Jòhánù 3:16 yọ, tó sọ pé: “Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ayé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni, kí olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ má bàa pa run, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.” Lílo ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà Kristi ń béèrè pé kí a wá sínú ìmọ̀ pípéye ti òtítọ́. Ó tún wé mọ́ yíya ìgbésí ayé wa sí mímọ́ fún Jèhófà, fífi ẹ̀rí èyí hàn nípa ìrìbọmi, àti gbígbé ní ìbámu pẹ̀lú àpẹẹrẹ tí Jésù Kristi fi lélẹ̀.—1 Pétérù 2:21.
Ìtòlẹ́sẹẹsẹ ti ọwọ́ ọ̀sán bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú àsọyé náà, “Ọ̀nà Ìfẹ́ Kì í Kùnà Láé.” Èyí jẹ́ ìjíròrò àwọn ẹsẹ tí ó wà nínú 1 Kọ́ríńtì 13:4-8 lọ́kọ̀ọ̀kan, níbi tí Pọ́ọ̀lù ti ṣàpèjúwe ìfẹ́ lọ́nà tó ru ìmọ̀lára ẹni sókè. A rán àwùjọ létí pé ìfẹ́ ìfara-ẹni-rúbọ ni a fi ń dá ẹ̀sìn Kristẹni mọ̀ àti pé ìfẹ́ Ọlọ́run àti ti aládùúgbò ẹni jẹ́ ara àmì pàtàkì tí a fi ń mọ ìjọsìn tí Jèhófà tẹ́wọ́ gbà.
Lẹ́yìn èyí ni àpínsọ ọ̀rọ̀ àsọyé alápá mẹ́ta tí a pe àkòrí rẹ̀ ní, “Ẹ̀yin Òbí—Ẹ Gbin Ọ̀nà Ọlọ́run Sínú Àwọn Ọmọ Yín.” Àwọn òbí lè ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ láti sin Ọlọ́run nípa fífi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ ní ti kíka Ọ̀rọ̀ rẹ̀, àti kíkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀. Wọ́n lè gbin òtítọ́ sọ́kàn àwọn ọmọ wọn nípa ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé tí a ń ṣe déédéé, ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a mú bá àìní ìdílé mu. Ó tún ṣe pàtàkì láti ran àwọn ọmọ lọ́wọ́ láti lọ́wọ́ nínú àwọn ìgbòkègbodò ìjọ àti iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé títọ́ àwọn ọmọ tí wọ́n bẹ̀rù Ọlọ́run dàgbà nínú ayé burúkú yìí kò rọrùn, ṣíṣe bẹ́ẹ̀ ń mú èrè ńlá wá.
Lẹ́yìn àpínsọ ọ̀rọ̀ àsọyé yìí ni a gbọ́ àsọyé náà, “Jẹ́ Kí Jèhófà Tún Ọ Ṣe fún Ìlò Tí Ó Ní Ọlá.” Gẹ́gẹ́ bí amọ̀kòkò kan ṣe ń mọ ìkòkò amọ̀, bẹ́ẹ̀ náà ni Ọlọ́run ṣe ń mọ àwọn tí ń sìn ín. (Róòmù 9:20, 21) Ó ń ṣe èyí nípa pípèsè ìmọ̀ràn nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ àti nípasẹ̀ ètò àjọ rẹ̀. Jèhófà yóò ràn wá lọ́wọ́ láti lo agbára wa dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ bí a bá mú ara wa wà lárọ̀ọ́wọ́tó, tí a lo àwọn àǹfààní tó bá ṣí sílẹ̀, tí a sì múra tán láti jẹ́ kí ó darí ìgbésẹ̀ wa.
