Ṣiṣẹ́ Lati Pa Idile Rẹ Mọ́ Wọnu Ayé Titun Ti Ọlọrun
“Iwọ ó pa wọn mọ́, Oluwa, iwọ ó pa olukuluku wọn mọ́ kuro lọwọ iran yii laelae.”—ORIN DAFIDI 12:7.
1, 2. (a) Bawo ni awọn idile kan ti ń ṣesi labẹ awọn ikimọlẹ ọjọ ikẹhin? (b) Bawo ni awọn idile Kristian ṣe lè wá ọ̀nà lati laaja?
“AYỌ kún inu mi lonii!” ni Kristian alagba kan ti orukọ rẹ̀ ń jẹ́ John fi idunnu sọ jade. Ki ni okunfa ìdùnnúṣubúlayọ̀ yii? Ó rohin pe, “Ọmọkunrin mi ti ó jẹ́ ọmọ ọdun 14 ati ọmọbinrin mi ti o jẹ́ ọmọ ọdun 12 ni a baptisi.” Ṣugbọn ayọ rẹ̀ kò pin sibẹ. Ó fikun un pe, “Ọmọkunrin mi ti ó jẹ́ ọmọ ọdun 17 ati ọmọbinrin mi ti ó jẹ́ ọmọ ọdun 16 ni awọn mejeeji ti jẹ́ oluranlọwọ aṣaaju-ọna ni ọdun ti ó kọja yii.”
2 Ọpọlọpọ idile laaarin wa ń ní iru iyọrisi rere kan-naa bi wọn ti ń fi awọn ilana Bibeli silo. Bi o ti wu ki o ri, awọn kan, ń niriiri iṣoro. Tọkọtaya Kristian kan kọwe pe, “A bí ọmọ marun-un, ó sì ti tubọ ń le koko siwaju sii lati bá wọn lò. A ti padanu ọmọ kan sinu eto-igbekalẹ ogbologboo yii ná. Awọn ọ̀dọ́langba wa ni wọn dabii agbegbe igbejakoni pataki fun Satani nisinsinyi.” Awọn tọkọtaya ti wọn ń niriiri ọ̀ràn iṣoro igbeyawo ti ó lékenkà, nigba miiran ti ó maa ń jálẹ̀ sí pipinya tabi ikọsilẹ tún wà. Bi o tilẹ ri bẹẹ, awọn idile ti wọn mú awọn animọ Kristian dagba lè la “ipọnju ńlá” ja ki wọn sì di ẹni ti a pamọ́ wọnu ayé titun ti Ọlọrun tí ń bọ̀. (Matteu 24:21; 2 Peteru 3:13) Nigba naa, ki ni iwọ lè ṣe lati mú itọjupamọ idile rẹ daju?
Mímú Ijumọsọrọpọ Sunwọn Sii
3, 4. (a) Bawo ni ijumọsọrọpọ ti ṣe pataki tó ninu igbesi-aye idile, eesitiṣe ti iṣoro fi maa ń sábàá dide nipa rẹ̀? (b) Eeṣe ti awọn ọkọ fi nilati lakaka lati jẹ́ olufetisilẹ rere?
3 Ijumọsọrọpọ tí ó dara ni ẹ̀jẹ̀-ìwàláàyè idile ti ó jíire; nigba ti kò bá sí, àìfararọ ati másùnmáwo ń pọ̀ sii. “Laisi ìgbìmọ̀, èrò a dasán,” ni Owe 15:22 sọ. Lọna ti ó fanilọkanmọra, olugbaninimọran igbeyawo kan rohin pe: “Ẹ̀sùn ti ó farajọra julọ ti mo ń gbọ́ lati ẹnu awọn aya ti mo ń gbanimọran ni ‘Oun kò jẹ́ bá mi sọrọ,’ ati ‘Oun kìí fetisilẹ si mi.’ Nigba ti mo bá sì mú ẹ̀sùn yii wá si afiyesi ọkọ wọn, wọn kò ní gbọ́ temi, bakan naa.”
