ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • wp16 No. 4 ojú ìwé 14-15
  • Àfiwé Tó Dára Jù Lọ Tó O Lè Ṣe

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àfiwé Tó Dára Jù Lọ Tó O Lè Ṣe
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2016
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • BÁ A ṢE LÈ FI ÌGBÀGBỌ́ WA WÉRA PẸ̀LÚ BÍBÉLÌ
  • Kí Ni Ìjọba Ọlọ́run?
    Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?
  • Ta Ni Jésù Kristi?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
  • Kí Ni Ìjọba Ọlọ́run?
    Kí Ni Bíbélì Kọ́ Wa?
  • Kí Ni Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Gbà Gbọ́?
    Kí Ni Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Gbà Gbọ́?
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2016
wp16 No. 4 ojú ìwé 14-15

Àfiwé Tó Dára Jù Lọ Tó O Lè Ṣe

ṢÉ KRISTẸNI ni ẹ́? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, á jẹ́ pé o wà lára àwọn èèyàn tó lé ní bílíọ̀nù méjì tó sọ pé ọmọlẹ́yìn Kristi làwọn, ìyẹn ìdá kan nínú ìdá mẹ́ta èèyàn tó wà láyé. Lóde òní, àwọn ẹ̀yà ìsìn tó ń pe ara wọn ní Kristẹni pọ̀ lọ súà, síbẹ̀ ẹ̀kọ́ wọn àti èrò wọn kò dọ́gba rárá. Ìyẹn ló fi jẹ́ pé ìgbàgbọ́ rẹ lè yàtọ̀ sí tàwọn míì tó pe ara wọn ní Kristẹni. Ṣó tiẹ̀ ṣe pàtàkì kó o gbé ohun tó o gbà gbọ́ yẹ̀wò? Bẹ́ẹ̀ ni. Torí pé ìyẹn ló máa jẹ́ kó o lè ṣe ẹ̀sìn Kristẹni tí Bíbélì fọwọ́ sí.

“Kristẹni” làwọn èèyàn mọ àwọn tó kọ́kọ́ di ọmọlẹ́yìn Kristi sí. (Ìṣe 11:26) Kò sídìí láti tún fi orúkọ míì pè wọ́n torí pé, kò sí àwọn míì tó tún jẹ́ Kristẹni nígbà yẹn. Àwọn Kristẹni máa ń tẹ̀ lé ẹ̀kọ́ Olùdásílẹ̀ ẹ̀sìn Kristẹni, ìyẹn Jésù Kristi. Ṣọ́ọ̀ṣì tó ò ń lọ ńkọ́? Ṣé ó dá ẹ lójú pé ẹ̀kọ́ Kristi ni wọ́n fi ń kọ́ni níbẹ̀, ìyẹn ẹ̀kọ́ tí àwọn tó kọ́kọ́ di ọmọlẹ́yìn Kristi gbà gbọ́? Báwo ló ṣe lè dá ẹ lójú? Ọ̀nà kan ṣoṣo tó o lè gbà mọ̀ ni pé, kó o ṣàyẹ̀wò ohun tí Bíbélì sọ.

Ronú nípa èyí ná: Jésù Kristi ní ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ fún Ìwé Mímọ́ pé ó jẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Kò fara mọ́ àwọn tó ń bomi la ẹ̀kọ́ Bíbélì, tí wọ́n sì ń gbé àṣà àwọn èèyàn lásán lárugẹ. (Máàkù 7:9-13) Ó yẹ ká gbà pé orí Bíbélì làwọn ọmọlẹ́yìn Kristi tòótọ́ máa gbé ìgbàgbọ́ wọn kà. Torí náà, ó yẹ kí Kristẹni kọ̀ọ̀kan bi ara rẹ̀ pé, ‘Ṣé ohun tí wọ́n ń kọ́ mi ní ṣọ́ọ̀ṣì ba Bíbélì mu?’ Láti dáhùn ìbéèrè yẹn, ó máa dáa kó o fi ohun tí ṣọ́ọ̀ṣì rẹ fi ń kọ́ni wéra pẹ̀lú ohun tí Bíbélì sọ?

Jésù sọ pé ìjọsìn Ọlọ́run gbọ́dọ̀ dá lórí òtítọ́, inú Bíbélì sì ni òtítọ́ yẹn wà. (Jòhánù 4:24; 17:17) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù náà sọ pé, ká tó lè rí ìgbàlà a gbọ́dọ̀ ní “ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́.” (1 Tímótì 2:4) Fún ìdí yìí, ó ṣe pàtàkì pé kí ìgbàgbọ́ wa dá lórí òtítọ́ Bíbélì, láìjẹ́ bẹ́ẹ̀ a ò lè ní ìgbàlà!

BÁ A ṢE LÈ FI ÌGBÀGBỌ́ WA WÉRA PẸ̀LÚ BÍBÉLÌ

A rọ̀ ẹ́ pé kó o ka àwọn ìbéèrè mẹ́fà tó wà nínú àpilẹ̀kọ yìí, kó o sì kíyè sí ohun tí Bíbélì sọ nípa wọn. Ka àwọn ẹsẹ Bíbélì tá a tọ́ka sí, kó o sì ronú lórí àwọn ìdáhùn náà. Kó o wá bi ara rẹ pé, ‘Ǹjẹ́ ohun tí wọ́n ń kọ́ mi ní ṣọ́ọ̀ṣì bá ohun táwọn ẹsẹ Bíbélì yìí sọ mu?’

