ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • lfb ẹ̀kọ́ 3 ojú ìwé 14-ojú ìwé 15 ìpínrọ̀ 3
  • Ádámù àti Éfà Ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ádámù àti Éfà Ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run
  • Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìdí Tí Wọ́n Fi Pàdánù Ibùgbé Wọn
    Ìwé Ìtàn Bíbélì
  • Àwọn Kan Wà Nípò Tó Ga Ju Tiwa Lọ
    Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà
  • Báwo Ni Ìgbésí Ayé Ṣe Rí Nínú Ọgbà Édẹ́nì?
    Tẹ́tí sí Ọlọ́run Kó O Lè Wà Láàyè Títí Láé
  • Ìgbésí Ayé Líle Koko Bẹ̀rẹ̀
    Ìwé Ìtàn Bíbélì
Àwọn Míì
Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
lfb ẹ̀kọ́ 3 ojú ìwé 14-ojú ìwé 15 ìpínrọ̀ 3
Ádámù àti Éfà jáde kúrò nínú ọgbà Édẹ́nì

Ẹ̀KỌ́ 3

Ádámù àti Éfà Ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run

Éfà fún Ádámù ní èso igi tí Ọlọ́run sọ pé kí wọ́n má jẹ

Lọ́jọ́ kan tí Éfà dá wà, ejò kan bá a sọ̀rọ̀. Ejò yẹn sọ pé: ‘Ṣé lóòótọ́ ni Ọlọ́run sọ pé ẹ ò gbọ́dọ̀ jẹ èyíkéyìí lára èso igi tó wà nínú ọgbà yìí?’ Éfà dáhùn pé: ‘A lè jẹ lára èso gbogbo igi tó wà nínú ọgbà yìí àyàfi ẹyọ kan péré tí Ọlọ́run sọ pé a ò gbọ́dọ̀ jẹ èso ẹ̀. Tá a bá jẹ èyí tó ní ká má jẹ, a máa kú.’ Ejò yẹn wá sọ pé: ‘Ẹ ò ní kú. Jẹ́ kí n sọ òtítọ́ fún ẹ, tẹ́ ẹ bá jẹ ẹ́, ẹ máa dà bí Ọlọ́run.’ Ṣé òótọ́ ni ejò yẹn sọ? Rárá, irọ́ ló pa. Àmọ́, Éfà gba ohun tí ejò yẹn sọ gbọ́. Torí pé Éfà tẹjú mọ́ èso yẹn, èso yẹn wù ú jẹ. Ó jẹ èso náà, ó sì tún fún ọkọ ẹ̀. Ádámù mọ̀ pé táwọn bá ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run, àwọn máa kú. Síbẹ̀, Ádámù jẹ èso náà.

Bí Ádámù àti Éfà ṣe jáde nínú ọgbà Édẹ́nì, idà oníná kan àtàwọn áńgẹ́lì ń ṣọ́ ẹnu ọ̀nà

Kí ilẹ̀ ọjọ́ yẹn tó ṣú, Jèhófà bá Ádámù àti Éfà sọ̀rọ̀. Ó ní kí wọ́n ṣàlàyé ìdí tí wọ́n fi ṣàìgbọràn. Ádámù sọ pé Éfà ló fún òun jẹ, Éfà sì sọ pé ejò ló fà á. Torí pé Ádámù àti Éfà ṣàìgbọràn, Jèhófà lé wọn jáde kúrò nínú ọgbà Édẹ́nì. Jèhófà wá fi àwọn áńgẹ́lì àti idà tó ń yọ iná ṣọ́ ẹnu ọ̀nà ọgbà yẹn. Ǹjẹ́ o mọ ìdí? Ìdí ni pé kò fẹ́ kí Ádámù àti Éfà pa dà sínú ọgbà yẹn mọ́ láéláé.

Jèhófà sọ pé òun máa fìyà jẹ ẹni tó parọ́ fún Éfà. Ǹjẹ́ o mọ̀ pé kì í ṣe ejò gan-an ló bá Éfà sọ̀rọ̀? Jèhófà kò dá àwọn ejò pé kí wọ́n máa sọ̀rọ̀. Áńgẹ́lì burúkú kan ló mú kí ejò yẹn sọ̀rọ̀. Ó ṣe bẹ́ẹ̀ kó lè tan Éfà jẹ ni. Áńgẹ́lì yẹn là ń pè ní Sátánì Èṣù. Lọ́jọ́ iwájú, Jèhófà máa pa Sátánì run. Tí Jèhófà bá ti pa á run, kò ní lè máa tan àwọn èèyàn jẹ mọ́.

“Apààyàn ni [Èṣù] láti ìbẹ̀rẹ̀, kò sì dúró ṣinṣin nínú òtítọ́, torí pé òtítọ́ ò sí nínú rẹ̀.”​—Jòhánù 8:44, àlàyé ìsàlẹ̀

Ìbéèrè: Kí ló fà á tí Éfà fi jẹ èso náà? Kí ló ṣẹlẹ̀ sí Ádámù àti Éfà lẹ́yìn tí wọ́n ṣàìgbọràn sí Jèhófà? Ta ni Sátánì Èṣù?

Jẹ́nẹ́sísì 3:1-24; Jòhánù 8:44; 1 Jòhánù 3:8; Ìfihàn 12:9

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́