Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Ìròyìn Yìí
Ọ̀SẸ̀ MAY 29, 2017–JUNE 4, 2017
3 “Ohun Tí O Jẹ́jẹ̀ẹ́, San Án”
Ẹ̀jẹ́ mélòó lo ti jẹ́ fún Jèhófà? Ṣé ẹyọ kan ni, méjì tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ? Ṣé ò ń ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe láti san àwọn ẹ̀jẹ́ náà? Ẹ̀jẹ́ ìyàsímímọ́ rẹ àti ẹ̀jẹ́ ìgbéyàwó rẹ ńkọ́? Àpilẹ̀kọ yìí máa rán wa létí àwọn àpẹẹrẹ rere Jẹ́fútà àti Hánà bá a ṣe ń sapá láti san àwọn ẹ̀jẹ́ wa fún Jèhófà.
Ọ̀SẸ̀ JUNE 5-11, 2017
9 Àwọn Nǹkan Wo Ló Máa Lọ tí Ìjọba Ọlọ́run Bá Dé?
A sábà máa ń ronú nípa àwọn nǹkan tí Jèhófà máa ṣe fún wa nínú Párádísè, àmọ́ nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò àwọn ohun tí Jèhófà máa mú kúrò. Kí làwọn ohun tó máa mú kúrò kí ayé yìí lè dùn ún gbé, ká sì lálàáfíà? Ìdáhùn sáwọn ìbéèrè yìí máa fún ìgbàgbọ́ wa lókun, á sì mú ká túbọ̀ máa fara dà á nìṣó.
14 Ìtàn Ìgbésí Ayé Mo Pinnu Pé Ọmọ Ogun Kristi Ni Màá Jẹ́
Ọ̀SẸ̀ JUNE 12-18, 2017
18 ‘Onídàájọ́ Ilẹ̀ Ayé’ Máa Ń Ṣe Ohun Tó Tọ́ Nígbà Gbogbo
Ọ̀SẸ̀ JUNE 19-25, 2017
23 Ṣé Èrò Tí Jèhófà Ní Nípa Ìdájọ́ Òdodo Ni Ìwọ Náà Ní?
Tó bá ń ṣe wá bíi pé wọ́n hùwà àìdáa sí wa, ohun tá a bá ṣe máa fi hàn bóyá a nígbàgbọ́, a lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, a sì tún jẹ́ adúróṣinṣin. Nínú àwọn àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò àpẹẹrẹ mẹ́ta nínú Bíbélì táá jẹ́ káwa náà ní èrò tí Jèhófà ní nípa ìdájọ́ òdodo.
Ọ̀SẸ̀ JUNE 26, 2017–JULY 2, 2017
28 Yọ̀ǹda Ara Rẹ Tinútinú, Kí Ìyìn Lè Jẹ́ ti Jèhófà!
Jèhófà ò ṣaláìní ohunkóhun, síbẹ̀ inú rẹ̀ máa ń dùn láti rí bá a ṣe ń sapá láti kọ́wọ́ ti ìṣàkóso rẹ̀. Àwọn Onídàájọ́ orí 4 àti 5 jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà máa ń mọyì rẹ̀ tá a bá fínnú-fíndọ̀ yọ̀ǹda ara wa fún iṣẹ́ rẹ̀.