Ìjọba Ọlọrun—O Ha Ń lóye Rẹ̀ Bí?
“Níti èyí tí a fún sórí erùpẹ̀ àtàtà, èyí ni ẹni naa tí ń gbọ́ ọ̀rọ̀ naa tí òye rẹ̀ sì ń yé e.”—MATTEU 13:23.
1. Kí ni díẹ̀ lára àwọn ìgbàgbọ́ tí ó wọ́pọ̀ nípa ‘ìjọba àwọn ọ̀run’?
OHA ‘lóye’ ohun tí Ìjọba Ọlọrun jẹ́ bí? Ìpìlẹ̀ èrò nípa ‘ìjọba àwọn ọ̀run’ ti yàtọ̀ síra lọ́nà gbígbòòrò jálẹ̀ àwọn ọ̀rúndún. Ìgbàgbọ́ tí ó wọ́pọ̀ láàárín àwọn mẹ́ḿbà ṣọ́ọ̀ṣì lónìí ni pé, Ìjọba náà jẹ́ ohun kan tí Ọlọrun ń fi sínú ọkàn-àyà ẹni nígbà ìyínilọ́kànpadà. Àwọn mìíràn rò pé, ó jẹ́ ibi tí àwọn ẹni rere ń lọ lẹ́yìn ikú láti gbádùn ẹ̀kún rẹ́rẹ́ ayọ̀ títí láé. Síbẹ̀, àwọn mìíràn sọ pé Ọlọrun ti yọ̀ọ̀da rẹ̀ fún àwọn ẹ̀dá ènìyàn, láti mú Ìjọba náà wá sórí ilẹ̀ ayé nípa ṣíṣiṣẹ́ láti mú àwọn ẹ̀kọ́ àti àṣà Kristian wọnú àlámọ̀rí ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà àti ti ìṣàkóso.
2. Báwo ni Bibeli ṣe ṣàlàyé Ìjọba Ọlọrun, kí sì ni yóò ṣàṣeparí rẹ̀?
2 Ṣùgbọ́n, Bibeli fi hàn kedere pé, Ìjọba Ọlọrun kì í ṣe ìgbékalẹ̀ kan lórí ilẹ̀ ayé. Kì í ṣe ipò ọkàn-àyà, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe sísọ àwùjọ ẹ̀dá ènìyàn di Kristian. Lóòótọ́, òye títọ̀nà nípa ohun tí Ìjọba yìí jẹ́, ń yọrí sí ìyípadà ńláǹlà nínú ìgbésí ayé àwọn tí ń lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀. Ṣùgbọ́n, Ìjọba náà fúnra rẹ̀ jẹ́ ìṣàkóso ti ọ̀run tí Ọlọrun gbé kalẹ̀ láti mú ìfẹ́ inú rẹ̀ ṣẹ, láti mú ipa ìdarí ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú kúrò, kí ó sì mú ipò òdodo padà bọ̀ sípò lórí ilẹ̀ ayé. Ní báyìí, Ìjọba náà ti gba agbára ní àwọn ọ̀run, láìpẹ́ “yóò sì fọ́ ọ túútúú, yóò sì pa gbogbo ìjọba [ẹ̀dá ènìyàn] wọ̀nyí run, ṣùgbọ́n òun óò dúró títí láéláé.”—Danieli 2:44; Ìṣípayá 11:15; 12:10.
3. Nígbà tí Jesu bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, kí ni a ṣí sílẹ̀ fún ẹ̀dá ènìyàn?
3 Òpìtàn H. G. Wells kọ̀wé pé: “Ó dájú pé ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ yìí nípa Ìjọba Ọ̀run, tí ó jẹ́ lájorí ẹ̀kọ́ Jesu, tí ó sì kó ipa kékeré nínú àwọn ìjẹ́wọ́ ìgbàgbọ́ Kristian, jẹ́ ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ oníyìípadà pàtàkì tí ó tí ì ru ìrònú ẹ̀dá ènìyàn sókè, tí ó sì tí ì yí i padà jù lọ rí.” Láti ìbẹ̀rẹ̀, ẹṣin ọ̀rọ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jesu ni: “Ẹ ronúpìwàdà, ẹ̀yin ènìyàn, nitori ìjọba awọn ọ̀run ti súnmọ́lé.” (Matteu 4:17) Ó wà níbẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé gẹ́gẹ́ bí Ọba tí a fòróró yàn, èyí tí ó dùn mọ́ni jù lọ ni pé, ọ̀nà náà ti ṣí sílẹ̀ nísinsìnyí fún àwọn ẹ̀dá ènìyàn, kì í ṣe kìkì láti nípìn-ín nínú àwọn ìbùkún Ìjọba náà nìkan, ṣùgbọ́n láti tún jẹ́ ajùmọ̀ṣàkóso àti àlùfáà pẹ̀lú Jesu nínú Ìjọba náà!—Luku 22:28-30; Ìṣípayá 1:6; 5:10.
