ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w13 11/15 ojú ìwé 8-9
  • Bá A Ṣe Lè Ṣèrànwọ́ Fún Àwọn Èèyàn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Bá A Ṣe Lè Ṣèrànwọ́ Fún Àwọn Èèyàn
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2013
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àṣẹ́kùsílẹ̀ Wọn Dí Àìnító Kan
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
  • “Iṣẹ́ Náà Pọ̀”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2016
  • Mọrírì Ìwà Ọ̀làwọ́ Jèhófà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
  • Jèhófà Máa Ń Bù Kún Àwọn Tó Ní Ẹ̀mí Ìmúratán
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2013
w13 11/15 ojú ìwé 8-9
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]

Bá A Ṣe Lè Ṣèrànwọ́ fún Àwọn Èèyàn

ALÀGBÀ ìjọ ni François, orílẹ̀-èdè kan tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà ló sì ń gbé, ó sọ pé: “Ìjà rẹpẹtẹ bẹ́ sílẹ̀ lẹ́yìn ìdìbò kan tí èsì rẹ̀ kò tẹ́ àwọn èèyàn lọ́rùn, èyí sì mú kí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sá kúrò nílé wọn. A kò rí oúnjẹ àti oògùn, èyí tá a bá sì rí máa ń wọ́n gan-an. Àwọn ilé ìfowópamọ́ ò ṣiṣẹ́, owó tán nínú àwọn ẹ̀rọ sanwósanwó kan, àwọn míì sì bà jẹ́.”

Kíákíá ni àwọn arákùnrin láti ẹ̀ka ọ́fíìsì wa bẹ̀rẹ̀ sí í ṣètò owó àtàwọn nǹkan míì táwọn Ẹlẹ́rìí tó sá filé sílẹ̀ nílò, wọ́n sì ń fi ránṣẹ́ sí wọn láwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba tí wọ́n kóra jọ sí káàkiri orílẹ̀-èdè náà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ẹgbẹ́ tó ń bára wọn jà gbégi dí ojú ọ̀nà, wọ́n mọ̀ pé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í dá sí ọ̀ràn òṣèlú, wọ́n sì ń jẹ́ kí àwọn ọkọ̀ ẹ̀ka ọ́fíìsì kọjá.

Arákùnrin François sọ pé: “Àwọn ọmọ ogun tó fara pamọ́ síbì kan yìnbọn lu ọkọ̀ wa nígbà tá à ń lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba kan. Àmọ́ ńṣe ni àwọn ọta ìbọn náà gba àárín wa kọjá. Bá a ṣe rí sójà kan tó ń sáré bọ̀ lọ́dọ̀ wa pẹ̀lú ìbọn lọ́wọ́, a yára fi ọkọ̀ sí rìfáàsì, a ṣẹ́rí pa dà, a sì kọrí sí ẹ̀ka ọ́fíìsì. Ńṣe là ń dúpẹ́ pé Jèhófà dá ẹ̀mí wa sí. Ní ọjọ́ kejì, gbogbo àádóje [130] àwọn ará tó wà nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba náà sá lọ síbi tí ààbò wà. Díẹ̀ lára wọn wá sí ẹ̀ka ọ́fíìsì, a sì pèsè àwọn ohun tí wọ́n nílò nípa tara àti fún ìjọsìn Ọlọ́run títí tí rògbòdìyàn náà fi parí.”

Arákùnrin François ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Ní ẹ̀ka ọ́fíìsì wa, ọ̀pọ̀ lẹ́tà ìdúpẹ́ la gbà látọ̀dọ̀ àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa káàkiri orílẹ̀-èdè yìí lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ náà. Wọ́n ti rí bí àwọn ará wọn tó wà níbòmíràn ṣe ṣèrànwọ́ fún wọn, èyí sì mú kí ìgbọ́kànlé wọn nínú Jèhófà túbọ̀ pọ̀ sí i.”

Bóyá àjálù ṣàdédé ṣẹlẹ̀ ni o, tàbí àwọn èèyàn ló fà á, a kì í sọ fún àwọn ará wa tó nílò ìrànlọ́wọ́ pé “kí ara yín yá gágá, kí ẹ sì jẹun yó dáadáa.” (Ják. 2:15, 16) Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe la máa ń pèsè àwọn ohun tí wọ́n nílò nípa ti ara. Lọ́nà kan náà, nígbà tí ìkìlọ̀ kan wáyé ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní pé ìyàn máa mú, “àwọn tí wọ́n jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn pinnu, ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn gẹ́gẹ́ bí agbára olúkúlùkù ti lè gbé e, láti fi ìpèsè a-dín-ìṣòro-kù ránṣẹ́ sí àwọn ará tí ń gbé ní Jùdíà.”—Ìṣe 11:28-30.