Àwọn ìbéèrè yìí máa mú kó o ṣe àfiwé tó dára jù lọ tó o lè ṣe. Ǹjẹ́ ó wù ẹ́ láti fi àwọn ẹ̀kọ́ ṣọ́ọ̀ṣì rẹ míì wéra pẹ̀lú ohun tí Bíbélì sọ? Inú àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa dùn láti ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè ṣàyẹ̀wò àwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́ inú Bíbélì. Ó ò ṣe ní kí ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wá máa kọ́ ẹ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? O sì lè lọ sórí ìkànnì wa, ìyẹn jw.org/yo.

1 ÌBÉÈRÈ: Ta ni Ọlọ́run?

ÌDÁHÙN: Jèhófà, òun ni Bàbá Jésù. Ọlọ́run ayérayé, òun sì ni atóbilọ́lá Ẹlẹ́dàá ohun gbogbo.

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ:

“Àwa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run Baba Olúwa wa Jésù Kristi nígbà gbogbo tí a bá ń gbàdúrà fún yín.”—Kólósè 1:3.

“Jèhófà, àní Ọlọ́run wa, ìwọ ni ó yẹ láti gba ògo àti ọlá àti agbára, nítorí pé ìwọ ni ó dá ohun gbogbo.”—Ìṣípayá 4:11.

Tún wo Róòmù 10:13; 1 Tímótì 1:17.

2 ÌBÉÈRÈ: Tá ni Jésù Kristi?

ÌDÁHÙN: Jésù ni àkọ́bí ọmọ Ọlọ́run. Ọlọ́run ló dá Jésù, torí náà, ó ní ìbẹ̀rẹ̀. Jésù máa ń tẹrí ba fún Ọlọ́run, ó sì máa ń gbọ́ràn sí i lẹ́nu.

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ:

“Baba tóbi jù mí lọ.”​—Jòhánù 14:28.

“[Jésù] ni àwòrán Ọlọ́run tí a kò lè rí, àkọ́bí nínú gbogbo ìṣẹ̀dá.”​—Kólósè 1:15.

Tún wo Mátíù 26:39; 1 Kọ́ríńtì 15:28.

3 ÌBÉÈRÈ: Kí ni ẹ̀mí mímọ́?

ÌDÁHÙN: Ẹ̀mí mímọ́ ni agbára tí Ọlọ́run ń lò láti ṣe ohun tó bá fẹ́. Kì í ṣe ẹnì kan. Àwọn èèyàn lè kún fún ẹ̀mí mímọ́, ó sì lè fún wọn lágbára.

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ:

“Bí Èlísábẹ́tì ti gbọ́ ìkíni Màríà, ọmọ inú ilé ọlẹ̀ rẹ̀ sọ; Èlísábẹ́tì sì kún fún ẹ̀mí mímọ́.”​—Lúùkù 1:41.

“Ẹ ó gba agbára nígbà tí ẹ̀mí mímọ́ bá bà lé yín.”​—Ìṣe 1:8.

Tún wo Jẹ́nẹ́sísì 1:2; Ìṣe 2:1-4; 10:38.

4 ÌBÉÈRÈ: Kí ni Ìjọba Ọlọ́run?

ÌDÁHÙN: Ìjọba tó ń ṣàkóso láti ọ̀run ni Ìjọba Ọlọ́run. Jésù ni Alákòóso Ìjọba Ọlọ́run. Láìpẹ́, Ìjọba yìí máa mú kí ìfẹ́ Ọlọ́run ṣẹ lórí ilẹ̀ ayé.

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ:

“Áńgẹ́lì keje sì fun kàkàkí rẹ̀. Ohùn rara sì dún ní ọ̀run, pé: ‘Ìjọba ayé di ìjọba Olúwa wa àti ti Kristi rẹ̀, yóò sì ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba títí láé àti láéláé.’”​—Ìṣípayá 11:15.

Tún wo Dáníẹ́lì 2:44; Mátíù 6:9, 10.

5 ÌBÉÈRÈ: Ṣé gbogbo èèyàn rere ló ń lọ sí ọ̀run?

ÌDÁHÙN: Rárá. Ìwọ̀nba àwọn olóòótọ́ èèyàn, tí Bíbélì pè ní “agbo kékeré,” ni Ọlọ́run yàn láti lọ sí ọ̀run. Wọ́n á ṣàkóso pẹ̀lú Jésù lórí àwọn èèyàn.

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ:

“Má bẹ̀rù, agbo kékeré, nítorí pé Baba yín ti tẹ́wọ́ gba fífi ìjọba náà fún yín.”​—Lúùkù 12:32.

“Wọn yóò jẹ́ àlùfáà Ọlọ́run àti ti Kristi, wọn yóò sì ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba pẹ̀lú rẹ̀.”​—Ìṣípayá 20:6.

Tún wo Ìṣípayá 14:1, 3.

6 ÌBÉÈRÈ: Kí ni Ọlọ́run ní lọ́kàn láti ṣe fún ilẹ̀ ayé àti aráyé?

ÌDÁHÙN: Tí Ìjọba Ọlọ́run bá dé, ayé máa di Párádísè, àwọn èèyàn olóòótọ́ máa ní ìlera pípé, aláàfíà máa jọba, àwọn èèyàn á sì wà láàyè títí láé.

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ:

“Àwọn ọlọ́kàn tútù ni yóò ni ilẹ̀ ayé, ní tòótọ́, wọn yóò sì rí inú dídùn kíkọyọyọ nínú ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà.”​—Sáàmù 37:10, 11.

“Yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn ohun àtijọ́ ti kọjá.”​—Ìṣípayá 21:3, 4.

Tún wo Sáàmù 37:29; 2 Pétérù 3:13.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́