4. Ní ọ̀rúndún kìíní, báwo ni àwọn ògìdìgbó ṣe dáhùn padà sí “ìhìnrere ìjọba naa,” ìdájọ́ wo ni ó yọrí sí?
4 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ògìdìgbó ni ó gbọ́ “ìhìnrere ìjọba naa,” ìwọ̀nba díẹ̀ ni ó gbà á gbọ́. Ní apá kan, ó jẹ́ nítorí pé àwọn aṣáájú ìsìn ti “sé ìjọba awọn ọ̀run pa níwájú awọn ènìyàn.” Wọ́n fi àwọn ẹ̀kọ́ èké wọn “mú kọ́kọ́rọ́ ìmọ̀ lọ.” Nítorí pé àwọn ènìyàn tí ó pọ̀ jù lọ ṣá Jesu tì gẹ́gẹ́ bí Messia àti Ọba Ìjọba Ọlọrun tí a ti fòróró yàn, Jesu wí fún wọn pé: “A óò gba ìjọba Ọlọrun kúrò lọ́wọ́ yín a óò sì fi fún orílẹ̀-èdè kan tí yoo máa mú èso rẹ̀ jáde.”—Matteu 4:23; 21:43; 23:13; Luku 11:52.
5. Báwo ni ọ̀pọ̀ jù lọ nínú àwọn tí wọ́n gbọ́ àkàwé Jesu ṣe fi hàn pé àwọn kò fi òye gbọ́ ọ?
5 Nígbà tí ó ń kọ́ ogunlọ́gọ̀ ní àkókò kan, Jesu, gẹ́gẹ́ bí àṣà rẹ̀, lo ọ̀wọ́ àwọn àkàwé láti dán ogunlọ́gọ̀ náà wò, kí ó sì ya àwọn tí kò ní ju ọkàn ìfẹ́ oréfèé nínú Ìjọba náà sọ́tọ̀. Àkàwé àkọ́kọ́ ní afúnrúgbìn tí ń fún irúgbìn sorí oríṣi erùpẹ̀ mẹ́rin nínú. Oríṣi mẹ́ta àkọ́kọ́ kò dára fún ṣíṣọ̀gbìn, ṣùgbọ́n èyí tí ó kẹ́yìn jẹ́ “erùpẹ̀ àtàtà” tí ń mú èso rere jáde. Àkàwé kúkúrú náà parí pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ìyànjú náà pé: “Kí ẹni tí ó bá ní etí fetísílẹ̀.” (Matteu 13:1-9) Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn tí wọ́n pésẹ̀ gbọ́ ohun tí ó sọ, ṣùgbọ́n wọn kò “fetísílẹ̀.” Wọ́n kò ní ẹ̀mí ìsúnniṣe, wọn kò ní ojúlówó ọkàn ìfẹ́ nínú mímọ bí irúgbìn tí a fún lábẹ́ ipò yíyàtọ̀ síra ṣe dà bí Ìjọba àwọn ọ̀run. Wọ́n padà sílé, sẹ́nu ìgbésí ayé wọn ojoojúmọ́, bóyá ní ríronú pé, àwọn àkàwé Jesu wulẹ̀ jẹ́ ìtàn aládùn tí ó dá lórí ọ̀nà ìwà híhù. Ẹ wo irú òye kíkún rẹ́rẹ́ àti àǹfààní òun àyè kíkọ yọyọ, tí wọ́n sọ nù nítorí pé ọkàn-àyà wọn yigbì!
6. Èé ṣe tí ó fi jẹ́ kìkì àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jesu ni a fi òye “àṣírí mímọ́-ọlọ́wọ̀ ti ìjọba” fún?
