ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w14 12/15 ojú ìwé 21
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Tẹ̀gbọ́n-tàbúrò Tí wọn Ò Láyọ̀ Ló “Kọ́ Ilé Ísírẹ́lì”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Jékọ́bù Lọ Sí Háránì
    Ìwé Ìtàn Bíbélì
  • Jékọ́bù Ní Ìdílé Ńlá
    Ìwé Ìtàn Bíbélì
  • Ìgbà Wo Ni Jèhófà Máa Ń Bù Kún—Ìsapá Tí A Fi Taratara Ṣe?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2002
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
w14 12/15 ojú ìwé 21

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Kí ni Jeremáyà ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé Rákélì ń sunkún nítorí àwọn ọmọkùnrin rẹ̀?

Jeremáyà 31:​15, sọ pé: “Èyí ni ohun tí Jèhófà wí, ‘Ní Rámà, a gbọ́ ohùn kan, ìdárò àti ẹkún kíkorò; Rákélì ń sunkún nítorí àwọn ọmọ rẹ̀. Ó kọ̀ láti gba ìtùnú nítorí àwọn ọmọ rẹ̀, nítorí pé wọn kò sí mọ́.’”

Rákélì ti kú ṣáájú àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ méjèèjì. Yàtọ̀ síyẹn, ohun tí Jeremáyà kọ ní ẹgbẹ̀rún ọdún kan lẹ́yìn ikú Rákélì lè fẹ́ dà bíi pé kò tọ̀nà.

Jósẹ́fù ni ọmọkùnrin àkọ́kọ́ tí Rákélì bí. (Jẹ́n. 30:​22-24) Nígbà tó yá ó bí ọmọkùnrin mí ì, Bẹ́ńjámínì lorúkọ rẹ̀. Àmọ́, Rákélì kú nígbà tó ń bí ọmọkùnrin rẹ̀ kejì yìí. Kí wá nìdí tí Jeremáyà 31:15 fi sọ pé Rákélì ń sunkún torí pé àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ “kò sí mọ́”?

Ohun kan tó yẹ ká fiyè sí ni pé, Jósẹ́fù tó jẹ́ àkọ́bí Rákélì ló bí Mánásè àti Éfúráímù. (Jẹ́n. 41:​50-52; 48:​13-20) Nínú gbogbo ìjọba Ísírẹ́lì tó wà ní àríwá, ẹ̀yà Éfúráímù ló gbajúmọ̀ jù tó sì jẹ́ abẹnugan, òun sì ni aṣojú fún ẹ̀yà Ísírẹ́lì mẹ́wàá. Lọ́wọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, ẹ̀yà tó wá látọ̀dọ̀ ọmọkùnrin kejì tí Rákélì bí, ìyẹn Bẹ́ńjámínì ló wá di apá kan lára ìjọba Ísírẹ́lì tó wà ní gúúsù pa pọ̀ pẹ̀lú Júdà. Torí náà, a lè sọ pé Rákélì ń ṣàpẹẹrẹ gbogbo ìyá tó bí àwọn tó di orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì, ìyẹn ìjọba Ísírẹ́lì tó wà ní àríwá àtèyí tó wà ní gúúsù.

Kó tó di pé Jeremáyà kọ̀wé rẹ̀ yìí, àwọn ará Ásíríà ti ṣẹ́gun ìjọba ẹ̀yà mẹ́wàá tó wà ní àríwá, wọ́n sì ti kó ọ̀pọ̀ nínú wọn lọ sí ìgbèkùn. Àmọ́, ó ṣeé ṣe kí àwọn kan nínú àwọn àtọmọdọ́mọ Éfúráímù ti sá lọ sí ìpínlẹ̀ Júdà. Ní ọdún 607 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, àwọn ará Bábílónì ṣẹ́gun ìjọba ẹ̀yà méjì ti Júdà tó wà ní gúúsù. Ó jọ pé, wọ́n kó ọ̀pọ̀ àwọn tí wọ́n kó lọ sí ìgbèkùn jọ sí ìlú Rámà tó wà ní nǹkan bí kìlómítà mẹ́jọ sí àríwá ìlú Jerúsálẹ́mù. (Jer. 40:1) Ó tiẹ̀ ṣeé ṣe kí wọ́n pa àwọn kan lára wọn sí ìpínlẹ̀ Bẹ́ńjámínì níbi tí wọ́n sin Rákélì sí. (1 Sám. 10:2) Torí náà ẹkún tí Rákélì ń sun nítorí àwọn ọmọ rẹ̀ lè jẹ́ ìṣàpẹẹrẹ. Ìyẹn ni pé lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, ó ń ṣọ̀fọ̀ nítorí ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì tàbí nítorí àwọn tó wà ní Rámà. Ọ̀rọ̀ yẹn sì tún lè túmọ̀ sí pé ńṣe ni gbogbo ìyá àwọn èèyàn Ọlọ́run ń sunkún nítorí ikú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tàbí torí pé wọ́n kó wọn lọ sí ìgbèkùn.

Bó ti wù kó rí, ọ̀rọ̀ tí Jeremáyà sọ pé Rákélì ń sunkún nítorí àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ jẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún lẹ́yìn ìyẹn, nígbà tí Jésù ṣì kéré tí ẹ̀mí rẹ̀ sì wà nínú ewu. Ó ṣẹlẹ̀ pé, Hẹ́rọ́dù Ọba pàṣẹ pé kí wọ́n pa gbogbo àwọn ọmọdékùnrin tó wà ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, ìyẹn ìlú tó wà ní gúúsù ìlú Jerúsálẹ́mù, látorí ọmọ ọdún méjì sísàlẹ̀. Nítorí náà, a lè sọ pé àwọn ọmọdékùnrin yẹn kò sí mọ́, wọ́n ti kú. Fojú wo bí àwọn abiyamọ yìí á ti máa pohùn réré ẹkún tí wọ́n á sì ṣọ̀fọ̀ àwọn ọmọkùnrin wọn tó ti kú! Ńṣe ló dà bíi pé ìró ẹkún wọn lọ jìnnà dé Rámà, ìyẹn ìlú tó wà ní àríwá ìlú Jerúsálẹ́mù.​—Mát. 2:​16-18.

Torí náà, ní ìgbà ayé Jeremáyà àti nígbà ayé Jésù, ẹkún tí Rákélì ń sun nítorí àwọn ọmọ rẹ̀ bá a mu wẹ́kú láti ṣàlàyé bí àwọn abiyamọ tí wọ́n jẹ́ Júù ṣe ń pohùn réré ẹkún nítorí àwọn ọmọ wọn tí wọ́n pa. Ní ti gidi, àwọn tó ti lọ sí “ilẹ̀ ọ̀tá,” ìyẹn àwọn tó ti kú lè bọ́ lábẹ́ agbára ọ̀tá yìí nígbà tí àwọn òkú bá jíǹde.​—⁠Jer. 31:16; 1 Kọ́r. 15:26.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́