ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w15 10/15 ojú ìwé 3
  • ‘Ẹ Máa Ka Irú Àwọn Ènìyàn Bẹ́ẹ̀ Sí Ẹni Ọ̀wọ́n’

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • ‘Ẹ Máa Ka Irú Àwọn Ènìyàn Bẹ́ẹ̀ Sí Ẹni Ọ̀wọ́n’
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kí Là Ń Pè Ní Ìgbìmọ̀ Olùdarí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà?
    Àwọn Ìbéèrè Táwọn Èèyàn Sábà Máa Ń Béèrè Nípa Ẹlẹ́rìí Jèhófà
  • Bí A Ṣe Ṣètò Ìgbìmọ̀ Olùdarí
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Ikede
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Ọ̀nà Wo Ni Ìgbìmọ̀ Olùdarí Gbà Ń Ṣiṣẹ́ Lóde Òní?
    Àwọn Wo Ló Ń Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà Lóde Òní?
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
w15 10/15 ojú ìwé 3
Àwòrán ọ̀kan lára ìgbìmọ̀ tí Ìgbìmọ̀ Olùdarí ń lò rèé, wọ́n ń ṣèpàdé

‘Ẹ Máa Ka Irú Àwọn Ènìyàn Bẹ́ẹ̀ Sí Ẹni Ọ̀wọ́n’

LÁTI ọdún 1992 ni Ìgbìmọ̀ Olùdarí ti ń yan àwọn alàgbà tó ní ìrírí tí òtítọ́ sì jinlẹ̀ nínú wọn láti máa ṣèrànwọ́ fún àwọn ìgbìmọ̀ tí wọ́n ń lò láti bójú tó iṣẹ́.a Ara “àwọn àgùntàn mìíràn” ni Ìgbìmọ̀ Olùdarí ti yan àwọn tó ń ràn wọ́n lọ́wọ́ yìí, iṣẹ́ ribiribi ni wọ́n sì ń ṣe. (Jòh. 10:16) Wọ́n máa ń ṣèpàdé pẹ̀lú ìgbìmọ̀ tí wọ́n yàn wọ́n sí lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, wọ́n máa ń fún ìgbìmọ̀ náà ní àwọn ìsọfúnni àti àbá tí wọ́n rí pé ó máa wúlò. Ìgbìmọ̀ Olùdarí ló máa ń ṣe ìpinnu, àmọ́ àwọn olùrànlọ́wọ́ yìí ló máa ń ṣiṣẹ́ lórí ìpinnu náà, wọ́n á sì ṣe iṣẹ́ èyíkéyìí tí Ìgbìmọ̀ Olùdarí bá yàn fún wọn. Àwọn olùrànlọ́wọ́ yìí àtàwọn mẹ́ńbà Ìgbìmọ̀ Olùdarí jọ máa ń lọ sí àpéjọ àkànṣe àti ti àgbáyé. Ìgbìmọ̀ Olùdarí tún máa ń rán wọn lọ bẹ àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì wò gẹ́gẹ́ bí aṣojú orílé-iṣẹ́.

Ọ̀kan nínú àwọn olùrànlọ́wọ́ náà tó ti ń sìn láti ìgbà tí ètò yìí ti bẹ̀rẹ̀ sọ pé: “Tí mo bá ń bójú tó iṣẹ́ tí wọ́n yàn fún mi, á ṣeé ṣe fún Ìgbìmọ̀ Olùdarí láti túbọ̀ pọkàn pọ̀ sórí ojúṣe rẹ̀.” Arákùnrin míì lára àwọn olùrànlọ́wọ́ tó ti sìn fún ohun tó lé ní ogún ọdún sọ pé: “Àǹfààní tí mi ò lè ronú kàn ni mo kà á sí.”

Iṣẹ́ bàǹtàbanta ni Ìgbìmọ̀ Olùdarí fi síkàáwọ́ àwọn arákùnrin olóòótọ́ tó jẹ́ òṣìṣẹ́ kára yìí, Ìgbìmọ̀ Olùdarí sì mọrírì iṣẹ́ ribiribi tí wọ́n ń ṣe. Ǹjẹ́ kí gbogbo wa “máa ka irú àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ sí ẹni ọ̀wọ́n.”—Fílí. 2:29.

a Tó o bá fẹ́ kà nípa iṣẹ́ ìgbìmọ̀ mẹ́fẹ̀ẹ̀fà tí Ìgbìmọ̀ Olùdarí ń lò, wo Àpótí náà “Bí Ìgbìmọ̀ Olùdarí Ṣe Ń Bójú Tó Àwọn Ohun Tó Jẹ Mọ́ Ìjọba Ọlọ́run” ní Orí 12 nínú ìwé Ìjọba Ọlọ́run Ti Ń Ṣàkóso!

Àwọn Tó Ń Ṣèrànwọ́ fún Ìgbìmọ̀ Mẹ́fẹ̀ẹ̀fà Tí Ìgbìmọ̀ Olùdarí Ń Lò

Ìgbìmọ̀ Olùṣekòkáárí

  • John Ekrann

  • Robert Wallen

Ìgbìmọ̀ Tó Ń Bójú Tó Àwọn Olùyọ̀ǹda Ara Ẹni

  • Gerald Grizzle

  • Patrick LaFranca

  • Daniel Molchan

  • Ralph Walls

Ìgbìmọ̀ Ìṣèwéjáde

  • Don Adams

  • Robert Butler

  • Harold Corkern

  • Donald Gordon

  • Robert Luccioni

  • Alex Reinmueller

  • David Sinclair

Ìgbìmọ̀ Iṣẹ́ Ìsìn

  • Gary Breaux

  • Joel Dellinger

  • Seth Hyatt

  • Christopher Mavor

  • Baltasar Perla, Jr.

  • William Turner, Jr.

  • Robert Wallen

  • Leon Weaver, Jr.

Ìgbìmọ̀ Ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́

  • Ronald Curzan

  • Kenneth Flodin

  • William Malenfant

  • Mark Noumair

  • David Schafer

Ìgbìmọ̀ Ìkọ̀wé

  • Robert Ciranko

  • James Mantz

  • Izak Marais

  • Gene Smalley

  • John Wischuk

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́