ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w13 10/1 ojú ìwé 5
  • Bí Ọlọ́run Ṣe Dá Aráyé Nídè

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Bí Ọlọ́run Ṣe Dá Aráyé Nídè
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2013
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìlérí tí Ọlọ́run Ṣe Láti Ẹnu Àwọn Wòlíì
    Ìgbàgbọ́ Òdodo Ló Máa Mú Kó O Ní Ayọ̀
  • Mèsáyà! Ọ̀nà Ìgbàlà Tí Ọlọ́run Pèsè
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • “Àwa Ti Rí Mèsáyà Náà”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Wọ́n Retí Mèsáyà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2013
w13 10/1 ojú ìwé 5
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]

KÓKÓ Ọ̀RỌ̀ | KÍ LÓ WÀ NÍNÚ BÍBÉLÌ?

Bí Ọlọ́run Ṣe Dá Aráyé Nídè

Ọlọ́run ṣèlérí fún Ábúráhámù ọkùnrin olóòótọ́ ìgbàanì pé “irú-ọmọ” tí òun ṣèlérí yẹn máa jẹ́ ọ̀kan lára àtọmọdọ́mọ rẹ̀. Nípasẹ̀ irú-ọmọ yẹn ni gbogbo “àwọn orílẹ̀-èdè” yóò rí ìbùkún gbà. (Jẹ́nẹ́sísì 22:18) Jékọ́bù tó jẹ́ ọmọ ọmọ Ábúráhámù ṣí lọ sí Íjíbítì, ibẹ̀ ni ìdílé rẹ̀ ti pọ̀ sí i, tí wọ́n sì di orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì àtijọ́.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]

Nígbà tó yá, Fáráò Ọba Íjíbítì tó jẹ́ òǹrorò kó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lẹ́rú kí Ọlọ́run tó wá gbé Mósè dìde láti ṣamọ̀nà àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò ní Íjíbítì nípa iṣẹ́ ìyanu tó ṣe tó fi pín Òkun Pupa níyà. Lẹ́yìn ìyẹn, Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láwọn òfin, títí kan Òfin Mẹ́wàá. Àwọn òfin yìí á máa tọ́ wọn sọ́nà, á sì máa dáàbò bò wọ́n. Àwọn òfin yẹn dìídì sọ àwọn ìrúbọ tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbọ́dọ̀ ṣe kí Ọlọ́run tó lè dárí ẹ̀ṣẹ̀ jì wọ́n. Ọlọ́run tún gbẹnu Mósè sọ pé òun máa rán wòlíì míì sí wọn. Wòlíì yìí ló máa wá jẹ́ “irú-ọmọ” tí Ọlọ́run ṣèlérí.

Ó lé ní nǹkan bí ọgọ́rùn-ún mẹ́rin [400] ọdún lẹ́yìn ìgbà yẹn kí Ọlọ́run tó ṣèlérí fún Dáfídì Ọba pé “irú-ọmọ” tí òun ṣèlérí ní Édẹ́nì yẹn máa ṣàkóso Ìjọba òun títí láé. Ẹni yẹn ló wá di Mèsáyà, ìyẹn olùdáǹdè tí Ọlọ́run yàn láti gba aráyé là, kí ó sì sọ ayé di Párádísè pa dà.

Ọlọ́run tipasẹ̀ Dáfídì àtàwọn wòlíì míì ṣí ọ̀pọ̀ nǹkan pa yá nípa Mèsáyà náà ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé. Àwọn wòlíì yẹn sọ pé Mèsáyà náà á jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ àti onínúure, àti pé nígbà tó bá ń ṣàkóso, kò ní sí ebi, ìrẹ́jẹ àti ogun mọ́. Kódà, gbogbo èèyàn á máa gbé pọ̀ ní àlàáfíà, kò ní sí ìṣọ̀tá láàárín èèyàn àtàwọn ẹranko mọ́. Àìsàn, ìyà àti ikú kò sí nínú nǹkan tí Ọlọ́run fẹ́ fún aráyé níbẹ̀rẹ̀ rárá. Gbogbo rẹ̀ ni yóò sì di àwátì. Kódà, àwọn tó ti kú á jíǹde.

Ọlọ́run tipasẹ̀ wòlíì Míkà sọ pé ìlú Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ni wọ́n máa bí Mèsáyà sí, ó sì tún tipasẹ̀ wòlíì Dáníẹ́lì sọ pé àwọn èèyàn máa pa á tó bá yá. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run máa jí Mèsáyà náà dìde, á sì yàn án ṣe Ọba ní ọ̀run. Ọlọ́run tún fi han Dáníẹ́lì nínú ìran pé Ìjọba Mèsáyà náà máa rọ́pò gbogbo ìjọba èèyàn pátápátá. Ǹjẹ́ Mèsáyà náà dé gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́ ṣe sọ?

​—A gbé e ka Jẹ́nẹ́sísì orí 22-50 àti Ẹ́kísódù, Diutarónómì, 2 Sámúẹ́lì, Sáàmù, Aísáyà, Dáníẹ́lì, Míkà, Sekaráyà 9:9.

ORÚKỌ ỌLỌ́RUN

Inú Jẹ́nẹ́sísì 2:4 ni Jèhófà, ìyẹn orúkọ Ọlọ́run, ti kọ́kọ́ fara hàn nínú Bíbélì. Kò sí ẹlòmíì tó ń bá Ọlọ́run jẹ́ orúkọ yìí, orúkọ náà sì fara hàn nínú Bíbélì ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méje [7,000] ìgbà. Orúkọ yẹn túmọ̀ sí “Alèwílèṣe,” ìyẹn ni pé Ọlọ́run lágbára láti ṣe ohunkóhun tó bá fẹ́ tàbí ohunkóhun tó bá ṣèlérí.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́