4 Ki ni ń ṣokunfa aisi ijumọsọrọpọ? Ohun kan ni pe, ọkunrin ati obinrin yatọsira, wọn sì sábà maa ń ní iru oriṣi ọ̀nà ijumọsọrọpọ yiyatọsira ti o rọrun lati kiyesi. Ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ kan ṣakiyesi pe ọkọ kan “ń ní itẹsi lati ṣe taarata ki o sì gbeṣẹ” ninu awọn ijumọsọrọpọ rẹ̀, nigba ti ó jẹ pe “ohun ti [aya kan] ń fẹ́ ju ohunkohun miiran lọ ni olufetisilẹ kan ti ń gbatẹniro.” Bi eyi bá gbé iṣoro kan kalẹ ninu igbeyawo rẹ, ṣiṣẹ lori mímú awọn ọ̀ràn sunwọn sii. Kristian ọkọ kan lè nilati ṣiṣẹ kára lori didi olufetisilẹ didara jù. Jakọbu sọ pe, “Ki olukuluku eniyan ki o maa yára lati gbọ́, ki ó lọ́ra lati fọhùn.” (Jakọbu 1:19) Kọ́ bi a tií fà sẹhin kuro ninu pipaṣẹ, kíkìlọ̀, ati fifi ọ̀rọ̀ baniwi nigba ti aya rẹ wulẹ ń fẹ́ “imọlara fun ẹlẹgbẹ ẹni.” (1 Peteru 3:8, NW) “Ẹni ti ó ní ìmọ̀, á ṣẹ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ kù,” ni Owe 17:27 sọ.
5. Ki ni awọn ọ̀nà diẹ ti awọn ọkọ lè gbà sunwọn sii ninu fifi èrò ati imọlara wọn hàn?
5 Ni ọwọ keji ẹwẹ, “ìgbà fífọhùn” wà, iwọ sì lè nilati kọ́ lati mọ bi iwọ yoo ṣe tubọ lè sọ èrò ati imọlara rẹ jade. (Oniwasu 3:7) Fun apẹẹrẹ, iwọ ha jẹ́ yinniyinni nipa awọn ohun ti aya rẹ bá ṣe ní aṣeyọri bi? (Owe 31:28) Iwọ ha fi araarẹ hàn bi ẹni ti ó kún fun ọpẹ́ fun iṣẹ àṣekára ti ó ń ṣe ni ṣiṣetilẹhin fun ọ ati bibojuto agbo-ile bi? (Fiwe Kolosse 3:15.) Tabi boya iwọ nilati sunwọn sii ninu sisọ ‘awọn ọ̀rọ̀ ifẹ’ jade. (Orin Solomoni 1:2) Ṣiṣe bẹẹ lè má rọrùn fun ọ lakọọkọ, ṣugbọn ó lè ṣeranwọ pupọpupọ ninu jijẹ ki aya rẹ nimọlara aabo ninu ifẹ rẹ fun un.
6. Ki ni awọn aya lè ṣe lati mú ijumọsọrọpọ idile sunwọn sii?
6 Ki ni nipa awọn Kristian aya? Aya kan ni a ṣàyọlò ọ̀rọ̀ rẹ̀ ní wiwi pe ọkọ oun mọ̀ pe oun mọriri rẹ̀, nitori naa kò pọndandan fun oun lati sọ́ fun un. Bi o ti wu ki o ri, awọn ọkunrin pẹlu ń ṣe daradara nigba ti a bá mọriri wọn, gboriyin fun wọn, ti a sì yin wọn. (Owe 12:8) Iwọ ha nilati tubọ mọ bí a tií sọrọ jade ni ọ̀nà yii bi? Ni ọwọ́ keji ẹ̀wẹ̀, boya iwọ nilati tubọ fun ọ̀nà ti o gbà ń fetisilẹ ni afiyesi. Bi kò bá rọrùn fun ọkọ rẹ lati jiroro awọn iṣoro, ibẹru, tabi aniyan rẹ̀ láìfọ̀rọ̀ sabẹ ahọ́n sọ, iwọ ha ti kẹkọọ bi iwọ ṣe lè mú ki ó bá ọ sọrọpọ, lọna oninuure ati pẹlu ọgbọ́n-ẹ̀wẹ́ bi?