6 Jesu sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Ẹ̀yin ni a yọ̀ǹda fún lati lóye awọn àṣírí mímọ́-ọlọ́wọ̀ ti ìjọba awọn ọ̀run, ṣugbọn awọn ènìyàn wọnnì ni a kò yọ̀ǹda fún.” Ní ṣíṣàyọlò ọ̀rọ̀ Isaiah, ó fi kún un pé: “‘Nitori ọkàn-àyà awọn ènìyàn yii ti sébọ́, wọ́n sì ti fi etí wọn gbọ́ láìsí ìdáhùnpadà, wọ́n sì ti di ojú wọn; kí wọ́n má baà fi ojú wọn rí láé kí wọ́n sì fi etí wọn gbọ́ kí òye rẹ̀ sì yé wọn ninu ọkàn-àyà wọn kí wọ́n sì yípadà, kí n sì mú wọn láradá.’ Bí ó ti wù kí ó rí, aláyọ̀ ni ojú yín nitori pé wọ́n rí, ati etí yín nitori pé wọ́n gbọ́.”—Matteu 13:10-16; Marku 4:11-13.
‘Lílóye’ Ìjọba Náà
7. Èé ṣe tí ó fi ṣe pàtàkì láti ‘lóye’ Ìjọba náà?
7 Jesu tọ́ka sí ìṣòro náà. Ó ní í ṣe pẹ̀lú ‘lílóye’ ìhìn iṣẹ́ Ìjọba náà. Ó sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ní ìkọ̀kọ̀ pé: “Nígbà naa, ẹ fetísílẹ̀ sí àpèjúwe ọkùnrin naa tí ó fúnrúgbìn. Níbi tí ẹni kan bá ti gbọ́ ọ̀rọ̀ ìjọba naa ṣugbọn tí òye rẹ̀ kò yé e, ẹni burúkú naa a wá a sì já ohun tí a ti gbìn sínú ọkàn-àyà rẹ̀ gbà lọ.” Ó ṣàlàyé síwájú sí i pé, àwọn oríṣi erùpẹ̀ mẹ́rin dúró fún onírúurú ipò ọkàn-àyà nínú èyí tí a óò gbin “ọ̀rọ̀ ìjọba naa” sí.—Matteu 13:18-23; Luku 8:9-15.
8. Kí ni ó dí “irúgbìn” tí a fún sí àwọn oríṣi erùpẹ̀ mẹta àkọ́kọ́ lọ́wọ́ láti mú èso jáde?
8 Nínú ọ̀ràn kọ̀ọ̀kan “irúgbìn” náà dára, ṣùgbọ́n èso náà yóò sinmi lé ipò tí erùpẹ̀ náà wà. Bí erùpẹ̀ ọkàn-àyà náà bá dà bí ojú ọ̀nà tí à ń rìn lọ rìn bọ̀, tí ẹsẹ̀ ti dùn, tí ọ̀pọ̀ ìgbòkègbodò tí kì í ṣe tẹ̀mí ti mú kí ó le koránkorán, yóò rọrùn fún ẹni náà tí ń gbọ́ ìhìn iṣẹ́ Ìjọba náà láti wá àwáwí, ní sísọ pé, kò sí àyè fún Ìjọba náà. A lè tètè já irúgbìn náà gbà kí ó tó fìdí múlẹ̀. Ṣùgbọ́n, bí a bá fún irúgbìn náà sínú ọkàn-àyà tí ó dà bí erùpẹ̀ àpáta ńkọ́? Irúgbìn náà lè hù, ṣùgbọ́n yóò ní ìṣòro mímú kí gbòǹgbò rẹ̀ lọ sísàlẹ̀ dé ìwọ̀n tí ó ti lè rí oúnjẹ, kí ó sì jí pépé. Ìfojúsọ́nà ti dídi onígbọràn ìránṣẹ́ Ọlọrun, ní pàtàkì nínú inúnibíni gbígbóná janjan, yóò gbé ìpènijà ńláǹlà kalẹ̀, ẹni náà yóò sì kọsẹ̀. Lẹ́ẹ̀kan sí i, bí erùpẹ̀ náà bá jẹ́ ọkàn-àyà tí ó kún fún àwọn àníyàn tí ó dà bí ẹ̀gún tàbí fún ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́nì, a óò fún ohun ọ̀gbìn hẹ́gẹhẹ̀gẹ ti Ìjọba náà pa. Nínú àwọn ipò ìṣàpẹẹrẹ ìgbésí ayé mẹ́tẹ̀ẹ̀ta wọ̀nyí, kò sí èso Ìjọba kankan tí a óò mú jáde.