Apá kan tó ru ìmọ̀lára sókè nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà ló tẹ̀ lé e—“Sísìn Gẹ́gẹ́ Bí Míṣọ́nnárì.” Lọ́wọ́lọ́wọ́ egbèjìlá dín mẹ́wàá [2,390] àwọn Kristẹni òjíṣẹ́ tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ bí míṣọ́nnárì ló ń sìn ní orílẹ̀-èdè méjìdínláàádọ́jọ [148] jákèjádò ayé. Wọ́n ń fi àpẹẹrẹ ìdúróṣinṣin àti ìtara lélẹ̀, wọ́n sì mọrírì àǹfààní iṣẹ́ ìsìn ní pápá ilẹ̀ òkèèrè gidigidi. Nígbà tí apá yìí ń lọ lọ́wọ́ nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ àwọn àpéjọpọ̀ àgbáyé, àwọn míṣọ́nnárì sọ ìpèníjà àti ayọ̀ tó wà nínú ìgbésí ayé míṣọ́nnárì.
Ẹṣin ọ̀rọ̀ àsọparí ọjọ́ náà ni, “Ìwàláàyè Ha Wà Lẹ́yìn Ikú Bí?” Ìbéèrè yìí ti da aráyé láàmú fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún. Ó ti pẹ́ táwọn èèyàn ní onírúurú àwùjọ ti ń bá kókó ọ̀rọ̀ náà wọ̀yá ìjà. Àwọn ìdáhùn tí wọ́n méfò lọ jàra. Bí àṣà àti ẹ̀sìn àwọn tó mú ìdáhùn náà wá ti pọ̀ tò, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn ìdáhùn náà pọ̀ tó. Síbẹ̀, àwọn ènìyàn ní láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́.
Bí ọ̀rọ̀ náà ti ń bá a lọ, olùbánisọ̀rọ̀ náà kéde ìmújáde ìwé pẹlẹbẹ aláwọ̀ mèremère olójú ìwé méjìlélọ́gbọ̀n náà, Kí Ní Ń Ṣẹlẹ̀ sí Wa Nígbà Tí A Bá Kú? Ìwé pẹlẹbẹ yìí ṣàlàyé ìpilẹ̀ṣẹ̀ ẹ̀kọ́ àìleèkú ọkàn, ó sì fi hàn bí èrò náà ṣe di apá pàtàkì nínú ohun tó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo ẹ̀sìn ayé lónìí. Lọ́nà tó ṣe kedere, tó sì fani mọ́ra, ó ṣàgbéyẹ̀wò ohun tí Bíbélì sọ nípa ọkàn, ìdí tí a fi ń kú, àti ohun tí ń ṣẹlẹ̀ sí wa táa bá kú. Ìwé pẹlẹbẹ náà tún ṣàlàyé ìrètí tó wà fún àwọn òkú àti àwọn alààyè. Ìbùkún ńláǹlà mà ni ìtẹ̀jáde yìí yóò jẹ́ fún àwọn tí ń wá òtítọ́ kiri níbi gbogbo o!
Ẹ Máa Ṣọ́ra Lójú Méjèèjì Ní Ti Bí Ẹ Ṣe Ń Rìn
Ẹ wó bí ẹṣin ọ̀rọ̀ yìí ṣe bá ọjọ́ kejì àpéjọpọ̀ náà mu tó! (Éfésù 5:15) Ìtòlẹ́sẹẹsẹ òwúrọ̀ dá lórí iṣẹ́ ìwàásù àti iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn. Lẹ́yìn ìjíròrò ẹsẹ ojoojúmọ́, ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà ń bá a lọ pẹ̀lú ọ̀rọ̀ náà, “Ríran Àwọn Ẹlòmíràn Lọ́wọ́ Láti Wà Ní Ọ̀nà Tí Ó Lọ Sí Ìyè.” Láti lè máa bá iṣẹ́ kánjúkánjú yìí lọ, ó ṣe pàtàkì láti ní ẹ̀mí rere, kí a mọ̀ pé àǹfààní ló jẹ́ láti ṣàjọpín òtítọ́ náà pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn, ó sì yẹ kí a mọ̀ pé ojúṣe wa ni. Ní ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Tiwa, ọ̀pọ̀ ènìyàn ni kò tẹ́wọ́ gba Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n, láìfi àtakò pè, àwọn ‘tí wọ́n ní ìtẹ̀sí-ọkàn fún ìyè àìnípẹ̀kun tí wọ́n sì di onígbàgbọ́’ wà nígbà náà. (Ìṣe 13:48, 50; 14:1-5) Bẹ́ẹ̀ náà ni nǹkan ṣe rí lónìí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ kò tẹ́wọ́ gba òtítọ́ Bíbélì, a ń bá a nìṣó láti máa wá àwọn tí yóò dáhùn padà lọ́nà rere.—Mátíù 10:11-13.
