ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • bm apá 2 ojú ìwé 5
  • A Sọ Párádísè Nù

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • A Sọ Párádísè Nù
  • Kí Ló Wà Nínú Bíbélì?
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Báwo Ni Ìgbésí Ayé Ṣe Rí Nínú Ọgbà Édẹ́nì?
    Tẹ́tí sí Ọlọ́run Kó O Lè Wà Láàyè Títí Láé
  • Àwọn Kan Wà Nípò Tó Ga Ju Tiwa Lọ
    Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà
  • Ádámù àti Éfà Ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run
    Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
  • A Lè Kẹ́kọ̀ọ́ Lára Tọkọtaya Ẹ̀dá Ènìyàn Àkọ́kọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
Àwọn Míì
Kí Ló Wà Nínú Bíbélì?
bm apá 2 ojú ìwé 5
Éfà fọwọ́ kan èso tí Ọlọ́run kà léèwọ̀

Apá 2

A Sọ Párádísè Nù

Áńgẹ́lì ọlọ̀tẹ̀ kan mú kí ọkùnrin àti obìnrin àkọ́kọ́, Ádámù àti Éfà, kọ ìṣàkóso Ọlọ́run sílẹ̀. Nítorí èyí, ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú wọnú ayé

TIPẸ́TIPẸ́ kí Ọlọ́run tó dá èèyàn, ló ti dá ọ̀pọ̀ ẹ̀dá ẹ̀mí tí kò ṣeé fojú rí, tá a mọ̀ sí àwọn áńgẹ́lì. Nínú ọgbà Édẹ́nì, áńgẹ́lì ọlọ̀tẹ̀ kan, tá a wá mọ̀ sí Sátánì Èṣù, fi ọgbọ́n àrékérekè tan Éfà kó bàa lè jẹ lára èso igi tí Ọlọ́run sọ pé wọn ò gbọ́dọ̀ jẹ nínú rẹ̀.

Sátánì gba ẹnu ejò sọ̀rọ̀, ó sì mú kó dà bíi pé ńṣe ni Ọlọ́run ń fawọ́ ohun kan tó ṣàǹfààní sẹ́yìn fún obìnrin náà àti ọkọ rẹ̀. Áńgẹ́lì náà sọ fún Éfà pé òun àti ọkọ rẹ̀ ò ní kú bí wọ́n bá jẹ èso tí Ọlọ́run kà léèwọ̀ náà. Sátánì tipa bẹ́ẹ̀ fẹ̀sùn kan Ọlọ́run pé ó ń purọ́ fáwọn ọmọ Rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ ẹ̀dá èèyàn. Ẹlẹ̀tàn yìí mú kó dà bíi pé ṣíṣàìgbọràn sí Ọlọ́run ló máa là wọ́n lójú kí òye wọn bàa lè pọ̀ sí i, tí wọ́n á sì wá dòmìnira. Àmọ́ irọ́ gbuu ló pa fún wọn, ìyẹn sì ni irọ́ àkọ́kọ́ tẹ́nikẹ́ni tíì pa rí lórí ilẹ̀ ayé. Ohun pàtàkì tó wà nínú ọ̀ràn tó délẹ̀ yìí ni pé ó kan ipò Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ ayé òun ọ̀run. Ìyẹn ni pé ó mú kéèyàn máa ṣe kàyéfì pé bóyá ni Ọlọ́run lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣàkóso àti pé ṣó tiẹ̀ ń ṣàkóso lọ́nà tó máa ṣe àwọn tó ń ṣàkóso lé lórí láǹfààní.