9. Èé ṣe tí irúgbìn tí a fún sí erùpẹ̀ rere fi lè mú èso rere jáde?
9 Ṣùgbọ́n, kí ni nípa tí irúgbìn Ìjọba náà tí a fún sorí erùpẹ̀ rere? Jesu dáhùn pé: “Níti èyí tí a fún sórí erùpẹ̀ àtàtà, èyí ni ẹni naa tí ń gbọ́ ọ̀rọ̀ naa tí òye rẹ̀ sì ń yé e, ẹni tí ń so èso níti gidi tí ó sì ń mú èso jáde, eléyìí ìlọ́po ọgọ́rùn-ún, èyíinì ọgọ́ta, òmíràn ọgbọ̀n.” (Matteu 13:23) Ní ‘lílóye’ Ìjọba náà, wọn yóò mú èso rere jáde bí ipò oníkálukú wọn bá ṣe yọ̀ọ̀da.
Ẹrù Iṣẹ́ Ń Bá Òye Rìn
10. (a) Báwo ni Jesu ṣe fi hàn pé, ‘lílóye’ Ìjọba náà ń mú àpapọ̀ ìbùkún àti ẹrù iṣẹ́ wa? (b) Iṣẹ́ àṣẹ Jesu láti lọ, kí a sì sọni di ọmọ ẹ̀yìn ha jẹ́ fún kìkì àwọn ọmọ ẹ̀yìn ní ọ̀rúndún kìíní bí?
10 Lẹ́yìn fífúnni ní àkàwé mẹ́fà sí i láti ṣàlàyé onírúurú apá Ìjọba náà, Jesu bi àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Òye gbogbo nǹkan wọnyi ha yé yín bí?” Nígbà tí wọ́n dáhùn pé “bẹ́ẹ̀ ni,” ó wí pé: “Bí ó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni ọ̀ràn rí, olúkúlùkù olùkọ́ni ní gbangba, nígbà tí a bá ti kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ nipa ìjọba awọn ọ̀run, dàbí ọkùnrin kan, baálé ilé kan, tí ń mú awọn ohun titun ati ògbólógbòó jáde lati inú ibi ìtọ́jú ìṣúra pamọ́ rẹ̀.” Àwọn ẹ̀kọ́ àti ìdálẹ́kọ̀ọ́ tí Jesu pèsè yóò sọ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ di Kristian tí ó dàgbà dénú, tí ó lè mú àwọn ìpèsè rẹpẹtẹ ti oúnjẹ tẹ̀mí dídọ́ṣọ̀ jáde láti inú ‘ibi ìtọ́jú nǹkan pamọ́ sí’ wọn. Púpọ̀ nínú èyí ní í ṣe pẹ̀lú Ìjọba Ọlọrun. Jesu mú un ṣe kedere pé, kì í ṣe kìkì àwọn ìbùkún nìkan ni ‘lílóye’ Ìjọba náà yóò mú wá, ṣùgbọ́n yóò mú ẹrù iṣẹ́ wá pẹ̀lú. Ó pàṣẹ pé: “Nitori naa ẹ lọ kí ẹ sì máa sọ awọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ-ẹ̀yìn, . . . ẹ máa kọ́ wọn lati máa pa gbogbo ohun tí mo ti paláṣẹ fún yín mọ́. Sì wò ó! mo wà pẹlu yín ní gbogbo awọn ọjọ́ títí dé ìparí ètò-ìgbékalẹ̀ awọn nǹkan.”—Matteu 13:51, 52; 28:19, 20.
11. Nígbà tí ó di 1914, àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wo tí ó ní í ṣe pẹ̀lú Ìjọba náà ni ó ṣẹlẹ̀?
