Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí
April 15, 2015
© 2015 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
Ẹ̀DÀ TÓ WÀ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́
JUNE 1-7, 2015
Ẹ̀yin Alàgbà, Ǹjẹ́ Ẹ Máa Ń Dá Àwọn Míì Lẹ́kọ̀ọ́?
OJÚ ÌWÉ 3 • ORIN: 123, 121
JUNE 8-14, 2015
Bí Àwọn Alàgbà Ṣe Ń Kọ́ Àwọn Míì Kí Wọ́n Lè Tóótun
JUNE 15-21, 2015
Ǹjẹ́ Ó Dá Ẹ Lójú Pé O Ní Àjọṣe Tó Dán Mọ́rán Pẹ̀lú Jèhófà?
JUNE 22-28, 2015
Ẹ Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà Nígbà Gbogbo!
OJÚ ÌWÉ 24 • ORIN: 106, 49
ÀWỌN ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́
▪ Ẹ̀yin Alàgbà, Ǹjẹ́ Ẹ Máa Ń Dá Àwọn Míì Lẹ́kọ̀ọ́?
▪ Bí Àwọn Alàgbà Ṣe Ń Kọ́ Àwọn Míì Kí Wọ́n Lè Tóótun
Báwo ló ti ṣe pàtàkì tó pé káwọn alàgbà dá àwọn arákùnrin tí wọn kò fi bẹ́ẹ̀ ní ìrírí lẹ́kọ̀ọ́? Àwọn ọ̀nà wo làwọn kan ti gbà dáni lẹ́kọ̀ọ́ tó sì yọrí sí rere? Kí ni àwọn alàgbà àtàwọn tó ń gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ lè rí kọ́ lára àwọn èèyàn ìgbàanì irú bíi Sámúẹ́lì, Èlíjà àti Èlíṣà? A máa rí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè yìí nínú ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ méjì yìí.
▪ Ǹjẹ́ Ó Dá Ẹ Lójú Pé O Ní Àjọṣe Tó Dán Mọ́rán Pẹ̀lú Jèhófà?
▪ Ẹ Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà Nígbà Gbogbo!
Tí àjọṣe tá a ní pẹ̀lú Jèhófà bá fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin, àdánwò ò ní lè borí wa. Àwọn àpilẹ̀kọ méjì yìí jẹ́ ká mọ bí a ṣe lè túbọ̀ mú àjọṣe àwa àti Jèhófà lágbára tá a bá ń bá Jèhófà sọ̀rọ̀ tá a sì ń jẹ́ kó máa bá wa sọ̀rọ̀, tí a sì tún gbẹ́kẹ̀ lé e nígbà gbogbo.
ÀWỌN ÀPILẸ̀KỌ MÍÌ NÍNÚ ÌTẸ̀JÁDE YÌÍ
14 Mo Gba Ọ̀pọ̀ Ìbùkún Ní “Àsìkò Tí Ó Rọgbọ àti Ní Àsìkò Tí Ó Kún Fún Ìdààmú”
ÀWÒRÁN IWÁJÚ ÌWÉ: Alàgbà kan ń dá ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ kan lẹ́kọ̀ọ́ lórí bó ṣe lè wàásù láwọn ibi tí èrò pọ̀ sí ní ojú pópó Haiphong, nílùú Kowloon
HONG KONG
IYE ÈÈYÀN
7,234,800
IYE AKÉDE
5,747
IYE ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ BÍBÉLÌ
6,382
180,000+
Ẹ̀ka ọ́fíìsì wa tó wà ní orílẹ̀-èdè Hong Kong ti bá wa ra àwọn ohun ìkówèésí tó ṣeé yí kiri, àwọn ibi tá a lè kó ìwé sí, àwọn ilé kékeré irú èyí tí wọ́n fi ń tajà àtàwọn tábìlì, a sì ti pín wọn káàkiri àwọn orílẹ̀-èdè tó kù