ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w17 November ojú ìwé 18-19
  • A Ó Bù Kún Ẹni Tí Ó Jẹ́ Ọ̀làwọ́

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • A Ó Bù Kún Ẹni Tí Ó Jẹ́ Ọ̀làwọ́
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2017
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • “Iṣẹ́ Náà Pọ̀”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2016
  • Mọrírì Ìwà Ọ̀làwọ́ Jèhófà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
  • Àṣẹ́kùsílẹ̀ Wọn Dí Àìnító Kan
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
  • Jèhófà Máa Ń Bù Kún Àwọn Tó Ní Ẹ̀mí Ìmúratán
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2017
w17 November ojú ìwé 18-19
Hánà mú Sámúẹlì wá sí àgọ́ ìjọsìn

A Ó Bù Kún Ẹni Tí Ó Jẹ́ Ọ̀làwọ́

ỌJỌ́ pẹ́ táwọn olùjọsìn tòótọ́ ti máa ń rúbọ. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń fi ẹran rúbọ, ìgbà gbogbo làwọn Kristẹni náà sì máa ń rú “ẹbọ ìyìn.” Bó ti wù kó rí, àwọn ẹbọ míì wà tá a lè rú táá múnú Ọlọ́run dùn. (Héb. 13:​15, 16) Nínú àwọn àpẹẹrẹ tá a fẹ́ gbé yẹ̀ wò báyìí, a máa rí i pé tá a bá ń rú àwọn ẹbọ yìí sí Jèhófà, àá láyọ̀, á sì bù kún wa.

Àpẹẹrẹ kan ni ti Hánà, tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà láyé àtijọ́. Ó wù ú gan-an pé kóun bímọ, àmọ́ kò rọ́mọ bí. Ó yíjú sí Jèhófà, ó sì ṣèlérí pé tí Jèhófà bá fún òun lọ́mọkùnrin, òun á “fi í fún Jèhófà ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀.” (1 Sám. 1:​10, 11) Nígbà tó yá Hánà lóyún, ó bí ọmọkùnrin kan, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Sámúẹ́lì. Lẹ́yìn tí Hánà já Sámúẹ́lì lẹ́nu ọmú, ó mú un lọ sí àgọ́ ìjọsìn bó ṣe jẹ́jẹ̀ẹ́ pé òun máa ṣe. Jèhófà bù kún Hánà torí pé ẹ̀mí rere tó ní ló mú kó yọ̀ǹda ọmọ rẹ̀. Jèhófà mú kó bí ọmọ márùn-ún míì, Sámúẹ́lì di wòlíì Ọlọ́run, ó sì tún wà lára àwọn tó kọ Bíbélì.​—1 Sám. 2:21.

Bíi ti Hánà àti Sámúẹ́lì, àwa Kristẹni náà ti ya ara wa sí mímọ́ fún Jèhófà Ẹlẹ́dàá wa, a sì ń fayé wa sìn ín. Bákan náà, Jésù ṣèlérí pé kò sóhun tá a yááfì torí ìjọsìn Jèhófà tó máa gbé torí pé Jèhófà máa bù kún wa gan-an.​—Máàkù 10:​28-30.

Ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, obìnrin kan wà nínú ìjọ tó ń jẹ́ Dọ́káàsì. Bíbélì sọ pé ó pọ̀ gidigidi nínú “àwọn iṣẹ́ rere àti àwọn ẹ̀bùn àánú,” ìyẹn ni pé ó jẹ́ ọ̀làwọ́. Àmọ́ nígbà tó yá, “ó dùbúlẹ̀ àìsàn, ó sì kú,” ìyẹn ba àwọn ará nínú jẹ́ gan-an. Nígbà tí wọ́n gbọ́ pé Pétérù wà lágbègbè wọn, wọ́n bẹ̀ ẹ́ pé kó tètè wá sọ́dọ̀ àwọn. Ẹ wo bí inú wọn ṣe máa dùn tó nígbà tí Pétérù dé tó sì jí Dọ́káàsì dìde! Èyí ni ìgbà àkọ́kọ́ tí ọ̀kan lára àwọn àpọ́sítélì Jésù máa jí òkú dìde. (Ìṣe 9:​36-41) Ọlọ́run ò gbàgbé àwọn iṣẹ́ rere tí Dọ́káàsì ṣe. (Héb. 6:10) Yàtọ̀ síyẹn, ìwà ọ̀làwọ́ rẹ̀ tún wà lákọọ́lẹ̀ nínú Bíbélì káwa náà lè fara wé e.