7. Ki ni ó lè jẹ́ ki ìjà ninu igbeyawo bẹ́ silẹ, bawo ni a sì ṣe lè ṣediwọ fun wọn?
7 Nitootọ, àní awọn tọkọtaya ti ó rọrun fun lati maa bá araawọn gbé deedee lè niriiri iwolulẹ ninu ijumọsọrọpọ lẹẹkọọkan. Ero-imọlara lè ṣíji bo iwoyeronu, tabi ki ijiroro jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ kan di eyi ti a yára yipada si ariyanjiyan gbigbona. (Owe 15:1) “Ninu ohun pupọ ni gbogbo wa ń ṣìṣe”; bi o ti wu ki o ri, gbún-gbùn-gbún laaarin ọkọ ati aya kan kò tumọsi opin igbeyawo. (Jakọbu 3:2) Ṣugbọn “ariwo, ati ọ̀rọ̀ buburu” kò bojumu ó sì jẹ́ aṣèparun fun ipo-ibatan eyikeyii. (Efesu 4:31) Yára nipa wiwa alaafia nigba ti ẹ bá ti sọ ọ̀rọ̀ ti ń dunni wọra si araayin. (Matteu 5:23, 24) Gbọ́nmi-síi-omi-ò-tó ni a sábà lè ṣedilọwọ fun lakọọkọ bi ẹyin mejeeji bá fi awọn ọ̀rọ̀ Paulu ni Efesu 4:26 silo pe: “Ẹ maṣe jẹ ki oorun wọ̀ bá ibinu yin.” Bẹẹni, ẹ yanju awọn iṣoro nigba ti wọn ṣì kéré ti wọn ṣì ṣeé fewémọ́; ẹ maṣe duro di ìgbà ti awọn ero-imọlara yin bá tó dé ori kókó ti yoo fi gbanájẹ. Lilo iwọnba iṣẹju diẹ lojoojumọ lati jiroro awọn ọ̀ràn ti ó kan ẹyin mejeeji lè ṣe ohun pupọ lati gbé ire ijumọsọrọpọ ga siwaju ki ó sì ṣedilọwọ fun awọn èdèkòyedè.
“Ilana-ero-ori ti Jehofa”
8. Eeṣe ti awọn ọ̀dọ́ kan fi lè lọ kuro ninu otitọ ni kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀?
8 Ó jọ bi ẹni pe ó tẹ́ awọn òbí kan lọ́rùn lati fààyè gba awọn ọmọ wọn lati maa dagba laisi idari. Awọn ọmọ naa ń lọ si ipade wọn sì ń ṣajọpin níwọ̀n ninu iṣẹ-isin pápá, ṣugbọn niye ìgbà wọn kò tíì gbé ipo-ibatan tiwọn funraawọn pẹlu Ọlọrun ró. Bi akoko ti ń lọ “ifẹkufẹẹ ara, ati ifẹkufẹẹ oju” lè sin ọpọ ninu iru awọn ọ̀dọ́ bẹẹ lọ kuro ninu otitọ. (1 Johannu 2:16) Bawo ni yoo ti jẹ́ ibanujẹ tó fun awọn òbí lati la Armageddoni ja ṣugbọn nitori àìkáràmáásìkí tó ni ìgbà ti o ti kọja ki wọn fi awọn ọmọ wọn sẹhin gẹgẹ bi abógunrìn!
9, 10. (a) Ki ni títọ́ awọn ọmọ dagba “ninu ibawi ati ilana-ero-ori ti Jehofa” ní ninu? (b) Eeṣe ti o fi ṣe pataki lati yọọda fun awọn ọmọ lati sọ tẹnu wọn jade fàlàlà?
9 Paulu tipa bayii kọwe pe: “Ẹyin baba, ẹ maṣe maa mú awọn ọmọ yin binu, ṣugbọn ẹ maa baa lọ ni títọ́ wọn dagba ninu ìbáwíẹ̀kọ́ ati ilana-ero-ori ti Jehofa.” (Efesu 6:4, NW) Lati ṣe bẹẹ, iwọ funraarẹ gbọdọ fi ifọkansi mọ awọn ọ̀pá-ìdiwọ̀n Jehofa dunju. Iwọ nilati fi apẹẹrẹ bibojumu lélẹ̀ nigba ti ó bá kan iru awọn nǹkan bẹẹ bii eré-ìnàjú tí o yàn, ìdákẹ́kọ̀ọ́, lilọ si ipade, ati iṣẹ-isin pápá. Awọn ọ̀rọ̀ Paulu tun dọgbọn tumọsi pe òbí kan gbọdọ (1) jẹ́ ẹni ti ń fi ìgbọ́nféfé ṣakiyesi awọn ọmọ ati pe ki o (2) pa ijumọsọrọpọ ti ó dara mọ pẹlu wọn. Kìkì nigba naa ni o tó lè mọ inu ibi ti wọn ti nilo “ilana-ero-ori.”
