ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w14 8/1 ojú ìwé 16
  • Ohun Tí Bíbélì Sọ

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Báwo Lo Ṣe Lè Mọ Ìsìn Tòótọ́?
    Ìròyìn Ayọ̀ Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run!
  • Ìròyìn Ayọ̀ Wo Ló Wà Nípa Ìsìn?
    Ìròyìn Ayọ̀ Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run!
  • Kí Lo Lè Fi Dá Ẹ̀sìn Tòótọ́ Mọ̀?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • Ìjọsìn Tó Ní Ìtẹ́wọ́gbà Ọlọ́run
    Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
w14 8/1 ojú ìwé 16

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ

Ǹjẹ́ gbogbo ìsìn ló ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run?

Tó o bá ń gbọ́ ìròyìn déédéé, ó ṣeé ṣe kó o ti kíyè sí i pé láwọn ìgbà míì, ńṣe làwọn èèyàn ń fi ẹ̀sìn bojú láti ṣiṣẹ́ ibi. Èyí fi hàn pé kì í ṣe gbogbo ìsìn ló ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. (Mátíù 7:15) Ká sóòótọ́, ìsìn ti ṣi ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́nà.—Ka 1 Jòhánù 5:19.

Síbẹ̀, Ọlọ́run ń kíyè sí àwọn tó ń fi ọkàn rere wá òtítọ́ tó sì ń sapá láti ṣe ohun tó dáa. (Jòhánù 4:23) Ọlọ́run sì ń fún irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ láǹfààní láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀.—Ka 1 Tímótì 2:3-5.

Báwo lo ṣe lè dá ìsìn tòótọ́ mọ̀?

Lónìí, Jèhófà Ọlọ́run ń kó àwọn èèyàn láti onírúurú ìsìn jọ, ó sì ń ṣe èyí nípa kíkọ́ wọn ní òtítọ́ àti kíkọ́ wọn láti nífẹ̀ẹ́ ara wọn. (Míkà 4:2, 3) Torí náà, àwọn tó ń ṣe ìsìn tòótọ́ máa ń nífẹ̀ẹ́ ara wọn, èyí sì jẹ́ ọ̀nà pàtàkì kan tó o fi lè dá wọn mọ̀.—Ka Jòhánù 13:35.

Jèhófà Ọlọ́run ń kó onírúurú àwọn èèyàn jọ nípasẹ̀ ìjọsìn tòótọ́.​—Sáàmù 133:1

Gbogbo ohun tí àwọn tó ń ṣe ìsìn tòótọ́ gbà gbọ́ ló wà nínú Bíbélì, wọ́n sì ń fi ohun tí wọ́n ń kọ́ ṣèwà hù nígbèésí ayé wọn. (2 Tímótì 3:16) Wọ́n tún máa ń gbé orúkọ Ọlọ́run ga. (Sáàmù 83:18) Wọ́n sì tún máa ń sọ fún àwọn èèyàn pé Ìjọba Ọlọ́run nìkan ló lè yanjú ìṣòro aráyé. (Dáníẹ́lì 2:44) Wọ́n ń farawé Jésù bí wọ́n ṣe ń hùwà tó dáa sí àwọn aládùúgbò wọn, wọ́n sì ń tipa bẹ́ẹ̀ jẹ́ kí ‘ìmọ́lẹ̀ wọn máa tàn.’ (Mátíù 5:16) Nítorí náà, gbogbo ìgbà ni àwọn Kristẹni tòótọ́ máa ń lọ sọ ìhìnrere Ìjọba Ọlọ́run fún àwọn èèyàn ní ilé wọn.—Ka Mátíù 24:14; Ìṣe 5:42; 20:20.

Tó o bá fẹ́ ìsọfúnni síwájú sí i, ka orí 15 nínú ìwé yìí Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?, Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é

Ó tún wà lórí ìkànnì www.jw.org/yo

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́