ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w15 8/1 ojú ìwé 3-4
  • Kí Ló Ń Ṣẹlẹ̀ Lẹ́yìn Ikú?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kí Ló Ń Ṣẹlẹ̀ Lẹ́yìn Ikú?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ipò wo làwọn òkú wà?
  • Kí Ni Ọ̀run Àpáàdì Jẹ́ Gan-an?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2002
  • Àjíǹde Máa Wà!
    Kí Ni Bíbélì Kọ́ Wa?
  • Ṣé Ọ̀run Àpáàdì Wà Lóòótọ́? Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Ọ̀run Àpáàdì?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Ikú Kọ́ Ni Òpin Ìgbésí Ayé Ẹ̀dá!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
w15 8/1 ojú ìwé 3-4

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | ṢÉ ÀWỌN TÓ TI KÚ LÈ JÍǸDE?

Kí Ló Ń Ṣẹlẹ̀ Lẹ́yìn Ikú?

Àwọn àgbà àtọmọdé dúró sẹ́gbẹ̀ẹ́ pósí kan níbi tí wọ́n ti fẹ́ sìnkú

“Ibi mẹ́ta ni mo rò pé èèyàn lè lọ lẹ́yìn tó bá kú, nínú kó lọ sí ọ̀run tàbí ọ̀run àpáàdì tàbí kó lọ sí pọ́gátórì. Mi ò rò pé ìwà mi dáa tó kí n rí ọ̀run wọ̀, àmọ́ kò burú débi tí máa fi lọ sí ọ̀run àpáàdì. Ohun tó ń ṣẹlẹ̀ ní pọ́gátórì kò sì yé mi rárá. Ẹnu àwọn èèyàn ni mo kúkú ti gbọ́ ọ, kò sí èyí tí mo rí nínú Bíbélì níbẹ̀.”​—Lionel.

“Ohun tí wọ́n kọ́ mi ni pé, ọ̀run ni gbogbo èèyàn ń lọ lẹ́yìn ikú, àmọ́ mi ò gbà gbọ́. Ohun témi rò ni pé ikú lòpin ohun gbogbo, kò sì sí ìrètí kankan fáwọn tó ti kú.”​—Fernando.

Ǹjẹ́ o ti rò ó rí pé: ‘Kí ló máa ń ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ikú? Ṣé àwọn èèyàn wa tó ti kú ń jìyà níbì kan? Ṣé a tún lè pa dà rí wọn? Kí ló máa jẹ́ kó dá wa lójú pé a lè rí wọn?’ Ó máa dáa ká mọ ohun tí Bíbélì sọ lórí kókó yìí. Lákọ̀ọ́kọ́, ẹ jẹ́ ká wo ohun tí Bíbélì fi ikú wé. Lẹ́yìn náà, a máa jíròrò ìrètí tí Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé ó wà fún àwọn tó ti kú.

Ipò wo làwọn òkú wà?

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ: “Nítorí àwọn alààyè mọ̀ pé àwọn yóò kú; ṣùgbọ́n ní ti àwọn òkú, wọn kò mọ nǹkan kan rárá, wọn kò sì ní owó ọ̀yà mọ́, nítorí pé a ti gbàgbé ìrántí wọn. Gbogbo ohun tí ọwọ́ rẹ bá rí láti ṣe, fi agbára rẹ ṣe é, nítorí pé kò sí iṣẹ́ tàbí ìhùmọ̀ tàbí ìmọ̀ tàbí ọgbọ́n ní Ṣìọ́ọ̀lù [tàbí Sàréè], ibi tí ìwọ ń lọ.”a​—Oníwàásù 9:​5, 10.

Ṣìọ́ọ̀lù ìyẹn Sàréè ni ibi tí gbogbo èèyàn ń lọ lẹ́yìn ikú; ó sì ń ṣàpẹẹrẹ ipò tí èèyàn kò ti mọ nǹkan kan mọ́, téèyàn ò sì lè ṣe ohunkóhun. Kí ni ohun tí Jóòbù ọkùnrin olóòótọ́ náà rò nípa Ṣìọ́ọ̀lù? Ọjọ́ kan ṣoṣo ni Jóòbù pàdánù àwọn ọmọ rẹ̀ àti gbogbo ohun tó ní, ni eéwo bá tún so sí gbogbo ara rẹ̀ látorí dé àtẹ́lẹsẹ̀. Ó wá bẹ Ọlọ́run pé: “Ì bá ṣe pé ìwọ yóò fi mí pa mọ́ sínú Ṣìọ́ọ̀lù [“ní ọ̀run àpáàdì,” Bíbélì Catholic Douay Version], pé ìwọ yóò pa mí mọ́.” (Jóòbù 1:​13-19; 2:7; 14:13) Ó dájú pé Jóòbù kò gbà pé Ṣìọ́ọ̀lù ìyẹn Sàréè jẹ́ ibi tí èèyàn ti ń joró nínú iná, níbi tí ìyà rẹ̀ ti máa pọ̀ sí i. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó gbà pé ibẹ̀ ni òun ti máa rí ìtura.