Tó bá dọ̀rọ̀ kéèyàn jẹ́ ọ̀làwọ́, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ torí pé ó lo àkókò rẹ̀ àti okun rẹ̀ fáwọn míì. Nínú lẹ́tà tó kọ sáwọn ará ní Kọ́ríńtì, ó sọ pé: “Ní tèmi, ṣe ni èmi yóò máa fi ìyọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀ gan-an náwó, a ó sì ná mi tán pátápátá fún ọkàn yín.” (2 Kọ́r. 12:15) Pọ́ọ̀lù kẹ́kọ̀ọ́ láti inú ìrírí ara rẹ̀ pé èèyàn á láyọ̀ téèyàn bá fi ara rẹ̀ jìn fún àwọn míì, ní pàtàkì jù lọ, èèyàn á rí ìbùkún àti ìtẹ́wọ́gbà Jèhófà.​—Ìṣe 20:​24, 35.

Kò sí àní-àní pé inú Jèhófà ń dùn bá a ṣe ń lo àkókò àti okun wa lẹ́nu iṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run, tá a sì tún ń ran àwọn ará wa lọ́wọ́. Àmọ́, ǹjẹ́ àwọn ọ̀nà míì wà tá a lè gbà ti iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run lẹ́yìn? Bẹ́ẹ̀ ni! Láfikún sí iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe, a tún lè fi ọrẹ àtinúwá bọlá fún Ọlọ́run. Ọrẹ yìí la fi ń bójú tó iṣẹ́ ìwàásù kárí ayé, òun náà la sì fi ń bójú tó àwọn míṣọ́nnárì àtàwọn míì tó wà lẹ́nu àkànṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún. Yàtọ̀ síyẹn, ọrẹ àtinúwá yìí náà là ń lò bá a ṣe ń ṣe ìwé àtàwọn fídíò, tá à ń túmọ̀ wọn sáwọn èdè míì, tá à ń ṣèrànwọ́ fáwọn tí àjálù bá, tá a sì ń kọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba tuntun. Ó dá wa lójú pé “a óò mú ọkàn tí ó lawọ́ sanra.” Ju gbogbo ẹ̀ lọ, tá a bá ń fún Jèhófà láwọn ohun ìní wa tó níye lórí, ṣe là ń bọlá fún un.​—Òwe 3:9; 11:25.

Ọ̀nà Táwọn Kan ń gbà Ṣètọrẹ Fún Iṣẹ́ Kárí Ayé

Bíi tàwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, ọ̀pọ̀ Kristẹni lónìí máa ń “ya ohun kan sọ́tọ̀,” tàbí kí wọ́n ya iye owó kan sọ́tọ̀, kí wọ́n sì fi owó náà sínú àpótí ìjọ tá a kọ “Ọrẹ fún Iṣẹ́ Kárí Ayé” sí. (1 Kọ́r. 16:2) Oṣooṣù làwọn ìjọ máa ń fi owó yìí ránṣẹ́ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì tó ń bójú tó iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè wọn. O sì tún lè fi ọrẹ ránṣẹ́ ní tààràtà sí ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ń bójú tó orílẹ̀-èdè tó ò ń gbé. Tó o bá fẹ́ mọ orúkọ àjọ tó ń bójú tó iṣẹ́ wa lábẹ́ òfin, jọ̀wọ́ kàn sí ẹ̀ka ọ́fíìsì tó ń bójú tó iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè tó ò ń gbé. Wàá rí àdírẹ́sì ẹ̀ka ọ́fíìsì náà lórí ìkànnì www.jw.org/yo. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé òfin tó rọ̀ mọ́ ọrẹ ṣíṣe ní ilẹ̀ kan yàtọ̀ sí òmíì, lára àwọn ọrẹ tó o lè fi ránṣẹ́ sí wa ní tààràtà rèé:

Ẹ̀BÙN

  • O lè fi ọrẹ ránṣẹ́ látinú àkáǹtì rẹ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì tàbí kó o lo káàdì tí owó wà lórí rẹ̀ tàbí káàdì tí wọ́n fi ń rajà láwìn láti fi ọrẹ ránṣẹ́, o sì lè fi owó ránṣẹ́ látorí fóònù rẹ. Ní àwọn orílẹ̀-èdè kan, o lè fi ọrẹ ránṣẹ́ látorí ìkànnì jw.org tàbí ìkànnì míì tí ẹ̀ka ọ́fíìsì bá fọwọ́ sí.

  • O lè fi owó, ohun ọ̀ṣọ́ tó ṣeyebíye tàbí dúkìá mìíràn ṣètọrẹ. Kọ lẹ́tà kó o sì fi ránṣẹ́ pẹ̀lú owó tàbí ọrẹ náà láti fi hàn pé ẹ̀bùn ni.

ỌRẸ TÓ ṢEÉ GBÀ PA DÀ

  • O lè fi owó síkàáwọ́ àjọ kan tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń lò pé kí wọ́n máa lò ó. Àmọ́, àjọ náà máa dá owó náà pa dà tó o bá béèrè fún un.

  • Kọ lẹ́tà láti fi hàn pé ńṣe lo fi owó náà síkàáwọ́ àjọ náà títí dìgbà tí wàá fẹ́ gbà á pa dà.

ỌRẸ TÉÈYÀN WÉWÈÉ

Yàtọ̀ sí pé ká dìídì fi owó tàbí dúkìá mìíràn ṣètọrẹ, àwọn ọ̀nà míì tún wà tá a lè gbà ṣètọrẹ tó máa ṣàǹfààní fún iṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run kárí ayé. Ọ̀nà yòówù kó o fẹ́ gbà ṣètọrẹ, jọ̀wọ́ kọ́kọ́ kàn sí ẹ̀ka ọ́fíìsì tó ń bójú tó iṣẹ́ wa lórílẹ̀-èdè rẹ, kí wọ́n lè jẹ́ kó o mọ ọ̀nà tó bófin mu tó o lè gbà ṣe é. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ohun tí òfin sọ nípa ọrẹ máa ń yàtọ̀ síra, ó ṣe pàtàkì pé kó o fi ọ̀rọ̀ lọ amòfin tó mọ̀ nípa rẹ̀ dáadáa kó o tó yan ọ̀nà tó o máa gbà ṣètọrẹ. Díẹ̀ lára àwọn ọ̀nà tó o lè gbà ṣètọrẹ rèé.

Owó Ìbánigbófò àti Owó Ìfẹ̀yìntì: O lè kọ orúkọ àjọ kan tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń lò gẹ́gẹ́ bí ẹni tí yóò gba owó ìbánigbófò ẹ̀mí tàbí owó ìfẹ̀yìntì rẹ lẹ́nu iṣẹ́ àti irú owó míì bẹ́ẹ̀.

Àkáǹtì Owó ní Báǹkì: A lè ṣètò pé lẹ́yìn ikú ẹni, kí àjọ kan tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń lò gba owó tá a fi pamọ́ sí báǹkì ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí ìlànà báǹkì sọ.