Àsọyé tó tẹ̀ lé e jíròrò ìpèníjà tó wà nínú mímú iṣẹ́ ìyè tọ àwọn ẹlòmíràn lọ. Níwọ̀n bó ti túbọ̀ ń ṣòro láti bá àwọn ènìyàn nílé, bí a bá fẹ́ mú iṣẹ́ Ìjọba náà dé ọ̀dọ̀ ọ̀pọ̀ ènìyàn, ó di dandan kí a ní ẹ̀mí ṣíṣe nǹkan láṣetán, kí a sì múra tán láti kojú onírúurú ipò. Ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀, àwọn akéde ìhìn rere ń ṣàṣeyọrí nípasẹ̀ jíjẹ́rìí lórí tẹlifóònù àti nípa wíwàásù ní ìpínlẹ̀ ìṣòwò, wọ́n sì ń tipa bẹ́ẹ̀ dé ọ̀dọ̀ àwọn tó ṣòro láti bá nílé.
Àsọyé tí a pe àkòrí rẹ̀ ní “Kíkọ́ Àwọn Ọmọ Ẹ̀yìn Ní Gbogbo Ohun Tí Kristi Pa Láṣẹ” dá lórí ìjẹ́pàtàkì dídi ọ̀jáfáfá nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa. Bí a ti ń kẹ́kọ̀ọ́ lára àwọn ẹlòmíràn, tí a sì ń fi ohun tí a ń kọ́ nínú àwọn ìpàdé ìjọ sílò, bẹ́ẹ̀ ni a óò máa túbọ̀ jáfáfá sí i. Bí a ti túbọ̀ ń jáfáfá nínú kíkọ́ni lẹ́kọ̀ọ́, ayọ̀ àti ìtẹ́lọ́rùn wa nínú iṣẹ́ ríran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ Bíbélì yóò máa pọ̀ sí i.
Ìtòlẹ́sẹẹsẹ ti òwúrọ̀ wá sí ìparí pẹ̀lú àsọyé náà nípa ìtumọ̀ ìyàsímímọ́ àti ìbatisí. Ọ̀kan lára àwọn kókó tí olùbánisọ̀rọ̀ náà mẹ́nu kàn ni pé, bí a bá gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run pátápátá, tí a sì fi tọkàntọkàn sapá láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀, òun yóò bù kún wa, yóò sì mẹ́sẹ̀ wa dúró. Ọkùnrin ọlọgbọ́n náà kọ̀wé pé: “Ṣàkíyèsí [Ọlọ́run] ní gbogbo ọ̀nà rẹ, òun fúnra rẹ̀ yóò sì mú àwọn ipa ọ̀nà rẹ tọ́.” (Òwe 3:6) Ayọ̀ ìbatisí alára tún jẹ́ ohun mánigbàgbé ní àpéjọpọ̀ náà, èyí tó fi hàn pé ọ̀pọ̀ ti bẹ̀rẹ̀ sí mú ìgbésí ayé wọn bá ọ̀nà Ọlọ́run mu.
