3 Ó Ń Jẹ́ Ká Fara Da Ìṣòro
Àwọn ìṣòro kan wà tá ò lè yẹra fún, kò sì sí ohun tá a lè ṣe láti yanjú wọn báyìí. Bí àpẹẹrẹ, tí ẹni tó o nífẹ̀ẹ́ gan-an bá kú tàbí tó o bá ń ṣàìsàn tó le gan-an, o lè má rí ohunkóhun ṣe sí i ju pé kó o wá bí wàá ṣe máa fara dà á lọ. Ṣé Bíbélì lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ nírú àkókò tó le yìí?
ÀÌSÀN TÓ LE GAN-AN
Obìnrin kan tó ń jẹ́ Rose sọ pé: “Mo ní àrùn inú ẹ̀jẹ̀ tó ń jẹ́ kí ara máa ro mí gan-an ní gbogbo ìgbà. Ọ̀rọ̀ ayé mi sú mi pátápátá.” Ohun tó ká a lára jù ni pé nígbà míì, ìṣòro yìí kì í jẹ́ kó lè gbádùn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àti àwọn nǹkan míì tó jẹ mọ́ ìjọsìn tó ń ṣe. Àmọ́ ọ̀rọ̀ Jésù tó wà ní Mátíù 19:26 ràn án lọ́wọ́ gan-an, Jésù sọ pé: “Lọ́dọ̀ Ọlọ́run ohun gbogbo ṣeé ṣe.” Rose wá rí i pé ọ̀nà míì tún wà tí òun lè máa gbà kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Torí pé ara tó máa ń ro ó kì í jẹ́ kó rọrùn fún un rárá láti ka Bíbélì nígbà míì, ó wá bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ́tí sí Bíbélì àtàwọn ìtẹ̀jáde míì tá a gba ohùn wọn sílẹ̀.a Ó sọ pé: “Mi ò bá má ní àjọṣe tó dán mọ́rán pẹ̀lú Ọlọ́run ká ní mi ò ṣe ohun tí mo ṣe yẹn láti máa kẹ́kọ̀ọ́.”
Nígbà tí ìbànújẹ́ dorí Rose kodò torí pé kò lè ṣe àwọn nǹkan tó máa ń ṣe tẹ́lẹ̀, ọ̀rọ̀ tó wà ní 2 Kọ́ríńtì 8:12 tù ú nínú, ẹsẹ Bíbélì náà sọ pé: “Bí ìmúratán bá kọ́kọ́ wà, ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà ní pàtàkì ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí ènìyàn ní, kì í ṣe ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí ènìyàn kò ní.” Ọ̀rọ̀ ìtùnú yìí jẹ́ kí Rose rántí pé inú Ọlọ́run ń dùn sí ìsapá rẹ̀ torí pé gbogbo ohun tí agbára rẹ̀ gbé ló ń ṣe.
Ẹ̀DÙN ỌKÀN
Delphine tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú èyí sọ pé: “Lẹ́yìn tí ọmọ mi obìnrin tó jẹ́ ọmọ ọdún méjìdínlógún [18] kú, ìbànújẹ́ mi pọ̀ débi pé mi ò mọ̀ pé màá ṣì wà láàyè títí di báyìí. Nǹkan ò lè dà bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́.” Àmọ́, ọ̀rọ̀ tó wà ní Sáàmù 94:19 tù ú nínú gan-an, ẹni tó kọ sáàmù yẹn sọ fún Ọlọ́run pé: “Nígbà tí ìrònú tí ń gbé mi lọ́kàn sókè di púpọ̀ nínú mi, ìtùnú tìrẹ ni ó bẹ̀rẹ̀ sí ṣìkẹ́ ọkàn mi.” Delphine wá sọ pé: “Mo gbàdúrà sí Jèhófà pé kó jẹ́ kí n rí ohun tí mo lè ṣe táá jẹ́ kí ara tù mí.”
Ni Delphine bá jẹ́ kí ọwọ́ rẹ̀ dí lẹ́nu iṣẹ́ ìyọ̀ǹda ara ẹni. Nígbà tó yá, ó fi ara rẹ̀ wé pẹ́ńsù tó kán, àmọ́ tó ṣì wúlò téèyàn bá tún un gbẹ́. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀dùn ọkàn tó ní jẹ́ kó dà bí ẹni pé ó kán, síbẹ̀ ó gbà pé òun ṣì lè ran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́. Delphine sọ pé: “Bí mo ṣe ń fi àwọn ìlànà Bíbélì kọ́ àwọn èèyàn, tí mo sì ń jẹ́ kí wọ́n mọ bí wọ́n ṣe lè ronú lórí ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ kó lè tù wọ́n nínú, mo wá rí i pé ńṣe ni Jèhófà ń fi ìyẹn tu èmi náà nínú, tó sì ń mú ẹ̀dùn ọkàn mi fúyẹ́.” Delphine kọ orúkọ àwọn tí Bíbélì sọ pé wọ́n ní ẹ̀dùn ọkàn tó le gan-an bíi tiẹ̀ sínú ìwé kan. Ó wá sọ pé òun kíyè sí i pé “gbogbo wọn pátá ni kò fi àdúrà ṣeré.” Ó tún sọ pé òun ti rí i pé “téèyàn bá ń ka Bíbélì léèyàn tó lè rí ohun tó máa ràn án lọ́wọ́ láti fara da ẹ̀dùn ọkàn.”
Ohun míì tó wá yé Delphine bó ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ni pé ó yẹ kí òun máa ronú nípa ọjọ́ iwájú, kì í ṣe ohun tó ti ṣẹlẹ̀ kọjá. Ọ̀rọ̀ tó ń fúnni ní ìrètí tó wà nínú Ìṣe 24:15 tù ú nínú, ẹsẹ náà kà pé: “Àjíǹde àwọn olódodo àti àwọn aláìṣòdodo yóò wà.” Báwo ló ṣe dá Delphine lójú tó pé Jèhófà máa jí ọmọbìnrin rẹ̀ dìde? Òun fúnra rẹ̀ sọ pé: “Mò ń fojú inú wo bí ọmọbìnrin mi ṣe máa jíǹde lọ́jọ́ iwájú. Ó dá mi lójú pé Jèhófà ti mú ọjọ́ tá a tún máa ríra. Rekete ni mò ń rí èmi àti ẹ̀ nínú ọgbà wa, tí mo sì ń kẹ́ ẹ bí mo ṣe kẹ́ ẹ lọ́jọ́ tí mo bí i.”
a Ọ̀pọ̀ àwọn ìtẹ̀jáde tá a gba ohùn wọn sílẹ̀ yìí ló wà lórí ìkànnì jw.org/yo.
Bíbélì lè tù ẹ́ nínú kódà ní àwọn ìgbà tí wàhálà bá bá ẹ