11 Gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣèlérí, Jesu ti ń bá a nìṣó láti máa wà pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ jálẹ̀ àwọn ọ̀rúndún títí di ọjọ́ òní. Ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn wọ̀nyí, ó ti fún wọn ní òye ní ṣísẹ̀ntẹ̀lé, ó sì ti gbé ẹrù iṣẹ́ lílo ìmọ́lẹ̀ òtítọ́ tí ń mọ́lẹ̀ sí i náà lé wọn lọ́wọ́. (Luku 19:11-15, 26) Ní 1914, àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ Ìjọba bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹlẹ̀ kíákíá àti lọ́nà tí ó múni jí gìrì. Ní ọdún yẹn, kì í ṣe “ìbí” Ìjọba náà tí a ti ń retí tipẹ́tipẹ́ nìkan ni ó ṣẹlẹ̀, ṣùgbọ́n, “òpin ètò-ìgbékalẹ̀ awọn nǹkan” bẹ̀rẹ̀. (Ìṣípayá 11:15; 12:5, 10; Danieli 7:13, 14, 27) Àwọn Kristian tòótọ́, tí ń fòye mọ ìtumọ̀ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ lọ́ọ́lọ́ọ́, ti ṣe ìgbétásì kíkàmàmà jù lọ nínú ìtàn nínú ìwàásù àti ìkọ́ni nípa Ìjọba náà. Jesu sọ èyí tẹ́lẹ̀, ní sísọ pé: “A óò sì wàásù ìhìnrere ìjọba yii ní gbogbo ilẹ̀-ayé tí a ń gbé lati ṣe ẹ̀rí fún gbogbo awọn orílẹ̀-èdè; nígbà naa ni òpin yoo sì dé.”—Matteu 24:14.
12. (a) Kí ni ó ti jẹ́ ìyọrísí ìjẹ́rìí Ìjọba náà lọ́nà gbígbòòrò lóde òní? (b) Nínú ayé oníyè méjì yìí, ewu wo ní ó wà fún àwọn Kristian?
12 Ìjẹ́rìí gbígbòòrò nípa Ìjọba yìí ti dé ilẹ̀ tí ó lé ní 230. Ní báyìí, iye tí ó lé ní mílíọ̀nù márùn-ún àwọn ọmọ ẹ̀yìn tòótọ́ ń nípìn-ín nínú iṣẹ́ yìí, a ń kó àwọn mìíràn jọ síbẹ̀. Ṣùgbọ́n bí a bá fi iye àwọn ọmọ ẹ̀yìn wéra pẹ̀lú bílíọ̀nù 5.6 àwọn olùgbé ayé, ó ṣe kedere pé, gẹ́gẹ́ bí ó ṣe rí ní ọjọ́ Jesu, àwọn tí ó pọ̀ jù lọ nínú aráyé kò ‘lóye’ Ìjọba náà. Gẹ́gẹ́ bí a ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀, ọ̀pọ̀ ń yọ ṣùtì, wọ́n sì ń sọ pé: “Wíwàníhìn-ín rẹ̀ yii tí a ti ṣèlérí naa dà?” (2 Peteru 3:3, 4) Ewu tí ó wà fún wa gẹ́gẹ́ bí Kristian ni pé, kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ìṣarasíhùwà aláìbìkítà, iyè méjì àti ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì wọn lè ní ipa lórí ojú tí a fi ń wo àwọn àǹfààní Ìjọba náà. Nítorí ti àwọn ènìyàn ayé yìí yí wa ká, ó rọrùn fún wa láti bẹ̀rẹ̀ sí í gba díẹ̀ nínú àwọn ìṣarasíhùwà àti ìṣe wọn lò. Ẹ wo bí ó ti ṣe pàtàkì tó pé kí a ‘lóye’ Ìjọba Ọlọrun, kí a sì dìrọ̀ mọ́ ọn pinpin!
Yíyẹ Ara Wa Wò ní Ìsopọ̀ Pẹ̀lú Ìjọba Náà
13. Ní ti iṣẹ́ àṣẹ náà láti wàásù ìhìn rere Ìjọba náà, báwo ni a ṣe lè ṣàyẹ̀wò bóyá a ń bá a nìṣó láti máa fi òye ‘gbọ́’?
