ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w14 5/1 ojú ìwé 16
  • Ohun Tí Bíbélì Sọ

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kí Nìdí Tí Ọlọ́run Fi Fàyè Gba Ìwà Ibi àti Ìyà?
    Ìròyìn Ayọ̀ Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run!
  • Kí Nìdí Tí Ọlọ́run Fi Fàyè Gba Ìwà Ibi àti Ìjìyà?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • Ta Ló Ń Darí Ayé Yìí?
    Ta Ló Ń Darí Ayé Yìí?
  • Kí Nìdí Tí Ìyà Fi Pọ̀ Láyé?
    Kí Ni Bíbélì Kọ́ Wa?
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
w14 5/1 ojú ìwé 16

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ

Ta ló ń darí ayé yìí?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

Tó bá jẹ́ pé Ọlọ́run ló ń ṣàkóso ayé lóòótọ́, ṣé ayé á kún fún ìyà bó ṣe rí lónìí?

Ọ̀pọ̀ èèyàn rò pé Ọlọ́run ló ń darí ayé yìí. Àmọ́ tó bá jẹ́ òun ni lóòótọ́, ṣé ayé á kún fún ìyà bó ṣe rí lónìí? (Diutarónómì 32:4, 5) Bíbélì jẹ́ ka mọ̀ pé ẹni burúkú kan ló ń ṣàkóso ayé yìí tó sì ń darí rẹ̀.—Ka 1 Jòhánù 5:19.

Báwo ni ẹni burúkú kan ṣe lè máa ṣàkóso ayé? Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ ní ìbẹ̀rẹ̀ ìtàn àwa èèyàn. Áńgẹ́lì kan ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run, ó tún tan àwọn òbí wa àkọ́kọ́ ìyẹn Ádámù àti Éfà láti ṣàìgbọràn. (Jẹ́nẹ́sísì 3:1-6) Àwọn tọkọtaya yìí yàn láti tẹ̀lé áńgẹ́lì burúkú náà, ìyẹn Sátánì, wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ sọ ọ́ di alákòóso wọn. Ọlọ́run Olódùmarè nìkan ló yẹ kó jẹ́ alákòóso wa, síbẹ̀ kò fi tipátipá mú wa láti jọ́sìn òun, kàkà bẹ́ẹ̀, ó fẹ́ ká yàn láti jọ́sìn òun torí ìfẹ́ tá a ní sí i. (Diutarónómì 6:6; 30:16, 19) Àmọ́, ó ṣeni láàánú pé ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn ni Sátánì ti tàn jẹ, tí àwọn náà sì ti ṣìnà bíi tàwọn tọkọtaya àkọ́kọ́.—Ka Ìṣípayá 12:9.

Ta ló máa yanjú ìṣòro aráyé?

Ǹjẹ́ Ọlọ́run á gba Sátánì láàyè láti máa bá ìṣàkóso rẹ̀ lọ títí? Rárá o! Ọlọ́run máa lo Jésù láti tún gbogbo nǹkan tí Sátánì ti bàjẹ́ ṣe.—Ka 1 Jòhánù 3:8.

Jésù máa lo agbára tí Ọlọ́run fún un láti pa Sátánì run. (Róòmù 16:20) Lẹ́yìn náà, Ọlọ́run máa ṣàkóso aráyé, á mú ká láyọ̀ ká sì máa gbé ní àlàáfíà gẹ́gẹ́ bó ṣe fẹ́ láti ìbẹ̀rẹ̀.—Ka Ìṣípayá 21:3-5.

Tó o bá fẹ́ ìsọfúnni síwájú sí i, wo orí 3 nínú ìwé yìí Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é

O lè wà á jáde lórí www.jw.org/yo

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́