Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí
January 15, 2015
© 2015 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
Ẹ̀DÀ TÓ WÀ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́
MARCH 2-8, 2015
Fi Ọpẹ́ Fún Jèhófà Kí O sì Gba Ìbùkún
MARCH 9-15, 2015
Ìdí Tí A Fi Ń Lọ Síbi Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa
MARCH 16-22, 2015
Bí Tọkọtaya Ṣe Lè Ṣera Wọn Lọ́kan Kí Wọ́n sì Láyọ̀
MARCH 23-29, 2015
Jẹ́ Kí Jèhófà Dáàbò Bo Ìgbéyàwó Rẹ Kó sì Fún Un Lókun
MARCH 30, 2015–APRIL 5, 2015
ÀWỌN ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́
▪ Fi Ọpẹ́ Fún Jèhófà Kí O sì Gba Ìbùkún
A lè fi hàn pé a moore ká sì máa ṣe bẹ́ẹ̀ nìṣó tá a bá ń ṣàṣàrò lórí àwọn ohun tí Jèhófà ti ṣe fún wa tá a sì ń dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀. Tá a bá ń dúpẹ́, a ò ní ya aláìmoore, àá sì lè fara da àwọn àdánwò tá a bá dojú kọ. Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wa ti ọdún 2015 máa jẹ́ kí èyí máa ró gbọnmọgbọnmọ lọ́kàn wa jálẹ̀ ọdún yìí.
▪ Ìdí Tí A Fi Ń Lọ Síbi Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa
Àpilẹ̀kọ yìí sọ ìdí pàtàkì tá a fi gbọ́dọ̀ máa ṣe Ìrántí Ikú Kristi. Ó sọ ohun tí búrẹ́dì àti wáìnì tí à ń lò nígbà Ìrántí Ikú Kristi ń ṣàpẹẹrẹ, ó sì jẹ́ ká mọ bí ẹnì kan ṣe lè mọ̀ bóyá ó yẹ kí òun jẹ àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ náà tàbí kò yẹ. Àpilẹ̀kọ yìí tún máa jẹ́ kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa mọ bá a ṣe lè múra sílẹ̀ de Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa.
▪ Bí Tọkọtaya Ṣe Lè Ṣera Wọn Lọ́kan Kí Wọ́n sì Láyọ̀
▪ Jẹ́ Kí Jèhófà Dáàbò Bo Ìgbéyàwó Rẹ Kó sì Fún Un Lókun
Ìdẹwò àti ìṣòro túbọ̀ ń dojú kọ àwọn tọkọtaya. Àmọ́ lọ́lá Jèhófà, wọ́n lè ṣera wọn lọ́kan, kí wọ́n sì láyọ̀. Àpilẹ̀kọ àkọ́kọ́ sọ ohun márùn-ún ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tá a lè pè ní búlọ́ọ̀kù tẹ̀mí tó máa mú kí tọkọtaya ṣe ara wọn lọ́kan kí ìgbéyàwó wọn lè wà pẹ́ títí. Àá tún jíròrò ohun tá a lè fi wé sìmẹ́ǹtì tó máa mú kí àárín tọkọtaya túbọ̀ gún régé. Àpilẹ̀kọ kejì dá lórí bí tọkọtaya ṣe lè dáàbò bo ìgbéyàwó wọn.
▪ Ǹjẹ́ Ìfẹ́ Àárín Tọkọtaya Lè Wà Pẹ́ Títí?
Báwo ló ṣe máa ń rí tí ọkùnrin àti obìnrin kan bá ní ìfẹ́ tòótọ́ láàárín ara wọn? Ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe kí ìfẹ́ wà pẹ́ títí? Báwo ni tọkọtaya ṣe lè fi irú ìfẹ́ yìí hàn síra wọn? Jẹ́ ká wo ohun tí Orin Sólómọ́nì kọ́ wa nípa ìfẹ́ tó lè wà pẹ́ títí.
ÀWỌN ÀPILẸ̀KỌ MÍÌ NÍNÚ ÌTẸ̀JÁDE YÌÍ
ÀWÒRÁN IWÁJÚ ÌWÉ: Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan gbé Bíbélì lọ́wọ́ ó ń wàásù fún ẹnì kan ní abúlé tó rẹwà tí wọ́n ń pè ní Grindelwald, Òkè Bernese ló wà lẹ́yìn ilé tí yìnyín bò mọ́lẹ̀ yẹn
SWITZERLAND
IYE ÈÈYÀN
7,876,000
IYE AKÉDE
18,646
ÀWỌN TÓ WÁ SÍBI ÌRÁNTÍ IKÚ KRISTI LỌ́DÚN (2013)
31,980