Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Ìròyìn Yìí
Ọ̀SẸ̀ JULY 3-9, 2017
3 Bá A Ṣe Lè Ran Àwọn Àjèjì Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Máa ‘Fayọ̀ Sin Jèhófà’
Ọ̀SẸ̀ JULY 10-16, 2017
8 Bá A Ṣe Lè Ṣèrànwọ́ Fáwọn Ọmọ Tí Òbí Wọn Jẹ́ Àjèjì
Àpilẹ̀kọ àkọ́kọ́ sọ̀rọ̀ nípa ìṣòro táwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tó ń wá ibi ìsádi máa ń ní, ó sì sọ àwọn nǹkan tá a lè ṣe láti ràn wọ́n lọ́wọ́. Àpilẹ̀kọ kejì sọ báwọn òbí tó ń wá ibi ìsádi ṣe lè fàwọn ìlànà Bíbélì sílò kí wọ́n sì ṣèpinnu tó máa ṣe àwọn ọmọ wọn láǹfààní.
13 Ìtàn Ìgbésí Ayé—Bí Mo Tiẹ̀ Jẹ́ Adití, Mò Ń Kọ́ Àwọn Míì Lẹ́kọ̀ọ́
Ọ̀SẸ̀ JULY 17-23, 2017
17 Ẹ Má Ṣe Jẹ́ Kí Ìfẹ́ Yín Di Tútù
Ọ̀SẸ̀ JULY 24-30, 2017
22 “Ìwọ Ha Nífẹ̀ẹ́ Mi Ju Ìwọ̀nyí Lọ Bí?”
Nǹkan ò rọrùn fáwa ìránṣẹ́ Jèhófà nínú ayé yìí. Àwọn àpilẹ̀kọ yìí sọ ohun tá a lè ṣe tí ìwà ìmọtara-ẹni-nìkan tó kúnnú ayé kò fi ní ràn wá, tí ìfẹ́ tá a sì ní fún Jèhófà, ẹ̀kọ́ òtítọ́ àtàwọn ará wa kò fi ní di tútù. Àwọn àpilẹ̀kọ náà tún sọ bá a ṣe lè mú kí ìfẹ́ Kristi jinlẹ̀ lọ́kàn wa dípò tá a fi máa jẹ́ káwọn nǹkan tó kúnnú ayé gbà wá lọ́kàn.
27 Bí Gáyọ́sì Ṣe Ran Àwọn Ará Lọ́wọ́
30 Ayọ̀ Tó Wà Nínú Kéèyàn Jẹ́ Kí Ohun Ìní Díẹ̀ Tẹ́ Òun Lọ́rùn