Lẹ́yìn àkókò ìsinmi fún oúnjẹ ọ̀sán, ìtòlẹ́sẹẹsẹ ọ̀sán bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú àsọyé náà, “Sísìn Pẹ̀lú Ète ti Níní Ìyè Àìlópin.” Ète Ọlọ́run pé kí àwọn ènìyàn onígbọràn máa sin òun títí láé lórí ilẹ̀ ayé yóò ní ìmúṣẹ. Ẹ wo bó ti bá a mu wẹ́kú tó nígbà náà pé, kí a pa ìrònú, ìwéwèé, àti ìrètí wa pọ̀ sórí sísin Jèhófà pẹ̀lú ìyè ayérayé lọ́kàn! Bí ó ti jẹ́ ìfẹ́ wa láti máa fi “ọjọ́ Jèhófà” sọ́kàn pẹ́kípẹ́kí, ó ṣe pàtàkì láti rántí pé góńgó wa ni láti sìn títí ayérayé. (2 Pétérù 3:12) Àìmọ àkókò náà gan-an tí Jésù yóò mú ìdájọ́ Ọlọ́run wá ń mú kí a wà lójúfò, ó sì ń fún wa láǹfààní lójoojúmọ́ láti sin Jèhófà láìní ẹ̀mí tara wa nìkan.
Àsọyé méjì tó tẹ̀ lé e ṣàtúpalẹ̀ orí kẹrin lẹ́tà Pọ́ọ̀lù sí àwọn ará Éfésù. Lára àwọn ohun tí a gbé yẹ̀ wò ni àǹfààní tí a ń jẹ lára “àwọn ẹ̀bùn tí ó jẹ́ ènìyàn,” àwọn ọkùnrin tó tóótun nípa tẹ̀mí, àwọn tí ẹ̀mí mímọ́ yàn. Àwọn alàgbà wọ̀nyí ń pèsè ìmọ̀ràn àti ìtọ́sọ́nà fún àǹfààní wa nípa tẹ̀mí. Lẹ́tà Pọ́ọ̀lù tí a mí sí tún rọ àwọn Kristẹni láti gbé “àkópọ̀ ìwà tuntun” wọ̀. (Éfésù 4:8, 24) Àkópọ̀ ìwà Ọlọ́run ní nínú àwọn ànímọ́ bí ìyọ́nú, inú rere, ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú, ìwà tútù, ìpamọ́ra, àti ìfẹ́.—Kólósè 3:12-14.
Ṣíṣọ́ra lójú méjèèjì ní ti bí a ti ń rìn kan pípa ara wa mọ́ láìlábàwọ́n nínú ayé—ìyẹn ni kókó ọ̀rọ̀ àsọyé tó tẹ̀ lé e. Ìwọ̀ntúnwọ̀nsì ṣe pàtàkì nínú yíyan eré ìnàjú, ìgbòkègbodò ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà, àti ìlépa ohun ti ara. Nípa fífi ìmọ̀ràn tó wà nínú Jákọ́bù 1:27 láti pa ara wa mọ́ láìlábàwọ́n nínú ayé sílò, a ń gbádùn ìdúró mímọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run, a sì ń ní ẹ̀rí-ọkàn rere. A tún lè gbé ìgbésí ayé tó ní ète nínú, a óò sì fi àlàáfíà, aásìkí nípa tẹ̀mí, àti àwọn ọ̀rẹ́ rere, jíǹkí wa.
