Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí
August 15, 2014
© 2014 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
Ẹ̀DÀ TÓ WÀ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́
SEPTEMBER 29, 2014–OCTOBER 5, 2014
Ipa Wo Ni Àwọn Obìnrin Ń Kó Nínú Mímú Ìfẹ́ Jèhófà Ṣẹ?
OCTOBER 6-12, 2014
Máa Lo Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run—Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ Yè!
OJÚ ÌWÉ 11 • ORIN: 114, 101
OCTOBER 13-19, 2014
Àwọn Ọ̀nà Tí Jèhófà Gbà Ń Sún Mọ́ Wa
OCTOBER 20-26, 2014
ÀWỌN ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́
▪ Ipa Wo Ni Àwọn Obìnrin Ń Kó Nínú Mímú Ìfẹ́ Jèhófà Ṣẹ?
Àpilẹ̀kọ yìí jẹ́ ká mọ ọṣẹ́ tí ọ̀tẹ̀ tó wáyé ní ọgbà Édẹ́nì ṣe fún tọkùnrin tobìnrin. Wàá kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn obìnrin ìgbàanì tí wọ́n bẹ̀rù Ọlọ́run. Bákan náà, wàá rí ipa tí àwọn Kristẹni obìnrin ń kó nínú mímú ìfẹ́ Ọlọ́run ṣẹ lónìí.
▪ Máa Lo Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run—Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ Yè!
Gbogbo akéde Ìjọba Ọlọ́run ló fẹ́ já fáfá lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Wàá rí àwọn àbá mélòó kan tó ṣeé mú lò nípa bá a ṣe lè lo Bíbélì àtàwọn ìwé àṣàrò kúkúrú láti fi bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò pẹ̀lú àwọn èèyàn àti bá a ṣe lè mú kí Ọ̀rọ̀ Jèhófà tó wà láàyè wọ̀ wọ́n lọ́kàn.
▪ Àwọn Ọ̀nà Tí Jèhófà Gbà Ń Sún Mọ́ Wa
Ó yẹ ká ní àjọṣe tó ṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Ẹlẹ́dàá wa. Kẹ́kọ̀ọ́ nípa bí ìràpadà àti Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó wà lákọọ́lẹ̀ ṣe jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run ló gbé ìgbésẹ̀ láti fà wá sún mọ́ ara rẹ̀.
▪ Máa Gbọ́ Ohùn Jèhófà Níbikíbi Tó O Bá Wà
Tá a bá fẹ́ máa rìn nínú òtítọ́, a gbọ́dọ̀ tẹ́tí sí ohun tí Jèhófà bá sọ. Kẹ́kọ̀ọ́ nípa bí a ò ṣe ní jẹ́ kí Sátánì àti àìpé dí wa lọ́wọ́ láti máa tẹ́tí sí ohùn Jèhófà. Àpilẹ̀kọ yìí máa jẹ́ ká mọyì bó ti ṣe pàtàkì tó pé ká máa bá Ọlọ́run tòótọ́ sọ̀rọ̀ déédéé.
ÀWỌN ÀPILẸ̀KỌ MÍÌ NÍNÚ ÌTẸ̀JÁDE YÌÍ
3 Ṣé Ò Ń Rí Oúnjẹ Gbà “Ní Àkókò Tí Ó Bẹ́tọ̀ọ́ Mu”?
26 ‘Pa Dà Kí O sì Fún Àwọn Arákùnrin Rẹ Lókun’
ÀWÒRÁN IWÁJÚ ÌWÉ: Àwọn arábìnrin méjì yìí ń wàásù lédè Rọ́ṣíà níbi táwọn èèyàn ti máa ń gbafẹ́ ní ìlú Tel Aviv. Àwọn òkè olókùúta là ń wò lẹ́yìn wọn yẹn níbi tá a wá mọ̀ sí ìlú Jaffa báyìí, ibùdókọ̀ òkun ni tẹ́lẹ̀ ní ìlú Jópà
ÍSÍRẸ́LÌ
IYE ÈÈYÀN
8,050,000
IYE AKÉDE NÍ ỌDÚN 2013
1,459
ÀWỌN TÓ WÁ SÍBI ÌRÁNTÍ IKÚ KRISTI NÍ ỌDÚN 2013
2,671