Ọ̀nà míì wà tá a tún lè gbà mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nígbà téèyàn bá kú. A lè ṣàyẹ̀wò ohun tí Bíbélì sọ nípa àwọn mẹ́jọ tí wọ́n jíǹde.​—Wo àpótí náà “Àjíǹde Mẹ́jọ Tí Bíbélì Mẹ́nu Kàn.”

Kò sí ọ̀kan nínú àwọn mẹ́jọ yìí tó sọ bóyá òun lọ gbádùn tàbí pé òun joró nígbà tí òun kú. Tó bá jẹ́ pé wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀, ó dájú pé wọ́n á sọ bí ọ̀hún ṣe rí fún àwọn míì. Tí wọ́n bá sì sọ ọ́, ǹjẹ́ irú àkọsílẹ̀ bẹ́ẹ̀ kò ní sí nínú Bíbélì fún wa? Àmọ́, kò sí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ nínú Bíbélì. Àwọn mẹ́jẹ̀ẹ̀jọ kò sọ nǹkan kan nípa ọ̀rọ̀ yìí. Kí nìdí? Ìdí ni pé wọn kò mọ nǹkan kan nígbà tí wọ́n kú, àfi bí ẹni tó sun oorun àsùnwọra. Kódà, Bíbélì sábà máa ń fi ikú wé oorun. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì sọ pé Dáfídì àti Sítéfánù “sùn nínú ikú.”​—Ìṣe 7:60; 13:36.

Tọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, ǹjẹ́ ìrètí kankan wà fún àwọn tó ti kú? Ṣé wọ́n lè jí lójú oorun yìí?

a Ọ̀rọ̀ Hébérù náà “Ṣìọ́ọ̀lù” àti ti Gíríìkì náà “Hédíìsì” túmọ̀ sí “Sàréè.” Àwọn ìtumọ̀ Bíbélì míì pè é ní “ọ̀run àpáàdì,” àmọ́ ẹ̀kọ́ pé èèyàn máa ń joró nínú ọ̀run àpáàdì kò bá Bíbélì mu.

ÀJÍǸDE MẸ́JỌ TÍ BÍBÉLÌ MẸ́NU KÀNb

Ọmọ opó kan Wòlíì Èlíjà jí ọmọ opó kan dìde. Ìlú Sáréfátì tó wà ní àríwá Ísírẹ́lì ni opó náà ń gbé.​—1 Àwọn Ọba 17:​17-24.

Ọmọkùnrin kan ní Ṣúnémù Wòlíì Èlíṣà tí Èlíjà fa iṣẹ́ lé lọ́wọ́ jí ọmọkùnrin kan dìde ní ìlú Ṣúnẹ́mù, ó sì fà á lé àwọn òbí rẹ̀ lọ́wọ́.​—2 Àwọn Ọba 4:​32-37.

Òkú ọkùnrin kan nínú ibojì Wọ́n ju òkú ọkùnrin kan tó ṣẹ̀ṣẹ̀ kú síbi tí wọ́n sin òkú Èlíṣà sí. Nígbà tí ara ọkùnrin náà kan eegun òkú wòlíì Èlíṣà, ọkùnrin náà jí dìde.​—2 Àwọn Ọba 13:​20, 21.

Ọmọkùnrin òpó tó wá láti Náínì Nígbà tí wọ́n fẹ́ lọ sin òkú ọ̀dọ́kùnrin kan sí ẹ̀yìn odi ìlú Náínì, Jésù jí ọmọ náà dìde ó sì fà á lé ìyá rẹ̀ tó ń ṣọ̀fọ̀ lọ́wọ́.​—Lúùkù 7:​11-15.

Ọmọbìnrin Jáírù Jáírù tó jẹ́ ọkàn lára àwọn òṣìṣẹ́ sínágọ́gù bẹ Jésù pé kó wá bá òun wo ọmọbìnrin òun tó ń ṣàìsàn. Jésù jí ọmọ náà dìde kété lẹ́yìn tó kú.​—Lúùkù 8:​41, 42, 49-56.

Lásárù, ọ̀rẹ́ Jésù àtàtà Lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́rin tí Lásárù ti kú, Jésù jí i dìde níṣojú gbogbo àwọn èèyàn tó wà níbẹ̀.​—Jòhánù 11:​38-44.

Dọ̀káàsì Àpọ́sítélì Pétérù jí obìnrin ọ̀wọ́n yìí dìde. Aláàánú èèyàn ni wọ́n mọ obìnrin yìí sí.​—Ìṣe 9:​36-42.

Yútíkọ́sì Ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń jẹ́ Yútíkọ́sì kú nígbà tó jábọ́ látojú wíńdò; àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sì jí i dìde.​—Ìṣe 20:​7-12.

b Àjíǹde tó ṣe pàtàkì jù ni ti Jésù Kristi fúnra rẹ̀. Àjíǹde tirẹ̀ yàtọ̀ pátápátá sí gbogbo àwọn mẹ́jọ tá a sọ yìí. A máa rí bó ṣe jẹ́ nínú àpilẹ̀kọ tó kàn.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́