13 Jesu sọ nípa sáà ìkórè tí a ń gbè nínú rẹ̀ pé: “Ọmọkùnrin ènìyàn yoo rán awọn áńgẹ́lì rẹ̀ jáde, wọn yoo sì kó gbogbo ohun tí ń fa ìkọ̀sẹ̀ jáde kúrò ninu ìjọba rẹ̀ ati awọn ènìyàn tí ń hu ìwà-àìlófin . . . Ní àkókò yẹn awọn olódodo yoo máa tàn yòò gẹ́gẹ́ bí oòrùn ninu ìjọba Baba wọn. Kí ẹni tí ó bá ní etí fetísílẹ̀.” (Matteu 13:41, 43) Ìwọ́ ha ń bá a nìṣó láti “gbọ́” àṣẹ náà láti wàásù Ìjọba náà, kí o sì sọni di ọmọ ẹ̀yìn pẹ̀lú ìdáhùnpadà onígbọràn bí? Rántí pé, “èyí tí a fún sórí erùpẹ̀ àtàtà” ‘gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, ó sì lóye rẹ̀,’ ó sì so èso rere.—Matteu 13:23.
14. Nígbà tí a bá fún wa ní ìtọ́ni, báwo ni a ṣe lè fi hàn pé a ‘lóye’ ìmọ̀ràn tí a fún wa?
14 Nígbà tí a bá ń ṣe ìdákẹ́kọ̀ọ́, tí a sì ń lọ sí àwọn ìpàdé Kristian, a ní láti ‘fi ọkàn wa sí òye.’ (Owe 2:1-4) Nígbà tí a bá fún wa nímọ̀ràn lórí ìwà, ìmúra, orin àti eré ìnàjú, a gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ó wọnú ọkàn-àyà wa ṣinṣin, kí ó sì sún wa láti ṣe àtúnṣe èyíkéyìí tí ó bá yẹ. Má ṣe dá ara rẹ láre, má ṣe wá àwíjàre, tàbí kí o kọ̀ láti dáhùn padà. Bí Ìjọba náà bá jẹ́ gidi nínú ìgbésí ayé wa, a óò máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà rẹ̀, a óò sì máa fi tìtaratìtara pòkìkí rẹ̀ fún àwọn ẹlòmíràn. Jesu wí pé: “Kì í ṣe olúkúlùkù ẹni tí ń wí fún mi pé, ‘Oluwa, Oluwa,’ ni yoo wọ inú ìjọba awọn ọ̀run, bíkòṣe ẹni naa tí ń ṣe ìfẹ́-inú Baba mi tí ń bẹ ní awọn ọ̀run ni yoo wọ̀ ọ́.”—Matteu 7:21-23.
15. Èé ṣe tí ó fi ṣe pàtàkì láti ‘kọ́kọ́ wa ìjọba náà àti òdodo Ọlọrun’?
15 Ó jẹ́ ìtẹ̀sí ẹ̀dá ènìyàn láti ṣàníyàn nípa oúnjẹ, aṣọ àti ibùgbé tí ó nílò, ṣùgbọ́n Jesu wí pé: “Ẹ máa bá a nìṣó, nígbà naa, ní wíwá ìjọba naa ati òdodo rẹ̀ [ti Ọlọrun] lákọ̀ọ́kọ́, gbogbo nǹkan mìíràn wọnyi ni a óò sì fi kún un fún yín.” (Matteu 6:33, 34) Ní gbígbé àwọn ohun ṣíṣe pàtàkì kalẹ̀, fi Ìjọba náà sí ipò kíní nínú ìgbèsí ayé rẹ. Jẹ́ kí ìgbésí ayé rẹ̀ rọrùn, nípa níní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú àwọn ohun kò-ṣeé-mánìí. Yóò jẹ́ ìwà òmùgọ̀ láti jẹ́ kí ìgbésí ayé wa kún fún àwọn ìgbòkègbodò àti ṣíṣàkójọ ohun ìní tí kò ṣe pàtàkì, bóyá ní dídá ara wa láre pé ṣíṣe èyí jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà, níwọ̀n bí àwọn nǹkan wọ̀nyí kò ti burú ní ti gidi fúnra wọn. Bí ìyẹn tilẹ̀ lè jẹ́ òtítọ́, kí ni kíkó àwọn ohun tí kò ṣe pàtàkì bẹ́ẹ̀ jọ àti lílò wọn yóò ṣe fún wíwéwèé ìdákẹ́kọ̀ọ́ wa, lílọ sí àwọn ìpàdé Kristian, àti lílọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù? Jesu wí pé, Ìjọba náà dà bí olówò kan tí ó rí “péálì kan tí ìníyelórí rẹ̀ ga, [tí] ó jáde lọ [tí] ó sì ta gbogbo ohun tí ó ní ní kánmọ́kánmọ́ [tí] ó sì rà á.” (Matteu 13:45, 46) Bí ó ṣe yẹ kí ìmọ̀lára wa nípa Ìjọba Ọlọrun rí nìyẹn. Ó yẹ kí a ṣàfarawé Paulu, kì í ṣe Demasi tí ó ṣá iṣẹ́ òjíṣẹ́ tì, “nitori pé ó nífẹ̀ẹ́ ètò-ìgbékalẹ̀ awọn nǹkan ìsinsìnyí.”—2 Timoteu 4:10, 18; Matteu 19:23, 24; Filippi 3:7, 8, 13, 14; 1 Timoteu 6:9, 10, 17-19.