Lẹ́yìn náà ni a gbọ́ àpínsọ ọ̀rọ̀ àsọyé alápá mẹ́ta tí a pe àkọlé rẹ̀ ní, “Ẹ̀yin Èwe—Ẹ Máa Tọ Ọ̀nà Ọlọ́run.” Ní mímọ̀ pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ wọn àti pé ó mọrírì ìsapá wọn láti gbé ìjọsìn mímọ́ gaara lárugẹ, ó yẹ kí àwọn èwe kọ́ agbára ìmòye wọn, kí wọ́n lè fi òótọ́ sìn ín. Ọ̀nà kan táa lè gbà mú agbára ìmòye wa dàgbà ni láti máa ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lójoojúmọ́, kí a sì máa ṣàṣàrò lé e lórí. Bí a bá ń ṣe èyí, a lè wá mọ àwọn ọ̀nà Jèhófà. (Sáàmù 119:9-11) A tún lè mú agbára ìmòye wa dàgbà nípa títẹ́wọ́gba ìmọ̀ràn tó mọ́yán lórí tí a ń rí gbà láti ọ̀dọ̀ àwọn òbí, àwọn alàgbà, àti èyí tí a ń rí nínú àwọn ìtẹ̀jáde Society. Nípa lílo agbára ìmòye wọn lọ́nà tí ó tọ́, àwọn ọ̀dọ́ lè dènà jíjẹ́ kí kíkó ohun ti ara jọ gbà wọ́n lọ́kàn, sísọ ọ̀rọ̀ àìmọ́, àti ṣíṣe àṣejù nínú eré ìnàjú, èyí tí a fi ń dá ayé tí a ti sọ dàjèjì sí Ọlọ́run mọ̀. Nípa títọ ọ̀nà ìgbésí ayé tí Ọlọ́run fẹ́, tàgbàtèwe lè gbádùn àṣeyọrí tòótọ́.
Ọ̀rọ̀ àsọparí ọjọ́ náà ni, “Ẹlẹ́dàá—Àkópọ̀ Ìwà Rẹ̀ àti Àwọn Ọ̀nà Rẹ̀.” Lẹ́yìn títọ́ka sí i pé ẹgbàágbèje àwọn ènìyàn ni kò mọ Ẹlẹ́dàá, olùbánisọ̀rọ̀ náà wí pé: “Ìtumọ̀ gidi nínú ìgbésí ayé ní í ṣe pẹ̀lú mímọ Ẹlẹ́dàá náà, Ọlọ́run àwa fúnra wa; mímọ àkópọ̀ ìwà rẹ̀, kí a sì fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn ọ̀nà rẹ̀. . . . Àwọn òtítọ́ wà nípa ayé wa àti nípa àwa fúnra wa tí o lè lò láti ran àwọn ènìyàn lọ́wọ́ láti tẹ́wọ́ gba Ẹlẹ́dàá, kí wọ́n sì rí i pé ó ní ìtumọ̀ sí wọn.” Lẹ́yìn èyí, ni olùbánisọ̀rọ̀ náà wá jíròrò ẹ̀rí tí ń tọ́ka sí i pé Ẹlẹ́dàá tí ó jẹ́ ọlọ́gbọ́n àti onífẹ̀ẹ́ kan ń bẹ. Àsọyé náà dé ibi tí ọ̀rọ̀ ti wọni lára gan-an nígbà tí a mú ìwé tuntun kan jáde—tí a pe àkòrí rẹ̀ ní Is There a Creator Who Cares About You?
“Èyí Ni Ọ̀nà. Ẹ Máa Rìn Nínú Rẹ̀”
Ẹṣin ọ̀rọ̀ ọjọ́ kẹta àpéjọpọ̀ náà nìyẹn. (Aísáyà 30:21) Ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú àpínsọ ọ̀rọ̀ àsọyé alápá mẹ́ta tó runi sókè, tó dá lórí ìran tẹ́ńpìlì tí Ìsíkíẹ́lì rí. Ìran yìí ní ìtumọ̀ ńláǹlà fún àwọn ènìyàn Ọlọ́run lónìí, níwọ̀n bí ó ti ní í ṣe pẹ̀lú ìjọsìn mímọ́ gaara ní àkókò wa. Àṣírí kan láti lóye ìran náà nìyí: Tẹ́ńpìlì ńlá ti Jèhófà nípa tẹ̀mí dúró fún ètò tí ó ṣe fún ìjọsìn mímọ́ gaara. Bí olùbánisọ̀rọ̀ náà ti ń jíròrò ìran náà, àwùjọ ń ronú lórí ohun tí àwọn ń ṣe láti kọ́wọ́ ti iṣẹ́ àwọn alábòójútó onífẹ̀ẹ́ ti àṣẹ́kù àwọn ẹni àmì òróró àti àwọn tí yóò di ìjòyè lẹ́yìnwá ọ̀la.