10 Ó jẹ́ ohun ti o bá ìwà ẹ̀dá mu fun awọn ọ̀dọ́langba lati lakaka fun ìwọ̀n ominira diẹ. Bi o ti wu ki o ri, iwọ gbọdọ wà lojufo ṣamṣam si awọn àmì ti ó ṣe kedere nipa agbara idari ti ayé ninu ọ̀rọ̀ sísọ, ironu, aṣọ ati imura, ati iru awọn ọ̀rẹ́ wọn ti wọn yàn. Baba ọlọgbọn kan sọ gẹgẹ bi a ti ṣakọsilẹ rẹ̀ ni Owe 23:26 pe: “Ọmọ mi, fi àyà rẹ fun mi.” Awọn ọmọ rẹ ha ni ominira fàlàlà lati ṣajọpin awọn èrò ati imọlara wọn pẹlu rẹ bi? Bi awọn ọmọ kò bá bẹru ìjájúmọ́ni oju-ẹsẹ, wọn lè tubọ di ẹni ti a sún lati ṣipaya imọlara wọn gan-an nipa iru awọn ọ̀ràn bii awọn igbokegbodo ẹhin wakati ikẹkọọ ni ile-ẹkọ, ajọṣepọ ọlọ́rẹ̀ẹ́sọ́rẹ̀ẹ́ pẹlu ẹ̀yà odikeji, ẹkọ-iwe giga, tabi otitọ Bibeli fúnraarẹ̀.
11, 12. (a) Bawo ni a ṣe lè lo awọn akoko ounjẹ lati gbé ijumọsọrọpọ idile larugẹ? (b) Ki ni ó lè jẹyọ lati inu awọn isapa onitẹpẹlẹmọ ti òbí kan lati gbé ijumọsọrọpọ pẹlu awọn ọmọ rẹ̀ larugẹ?
11 Ni ọpọ ilẹ ó jẹ́ ohun aṣa fun awọn idile lati jẹun papọ. Nipa bayii akoko ounjẹ alájẹpọ̀ naa lè pese anfaani rere fun gbogbo mẹmba idile pata lati ṣajọpin ijumọsọrọpọ ti ń gbeniro. Bi ó ti sábà maa ń ri nigba gbogbo akoko ounjẹ àjẹpọ̀ ti idile ni tẹlifiṣọn ati awọn ohun ipinya miiran ti fúnpa. Bi o ti wu ki o ri, fun wakati gbọọrọ, ó fẹrẹẹ jẹ pe awọn ọmọ rẹ ni a ti mú ni àmúdá ni ile-ẹkọ ti a sì ṣí wọn payá si ironu ti ayé. Awọn akoko ounjẹ ni akoko ti ó wọ̀ lati bá awọn ọmọ rẹ sọrọpọ. “A ń lo akoko ounjẹ lati sọrọ nipa awọn nǹkan ti ó wáyé ni wakati ọ̀sán,” ni òbí kan sọ. Sibẹ, awọn akoko ounjẹ ni kò nilati jẹ́ akoko ijokoo ibaniwi ti ń kotijubani tabi ìfìbéèrè-wádìí-òkodoro. Jẹ ki akoko naa tunilara ki ó sì gbadunmọni!
12 Lati jẹ ki awọn ọmọ túraká lati bá ọ sọrọ jẹ́ ipenija ó sì lè beere fun suuru ti kò lopin. Bi o ti wu ki o ri, bi akoko ti ń lọ, iwọ lè rí iyọrisi amọ́kànyọ̀. “Ọmọkunrin wa ti ó jẹ́ ọmọ ọdun 14 ni a ti mu sorikọ ti ó sì ti di onitiju,” ni ìyá kan ti ó bikita pada ranti. “Nipasẹ adura wa ati itẹpẹlẹmọ, oun ti bẹrẹ sii túraká lati bá wa sọrọ!”
