ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • wp17 No. 3 ojú ìwé 16
  • Ohun Tí Bíbélì Sọ

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2017
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ǹjẹ́ àkókò kan ń bọ̀ tí gbogbo èèyàn á máa ṣe ìdájọ́ òdodo?
  • Ṣé Ọlọ́run ka àwọn èèyàn kan sí pàtàkì ju àwọn míì lọ?
  • Jèhófà—Orísun Òdodo àti Ìdájọ́ Òdodo
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • “Ó Ń Ṣe Ìdájọ́ Òdodo Ní Gbogbo Ọ̀nà Rẹ̀”
    Sún Mọ́ Jèhófà
  • Ṣé Ìdájọ́ Òdodo Máa Wà?
    Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
  • Fara Wé Jèhófà—Máa Ṣe Òdodo àti Ìdájọ́ Òdodo
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2017
wp17 No. 3 ojú ìwé 16
Àwọn èèyàn láti oríṣiríṣi ẹ̀yà

Ohun Tí Bíbélì Sọ

Ǹjẹ́ àkókò kan ń bọ̀ tí gbogbo èèyàn á máa ṣe ìdájọ́ òdodo?

Kí ni ìdáhùn rẹ?

  • Bẹ́ẹ̀ ni

  • Bẹ́ẹ̀ kọ́

  • Kò dá mi lójú

Ohun tí Bíbélì sọ

“Èmi mọ̀ dunjú pé Jèhófà yóò ṣe ẹ̀tọ́ lábẹ́ òfin fún ẹni tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́, èyíinì ni ìdájọ́ àwọn òtòṣì.” (Sáàmù 140:12) Ìjọba Ọlọ́run máa jẹ́ kí ìdájọ́ òdodo wà láyé.

Kí làwọn nǹkan míì tí Bíbélì sọ?

  • Ọlọ́run ń rí bí ìdájọ́ òdodo ò ṣe sí láyé mọ́, ó sì máa ṣe àtúnṣe sí i.​—Oníwàásù 5:8.

  • Tí Ọlọ́run bá mú ìdájọ́ òdodo wá, àlàáfíà àti ààbò máa wà láyé.​—Aísáyà 32:16-18.

Ṣé Ọlọ́run ka àwọn èèyàn kan sí pàtàkì ju àwọn míì lọ?

Èrò àwọn kan ni pé Ọlọ́run bù kún àwùjọ àwọn èèyàn pàtó kan, ó sì ti gégùn-ún fún àwọn kan. Àwọn míì sì gbà pé bákan náà ni gbogbo èèyàn ṣe rí lójú Ọlọ́run. Kí lèrò rẹ?

Ohun tí Bíbélì sọ

“Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú, ṣùgbọ́n ní gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹni tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀, tí ó sì ń ṣiṣẹ́ òdodo ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún un.” (Ìṣe 10:34, 35) Bákàn náà ni gbogbo èèyàn ṣe rí lójú Ọlọ́run.

Kí làwọn nǹkan míì tí Bíbélì sọ?

  • “Gbogbo orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ahọ́n àti ènìyàn” ni “ìhìn rere” tàbí ìròyìn ayọ̀ tó wà nínú Bíbélì wà fún.​—Ìṣípayá 14:6.

Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa ìgbà tí ìdájọ́ òdodo máa wà láyé, ka orí 3 nínú ìwé yìí, Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?, Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é

Ó tún wà lórí ìkànnì www.jw.org/yo

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́