Nígbà tó ṣe sàà ní òwúrọ̀ ọjọ́ náà, a wo àwòkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan tó gbádùn mọ́ni, nínú èyí tí àwọn olùkópa kan ti múra bí àwọn ará ìgbàanì. Ẹṣin ọ̀rọ̀ àwòkẹ́kọ̀ọ́ náà ni, “Ẹ̀yin Ìdílé—Ẹ Jẹ́ Kí Kíka Bíbélì Lójoojúmọ́ Jẹ́ Ọ̀nà Ìgbésí Ayé Yín!” Ó ṣàgbéyọ ìgbàgbọ́ àti ìgboyà àwọn Hébérù mẹ́ta tí wọ́n kọ̀ láti forí balẹ̀ fún ère oníwúrà tí Nebukadinésárì Ọba Bábílónì gbé kalẹ̀. Àwòkẹ́kọ̀ọ́ náà kọ́ni pé, kì í ṣe kìkì pé Bíbélì jẹ́ ìwé ìtàn ìgbàanì, ṣùgbọ́n ó tún jẹ́ ìwé kan tí àwọn ìmọ̀ràn rẹ̀ wúlò lọ́pọ̀lọ́pọ̀ fún tọmọdétàgbà lónìí.
Ìgbà ìtòlẹ́sẹẹsẹ ọ̀sán la gbọ́ àsọyé fún gbogbo ènìyàn “Ọ̀nà Kan Ṣoṣo sí Ìyè Àìnípẹ̀kun.” Lẹ́yìn sísọ ìtàn bí aráyé ṣe ṣubú sínú ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú, olùbánisọ̀rọ̀ fi àwọn ọ̀rọ̀ amúnironújinlẹ̀ yìí kádìí ọ̀rọ̀ rẹ̀: “Ẹṣin ọ̀rọ̀ Bíbélì fún àpéjọpọ̀ tòní ni Aísáyà orí 30, ẹsẹ 21, tí ó sọ pé: ‘Etí rẹ yóò . . . gbọ́ ọ̀rọ̀ kan lẹ́yìn rẹ tí ń sọ pé: “Èyí ni ọ̀nà. Ẹ máa rìn nínú rẹ̀,” bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ẹ lọ sí apá ọ̀tún tàbí bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ẹ lọ sí apá òsì.’ Ọ̀nà wo ni a gbà ń gbọ́ ohùn yìí? Ó jẹ́ nípa fífetí sí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, Bíbélì Mímọ́, àti nípa títẹ̀lé ìdarísọ́nà tí Olùkọ́ni wa Atóbilọ́lá, Jèhófà Ọlọ́run, ń pèsè nípasẹ̀ rẹ̀ àti nípasẹ̀ ètò àjọ rẹ̀ ti àwọn Kristẹni òde òní. Láìsí àní-àní, ṣíṣe èyí ni ọ̀nà kan ṣoṣo sí ìyè àìnípẹ̀kun.”
Lẹ́yìn àkópọ̀ àpilẹ̀kọ ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ fún ọ̀sẹ̀ náà ni a gbọ́ ọ̀rọ̀ àsọparí, tí ó ní àkòrí náà, “Ẹ Máa Bá A Nìṣó Ní Rírìn Ní Ọ̀nà Jèhófà.” Lápá kan, ó ṣàtúnyẹ̀wò àwọn kókó pàtàkì inú ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà. Lẹ́yìn èyí ni olùbánisọ̀rọ̀ wá sọ àwọn ìpinnu tó ṣàlàyé ìmúratán wa láti máa gbé ìgbésí ayé ní ọ̀nà Ọlọ́run.