Ìpín Ìdókòwò, Ẹ̀tọ́ Orí Owó Ìdókòwò àti Ti Ètò Ẹ̀yáwó: A lè fi ẹ̀tọ́ ìpín ìdókòwò, ẹ̀tọ́ orí owó ìdókòwò àti ti ẹ̀yáwó ta àjọ kan tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń lò lọ́rẹ. A sì lè tọwọ́ bọ ìwé àdéhùn, pé kí ẹ̀tọ́ náà di ti àjọ náà lẹ́yìn ikú ẹni.

Ilẹ̀ àti Ilé: A lè fi ilẹ̀ tó ṣeé tà tọrẹ fún àjọ kan tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń lò, yálà nípa fífi ṣe ẹ̀bùn, tàbí tó bá jẹ́ ilẹ̀ tí ilé wà lórí rẹ̀ téèyàn ṣì ń gbé inú rẹ̀, olùtọrẹ náà lè fi tọrẹ àmọ́ kó sọ pé òun á ṣì máa gbé inú rẹ̀ ní gbogbo ìgbà tóun bá ṣì wà láàyè.

Ìwé Ìhágún àti Ohun Ìní Téèyàn Fi Síkàáwọ́ Onígbọ̀wọ́: A lè fi dúkìá tàbí owó sílẹ̀ bí ogún fún àjọ kan tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń lò nípasẹ̀ ìwé ìhágún tá a ṣe lábẹ́ òfin, tàbí ká ṣe ìwé pé àjọ náà ni ẹni tí yóò ni ohun ìní tá a fi síkàáwọ́ onígbọ̀wọ́. Ètò yìí lè mú kí iye owó orí tí ìjọba máa gbà lọ́wọ́ ẹni tó ṣètọrẹ náà dín kù.

Gbólóhùn náà, “ọrẹ téèyàn wéwèé” fi hàn pé ẹni tó fẹ́ ṣètọrẹ gbọ́dọ̀ ronú dáadáa kó tó ṣe irú ìtọrẹ bẹ́ẹ̀. Láti ṣèrànwọ́ fáwọn èèyàn tó fẹ́ ṣètìlẹyìn fún iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé nípasẹ̀ oríṣiríṣi ọrẹ tá a wéwèé, a ti ṣe ìwé pẹlẹbẹ kan lédè Gẹ̀ẹ́sì àti èdè Spanish, orúkọ rẹ̀ ni Charitable Planning to Benefit Kingdom Service Worldwide. A fi ìwé yìí ṣàlàyé oríṣiríṣi ọ̀nà tẹ́nì kan lè gbà ṣètọrẹ bóyá nísinsìnyí tàbí gẹ́gẹ́ bí ogún lẹ́yìn tí onítọ̀hùn bá kú. Àwọn ìsọfúnni kan lè wà nínú ìwé yẹn tí kò fi bẹ́ẹ̀ bá ipò rẹ mu torí pé òfin àti ìlànà tó jẹ mọ́ owó orí àtàwọn nǹkan míì lórílẹ̀-èdè tó o wà lè yàtọ̀ sáwọn ìlànà tá a kọ sínú ìwé náà. Ọ̀pọ̀ ti lo onírúurú ọ̀nà téèyàn lè gbà wéwèé tó wà nínú ìwé yẹn láti ṣètìlẹ́yìn fún ìjọsìn wa títí kan àwọn ìrànwọ́ tá à ń ṣe kárí ayé, ìyẹn sì ti mú kí ìjọba dín owó orí tí wọ́n máa san kù. Tí ìwé náà bá wà lórílẹ̀-èdè tó o wà, o lè gba ẹ̀dà kan lọ́wọ́ akọ̀wé ìjọ yín.

Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa ọ̀rọ̀ yìí, lọ sí ìlujá náà “Ṣe Ọrẹ Láti Ti Iṣẹ́ Tá À Ń Ṣe Kárí Ayé Lẹ́yìn” tó wà lọ́wọ́ ìsàlẹ̀ ojúde ìkànnì wa, ìyẹn jw.org/yo tàbí kó o kàn sí ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ń bójú tó orílẹ̀-èdè tó ò ń gbé.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́