Àwa tá a jẹ́ ìránṣẹ́ Jèhófà máa ń fẹ́ láti fi àwọn ohun ìní ti ara ṣèrànwọ́ fún àwọn tó ṣaláìní. Àmọ́ ṣá o, ó tún ṣe pàtàkì pé kí àwọn èèyàn sún mọ́ Ọlọ́run. (Mát. 5:3) Nítorí pé Jésù fẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé ó ṣe pàtàkì kí wọ́n sún mọ́ Ọlọ́run, kí wọ́n sì gbé ìgbésẹ̀ tó yẹ, ó pàṣẹ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n máa sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn. (Mát. 28:19, 20) Lẹ́nì kọ̀ọ̀kan, a máa ń lo ọ̀pọ̀ lára àkókò wa, okun wa àti àwọn ohun ìní wa láti ṣe iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn. Nínú ètò Ọlọ́run tá a wà, a máa ń fi díẹ̀ lára ọrẹ tó wá látọ̀dọ̀ àwọn èèyàn pèsè ohun ìní ti ara fún àwọn tó ṣaláìní, ṣùgbọ́n a máa ń lo èyí tó pọ̀ jù lára ọrẹ yìí fún àwọn ohun tó ní í ṣe pẹ̀lú iṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run àti ìhìn rere náà. À ń tipa báyìí fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àti àwọn aládùúgbò wa.—Mát. 22:37-39.

A fẹ́ kí àwọn tó ń ṣètìlẹyìn fún iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé mọ̀ dájú pé à ń lo àwọn ọrẹ náà lọ́nà tó yẹ àti lọ́nà tó dára jù lọ. Ǹjẹ́ o lè pèsè ìtura fún àwọn arákùnrin àti arábìnrin rẹ tó nílò ìrànlọ́wọ́? Ṣé ó wù ẹ́ pé kó o ṣètìlẹyìn fún iṣẹ́ sísọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni, “má fawọ́ ohun rere sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ ẹni tí ó yẹ kí o ṣe é fún, nígbà tí ó bá wà ní agbára ọwọ́ rẹ láti ṣe é.”—Òwe 3:27.

Ọ̀NÀ TÁWỌN KAN Ń GBÀ ṢÈTỌRẸ FÚN IṢẸ́ KÁRÍ AYÉ

Bó ṣe rí nígbà ayé àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń “ya ohun kan sọ́tọ̀,” tàbí kí wọ́n ya iye owó kan sọ́tọ̀, kí wọ́n sì fi owó náà sínú àpótí ìjọ tá a kọ “Ọrẹ fún Iṣẹ́ Kárí Ayé” sí. (1 Kọ́r. 16:2) Oṣooṣù làwọn ìjọ máa ń fi owó yìí ránṣẹ́ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lórílẹ̀-èdè wọn. O sì tún lè fi ọrẹ ránṣẹ́ ní tààràtà sí ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ń bójú tó orílẹ̀-èdè rẹ. Tó o bá fẹ́ mọ orúkọ àjọ tó ń bójú tó iṣẹ́ wa lábẹ́ òfin, jọ̀wọ́ kàn sí ẹ̀ka ọ́fíìsì tó ń bójú tó iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè rẹ. O lè rí àdírẹ́sì ẹ̀ka ọ́fíìsì náà lórí ìkànnì www.jw.org/yo. Lára àwọn ọrẹ tó o lè fi ránṣẹ́ sí wa ní tààràtà rèé:

  • Ẹ̀BÙN

    • O lè fi owó, ohun ọ̀ṣọ́ tó ṣeyebíye tàbí dúkìá mìíràn ṣètọrẹ.

    • Kọ lẹ́tà kó o sì fi ránṣẹ́ pẹ̀lú owó tàbí ọrẹ náà láti fi hàn pé ẹ̀bùn ló jẹ́.

  • ỌRẸ TÓ ṢEÉ GBÀ PA DÀ

    • O lè fi owó síkàáwọ́ àjọ kan tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń lò pé kí wọ́n máa lò ó. Àmọ́, àjọ náà máa dá owó náà pa dà tó o bá béèrè fún un.

    • Kọ lẹ́tà láti fi hàn pé ńṣe lo fi owó náà síkàáwọ́ àjọ náà títí dìgbà tí wàá fẹ́ láti gbà á pa dà.