Ikẹkọọ Idile Ti Ń Gbeniro
13. Eeṣe ti ìdánilẹ́kọ̀ọ́ awọn ọmọ ni kutukutu fi ṣe pataki tobẹẹ, bawo sì ni a ṣe lè ṣaṣepari rẹ̀?
13 “Ilana-ero-ori” tún ní itọni lati inu Ọ̀rọ̀ Ọlọrun lọna bi aṣa ninu. Gẹgẹ bi o ti ri pẹlu Timoteu, iru ìdánilẹ́kọ̀ọ́ bẹẹ nilati bẹrẹ “lati ìgbà ọmọde.” (2 Timoteu 3:15) Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ti a tètè bẹrẹ ń fun awọn ọmọ ni okun fun idanwo igbagbọ ti ó lè wá ni awọn ọdun ile-ẹkọ—ayẹyẹ ọjọ́-ìbí, awọn ayẹyẹ ifọkansin orilẹ-ede, tabi awọn isinmi isin. Laisi imurasilẹ fun iru awọn idanwo bẹẹ, igbagbọ ọmọ kan ni a lè fọ́ túútúú. Nitori naa lo anfaani awọn ohun eelo iṣẹ ti Watch Tower Society ti mú wà ni sẹpẹ́ fun awọn ọmọde, iru bii iwe Fifetisilẹ si Olukọ Nla na ati Iwe Itan Bibeli Mi.a
14. Bawo ni a ṣe lè mú ki ikẹkọọ idile jẹ́ eyi ti a ń ṣe deedee, ki ni iwọ sì ti ṣe lati ni ikẹkọọ idile deedee?
14 Agbegbe miiran ti ó yẹ fun afiyesi ni ikẹkọọ idile, eyi ti ó ṣeeṣe ki o di alaiṣedeedee ni kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ tabi ki ó di ọ̀ràn ti kò taniji, ti afaraṣe-mafọkanṣe ti ń danniwo fun awọn òbí ati ọmọ. Bawo ni o ṣe lè mú ọ̀ràn sunwọn sii? Lakọọkọ, iwọ gbọdọ “ra ìgbà pada” fun ikẹkọọ, laini yọnda ki tẹlifiṣọn tabi awọn ohun agbanilafiyesi miiran fún un pa. (Efesu 5:15-17) “A ni iṣoro ninu ṣiṣe ikẹkọọ idile wa deedee,” ni olórí idile kan jẹwọ. “A gbiyanju oriṣiriṣi akoko ki a tó wá rí akoko kekere kan ti ó gbéṣẹ́ fun wa ni alẹ́ patapata. Nisinsinyi ikẹkọọ idile wa ń lọ deedee.”
15. Bawo ni iwọ ṣe lè mú ikẹkọọ idile rẹ bá aini idile rẹ mu?
15 Eyi ti ó kàn ni pe, gbé awọn aini pàtó ti o jẹ ti idile rẹ yẹwo. Ọpọlọpọ idile gbadun mimura ikẹkọọ Ilé-Ìṣọ́nà wọn ọsọọsẹ silẹ papọ. Bi o ti wu ki o ri, lati ìgbà dé ìgbà, idile rẹ lè ni awọn ọ̀ràn pàtó kan ti ẹ nilati jiroro, eyi ti ó ni awọn iṣoro ti wọn ń dojukọ ni ile-ẹkọ ninu. Iwe naa Questions Young People Ask—Answers That Work ati awọn ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ lati inu Ilé-Ìṣọ́nà ati Ji! lè kaju aini yii. “Bi a bá lóye awọn iṣarasihuwa eyikeyii níhà ọ̀dọ̀ awọn ọmọkunrin wa ti ó nilo atunṣe,” ni baba kan sọ, “a ń kó afiyesi jọ sori akori pataki naa ti o kárí rẹ̀ ninu iwe Young People Ask.” Aya rẹ̀ fikun un pe: “A ń gbiyanju lati maṣe wonkoko jù. Bi a bá ni ohun kan ti a wéwèé fun ikẹkọọ wa, ti aini naa sì dide lati jiroro ohun miiran kan, nigba naa awa yoo ṣe iyipada ni ibamu pẹlu aini naa.”
16. (a) Bawo ni iwọ ṣe lè ni idaniloju pe awọn ọmọ rẹ lóye ohun ti wọn ń kọ́? (b) Ki ni a nilati maa yẹra fun nigba gbogbo ninu didari ikẹkọọ idile kan?
