ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w13 10/1 ojú ìwé 16
  • Ohun tí Bíbélì sọ

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ohun tí Bíbélì sọ
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2013
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ǹjẹ́ Ìrètí Wà fún Àwọn Tó Ti Kú?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • Kí Ni Bíbélì Sọ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
  • Ìrètí Wo Ló Wà fún Àwọn Tó Ti Kú?
    Ìròyìn Ayọ̀ Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run!
  • Kí Ni Àjíǹde?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2013
w13 10/1 ojú ìwé 16
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ

Ìrètí wo ló wà fún àwọn tó ti kú?

Ikú dà bí oorun tẹ́nì kan sùn, tí kò mọ nǹkan kan, tí kò sì lè ṣe ohunkóhun. Àmọ́, Ẹlẹ́dàá wa lágbára láti gbé àwọn òkú dìde nípasẹ̀ àjíǹde. Ẹ̀rí yìí túbọ̀ dájú nígbà tí Jésù wà láyé, Ọlọ́run fún un lágbára láti jí ọ̀pọ̀ òkú dìde.—Ka Oníwàásù 9:5; Jòhánù 11:11, 43, 44.

Báwo ni ikú ṣe dà bí oorun?

Ọlọ́run kò ní gbàgbé gbogbo àwọn tó jẹ́ tirẹ̀ tí wọ́n ti kú, ó máa jí wọn dìde sínú ayé tuntun òdodo. Òun nìkan ló ní agbára láti jí àwọn tó wà ní ipò òkú dìde, ó sì máa ṣe bẹ́ẹ̀ tó bá tó àkókò lójú rẹ̀. Ó wu Ọlọ́run Olódùmarè pé kí ó lo agbára rẹ̀ láti jí àwọn òkú dìde.—Ka Jóòbù 14:14, 15.

Báwo ni àjíǹde ṣe máa rí?

Gbogbo àwọn tí Ọlọ́run bá jí dìde ṣì máa dá àwọn ọ̀rẹ́ àti mọ̀lẹ́bí wọn mọ̀. Tí ara ẹnì kan bá tiẹ̀ ti jẹrà mọ́lẹ̀, Ọlọ́run ṣì lè jí ẹni náà pa dà pẹ̀lú ara tuntun.—Ka 1 Kọ́ríńtì 15:35, 38.

Ìwọ̀nba díẹ̀ ni àwọn tí Ọlọ́run máa jí dìde sí ọ̀run. (Ìṣípayá 20:6) Èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn tí Ọlọ́run máa jí dìde ni yóò wà nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé. Àwọn wọ̀nyí á bẹ̀rẹ̀ ayé wọn lákọ̀tun, wọn yóò sì máa wà láàyè títí láé.—Ka Sáàmù 37:29; Ìṣe 24:15.

Tó o bá fẹ́ ìsọfúnni síwájú sí i, ka orí 6 àti 7 nínú ìwé yìí Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é

O lè wà á jáde lórí www.jw.org

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́