ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w13 10/1 ojú ìwé 4
  • Báwo La Ṣe Dé Ayé?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Báwo La Ṣe Dé Ayé?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2013
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kí Ni Ọlọ́run Ní Lọ́kàn fún Aráyé?
    Kí Ni Bíbélì Kọ́ Wa?
  • A Sọ Párádísè Nù
    Kí Ló Wà Nínú Bíbélì?
  • Ìdí Tí Ìwà Ibi Ṣì Fi Wà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Kí Nìdí Tí Nǹkan Burúkú Fi Ń Ṣẹlẹ̀ Tá A sì Ń Jìyà?
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2013
w13 10/1 ojú ìwé 4
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]

KÓKÓ Ọ̀RỌ̀ | KÍ LÓ WÀ NÍNÚ BÍBÉLÌ?

Báwo La Ṣe Dé Ayé?

Ní kúkúrú, Jẹ́nẹ́sísì tó jẹ́ ìwé àkọ́kọ́ nínú Bíbélì ṣàlàyé bí ayé àti ọ̀run ṣe bẹ̀rẹ̀, ó ní: “Ní ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀, Ọlọ́run dá ọ̀run àti ilẹ̀ ayé.” (Jẹ́nẹ́sísì 1:1) Lẹ́yìn tí Ọlọ́run dá ewéko àti ẹranko ló wá dá àwọn èèyàn àkọ́kọ́, ìyẹn Ádámù àti Éfà. Wọ́n yàtọ̀ sí ẹranko torí pé wọ́n lè fìwà jọ Ọlọ́run dé ìwọ̀n àyè kan, wọ́n sì tún láǹfààní láti yan ohun tí wọ́n fẹ́. Torí náà, wọn yóò jíhìn ohun tí wọ́n bá ṣe. Ká ní Ádámù àti Éfà ṣègbọràn sí ìtọ́ni Ọlọ́run ni, ohun tí ó fẹ́ fún wọn ni pé kí wọ́n di òbí àkọ́kọ́ fún aráyé, kí wọ́n máa gbé ní àlàáfíà, kí wọ́n sì wà láàyè títí láé bí ẹ̀dá pípé.

Àmọ́, áńgẹ́lì kan tàn wọ́n jẹ kí wọ́n lè ṣe ìfẹ́ inú tirẹ̀. Bí ẹ̀dá ẹ̀mí yìí ṣe sọ ara rẹ̀ di Sátánì, tó túmọ̀ sí “Alátakò” nìyẹn. Sátánì lo ejò láti fi bá Éfà sọ̀rọ̀, ó sọ pé nǹkan á dáa fún un láìsí ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run. Àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, Ádámù àti Éfà gbọ́ ti Sátánì, wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ kẹ̀yìn sí Ẹlẹ́dàá wọn. Torí pé àwọn òbí wa àkọ́kọ́ ṣe ìpinnu tí kò dáa, wọ́n pàdánù ìyè ayérayé, a wá jogún ẹ̀ṣẹ̀, àìpé àti ikú tó ń pa gbogbo ẹ̀dá.

Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ni Ọlọ́run ti sọ ohun tí òun máa ṣe láti yanjú wàhálà ńlá tí àwọn òbí wa àkọ́kọ́ dá sílẹ̀, kí àwọn àtọmọdọ́mọ wọn lè ní ìyè ayérayé. Ọlọ́run sọ tẹ́lẹ̀ pé “irú-ọmọ” tàbí ẹ̀dá pàtàkì kan máa pa Sátánì run, ó sì máa fòpin sí gbogbo ìyà tí Sátánì, Ádámù àti Éfà ti fà. (Jẹ́nẹ́sísì 3:15) Tani irú ọmọ yìí máa wá jẹ́ o? Ó máa fara hàn tí àkókò tó.

Àmọ́ látìgbà yẹn ni Sátánì ti ń wá gbogbo ọ̀nà láti rí i pé òun da àwọn ohun rere tí Ọlọ́run fẹ́ ṣe rú. Ẹ̀ṣẹ̀ àti ìwà ibi bẹ̀rẹ̀ sí í gbèèràn bí iná ọyẹ́. Ni Ọlọ́run bá pinnu láti fi ìkún-omi pa àwọn ẹni ibi run. Ó sọ fún Nóà tó jẹ́ olódodo pé kí ó kan áàkì, ìyẹn ọkọ̀ ojú omi tó dà bí àpótí ńlá kan tí ó lè léfòó lórí omi. Inú rẹ̀ ni Nóà àti ìdílé rẹ̀ àtàwọn ẹranko tí Ọlọ́run sọ pé kí ó kó sínú áàkì náà máa wà láìséwu.

Ọdún kan lẹ́yìn Ìkún-omi yẹn ni Nóà àti ìdílé rẹ̀ tó jáde nínú áàkì náà. Nígbà tí wọ́n bọ́ síta wọ́n rí i pé gbogbo ilẹ̀ ayé ti mọ́ tónítóní. Àmọ́ “irú-ọmọ” yẹn ò tíì dé.

​—A gbé e ka Jẹ́nẹ́sísì orí 1-11; Júúdà 6, 14, 15; Ìṣípayá 12:9.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́