16 Bawo ni iwọ ṣe lè ní idaniloju pe awọn ọmọ rẹ lóye ohun ti wọn ń kọ́ niti gidi? Ọ̀gá Olukọ naa, Jesu, beere awọn ibeere oju-iwoye, iru bii, “Iwọ ti rò ó sí?” (Matteu 17:25) Nipa ṣiṣe ohun kan-naa, gbiyanju lati wadii ohun ti awọn ọmọ rẹ ń rò niti gidi. Fun ọmọ kọọkan niṣiiri lati dahun ni awọn ọ̀rọ̀ tirẹ̀. Nitootọ, bi o bá fi ibinu tabi iyalẹnu òjijì huwapada ju bi ó ti yẹ lọ si awọn isọjade alailabosi wọn, wọ́n lè ṣatunyẹwo ironu wọn nipa bíbá ọ jumọsọrọpọ lẹẹkan sii. Nitori naa farabalẹ pẹ̀sẹ̀. Yẹra fun yíyí ikẹkọọ idile si akoko fun nínani ní patiyẹ. Ó nilati jẹ́ eyi ti ó gbadunmọni, ti ń gbeniro. Baba kan wi pe, “Bi mo bá rí i pe ọ̀kan ninu awọn ọmọ mi ni iṣoro kan, emi yoo yanju rẹ̀ ni akoko miiran.” “Bi a bá dá yanju ọ̀rọ̀ naa pẹlu ọmọ naa nikan,” ni ìyá kan fikun un, “ọmọ naa ni a kì yoo ṣe bẹẹ kótìjú bá yoo sì ni itẹsi lati tubọ sọrọ fàlàlà sii ju bi a bá gbà á nimọran lakooko ikẹkọọ idile lọ.”
17. Ki ni a lè ṣe lati mú ki ikẹkọọ idile gbadunmọni, ki ni ó sì ti ṣiṣẹ daradara fun idile rẹ?
17 Mímú ki awọn ọmọ kópa ninu ikẹkọọ idile lè jẹ́ ipenija kan, ni pataki nigba ti o bá ń ba awọn ọmọ ti ọjọ-ori wọn yatọsira lò. Awọn ti wọn tubọ jẹ́ ọmọde lè ní itẹsi lati jẹ́ aláraàbalẹ̀, aláìgbéjẹ́ẹ́, tabi ki ìpọkànpọ̀ wọn má tó nǹkan. Ki ni iwọ lè ṣe? Gbiyanju lati mú imọlara ayika ikẹkọọ naa tura gbẹ̀dẹ̀gbẹdẹ. Bi akoko ìpọkànpọ̀ awọn ọmọ rẹ bá kuru, gbiyanju awọn akoko ijokoo ti ó tubọ kúrú ju ṣugbọn ti ó tubọ ṣe lemọlemọ. Ó tun ń ṣeranwọ bi o bá ni ìtara-ọkàn. “Ẹni ti ń ṣe olórí, ki o maa ṣe é ni oju mejeeji.” (Romu 12:8) Jẹ ki gbogbo wọn dá sí i. Ó lè ṣeeṣe fun awọn ọmọde ti wọn tubọ kéré lati ṣalaye lori awọn aworan tabi dahun awọn ibeere ti ó rọrùn. Awọn ọ̀dọ́langba ni a lè sọ fun lati ṣe afikun iwadii tabi ki wọn ṣalaye ifisilo gbigbeṣẹ tí ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ naa ti a ń jiroro ní.
18. Bawo ni awọn òbí ṣe lè tẹ Ọ̀rọ̀ Ọlọrun mọ́ni lọ́kàn ni gbogbo ìgbà, pẹlu abajade wo sì ni?
18 Bi o ti wu ki o ri, maṣe fi itọni tẹmi mọ sori wakati kan lọ́sẹ̀. Tẹ Ọ̀rọ̀ Ọlọrun mọ́ awọn ọmọ rẹ lọ́kàn ni gbogbo ìgbà ti anfaani bá ṣí silẹ. (Deuteronomi 6:7) Wá akoko lati fetisilẹ si wọn. Gbà wọn niyanju ki o sì tù wọn ninu nigba ti ó bá pọndandan. (Fiwe 1 Tessalonika 2:11.) Jẹ́ agbatẹniro ati alaaanu. (Orin Dafidi 103:13; Malaki 3:17) Ni ṣiṣe bẹẹ, iwọ yoo ‘rí inu didun’ ninu awọn ọmọ rẹ iwọ yoo sì ṣetilẹhin fun ìpamọ́ wọn wọnu ayé titun ti Ọlọrun.—Owe 29:17.
