ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • wp17 No. 1 ojú ìwé 16
  • Ohun Tí Bíbélì Sọ

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2017
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ṣé Ọlọ́run ló ń fa ìjìyà?
  • Ṣé ìyà máa dópin?
  • Ìyà
    Jí!—2015
  • Ìbéèrè Kẹta: Kí Nìdí Tí Ọlọ́run Fi Jẹ́ Kí Ìyà Máa Jẹ Mí?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
  • Kí Nìdí Tí Ọlọ́run Fi Fàyè Gba Ìyà Tó Ń Jẹ Aráyé?
    Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?
  • Báwo ló ṣe máa ń rí lára Ọlọ́run tó o bá ń jìyà?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2018
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2017
wp17 No. 1 ojú ìwé 16
Ìyá kan gbá ọmọ rẹ̀ mọ́ra nígbà tógun ń jà

Àwọn èèyàn ń jìyà gan-an nínú ayé, àmọ́ ṣé Ọlọ́run ló fà á?

Ohun Tí Bíbélì Sọ

Ṣé Ọlọ́run ló ń fa ìjìyà?

Kí ni ìdáhùn rẹ?

  • Bẹ́ẹ̀ ni

  • Bẹ́ẹ̀ kọ́

  • Kò dá mi lójú

Ohun tí Bíbélì sọ

“Kí a má rí i pé Ọlọ́run tòótọ́ yóò hùwà burúkú, àti pé kí Olódùmarè hùwà lọ́nà tí kò bá ìdájọ́ òdodo mu!” (Jóòbù 34:10) Ọlọ́run kọ́ ló ń fa ìwà ibi àti ìjìyà tó ń ṣẹlẹ̀ láyé.

Kí làwọn nǹkan míì tí Bíbélì sọ?

  • Sátánì Èṣù tó jẹ́, “olùṣàkóso ayé,” ló ń fa ìyà tó ń jẹ wá.​—Jòhánù 14:30.

  • Táwa èèyàn bá tún ṣe ìpinnu tí kò dáa, ó máa ń yọrí sí nǹkan burúkú àti ìyà.​—Jákọ́bù 1:14, 15.

Ṣé ìyà máa dópin?

Èrò àwọn kan ni pé táwa èèyàn bá ṣera wa lóṣùṣù ọwọ̀, nǹkan á dáa, àwọn míì sì gbà pé kò sí ohun tó lè mú kí ayé yìí dára sí i, kàkà bẹ́ẹ̀ ńṣe ní yóò máa burú sí i. Kí lèrò rẹ?

Ohun tí Bíbélì sọ

Ọlọ́run máa mú ìyà kúrò. “Ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́.”​—Ìṣípayá 21:3, 4.

Kí làwọn nǹkan míì tí Bíbélì sọ?

  • Ọlọ́run máa lo Jésù láti fòpin sí ìyà tí Èṣù ti fà.​—1 Jòhánù 3:8.

  • Àwọn èèyàn rere á máa gbé ní àlááfíà lórí ilẹ̀ ayé títí láé.​—Sáàmù 37:9-11, 29.

Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa ìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba ìyà tó ń jẹ wá, ka orí 11 nínú ìwé yìí,Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?, Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é

Ó tún wà lórí ìkànnì www.jw.org/yo

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́