  • ỌRẸ TÉÈYÀN WÉWÈÉ

    Yàtọ̀ sí pé ká dìídì fi owó tàbí dúkìá mìíràn ṣètọrẹ, àwọn ọ̀nà mìíràn tún wà tá a lè gbà ṣètọrẹ tó máa ṣàǹfààní fún iṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run kárí ayé. Ọ̀nà yòówù kó o fẹ́ láti gbà ṣètọrẹ, jọ̀wọ́ kọ́kọ́ kàn sí ẹ̀ka ọ́fíìsì tó ń bójú tó iṣẹ́ wa lórílẹ̀-èdè rẹ kí wọ́n lè jẹ́ kó o mọ ọ̀nà tó bófin mu tó o lè gbà ṣe é. Ohun tí òfin sọ nípa ọrẹ máa ń yàtọ̀ síra, ó ṣe pàtàkì pé kó o fi ọ̀rọ̀ lọ amòfin tó mọ̀ nípa ẹ̀ dáadáa kó o tó yan ọ̀nà tó o máa gbà ṣètọrẹ. Díẹ̀ lára àwọn ọ̀nà tó o lè gbà ṣètọrẹ rèé:

    Owó Ìbánigbófò: A lè kọ orúkọ àjọ kan tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń lò gẹ́gẹ́ bí ẹni tí yóò gba owó ìbánigbófò ẹ̀mí tàbí owó ìfẹ̀yìntì ẹni lẹ́nu iṣẹ́.

    Àkáǹtì Owó ní Báńkì: A lè fi àkáǹtì owó tá a ní sí báńkì, tàbí owó tá a fi pa mọ́ sí báńkì fún àkókò pàtó kan, tàbí àkáǹtì owó ìfẹ̀yìntì ẹni lẹ́nu iṣẹ́, síkàáwọ́ àjọ kan tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń lò pé kí àjọ náà máa lò ó tàbí ká ṣètò pé kí wọ́n san owó náà fún àjọ náà lẹ́yìn ikú ẹni náà gẹ́gẹ́ bí ìlànà báńkì ti sọ.

    Ìpín Ìdókòwò, Ẹ̀tọ́ Orí Owó Ìdókòwò àti Ti Ètò Ẹ̀yáwó: A lè fi ẹ̀tọ́ ìpín ìdókòwò, ẹ̀tọ́ orí owó ìdókòwò àti ti ẹ̀yáwó ta àjọ kan tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń lò lọ́rẹ. A sì lè ní kí ẹ̀tọ́ náà di ti àjọ náà lẹ́yìn ikú ẹni.

    Ilẹ̀ àti Ilé: A lè fi ilẹ̀ tó ṣeé tà tọrẹ fún àjọ kan tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń lò, yálà nípa fífi ṣe ẹ̀bùn, tàbí tó bá jẹ́ ilẹ̀ tí ilé wà lórí rẹ̀ téèyàn ṣì ń gbé inú rẹ̀, olùtọrẹ náà lè fi tọrẹ àmọ́ kó sọ pé òun á ṣì máa gbé inú rẹ̀ ní gbogbo ìgbà tóun bá ṣì wà láàyè.

    Ìwé Ìhágún àti Ohun Ìní Téèyàn Fi Síkàáwọ́ Onígbọ̀wọ́: A lè fi dúkìá tàbí owó sílẹ̀ bí ogún fún àjọ kan tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń lò nípasẹ̀ ìwé ìhágún tá a ṣe lábẹ́ òfin, tàbí ká ṣe ìwé pé àjọ náà ni ẹni tí yóò ni ohun ìní tá a fi síkàáwọ́ onígbọ̀wọ́.

Gbólóhùn náà, “ọrẹ téèyàn wéwèé” fi hàn pé ẹni tó fẹ́ ṣètọrẹ gbọ́dọ̀ ronú dáadáa kó tó ṣe irú ìtọrẹ bẹ́ẹ̀.

Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa ọ̀rọ̀ yìí, o lè kàn sí Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Nàìjíríà, yálà nípa kíkọ̀wé sí àdírẹ́sì tá a kọ sísàlẹ̀ yìí tàbí kó o fi nọ́ńbà tẹlifóònù tó wà nínú àdírẹ́sì náà pè wá, tàbí kó o kàn sí ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ń bójú tó orílẹ̀-èdè rẹ.

JEHOVAH’S WITNESSES

P.M.B. 1090,

Benin City 300001,

Edo State, Nigeria.

Nọ́ńbà tẹlifóònù wa ni: 07080662020

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́