Éfà gba irọ́ tí Sátánì pa gbọ́. Ojú rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í wọ èso náà, nígbà tó yá, ó mú un ó sì jẹ ẹ́. Nígbà tí ọkọ ẹ̀ dé, ó fún un lára èso náà, òun náà sì jẹ ẹ́. Bí wọ́n ṣe di ẹlẹ́ṣẹ̀ nìyẹn o. Ó lè dà bíi pé ohun tí wọ́n ṣe yẹn ò tó nǹkan lóòótọ́, àmọ́ ìwà ọ̀tẹ̀ gbáà ni. Níwọ̀n bí Ádámù àti Éfà ti mọ̀ọ́mọ̀ ṣàìgbọràn sí àṣẹ Ọlọ́run, ńṣe ni wọ́n kọ ìṣàkóso Ẹlẹ́dàá, ẹni tó fi ohun gbogbo, tó fi mọ́ ìwàláàyè pípé, jíǹkí wọn.

Irú-ọmọ náà “yóò pa ọ́ ní orí, ìwọ yóò sì pa á ní gìgísẹ̀.”—Jẹ́nẹ́sísì 3:15

Ọlọ́run kéde ìdájọ́ sórí àwọn ọlọ̀tẹ̀ yẹn torí ohun tí wọ́n ṣe. Ó sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa Irú-ọmọ, tàbí Olùdáǹdè, tó máa mú ìparun wá sórí Sátánì, tó lo ejò láti tan Éfà jẹ. Ọlọ́run ò mú ikú wá sórí Ádámù àti Éfà lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, kó bàa lè fi àánú hàn sáwọn ọmọ wọn tí wọn ò tíì bí. Àwọn ọmọ yẹn á sì lè máa fojú sọ́nà fún ọjọ́ ọ̀la aláyọ̀ torí pé Ẹni tí Ọlọ́run máa rán á sọ àbájáde búburú ìṣọ̀tẹ̀ tó wáyé nínú ọgbà Édẹ́nì di asán. Bí Ọlọ́run ṣe máa mú ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ nípa Olùgbàlà tó ń bọ̀ wá yìí àti ẹni tí Olùgbàlà náà máa jẹ́, bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe kedere sí i bí àkọsílẹ̀ Bíbélì ṣe ń ṣí i payá ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé.

Ọlọ́run lé Ádámù àti Éfà kúrò nínú Párádísè. Ní báyìí, ó di pé kí wọ́n máa ṣiṣẹ́ àṣelàágùn kí ilẹ̀ tí wọ́n fi ń ṣọ̀gbìn lẹ́yìn òde ọgbà Édẹ́nì tó lè mú oúnjẹ jáde fún wọn. Lẹ́yìn náà, Éfà lóyún, ó sì bí Kéènì, àkọ́bí wọn. Àwọn tọkọtaya náà tún bí àwọn ọmọ míì, lọ́kùnrin àti lóbìnrin, lára wọn ni Ébẹ́lì àti Sẹ́ẹ̀tì, baba ńlá Nóà.

—A gbé e ka Jẹ́nẹ́sísì orí 3 sí 5; Ìṣípayá 12:9.

  • Kí ni irọ́ àkọ́kọ́, ta ló sì pa á?

  • Báwo ni Ádámù àti Éfà ṣe sọ Párádísè nù?

  • Nígbà tí Ọlọ́run ń fi ìwà ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ọlọ̀tẹ̀ náà bi wọ́n, báwo ló ṣe jẹ́ kó ṣe kedere pé ìrètí ṣì wà fáwọn ọmọ wọn?

ÀÌPÉ LÓ Ń FA IKÚ

Ọlọ́run dá Ádámù àti Éfà ní pípé, ó sì fẹ́ kí wọ́n máa wà láàyè títí láé nínú Párádísè. Àmọ́, nígbà tí wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run, wọ́n dẹ́ṣẹ̀. Ádámù àti Éfà tipa bẹ́ẹ̀ pàdánù ìjẹ́pípé wọn, wọ́n sì já ara wọn gbà kúrò lọ́wọ́ Orísun ìyè, Jèhófà. Látìgbà náà lọ, àwọn àti gbogbo àtọmọdọ́mọ wọn ò lè ṣe kí wọ́n máà dẹ́ṣẹ̀, ìyẹn ló sì ń yọrí sí ikú.—Róòmù 5:12.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́