ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w17 January ojú ìwé 32
  • Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ǹjẹ́ O Mọ̀?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2017
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Aṣebi-ṣoore Ni Iná Jẹ́
    Jí!—2002
  • Ẹ̀rí Tó Ta Yọ Jù Lọ Pé Ọlọ́run Nífẹ̀ẹ́ Wa
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Ọlọ́run Dán Ìgbàgbọ́ Ábúráhámù Wò
    Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
  • Ọlọ́run Dán Ìgbàgbọ́ Ábúráhámù Wò
    Ìwé Ìtàn Bíbélì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2017
w17 January ojú ìwé 32
Ísákì ru igi, Ábúráhámù sì gbé ìkòkò tí ẹ̀ṣẹ́ iná wà nínú rẹ̀ dání

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Báwo ni wọ́n ṣe ń mú iná láti ibì kan dé ibòmíì láyé àtijọ́?

ÌWÉ Jẹ́nẹ́sísì 22:6 jẹ́ ká mọ̀ pé nígbà tí Ábúráhámù fẹ́ lọ rúbọ níbì kan tó jìnnà gan-an sílé, ó ‘mú igi ọrẹ ẹbọ sísun, ó gbé e sórí Ísákì ọmọkùnrin rẹ̀, ó sì mú iná àti ọ̀bẹ ìpẹran lọ́wọ́, àwọn méjèèjì sì jùmọ̀ lọ.’

Ìwé Mímọ́ ò sọ bí wọ́n ṣe máa ń fọn iná láyé àtijọ́. Nígbà tí ẹnì kan tó ń ṣàlàyé Bíbélì ń sọ̀rọ̀ nípa ìtàn yìí, ó sọ pé kò dájú pé Ábúráhámù àti Ísákì á lè mú iná dání lọ sí ìrìn-àjò tó jìnnà tó bẹ́ẹ̀. Torí náà, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àwọn ohun èlò tí wọ́n fẹ́ fi dá iná ni ibẹ̀ yẹn ń sọ.

Àwọn míì sì sọ pé kò rọrùn láti dá iná láyé àtijọ́. Àmọ́ ohun kan ni pé á rọrùn fáwọn èèyàn láti fọn ẹ̀ṣẹ́ iná látọ̀dọ̀ àwọn aládùúgbò wọn dípò kí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ dáná yẹn fúnra wọn. Àwọn ọ̀mọ̀wé kan sì gbà pé ṣe ni Ábúráhámù kó ẹ̀ṣẹ́ iná sínú ìkòkò kan tó ní ìfàlọ́wọ́, ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ pé inú iná tó wà nínú ààrò mọ́jú ló ti mú ẹ̀ṣẹ́ iná náà. (Aísá. 30:14) Torí náà, ó ṣeé ṣe fún àwọn èèyàn láti gbé ẹ̀ṣẹ́ iná àti igi ìdáná dání tí wọ́n bá ń rìnrìn-àjò, kí wọ́n sì fi dá iná nígbà tí wọ́n bá fẹ́.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́