ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w15 12/1 ojú ìwé 4-5
  • Ìwé Kan Tó Yẹ Ká Mọ̀ Dunjú

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìwé Kan Tó Yẹ Ká Mọ̀ Dunjú
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • WỌ́N KỌ BÍBÉLÌ LỌ́NÀ TÓ MÁA GBÀ YÉNI
  • Ó WÀ FÚN GBOGBO ÈÈYÀN
  • Kí Ni Bíbélì?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó O Ka Bíbélì?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2013
  • Ẹ̀kọ́ Òtítọ́ Tínú Ọlọ́run Dùn Sí
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
  • Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Ni Bíbélì Ti Wá
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
w15 12/1 ojú ìwé 4-5
Kíka Bíbélì tí wọ́n tẹ̀ àti èyí tó wà lórí fóònù

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | O LÈ LÓYE BÍBÉLÌ

Ìwé Kan Tó Yẹ Ká Mọ̀ Dunjú

Ọjọ́ pẹ́ tí wọ́n ti kọ Bíbélì. Báwo ló ṣe pẹ́ tó? Wọ́n bẹ̀rẹ̀ kíkọ Bíbélì ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ààbọ̀ [3,500] ọdún sẹ́yìn. Ìyẹn jẹ́ àkókò kan náà pẹ̀lú ìjọba Shang tọ́jọ́ rẹ̀ pẹ́ jù lọ nínú ìtàn ilẹ̀ Ṣáínà, ó sì jẹ́ nǹkan bí ẹgbẹ̀rún kan ọdún kí wọ́n tó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ẹ̀sìn Búdà lórílẹ̀-èdè Íńdíà. ​—Wo àpótí náà “Ìsọfúnni Nípa Bíbélì.”

Bíbélì fún wa ní àwọn ìdáhùn tó ń tẹ́ni lọ́rùn sí àwọn ìbéèrè tó ṣe pàtàkì nígbèésí ayé

Tí ìwé kan bá máa ṣe wá láǹfààní, tó sì máa ṣamọ̀nà wa, a gbọ́dọ̀ lóye ohun tó wà nínú rẹ̀, ká sì rí i pé lóòótọ́ ló wúlò fún wa. Irú ìwé tí Bíbélì jẹ́ gan an nìyẹn. Ó fún wa ní àwọn ìdáhùn tó ń tẹ́ni lọ́rùn sí àwọn ìbéèrè tó ṣe pàtàkì nígbèésí ayé.

Bí àpẹẹrẹ, ṣé o máa ń ṣe kàyéfì pé, ‘Kí la wá ṣe láyé?’ Kì í ṣòní kì í ṣàná táwọn èèyàn ti ń béèrè ìbéèrè yìí, títí di báyìí ọ̀pọ̀ ló ṣì ń wá ìdáhùn sí ìbéèrè náà. Síbẹ̀, ìdáhùn sí ìbéèrè yìí wà nínú orí méjì tó ṣáájú nínú ìwé Jẹ́nẹ́sísì, tó jẹ́ ìwé àkọ́kọ́ nínú Bíbélì. Níbẹ̀, Bíbélì sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ ní “ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀,” ìyẹn ní ọ̀pọ̀ bílíọ̀nù ọdún sẹ́yìn nígbà tí Ọlọ́run dá àgbáálá ayé wa, òṣùpá àtàwọn ìràwọ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 1:1) Ó tún ṣàlàyé bí Ọlọ́run ṣe sọ ayé di ibi tó ṣe é gbé, tó sì dá àwọn ewéko àti onírúurú ẹranko. Lẹ́yìn náà ló sọ bó ṣe dá àwa èèyàn, tó sì ṣàlàyé ìdí tó fi dá wa.

WỌ́N KỌ BÍBÉLÌ LỌ́NÀ TÓ MÁA GBÀ YÉNI

Bíbélì fún wa láwọn ìmọ̀ràn tó máa jẹ́ ká lè borí àwọn ìṣòro tá a sábà máa ń kojú. Àwọn ìmọ̀ràn yìí rọrùn láti lóye. Ohun méjì ló mú kí èyí rí bẹ́ẹ̀.

Àkọ́kọ́, àwọn ọ̀rọ̀ inú Bíbélì ṣe tààràtà, kò lọ́jú pọ̀, ó sì tuni lára. Dípò kí wọ́n lo àwọn ọ̀rọ̀ kàbìtìkàbìtì tó ṣòro lóye, ńṣe ni wọ́n lo àwọn ọ̀rọ̀ tó máa tètè yéni. Bíbélì máa ń lo àwọn nǹkan tí kò ṣàjèjì sí wa láti ṣàlàyé àwọn ọ̀rọ̀ tó bá ta kókó ká lè lóye wọn.

Bí àpẹẹrẹ, Jésù lo àwọn àpèjúwe tó dá lórí nǹkan táwọn èèyàn mọ̀ dáadáa kó lè fi kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ tó máa wọ̀ wọ́n lọ́kàn. A máa rí ọ̀pọ̀ àwọn àpèjúwe yìí nínú ìwàásù kan táwọn èèyàn mọ̀ sí Ìwàásù Lórí Òkè tó wà nínú ìwé Mátíù orí 5 sí 7. Ọgbẹ́ni alálàyé kan pè é ní “ìwàásù tó ṣeé múlò.” Ó wá fi kún un pé kì í ṣe pé Jésù “kàn rọ́ ìsọfúnni kalẹ̀ fún wa, àmọ́ ó fún wa láwọn ìmọ̀ràn tó máa tọ́ wa sọ́nà nígbèésí ayé.” O lè ka àwọn orí yẹn láàárín ogún ìṣẹ́jú, á sì yà ẹ́ lẹ́nu láti rí i bí àwọn ọ̀rọ̀ Jésù ṣe wúlò tó.

