ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w13 10/1 ojú ìwé 3
  • Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó O Ka Bíbélì?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó O Ka Bíbélì?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2013
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó O Kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
  • Ìwé Kan Tó Yẹ Ká Mọ̀ Dunjú
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
  • Ẹ̀kọ́ Òtítọ́ Tínú Ọlọ́run Dùn Sí
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
  • Orisun Àrà-ọ̀tọ̀ Ti Ọgbọn Ti O Ga Ju
    Ki Ni Ète Igbesi-Aye? Bawo Ni Iwọ Ṣe Le Rí I?
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2013
w13 10/1 ojú ìwé 3
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 3]

KÓKÓ Ọ̀RỌ̀ | KÍ LÓ WÀ NÍNÚ BÍBÉLÌ?

Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó O Ka Bíbélì?

Bíbélì jẹ́ ìwé kan tí gbogbo èèyàn nílé lóko mọ. Kí nìdí? Ìdí ni pé ó rọrùn láti lóye. Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa àwọn èèyàn tó ti gbé láyé rí, ó sì jẹ́ ká mọ àwọn ohun tó wáyé láàárín wọn àti irú àjọṣe tí wọ́n ní pẹ̀lú Ọlọ́run. Àkọsílẹ̀ inú Bíbélì kọ́ni ní ẹ̀kọ́ tó bọ́gbọ́n mu, kò sì lọ́jú pọ̀. Èyí mú kó rọrùn fún gbogbo èèyàn láti lóye rẹ̀. Wọ́n tú Bíbélì sí ọgọ́rọ̀ọ̀rún èdè, ó sì wà lárọ̀ọ́wọ́ tó àwọn èèyàn kárí ayé. Kò sígbà tí àwọn ìlànà Bíbélì ò wúlò.

Pabanbarì rẹ̀ ni pé, Bíbélì kì í ṣe ìwé tó kàn sọ nípa Ọlọ́run, àmọ́ ó tún jẹ́ ìwé tó ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá. Bíbélì sọ orúkọ Ọlọ́run, irú ẹni tó jẹ́, àti ìdí tó fi dá àwa èèyàn sáyé. Ó tún jẹ́ ká mọ̀ pé ọjọ́ pẹ́ tí Sátánì ti ń ṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run àmọ́ Jèhófà ò ní pẹ́ fi Sátánì hàn ní ẹni ibi, á sì paná gbogbo ìwà ọ̀tẹ̀ tó ti hù. Tí a kò bá fiyè méjì ka Bíbélì, á jẹ́ ká lè ní ìgbàgbọ́ àti ìrètí tó dájú.

Àwọn ìsọfúnni tó wà Bíbélì ò láfiwé. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì jẹ́ ká mọ òtítọ́ nípa àwọn kókó pàtàkì bíi:

  • Ibi tí a ti ṣè wá àti ìdí tí ìyà fi ń jẹ́ ọmọ aráyé

  • Ètò ti Ọlọ́run ṣe láti dá aráyé nídè

  • Ohun tí Jésù ṣe fún wa

  • Ohun tó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ sí ayé yìí àti àwa èèyàn lọ́jọ́ iwájú

Jọ̀wọ́ fara balẹ̀ wo àwọn ojú ìwé tó tẹ̀ lé e kí o lè mọ ohun tó wà nínú Bíbélì.

ÌSỌFÚNNI NÍPA BÍBÉLÌ

  • Ẹṣin Ọ̀rọ̀: Bí Ìjọba Ọlọ́run ṣe máa mú kí òdodo àti àlàáfíà pa dà wà lórí ilẹ̀-ayé

  • Àwọn ìwé inú rẹ̀: Ìwé mọ́kàndínlógójì [39] ni wọ́n kọ ní èdè Hébérù àti apá díẹ̀ ní èdè Árámáíkì, ìwé mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n [27] yòókù sì jẹ́ ní èdè Gíríìkì

  • Àwọn tí ó kọ ọ́: Nǹkan bí ogójì [40] ọkùnrin ló kọ Bíbélì. Ó tó nǹkan bí ẹgbẹ̀jọ [1,600] ọdún kí wọ́n tó kọ ọ́ tán, bẹ̀rẹ̀ láti ọdún 1513 ṣáájú Sànmánì Kristẹni títí dé ọdún 98 Sànmánì Kristẹni

  • Èdè: Ní báyìí, Bíbélì ti wà ní èdè tí ó ju ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀tàlá [2,500] lọ, yálà ní odindi tàbí ní apá kan

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́