Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́
April 2017
ÀWỌN ÀPILẸ̀KỌ TÁ A MÁA KẸ́KỌ̀Ọ́ NÍ: MAY 29–JULY 2, 2017
© 2016 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
ÀWÒRÁN IWÁJÚ ÌWÉ:
SÁŃBÍÀ
Àwùjọ àwọn ará wa kan rèé nílùú Lusaka lórílẹ̀-èdè Sáńbíà, inú wọn ń dùn bí wọ́n ṣe ń lọ sóde ẹ̀rí. Bí Gbọ̀ngàn Ìjọba wọn àti àyíká rẹ̀ ṣe wà ní mímọ́ ń jẹ́rìí nípa Jèhófà fún ọ̀pọ̀ èèyàn
IYE AKÉDE
183,586
IYE ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ BÍBÉLÌ
415,706
ÀWỌN TÓ WÁ SÍBI ÌRÁNTÍ IKÚ KRISTI (2016)
782,527
Ìtẹ̀jáde yìí kì í ṣe títà. Ó jẹ́ ara iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kárí ayé tá à ń fi ọrẹ àtinúwá tì lẹ́yìn.
Tó o bá fẹ́ ṣètọrẹ, jọ̀wọ́ lọ sí ìkànnì wa www.jw.org/yo.
Bá ò bá fi hàn pé ó yàtọ̀, inú Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun, la ti mú gbogbo ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a lò.