“Ìgbà Rírẹ́rìn-ín”
19, 20. (a) Ipa wo ni eré-ìtura ń kó ninu igbesi-aye idile? (b) Ki ni awọn ọ̀nà diẹ ti awọn òbí lè gbà ṣeto fun eré-ìtura fun idile wọn?
19 “Ìgbà rírẹ́rìn-ín . . . , ìgbà jíjó” wà. (Oniwasu 3:4) Ọ̀rọ̀ Heberu naa fun “rẹ́rìn-ín” ni a tun lè tumọ pẹlu iru awọn ọ̀rọ̀ bii “ṣàjọ̀dún,” “ṣiré,” “ṣe eré-ìdárayá,” tabi “gbadun akoko daradara” paapaa. (2 Samueli 6:21; Jobu 41:5; Onidajọ 16:25; Eksodu 32:6; Genesisi 26:8, NW) Eré ṣiṣe lè ṣiṣẹ fun ète ti ó ṣanfaani, ó sì ṣe pataki fun awọn ọmọde ati awọn ọ̀dọ́. Ni awọn akoko ti a kọ Bibeli awọn òbí ń ṣeto eré-ìnàjú ati eré-àṣedárayá fun awọn idile wọn. (Fiwe Luku 15:25.) Iwọ ha ń ṣe bakan naa bi?
20 “A ń lo anfaani awọn ọgbà eré-àṣedárayá fun gbogbo eniyan,” ni Kristian ọkọ kan sọ. “Awa yoo késí awọn arakunrin ọ̀dọ́ diẹ a o sì ṣeré bọọlu gbígbá ati ìjáde ìnajú. Wọn gbadun akoko daradara wọ́n sì gbadun ibakẹgbẹ pipeye.” Òbí miiran fikun un pe: “A ń wéwèé awọn nǹkan ti a o bá awọn ọdọmọkunrin wa ṣe. A maa ń lọ lúwẹ̀ẹ́, gbá bọọlu, gba akoko isinmi kuro lẹnu iṣẹ́. Ṣugbọn a ń pa eré-ìnàjú mọ́ si ipo rẹ̀ bibojumu. Mo ń tẹnumọ aini naa lati pa iwadeedee mọ́.” Eré-ìtura pipeye, iru bii ikorajọpọ ṣiṣewẹku tabi irin-ajo kukuru lọ si awọn ọgbà ẹranko ati ilé-àkójọ-ohun-ìṣẹ̀m̀báyé, lè ṣe ohun pupọ lati maṣe jẹ́ ki ọmọ kan di ẹni ti awọn igbadun ayé fà lọ́kàn mọra.
21. Bawo ni awọn òbí ṣe lè ṣediwọ fun jíjẹ́ ki awọn ọmọ wọn nimọlara pe a fi nǹkan dù wọn nitori ṣiṣai ṣayẹyẹ awọn họlide ti ayé?
21 Ó tun ṣe pataki pe ki awọn ọmọ rẹ maṣe nimọlara pe o fi nǹkan dù wọn nitori pe wọn kò ṣayẹyẹ ọjọ́-ìbí tabi awọn họlide ti kìí ṣe ti Kristian. Pẹlu iwọn iṣetojọ kan ni apa ọ̀dọ̀ rẹ, wọn lè fojusọna fun ọpọlọpọ awọn akoko igbadun jalẹ ọdun. Họwu, òbí rere kan kò nilo awọn họlide kan gẹgẹ bi àwáwí fun fifi ifẹ rẹ̀ hàn ni ọ̀nà ohun ti ara. Bii Baba rẹ̀ ọrun, oun mọ ‘bi oun yoo ti fi ẹbun rere fun awọn ọmọ rẹ’—lọna àdánúṣe.—Matteu 7:11.
Titọju Ọjọ-ọla Ayeraye kan fun Idile Rẹ
22, 23. (a) Bi ipọnju nla naa ti ń sunmọle, nipa ki ni awọn òbí olubẹru Ọlọrun lè ni idaniloju? (b) Ki ni awọn idile lè ṣe lati ṣiṣẹ siha ìpamọ́ wọnu ayé titun ti Ọlọrun?
