ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w92 3/15 ojú ìwé 3-4
  • Ohun Ti Ijọba Ọlọrun Tumọsi Fun Ọpọlọpọ

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ohun Ti Ijọba Ọlọrun Tumọsi Fun Ọpọlọpọ
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Oju Ti A Ti Fi Wo Ijọba Naa
  • Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó O Mọ̀ Nípa Ìjọba Ọlọ́run?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
  • Awọn Wolii Èké Lonii
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Ìjọba Ọlọ́run
    Jí!—2013
  • Ìjọba Ọlọrun—O Ha Ń lóye Rẹ̀ Bí?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
w92 3/15 ojú ìwé 3-4

Ohun Ti Ijọba Ọlọrun Tumọsi Fun Ọpọlọpọ

JESU KRISTI sábà maa ń sọrọ nipa Ijọba Ọlọrun. Nipa eyi opitan H. G. Wells kọwe pe: “Ijẹpataki ńláǹlà ti Jesu fifun ẹkọ ohun tí ó pè ni Ijọba Ọrun, ati ifiwera àìjámọ́ nǹkan rẹ̀ ninu ọna igbaṣe ati ẹkọ ọpọ julọ awọn ṣọọṣi Kristẹni jẹ́ eyi ti o jọniloju. Ó daju pe ẹkọ nipa Ijọba Ọrun yii, eyi ti o jẹ́ ẹkọ pataki ti Jesu, ti o sì kó ipa kekere tobẹẹ ninu awọn ijẹwọ igbagbọ Kristẹni, ni ọ̀kan lara awọn ẹkọ yiyatọ patapata julọ ti o tíì ru ironu eniyan soke tí ó sì tíì yí i pada rí.”

Eeṣe ti awọn ṣọọṣi kò fi ni ohun ti o pọ̀ tó lati sọ nipa Ijọba Ọlọrun? Idi kan lè jẹ́ pe aidaniloju wà nipa Ijọba naa. Oju-iwoye wo ni awọn eniyan ti ní nipa rẹ̀?

Oju Ti A Ti Fi Wo Ijọba Naa

Awọn kan ti mọ Ijọba Ọlọrun mọ́ Ṣọọṣi Katoliki. Lẹhin ti awọn biṣọọbu ti gba Olu-ọba Constantine gẹgẹ bi olori wọn ní Igbimọ Nicaea ni ọdun 325 C.E., ṣọọṣi naa kowọnu oṣelu, a sì sọ fun awọn eniyan pe Ijọba naa ti dé ná. Iwe gbédègbẹ́yọ̀ Encyclopædia Britannica ṣalaye pe ni ibamu pẹlu imọ-ẹkọ isin Augustine (354–430 C.E.), “Ijọba Ọlọrun ti bẹrẹ ná ninu ayé yii pẹlu idasilẹ ṣọọṣi naa” ó sì ti “wà ninu awọn sakaramẹnti ṣọọṣi naa ṣaaju.”

Awọn miiran ń wo Ijọba Ọlọrun gẹgẹ bi aṣeyọri eniyan kan. Iwe gbédègbẹ́yọ̀ kan naa sọ pe: “Laipẹ laijinna awọn ṣọọṣi Alatun-un-ṣe . . . di ṣọọṣi elétò idasilẹ ẹlẹ́kùn ipinlẹ, eyi ti o tẹ ifojusọna fun akoko opin rì” niti dide Ijọba Ọlọrun. H. G. Wells kọwe pe: “Awọn eniyan gbé apa pataki igbesi-aye wọn kuro lori ijọba Ọlọrun ati àjọṣepọ̀ araye lọ sori awọn wọnni ti wọn farahan pe awọn jẹ́ otitọ gidi ti ń gbeṣẹ ṣe, France ati England, Russia Mímọ́, Spain, Prussia . . . Awọn ni wọn jẹ́ ojulowo ọlọrun Europe ti wọn sì ń gbeṣẹ ṣe.”

Ni akoko ode oni pẹlu, Ijọba naa ni wọn ti sọ di ti ayé. Iwe gbédègbẹ́yọ̀ Encyclopædia Britannica ṣalaye pe: “Iṣarasihuwa ipilẹ naa jẹ́ ami animọ pe eniyan funraarẹ nilati ṣeto awujọ pípé ọjọ-ọla ní ọna imujade ati iṣeto ati pe ‘rireti’ ati ‘diduro’ ni a fi idanuṣe eniyan rọpo.” Niti “ihinrere ẹgbẹ-oun-ọgba,” iwe kan naa ń baa lọ pe: “Ajọ igbokegbodo yii wo ihin-iṣẹ Kristẹni nipa Ijọba Ọlọrun ni pataki gẹgẹ bi èrò inu òjijì fun ìṣàtúntò awọn ipo awujọ alaijẹ tẹmi ni ero itumọ ti ilana eto ti Ijọba Ọlọrun.”

Ọpọlọpọ awọn Juu tun ti wo Ijọba naa gẹgẹ bi aṣeyọri eniyan kan. Ni 1937 àpérò awọn rábì Alatun-un-ṣe ni Columbus, Ohio, U.S.A., sọ pe: “A kà á sí iṣẹ onijẹẹpataki pupọ tiwa lati fọwọsowọpọ pẹlu gbogbo awọn eniyan ninu fifi idi ijọba Ọlọrun, àjọṣepọ̀ agbaye, idajọ ododo, otitọ ati alaafia lori ilẹ̀-ayé mulẹ. Eyi ni gongo mesaya wa.”

Oju-iwoye ti a tẹwọgba kaakiri miiran ni pe Ijọba Ọlọrun jẹ́ ipo inu ọkan-aya ẹnikan. Ni United States, fun apẹẹrẹ, eto isin kan ti a pe ni Southern Baptist Convention ti 1925 polongo pe: “Ijọba Ọlọrun ni iṣakoso Ọlọrun ninu ọkan-aya ati igbesi-aye ẹnikọọkan ninu gbogbo ipo ibatan eniyan, ati ni oniruuru ati eto idasilẹ awujọ eniyan ti a ṣetojọ. . . . Ijọba Ọlọrun yoo pé pérépéré nigba ti a o mu gbogbo ironu ati ifẹ inu eniyan wá sinu igbekun si ifẹ inu Kristi.”

Wayi o, nitori naa, ṣọọṣi ha ni Ijọba Ọlọrun bi? Ijọba yẹn ni a o ha mú wá nipasẹ ọna ti ayé bi? Ó ha jẹ́ ipo inu ọkan-aya bi? Ki sì ni Ijọba Ọlọrun lè tumọsi fun ọ?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́