Ohun míì tó jẹ́ kí Bíbélì rọrùn láti lóye ni ohun tí Bíbélì fúnra rẹ̀ sọ̀rọ̀ lé lórí. Kì í ṣe ìtàn àròsọ ló wà nínú rẹ̀. Ìwé The World Book Encyclopedia sọ pé, Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa “onírúurú àwọn èèyàn,” ó sì sọ “ìlàkàkà wọn, ìrètí wọn, àṣìṣe wọn àtàwọn àṣeyọrí wọn.” Torí èèyàn bíi tiwa làwọn wọ̀nyí, ó rọrùn láti lóye ohun tí Bíbélì sọ nípa wọn, ká sì kẹ́kọ̀ọ́ látinú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí wọn.​—Róòmù 15:4.

Ó WÀ FÚN GBOGBO ÈÈYÀN

Kí ohun tí wọ́n kọ sínú ìwé kan tó lè yé ẹ, wọ́n gbọ́dọ̀ kọ́ ọ ní èdè tó o mọ̀ ọ́n kà. Lóde òní, ó ṣeé ṣe kí Bíbélì wà ní èdè tó o mọ̀ láìka ibi tí ò ń gbé tàbí ẹ̀yà tó o ti wá. Ẹ jẹ́ ká wo àwọn nǹkan tó mú kí èyí ṣeé ṣe.

Iṣẹ́ ìtumọ̀ èdè. Èdè Hébérù, Árámáíkì àti Gíríìkì ni wọ́n fi kọ Bíbélì láyé àtijọ́. Àmọ́, ìwọ̀nba èèyàn díẹ̀ ló mọ àwọn èdè yìí. Àwọn atúmọ̀ èdè wá ṣe iṣẹ́ takuntakun kí wọ́n lè túmọ̀ Bíbélì sí ọ̀pọ̀ àwọn èdè míì. Ọpẹ́lọpẹ́ wọn, Bíbélì ti wà lódindi tàbí lápá kan ní èdè tí ó tó ẹgbẹ̀rún méjì àti ọgọ́rùn-ún méje [2,700]. Èyí fi hàn pé ohun tó ju ìdá mẹ́sàn nínú mẹ́wàá àwọn èèyàn kárí ayé ló lè ka Bíbélì ní èdè abínibí wọn.

Iṣẹ́ ìtẹ̀wé. Orí àwọn nǹkan tó lè tètè bà jẹ́ irú bí awọ àti òrépèté ni wọ́n kọ Bíbélì sí láyé àtijọ́. Èyí gbà pé kí wọ́n máa ṣe àdàkọ rẹ̀ lóòrèkóòrè. Àmọ́ àwọn àdàkọ yìí wọ́n gan-an, àwọn tó bá sì jẹun kánú ló lè rà á. Ṣùgbọ́n àtìgbà tí wọ́n ti ṣe ẹ̀rọ̀ ìtẹ̀wé Gutenberg ní ohun tó lé ní àádọ́ta lé ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [550] ọdún sẹ́yìn, ó ti túbọ̀ rọrùn gan-an láti tẹ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀dà Bíbélì jáde. Àwọn kan tiẹ̀ fojú bù ú pé, ohun tó ju bílíọ̀nù márùn-ún Bíbélì bóyá lódindi tàbí lápá kan ni wọ́n ti pín káàkiri.

Kò sí ìwé ìsìn míì tó dà bíi Bíbélì láwọn ọ̀nà wọ̀nyí. Èyí fi hàn gbangba pé a lè lóye ohun tó wà nínú Bíbélì. Àmọ́ nígbà míì, ó lè dà bíi pé ó ṣòro láti lóye rẹ̀. Fọkàn balẹ̀, ohun tó o lè ṣe wà. Ibo lo ti lè rí ìrànlọ́wọ́ yìí? Èrè wo lo máa rí tó o bá lóye Bíbélì? Wà á rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí nínú àpilẹ̀kọ tó kàn.

Ìsọfúnni Nípa Bíbélì

  • Ìwé mẹ́rìndínláàádọ́rin [66] ló para pọ̀ di Bíbélì.

  • Àwọn òfin, àsọtẹ́lẹ̀, òwe, orin, ewì, lẹ́tà àti ìtàn ló wà nínú Bíbélì.

  • Ọdún 1513 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ kíkọ Bíbélì, ó parí ní ọdún 98 Sànmánì Kristẹni. Ìyẹn sì lé ní ẹgbẹ̀jọ [1,600] ọdún.

  • Ọlọ́run fi ẹ̀mí mímọ́ darí nǹkan bí ogójì [40] ọkùnrin láti kọ Bíbélì.

Was Life Created?

Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa bí ìgbésí ayé ṣe bẹ̀rẹ̀, ka ìwé pẹlẹbẹ náà, Was Life Created? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe ẹ́. Ó tún wà lórí ìkànnì wa ìyẹn, www.jw.org.

Kí Ló Wà Nínú Bíbélì?

Tó o bá fẹ́ mọ púpọ̀ sí i nípa Bíbélì, ka ìwé pẹlẹbẹ náà Kí Ló Wà Nínú Bíbélì? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é. Ó tún wà lórí ìkànnì wa, ìyẹn www.jw.org/yo.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́