22 Olórin naa gbadura pe: “Iwọ ó pa wọn mọ́, Oluwa, iwọ ó pa olukuluku wọn mọ́ kuro lọwọ ìran yii laelae.” (Orin Dafidi 12:7) Ikimọlẹ lati ọ̀dọ̀ Satani ni ó daju pe yoo pọ sii—ni pataki lodisi idile awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Sibẹ, ó ṣeeṣe lati rí ara gba igbejakoni ti ń pọ sii ṣáá yii. Pẹlu iranlọwọ Jehofa ati ipinnu tagbaratagbara ati iṣẹ àṣekára ni iha ọ̀dọ̀ awọn ọkọ, aya, ati ọmọ, awọn idile—ti ó ni idile rẹ ninu—lè ní ireti didi eyi ti a pamọ láàyè nigba ipọnju nla naa.
23 Ẹyin ọkọ ati aya, ẹ mú alaafia ati iṣọkan wá sinu igbeyawo yin nipa kíkó ipa ti Ọlọrun yàn fun yin. Ẹyin òbí, ẹ maa baa lọ lati gbé apẹẹrẹ ti o tọna kalẹ fun awọn ọmọ yin, ní ríra ìgbà pada lati fun wọn ni ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ati ibawi ti wọn nilo gidigidi. Ẹ bá wọn sọrọ. Ẹ fetisilẹ si wọn. Iwalaaye wọn wà ninu ewu! Ẹyin ọmọ, ẹ fetisilẹ ki ẹ sì ṣegbọran si awọn òbí yin. Pẹlu iranlọwọ Jehofa ẹ lè kẹ́sẹjárí ki ẹ sì tọju ọjọ-ọla ayeraye kan ninu ayé titun ti Ọlọrun tí ń bọ̀ pamọ fun araayin.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Kasẹẹti àtẹ́tísí tun wà ni awọn èdè kan.
Iwọ Ha Ranti Bi?
◻ Bawo ni awọn ọkọ ati aya ṣe lè mú ijumọsọrọpọ wọn sunwọn sii?
◻ Bawo ni awọn òbí ṣe lè tọ́ awọn ọmọ dagba ninu “ilana-ero-ori ti Jehofa”? (Efesu 6:4, NW)
◻ Ki ni awọn ọ̀nà diẹ lati mú ki ikẹkọọ idile jẹ́ eyi ti ń gbeniro ki ó sì tubọ gbadunmọni?
◻ Ki ni awọn òbí lè ṣe niti ṣiṣeto eré-ìtura ati eré-ìnàjú fun awọn idile wọn?
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 16]
OHùn-Orin—Agbara-Idari Ńláǹlà Kan
Oluṣewe kan lori ọmọ títọ́ sọ pe: “Bi emi bá nilati duro niwaju awujọ kan . . . kí n sì gbẹnusọ fun imutipara alárìíyá ẹhànnà, gbigba cocaine pé, mímu igbó, tabi eyikeyii ninu awọn oogun miiran ti ń mọ́kàn pòrúrùu, wọn yoo wò mi pẹlu iyalẹnu ńláǹlà. . . . [Sibẹ] awọn òbí lọpọ ìgbà maa ń pese owó fun awọn ọmọ wọn lati fi ra awọn rẹkọọdu tabi kasẹẹti ti a ti gbohùn si eyi ti ń gbẹnusọ fun irú awọn nǹkan wọnni.” (Raising Positive Kids in a Negative World, lati ọwọ́ Zig Ziglar) Ni United States, fun apẹẹrẹ, awọn ọ̀rọ̀ orin kíkọ ti ń ṣalaye kulẹkulẹ ibalopọ takọtabo jù wà létè ọpọlọpọ awọn ọ̀dọ́. Iwọ ha ń ran awọn ọmọ rẹ lọwọ lati lo iṣọra ninu awọn ohùn-orin ti wọn yàn ki wọn baa lè yẹra fun iru awọn idẹkun ẹmi eṣu bẹẹ bi?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Awọn akoko ounjẹ lè jẹ́ awọn akoko gbigbadunmọni tí ń gbé iṣọkan ati ijumọsọrọpọ idile larugẹ