“Awọn Aláìṣòdodo Ènìyàn Kì Yoo Jogún Ìjọba Ọlọrun”
16. Báwo ni ‘lílóye’ Ìjọba Ọlọrun yóò ṣe ràn wá lọ́wọ́ láti yẹra fún ìwà àìtọ́?
16 Nígbà tí ìjọ Korinti ń fàyè gba ìwà pálapàla, Paulu sọ láìfọ̀rọ̀ bọpobọyọ̀ pé: “Kínla! Ẹ̀yin kò ha mọ̀ pé awọn aláìṣòdodo ènìyàn kì yoo jogún ìjọba Ọlọrun? Kí a máṣe ṣì yín lọ́nà. Kì í ṣe awọn àgbèrè, tabi awọn abọ̀rìṣà, tabi awọn panṣágà, tabi awọn ọkùnrin tí a pamọ́ fún awọn ète tí ó lòdì sí ti ẹ̀dá, tabi awọn ọkùnrin tí ń bá ọkùnrin dàpọ̀, tabi awọn olè, tabi awọn oníwọra ènìyàn, tabi awọn ọ̀mùtípara, tabi awọn olùkẹ́gàn, tabi awọn alọ́nilọ́wọ́gbà ni yoo jogún ìjọba Ọlọrun.” (1 Korinti 6:9, 10) Bí a bá ‘lóye’ Ìjọba Ọlọrun, a kò ní tan ara wa jẹ nípa ríronú pé, Jehofa yóò fàyè gba irú àwọn ìwà pálapàla kan níwọ̀n ìgbà tí ó bá ti ń rí i tí ọwọ́ wá dí fọ́fọ́ nínú iṣẹ́ ìsìn Kristian. Kò tilẹ̀ yẹ kí a mẹ́nu kan ìwà àìmọ́ láàárín wa rárá. (Efesu 5:3-5) O ha ṣàkíyèsí pé díẹ̀ lára ìrònú tàbí àṣà ẹlẹ́gbin ayé yìí ti bẹ̀rẹ̀ sí í yọ́ wọnú ìgbésí ayé rẹ bí? Mú wọn kúrò nínú ìgbésí ayé rẹ̀ ní kíá mọ́sá! Ìjọba náà ṣeyebíye fíìfíì ju ohun tí a lè tìtorí irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ pàdánù lọ.—Marku 9:47.
17. Ní àwọn ọ̀nà wo ni ìmọrírì fún Ìjọba Ọlọrun yóò ṣe gbé ìrẹ̀lẹ̀ lárugẹ, tí yóò sì mú ohun ìkọ̀sẹ̀ kúrò?
17 Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jesu béèrè pé: “Níti tòótọ́ ta ni ó tóbi jùlọ ninu ìjọba awọn ọ̀run?” Jesu dáhùn nípa pípe ọmọ kékeré kan sáàárín wọn, ó sì sọ pé: “Ní òótọ́ ni mo wí fún yín, Láìjẹ́ pé ẹ yípadà kí ẹ sì dàbí awọn ọmọ kéékèèké, ẹ̀yin kì yoo wọ inú ìjọba awọn ọ̀run lọ́nàkọnà. Nitori naa, ẹni yòówù tí ó bá rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ bí ọmọ kékeré yii ni ẹni naa tí ó tóbi jùlọ ninu ìjọba awọn ọ̀run.” (Matteu 18:1-6) Kì yóò sí àwọn agbéraga, amúnilápàpàǹdodo, aláìbìkítà àti aláìlófin nínú Ìjọba Ọlọrun, bẹ́ẹ̀ sì ni wọn kì yóò jẹ́ ọmọ abẹ́ Ìjọba náà. Ǹjẹ́ ìfẹ́ rẹ fún àwọn arákùnrin rẹ, ìrẹ̀lẹ̀ rẹ, ìbẹ̀rù Ọlọrun rẹ, ha ń sún ọ láti yẹra fún mímú àwọn ẹlòmíràn kọsẹ̀ nípa ìwà rẹ? Tàbí o ha máa ń rin kinkin mọ́ “àwọn ẹ̀tọ́” rẹ, láìka ipa tí ìṣarasíhùwà àti ìwà rẹ̀ lè ní lórí àwọn ẹlòmíràn sí?—Romu 14:13, 17.