Àwọn ọ̀rọ̀ ìwúrí tó kádìí ìpinnu náà nìyí: “Ó dá wa lójú pé gbígbé ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìlànà, ìmọ̀ràn, àti ìṣílétí tí ó wà nínú Ìwé Mímọ́ yóò túmọ̀ sí ọ̀nà ìgbésí ayé tí ó dára jù lọ lónìí, a óò sì fi ìpìlẹ̀ tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀ lélẹ̀ de ẹ̀yìn ọ̀la, kí a lè di ìyè tòótọ́ mú gírígírí. Lékè gbogbo rẹ̀, a ṣe ìpinnu yìí nítorí pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà, ọkàn, èrò inú, àti okun wa!” Láti fi hàn pé àwọn fara mọ́ ọn, gbogbo àwọn tó pésẹ̀ dáhùn pé bẹ́ẹ̀ ni, èyí tó dún lọ réré!
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]
Ẹlẹ́dàá Kan Ha Wà Tó Bìkítà Nípa Rẹ Bí?
Ìwé tuntun náà, Is There a Creator Who Cares About You?, gbé ẹ̀rí tí kò ṣeé já ní koro kalẹ̀ pé Jèhófà, Ẹlẹ́dàá, ń bẹ, ó sì jíròrò àwọn ànímọ́ rẹ̀. A ṣe é ní pàtàkì fún àwọn tó jẹ́ ọ̀mọ̀wé ṣùgbọ́n tí wọn kò gba Ọlọ́run gbọ́. Ìwé yìí tí ojú ìwé rẹ̀ dín mẹ́jọ ní igba tún ṣàlékún ìgbàgbọ́ àwọn tí wọ́n ti gba Ọlọ́run gbọ́ tẹ́lẹ̀, ó sì jẹ́ kí wọ́n túbọ̀ ní ìmọrírì fún ìwà àti ọ̀nà rẹ̀.
Ìwé náà, Is There a Creator Who Cares About You? kò kàn gbà pé òǹkàwé náà gba Ọlọ́run gbọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó jíròrò nípa bí àwọn ìwádìí sáyẹ́ǹsì ní lọ́ọ́lọ́ọ́ àti àwọn èròǹgbà wọn ṣe jẹ́rìí sí i pé Ẹlẹ́dàá ń bẹ. Lára àwọn àkòrí rẹ̀ ni “What Can Add Meaning to Your Life?” (Kí Ló Lè Jẹ́ Kí Ìgbésí Ayé Rẹ̀ Túbọ̀ Nítumọ̀?), “How Did Our Universe Get Here?—The Controversy,” (Báwo Ni Àgbáyé Wa Ṣe Déhìn-Ín?—Awuyewuye Rẹ̀) àti “How Unique You Are!” (Wo Bí O Ṣe Jẹ́ Aláìlẹ́gbẹ́ Tó!) Àwọn àkòrí mìíràn ṣàgbéyẹ̀wò ìdí tó fi lè dá wa lójú pé Bíbélì ní ìmísí Ọlọ́run. Ìwé tuntun náà tún fúnni ní àkópọ̀ Bíbélì lódindi, èyí tó fi àkópọ̀ ìwà àti ọ̀nà Ẹlẹ́dàá náà hàn. Kì í kàn ṣe pé ìwé náà jíròrò ìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba ìjìyà tó pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ nìkan ni, àmọ́ ó tún ṣàlàyé bí yóò ṣe fòpin sí i títí ayé.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Ọ̀pọ̀ ló ṣe batisí
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
A. D. Schroeder, ọ̀kan lára Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ló kéde ìmújáde ìwé pẹlẹbẹ náà
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8, 9]
Àwòkẹ́kọ̀ọ́ alárinrin rọni láti máa ka Bíbélì lójoojúmọ́