KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | ÌJỌBA ỌLỌ́RUN—ÀǸFÀÀNÍ WO LÓ MÁA ṢE Ẹ́?
Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó O Mọ̀ Nípa Ìjọba Ọlọ́run?
Ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn kárí ayé ló ń retí Ìjọba Ọlọ́run. Wọ́n ń tẹ̀ lé ipasẹ̀ Jésù tó kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ kí wọ́n máa gbàdúrà pé: “Kí ìjọba rẹ dé; ìfẹ́ tìrẹ ni kí a ṣe ní ayé.”—Mátíù 6:10, Bíbélì Mímọ́.
Àmọ́, ó ya ni lẹ́nu pé, bí ọ̀pọ̀ èèyàn ṣe ń yánhànhàn láti mọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run tó, ọ̀pọ̀ ìsìn ò tiẹ̀ já a kúnra rárá. Ọ̀rọ̀ yìí ká òpìtàn kan tó ń jẹ́ H. G. Well lára tó bẹ́ẹ̀ tó fi sọ pé: “Jésù ka ìwàásù nípa Ìjọba Ọ̀run sí pàtàkì gan-an, àmọ́ ọ̀pọ̀ ṣọ́ọ̀ṣì ò ka ọ̀rọ̀ Ìjọba Ọ̀run sí rárá.”
Ṣùgbọ́n àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ò dà bí àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì yẹn, tọkàntọkàn la fi ń pòkìkí Ìjọba Ọlọ́run láìdabọ̀! Bí àpẹẹrẹ, à ń tẹ lájorí ìwé ìròyìn wa tó ò ń kà lọ́wọ́ yìí sí okòólérúgba [220] èdè. Iye ẹ̀dà tá à ń tẹ̀ jáde lẹ́ẹ̀kan sì ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó mílíọ̀nù mẹ́rìndínláàádọ́ta [46]. Abájọ tó fi jẹ́ pé òun ni ìwé ìròyìn tí ìpínkiri rẹ̀ gbòòrò jù lọ láyé. Kí wá ni ìwé ìròyìn yìí dá lé? Ohun tó dá lé wà lára àkọlé rẹ̀ tó sọ pé: Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jèhófà.a
Kí nìdí tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi ń kéde Ìjọba Ọlọ́run káàkiri? A gbà pé, Ìjọba Ọlọ́run ni lájorí ọ̀rọ̀ inú Bíbélì, ìyẹn ìwé tó ṣe pàtàkì jù láyé yìí. Ó sì dá wa lójú pé, Ìjọba Ọlọ́run ni ojútùú kan ṣoṣo sí gbogbo ìṣòro tí ẹ̀dá èèyàn ń dojú kọ lónìí.
Àpẹẹrẹ Jésù làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń tẹ̀ lé bá a ṣe ń darí àfiyèsí àwọn èèyàn sí Ìjọba Ọlọ́run. Nígbà tí Jésù wà láyé, Ìjọba Ọlọ́run ló gbájú mọ́, òun sì ni lájorí ohun tó ń wàásù fáwọn èèyàn. (Lúùkù 4:43) Kí nìdí tí ọ̀rọ̀ Ìjọba Ọlọ́run fi ṣe pàtàkì gan-an sí Jésù? Àǹfààní wo ni Ìjọba yẹn máa ṣe fún ìwọ náà? A rọ̀ ẹ́ pé kó o ka ìdáhùn Bíbélì sí àwọn ìbéèrè yìí nínú àwọn àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e.
a Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run.