18. Kí ni yóò yọrí sí fún aráyé onígbọràn, nígbà tí Ìjọba Ọlọrun bá mú ìfẹ́ inú Rẹ̀ ṣẹ “gẹ́gẹ́ bí ní ọ̀run, lórí ilẹ̀-ayé pẹlu”?
18 Láìpẹ́, Bàbá wa ọ̀run, Jehofa, yóò dáhùn àdúrà onítara wa lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́ pé: “Kí ìjọba rẹ dé. Kí ìfẹ́-inú rẹ ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí ní ọ̀run, lórí ilẹ̀-ayé pẹlu.” Láìpẹ́, Ọba tí ń ṣàkóso náà, Jesu Kristi, yóò wá lọ́nà ti jíjókòó lórí ìtẹ́ rẹ̀ fún ìdájọ́, láti ya “awọn àgùtàn” kúrò lára “awọn ewúrẹ́.” Ní àkókò tí a yàn kalẹ̀ yẹn, “ọba yoo wí fún awọn wọnnì tí wọ́n wà ní ọ̀tún rẹ̀ pé, ‘Ẹ wá, ẹ̀yin tí Baba mi ti bùkún, ẹ jogún ìjọba tí a ti pèsè sílẹ̀ fún yín lati ìgbà pípilẹ̀ ayé.’” Àwọn ewúrẹ́ “yoo . . . lọ sínú ìkékúrò àìnípẹ̀kun, ṣugbọn awọn olódodo sínú ìyè àìnípẹ̀kun.” (Matteu 6:10; 25:31-34, 46) “Ìpọ́njú ńlá naa” yóò palẹ̀ ètò ìgbékalẹ̀ ògbólógbòó náà mọ́ àti gbogbo àwọn tí wọ́n kọ̀ láti ‘lóye’ Ìjọba náà. Ṣùgbọ́n, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn olùla “ìpọ́njú ńlá” já àti ọ̀pọ̀ bílíọ̀nù tí a óò jí dìde yóò jogun àwọn ìbùkún Ìjọba náà láìlópin nínú ilẹ̀ ayé tí a sọ di Paradise. (Ìṣípayá 7:14) Ìjọba náà ni ìṣàkóso tuntun ti orí ilẹ̀ ayé, tí ń ṣàkóso láti àwọn ọ̀run. Yóò ṣàṣeparí ète Jehofa fún ilẹ̀ ayé àti ìran ènìyàn, gbogbo rẹ̀ fún ìsọdimímọ́ orúkọ rẹ̀ tí ó jẹ́ mímọ́ jú lọ. Ìyẹn kò ha jẹ́ ogún tí ó tóó ṣiṣẹ́ fún, tí ó tóó ṣe ìrúbọ fún, tí ó sì tóó dúró dè bí? Èyí ni ohun tí ‘lílóye’ Ìjọba náà yẹ kí ó túmọ̀ sí fún wa!
Báwo Ni Ìwọ Yóò Ṣe Dáhùn?
◻ Kí ni Ìjọba Ọlọrun?
◻ Èé ṣe tí ọ̀pọ̀ jù lọ nínú àwọn olùgbọ́ Jesu kò fi ‘lóye’ Ìjọba náà?
◻ Báwo ni ‘lílóye’ Ìjọba náà ṣe ń mú ìbùkún àti ẹrù iṣẹ́ wá?
◻ Ní ti iṣẹ́ ìwàásù, kí ní ń fi hàn bóyá a ‘lóye’ Ìjọba náà?
◻ Báwo ni a ṣe lè fi han nípa ìwà wa, pé a ‘lóye’ ìmọ̀ràn tí a fún wa?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jesu ‘lóye’ Ìjọba náà, wọ́n sì mú èso rere jáde